ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/22 ojú ìwé 24-25
  • Kàkàkí Didgeridoo àti Àwọn Ìró Rẹ̀ Fífani-Lọ́kànmọ́ra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kàkàkí Didgeridoo àti Àwọn Ìró Rẹ̀ Fífani-Lọ́kànmọ́ra
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìró Aláìlẹ́gbẹ́ Kan
  • Ṣíṣe Kàkàkí Didgeridoo
  • Ìdí Tí Orin Fi Ń Lágbára Lórí Wa
    Jí!—1999
  • Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Ki Àṣejù Bọ Orin Gbígbọ́?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Ṣé Mo Lè Yan Orin Tó Bá Ṣáà Ti Wù Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Jí!—1997
g97 4/22 ojú ìwé 24-25

Kàkàkí Didgeridoo àti Àwọn Ìró Rẹ̀ Fífani-Lọ́kànmọ́ra

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

Ẹ BÁ wa kálọ síbi ijó òru àwọn Ọmọ Onílẹ̀ kan ní Àgbègbè Àríwá Australia, tí ó jẹ́ ìrìn wákàtí mélòó kan láti Darwin, olú ìlú rẹ̀, bí a bá wọkọ̀. Kàkà kí a máa ṣe é bí ohun àṣeṣáájú-ogun ti ẹ̀yà ìran, ọ̀pọ̀ ijó òru òde òní ni a pilẹ̀ ń ṣe fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́. Irú èyí la fẹ́ lọ.

Àwọn òṣèré náà, tí wọ́n kun ara wọn láwọ̀ títàn, dúró jẹ́ẹ́ bí wọ́n ṣe ń dúró kí orin náà fún wọn ní àmì pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ijó. Lójijì ni orin bẹ̀rẹ̀, tí ìró ìlùkìkì, tí ó lágbára kan, sì ń bú wá láti inú ìparọ́rọ́ tí ó wà nínú òkùnkùn àgbègbè àrọko àdádó náà. A ṣàfikún ìró náà pẹ̀lú àwọn igi tí a fi ń lura wọn—àwọn igi kéékèèké méjì tí a fi ń lura wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìró ohùn orin tí a ń fi kàkàkí didgeridoo kọ.

Bóyá iye ènìyàn kéréje tí kò gbé Australia ló ti gbọ́ nípa kàkàkí didgeridoo, ohun èlò ìkọrin tí ó jẹ́ ti kìkì àwọn Ọmọ Onílẹ̀ Australia yí. A sábà máa ń fi ẹ̀ka igi eucalyptus tí a gbẹ́ inú rẹ̀ ṣe é, gígùn rẹ̀ tí a sì yàn láàyò jẹ́ láti mítà kan sí mítà kan ààbọ̀. Akọrin náà ń jókòó lórí ilẹ̀ ní apá kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbo eré náà gan-an, tí yóò máa fun kàkàkí didgeridoo rẹ̀—ohun èlò kan tí ó jọ pé ó rọrùn, síbẹ̀ tí ń fani lọ́kàn mọ́ra.

Ìró Aláìlẹ́gbẹ́ Kan

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kàkàkí didgeridoo máa ń mú ohùn tí ó jọ pé kì í yí pa dà jáde—lọ́nà bíbáamu, a ṣàpèjúwe rẹ̀ bíi “kàkàkí oníròó ológooro rírinlẹ̀”—ó lè mú ìròkèrodò ohùn lílọ́júpọ̀ àti ìdún onípààrọ̀-ohùn-méjì jáde. Níṣẹ̀ẹ́jú kan, ó ní ohùn ohun èlò olóhùn kan, ṣùgbọ́n níṣẹ̀ẹ́jú tó tẹ̀ lé ìyẹn, ó lè ní agbára àti àfihàn ìmọ̀lára kíkún bí ẹgbẹ́ akọrin olóhun èlò orin kíkún kan.

Kí àwọn ará Europe tó dé Australia ní nǹkan bí 200 ọdún sẹ́yìn, àwọn Ọmọ Onílẹ̀ tí ń kiri ní apá ìhà àríwá kọ́ńtínẹ́ǹtì erékùṣù náà nìkan ló mọ kàkàkí didgeridoo. Níbi àwọn ijó òru, òun ni wọ́n máa ń fi kọrin sí àwọn ijó tí ń ṣàṣefihàn ìtàn ìwáṣẹ̀ àwọn Ọmọ Onílẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá. Nígbà náà, àwọn tí ń fun kàkàkí didgeridoo dáadáa máa ń gbayì gidigidi, lónìí pàápàá, a ṣì ń ka ẹni tí ó bá mọ̀ ọ́n fun dáradára sí mẹ́ńbà tí ó lókìkí láàárín ẹ̀yà náà.

Àwọn ògbóṣáṣá afunkàkàkí didgeridoo máa ń fọgbọ́n ṣàgbéyọ àfiwé ìró ohùn àwọn ẹranko àti ẹyẹ lórí àwọn ìró ìpìlẹ̀ tí ó ní. Lára àwọn àfarawé ìró tí wọ́n ń fọgbọ́n gbé jáde ni ẹ̀rín ẹyẹ kookaburra; híhu ajá igbó Australia, tàbí dingo; ìró jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ti ẹyẹ àdàbà; àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìró mìíràn.

