Ìdí Tí Orin Fi Ń Lágbára Lórí Wa
NÍNÚ gbogbo ẹ̀dá tí ń bẹ láyé, èèyàn nìkan ló mọ̀ nípa èdè sísọ àti pípa ìlù àtorin pọ̀, kó ṣe rẹ́gí. Ká ní kò sí èdè àtorin láyé ni, ayé ọ̀hún ì bá mà ṣòroó gbé o. Ìwé The Musical Mind sọ pé: “Ó jọ pé àárín ẹ̀dá ènìyàn ni èdè àtorin ti wọ́pọ̀ jù lọ lágbàáyé.” Àwọn nǹkan wọ̀nyí ló ń fi ìjẹ́pàtàkì ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ hàn. Nítorí náà, bíi ti èdè, òótọ́ ni pé nígbà tí orin bá “ń sọ̀rọ̀” ara wa máa “ń gbọ́.”
Báwo ni orin ṣe ń bá ara wa sọ̀rọ̀, èé sì ti ṣe? Láti lè dáhùn, ẹ jẹ́ ká gbé nǹkan wọ̀nyí yẹ̀ wò: (1) ìró ohùn orin àti bí wọ́n ṣe ń bá ọpọlọ wa ṣiṣẹ́; (2) ìmọ̀lára wa àti ohun táa gbọ́njú bá, tó ń darí ìṣarasíhùwà wa sí orin; àti (3) èdè, tó tún lè kan ìṣesí wa.
Ìró Ohùn
Oríṣiríṣi ohùn táa ń gbọ́ nínú orin ni wọ́n ń pè ní “ìró ohùn.” Èyí ní nínú ohùn, tàbí ìró tí ohun èlò kọ̀ọ̀kan ń mú jáde. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé fèrè àwọn Faransé máa ń dún “tínrín-tínrín,” tàbí kí ó han gooro, àti pé ìró rẹ̀ kò rinlẹ̀ tó ti kàkàkí tí ń dún “lákọlákọ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà fèrè ni méjèèjì, dídún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra. Ìyẹn ni wọ́n fi ń sọ pé olúkúlùkù wọn ló ní “ohùn” tirẹ̀. Àwọn tí ń kọ orin máa ń lo ànímọ́ wọ̀nyí láti fi mú ìró kan pàtó jáde láti fi ru ìmọ̀lára olùgbọ́ sókè.
Bóyá ọ̀kan lára àwọn ìró táa kọ́kọ́ gbọ́ ni ìró tí ń lù kìkì—bóyá nígbà táa ṣì wà nínú ilé ọlẹ̀, táa ń gbọ́ ìlùkìkì ọkàn ìyá wa. Àwọn kan sọ pé ìlùkìkì ọkàn wa tàbí mímí wa pàápàá lè lágbára lórí báa ṣe ń dáhùn sí ìró orin. Ó kúkú lè jẹ́ ohun tó fà á nìyí tí èèyàn púpọ̀ jù lọ fi máa ń fẹ́ orin tí ń lù kìkì níwọ̀n àádọ́rin sí ọgọ́rùn-ún láàárín ìṣẹ́jú kan—torí pé ìwọ̀n yẹn ni bí ọkàn géńdé ṣe máa ń lù kìkì. Ìwé ìròyìn Perceptual and Motor Skills ló gbé àbá yìí kalẹ̀.
A lè mọ onírúurú ìró ohùn orin, táa bá fara balẹ̀ fetí sí oríṣiríṣi ohun èlò orin àti ìró wọn. Fàfofàfo tí fèrè bassoon ń dún ní ẹsẹ kejì orin tí Mozart fi fèrè bassoon kọ lè ru ìmọ̀lára sókè gan-an. Ìró olóhùn arò tí fèrè shakuhachi tàwọn ará Japan ń mú jáde lè rọra wọnú ọkàn lọ. Ìró olóhùn gẹ̀dẹ̀gbẹ̀ tí fèrè saxophone ní, máa ń jẹ́ kí orin atunilára tí ń lọ ní mẹ̀lọmẹ̀lọ máa gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn. Gbìgbìgbì tí fèrè tuba àwọn ará Jámánì ń dún, sábà máa ń ru ìmọ̀lára ìgbóná ọkàn sókè. Orin dídùn yùngbà-yungba tí ọ̀gbẹ́ni Strauss fi gìtá violin kọ, ló máa ń jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbọ́ ọ bọ́ ságbo, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ rajó. Irú nǹkan báwọ̀nyí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀, nítorí pé “gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ni orin máa ń bá sọ̀rọ̀,” èyí lọ̀rọ̀ tí Clive E. Robbins sọ, ẹni tó jẹ́ gíwá Iléeṣẹ́ Nordoff-Robbins Tí Ń Fi Orin Ṣèwòsàn, ní New York.