Ìwé atúmọ̀ èdè The New Grove Dictionary of Music and Musicians sọ nípa afunkàkàkí didgeridoo pé: “Lára àwọn ànímọ́ rẹ̀ ni lílo ahọ́n rẹ̀ lọ́nà yíyára, tó sì ṣe gẹ́lẹ́, ṣíṣàkóso èémí lọ́nà gbígbéṣẹ́, pípa ètè pọ̀ pátápátá ní ìparí túùbù náà àti rírántí orin lọ́nà títayọlọ́lá. . . . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ àti àwọn ohun èlò, tí kò sì mọ nǹkan kan nípa ohun èlò àtìbọnu, nǹkan ìkọrin onígi òun esùsú, apá àtìwọnú-tìjáde ohun èlò ìkọrin tàbí ihò àfìkabò lára ohun èlò ìkọrin, [Ọmọ Onílẹ̀] náà ti sọ ohun èlò rírọrùn kan di ohun èlò ìkọrin ọlọ́gbọ́n ọnà títayọ kan nípa lílo ìrònú nípa orin àti òye iṣẹ́ títayọlọ́lá.”

Kò síyè méjì pé apá tí ó gbàfiyèsí jù lọ lára orin kàkàkí didgeridoo ni ohùn gooro tí ó ní. Afunkàkàkí náà ń mú kí a rò pé ẹ̀dọ̀fóró òun ní agbára àìlópin kan, nítorí pé ó lè ṣàìdánudúró nínú ohùn orin náà fún ìṣẹ́jú mẹ́wàá lẹ́ẹ̀kan.

Ṣíṣe Kàkàkí Didgeridoo

Oníṣọ̀nà ìbílẹ̀ kan máa ń lo ojú rẹ̀ tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ láti wá igi líle kan, bóyá igi eucalyptus tí a yàn láàyò, kàn nínú igbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a lè lo igi rírọ̀, igi líle máa ń mú ohùn tí ó túbọ̀ sunwọ̀n jáde. Ó yẹ kí a wá igi náà síbi tí kò jìnnà sí ilé ikán, nítorí pé àwọn ikán ni onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kàkàkí didgeridoo. Àwọn ni wọ́n ń gbẹ́ ihò sínú ẹ̀ka igi tí a ń lò fún ohun èlò orin yìí.

Lẹ́yìn tí a bá ti ṣàṣàyàn ẹ̀ka igi náà, a óò gé e sí ìwọ̀n gígùn tí a bá fẹ́. Ìwọ̀n gígùn tí a yàn náà ní ń pinnu bí ohùn ohun ìkọrin náà yóò ṣe rinlẹ̀ tó. Nígbà náà ni a óò pa èèpo rẹ̀, tí a óò ha apá tí kò lágbára tí ó wà lára rẹ̀ kúrò kí ó má baà sán, a óò sì gbẹ́ inú rẹ̀. Bí àwọn ikán bá ti jẹ inú rẹ̀ dáradára tó, yóò ṣeé ṣe láti yí ẹyọ owó títóbi kan geere gba àárín rẹ̀. Ìgbésẹ̀ tí ó kàn ni ṣíṣeélọ́ṣọ̀ọ́, èyí tí ó lè fani mọ́ra gan-an. Àmọ́ iṣẹ́ ara kàkàkí didgeridoo kò tí ì parí tó kí a máa fun ún.

Awọ àyíká ẹnu afunkàkàkí náà yóò máa yún un láìpẹ́ bí ó ti ń fi ẹnu kínrin igi náà. Nítorí náà, wọ́n máa ń fi àtè oyin síbi ojú ihò kàkàkí didgeridoo, tí ń mú kí ẹnu rẹ̀ máa dán, tí kò sì ní jẹ́ kí awọ ẹnu afunkàkàkí máa yún un. Bí ó ti wù kí ó rí, lóde òní, ọ̀pọ̀ kàkàkí didgeridoo ló jẹ́ pé ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ kan la ti ṣe wọ́n, igi rírọ̀ la sì ń lò. Ṣùgbọ́n àwọn kàkàkí didgeridoo tí a ṣe nílé iṣẹ́ ẹ̀rọ kò sábà máa ń ní ohùn aláìlẹ́gbẹ́ àti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohùn tí àwọn àṣejáde onígi líle ti àdánidá ń ní.

Nítorí náà, bí ijó òru náà ṣe ń parí lọ, tí àṣálẹ́ tí a lò ní ilẹ̀ olóoru náà, lábẹ́ àwọn ìràwọ̀ tí ń tàn lókè sì ń tán lọ, a kò ka kàkàkí didgeridoo sí ìtọpinpin kan lásán mọ́. Ní ti gidi, àwọn ìró ohùn orin kàkàkí didgeridoo tí ń dún ní àìdáwọ́dúró léraléra mú iyì bá àwọn olùfẹ́ orin kíkọ tí ń gbé níhà ìsàlẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

A lè kun kàkàkí didgeridoo láwọ̀ mèremère

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ijó òru ti àwọn Ọmọ Onílẹ̀

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Ojú ìwé 24 àti 25 Àwọn Ọmọ Onílẹ̀: Nípasẹ̀ Ìyọ̀ǹda Onínúure Australian Northern Territory Tourist Commission

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́