Àwọn Orin Adúnbárajọ, Ohùn Tí Ń Hanni Létí, àti Orin Aládùn
Àwọn orin adúnbárajọ ń mú ìró tó tuni lára jáde, nígbà tó jẹ́ pé háráhárá làwọn ohùn tí ń hanni létí máa ń dún. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohùn méjèèjì ló ní iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú irú àwọn orin kan? Ìlù àtorin tó ń dún bára jọ lè ní ọ̀pọ̀ ohùn tí ń dún háráhárá nínú ju bí o ti lérò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè má mọ̀, bí ohùn tí ń dún bára jọ àti èyí tí ń hanni létí ṣe máa ń ṣiṣẹ́ pọ̀, máa ń jẹ́ kí orin ròkè lálá, kó sì tún wálẹ̀, ìyẹn ló fi máa ń mú wa lórí yá. Ìmóríyá yìí máa ń mára túni, bẹ́ẹ̀, ṣe ni orin tó ń dún háráhárá máa ń hanni létí—bí ìgbà téèyàn bá ń fi èékánná ha igbá. Bẹ́ẹ̀ sì tún rèé, bó bá ṣe pé ohùn tó ń dún bára jọ nìkan lorín ní, kíá ló máa súni.
Orin aládùn [mẹ́lọ́dì] jẹ́ àpapọ̀ àwọn ohùn táa ṣètò ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ògbógi kan ti wí, ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà melody wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà meʹlos, tó túmọ̀ sí “orin.” Àwọn ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ sọ pé “mẹ́lọ́dì” túmọ̀ sí orin aládùn, ìró èyíkéyìí tó bá gbádùn mọ́ni.
Àmọ́, kì í kàn-án ṣe ohùn èyíkéyìí táa bá mú pa pọ̀ ló máa ń di orin aládùn. Fún àpẹẹrẹ, bí àlàfo bá pọ̀ jù léraléra láàárín ìró kan sí èkejì, èyí lè gbàfiyèsí o, ṣùgbọ́n kò ní dùn-ún gbọ́ létí. Bẹ́ẹ̀ rèé, bí àlàfo tó yẹ bá wà láàárín ìró kan sí èkejì, orin náà yóò gbádùn mọ́ni. Onírúurú ọ̀nà ìṣètò ohùn àti àlàfo táa fi sí i, ló lè jẹ́ kí orin kan múni rẹ̀wẹ̀sì tàbí kó múni láyọ̀. Gẹ́gẹ́ bó ti rí nínú ọ̀ràn àwọn ohùn tí ń dún bára jọ, bẹ́ẹ̀ náà ni ti orin aládùn, ìgbà mí-ìn á ròkè lálá, ìgbà mí-ìn á tún wálẹ̀, ìyẹn ló fi máa ń gbà wá lọ́kàn—ó sinmi lórí bí ìró náà ti ròkè tó tàbí bó ṣe lọọlẹ̀ tó.
Nígbà táa bá lo gbogbo ìró wọ̀nyí, ó lè wá lágbára gan-an, débi pé ó lè ru ìmọ̀lára wa sókè tàbí kó mú un rọlẹ̀. Èyí jẹ́ nítorí onírúurú ọ̀nà tí ọpọlọ fi ń túmọ̀ orin.
Iṣẹ́ Tí Orin Ń Ṣe Nínú Ọpọlọ
Àwọn kan sọ pé apá òsì ọpọlọ ló ń bójú tó èdè àti agbára ìrònú, nígbà tó ṣe pé apá ọ̀tún ọpọlọ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀lára ló ń bójú tó orin. Bí bẹ́ẹ̀ ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó ṣe kedere pé orin máa ń ta àwọn tí ń gbọ́ ọ jí. Ohun tí ìwé ìròyìn Perceptual and Motor Skills mú kí a lóye nípa orin ni pé: “Orin lágbára láti ru ìmọ̀lára sókè ní kíákíá, lọ́nà tó gbéṣẹ́. Ohun tó máa gba ọ̀pọ̀ gbólóhùn nínú ìwé kó tó lè ru ìmọ̀lára sókè . . . , tó bá jẹ́ pé nínú orin ni, tìn-rinrín kan lásán ti tó.”
Ní ti àjọṣe tó wà láàárín rírí àti gbígbọ́, àti bí ara ṣe ń dáhùn sí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ìwé náà Music and the Mind sọ ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí yìí, pé: “Ohun téèyàn gbọ́ lè tètè ru ìmọ̀lára ẹni sókè ju ohun téèyàn rí. . . . Rírí ẹranko kan tó ṣèṣe tàbí ẹnì kan tó ń jìyà láìfọhùn lè má fi bẹ́ẹ̀ ru ìmọ̀lára ẹni tó rí i sókè. Ṣùgbọ́n gbàrà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí lọgun ni ara ẹni tó rí i yóò ti bù máṣọ.”
Ipa Tí Orin àti Ọ̀rọ̀ Inú Rẹ̀ Lè Ní Lórí Rẹ
Àwọn kan sọ pé ipa kan náà ni orin kan pàtó ń ní lórí gbogbo àwọn tó bá gbọ́ ọ. Àmọ́, àwọn mí-ìn sọ pé ìṣarasíhùwà èèyàn sí orin máa ń sinmi lórí ipò tẹ́nì kan wà nígbà tó ń gbọ́ ọ tàbí ìrírí rẹ̀ àtẹ̀yìnwá. A lè lo àpẹẹrẹ ẹnì kan tí èèyàn rẹ̀ ṣaláìsí, tó gbọ́ orin kan, bóyá níbi ìjọsìn. Orin náà lè rán an létí àwọn nǹkan kan, kí ó sì fa ìbànújẹ́ tàbí kó tilẹ̀ jẹ́ kí omijé lé ròrò lójú rẹ̀. Àwọn mí-ìn tí kò sí ní ipò yẹn lè fi tayọ̀tayọ̀ kọ orin kan náà.
Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣàgbéyẹ̀wò ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìró fèrè àwọn Faransé àti ti kàkàkí táa mẹ́nu kàn ní ìṣáájú. O lè má gbà pé fèrè àwọn Faransé máa ń dún tínrín-tínrín. Lójú tìẹ, ó lè jẹ́ pé ṣe ló ń pariwo líle tàbí tí dídún rẹ̀ kàn jọ erémọdé, ṣùgbọ́n ní ti kàkàkí, ó lè jẹ́ èyí tí ń wọni lákínyẹmí ara. Bẹ́ẹ̀ ni, orin lè fa oríṣiríṣi ìmọ̀lára tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nínú wa, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni ìṣarasíhùwà kálukú wa sí i.
Orin máa ń jẹ́ ká lè so ọ̀rọ̀ tàbí ojú ìwòye pọ̀ mọ́ ìmọ̀lára. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ṣàṣà ni ìpolówó ọjà tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí rédíò tí kì í lórin nínú. Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ kì í sábàá nítumọ̀. Àmọ́, gbàrà tí wọ́n bá ti fi orin aládùn kan gbá a lẹ́gbẹ̀ẹ́, ṣe ni ó máa ń gba àwọn olùgbọ́ lọ́kàn. Òótọ́ mà tiẹ̀ ni pé, ète ọ̀pọ̀ jù lọ ìpolówó ọjà ni láti tì ẹ́ ra kiní kan nítorí ìmọ̀lára rẹ dípò kí ó jẹ́ nítorí ohun tí o ti pète-pèrò!
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpolówó ọjà máa ń gbọ́n àpò àwọn èèyàn gbẹ, síbẹ̀ ipa búburú tí ọ̀rọ̀ àtorin inú ìpolówó ọjà ń ní tún rìn jìnnà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìwé ìròyìn Journal of Youth and Adolescence sọ pé nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ táwọn olórin ń kọ lórin léraléra, èrò tí wọ́n ń gbìn sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ ni pé kí wọ́n máà dá ẹnikẹ́ni lóhùn o jàre, “tinú wọn ni kí wọ́n máa ṣe.” Ìwé ìròyìn mí-ìn sọ pé, àwọn ìsọfúnni tó ń jáde nínú “orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò . . . , tó tún le ju àwọn èyí táwọn èèyàn ń gbọ́ nínú àwọn orin onílù dídún kíkankíkan lọ,” lè sọ ìmọ̀lára ẹni tí ń gbọ́ ọ di ìdàkudà, ó sì lè fa ìwà jàǹdùkú láwùjọ.
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti yẹra fún ìṣarasíhùwà òdì béèyàn bá kàn ń gbọ́ ìlù tí wọ́n ń lù láìfetí sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ? Tóò, ohun táwọn èèyàn sọ ni pé ó ṣòro gan-an láti gbọ́ ọ̀rọ̀ orin onílù dídún kíkankíkan àti ti orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò. Kódà, ariwo ìlù wọn kì í jẹ́ kéèyàn gbọ́ nǹkan tí wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, yálà èèyàn gbọ́ tàbí kò gbọ́, ẹ̀mí tí wọ́n fẹ́ gbìn síni lọ́kàn ṣì ń dún nínú ìró àti ìlù wọn tí ń dún kíkankíkan!
Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àní kìkì àkọlé àwọn orin kan máa ń gbin èrò kan síni lọ́kàn. Kò tán síbẹ̀ o, orin náà alára ní bó ṣe ń gbé èrò náà kalẹ̀. Èrò wo ló máa ń gbé jáde? Ìwé ìròyìn kan tó jẹ́ tàwọn ọ̀dọ́ sọ pé: “Ó jẹ́ èrò jíjẹ gàba, jíjẹ́ alágbára, àti ṣíṣẹ́gun ẹ̀yà kejì, takọ tàbí tabo.” Òmíràn sọ pé: “Ẹṣin ọ̀rọ̀ wọn . . . ni ìwà ọ̀tẹ̀, ìwà ipá tó lékenkà, ìjoògùnyó, iṣẹ́ aṣẹ́wó, ìwà pálapàla, àti ìjọsìn Sátánì.”
Àwọn èwe kan gbà pé òótọ́ kúkú lọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọ́n á ní ìyẹn ò sọ pé kí àwọn di irú èèyàn báyẹn. Wọ́n lè sọ pé irú orin yẹn ṣàǹfààní nítorí pé ó ‘ń ran àwọn lọ́wọ́ láti mọ irú ẹni táwọn jẹ́’ gan-an. Ṣóòótọ́ ni? Ìwé ìròyìn Journal of Youth and Adolescence dáhùn pé: “Ìbínú, àtàwọn ọ̀rọ̀ bí-ìjà-bí-ìjà àti agbára táwọn ọ̀dọ́kùnrin kan sọ pé àwọn ń gbádùn nínú àwọn orin onílù dídún kíkankíkan lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, àgàgà tó bá jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n bá wọn wí pé wọn ò ṣe dáadáa níléèwé.” Ó wá fi kún un pé: “Ohun tó wá yani lẹ́nu tàbí tó rúni lójú níbẹ̀ ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ ya ara wọn láṣo, kí wọ́n sì máa ṣe ìfẹ́ inú ara wọn, àwọn ohun tó lè táṣìírí wọn ni wọ́n ń lò. Nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá dá wà, dípò kí wọ́n máa dánú rò, kí wọ́n sì dá gbé èrò wọn kalẹ̀, àwọn gbajúmọ̀ olórin ni wọ́n máa ń fi ṣe àwòkọ́ṣe.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ẹlòmí-ìn ló ń pàṣẹ ohun táwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí ń finú wọn rò àti ohun tó yẹ kí ìmọ̀lára wọn jẹ́.
Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ń lọ lágbo orin rọ́ọ̀kì. Ipa wo ló máa ń ní lórí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí ń lọ? Ìwé náà Music and the Mind dáhùn pé: “Kò sírọ́ ńbẹ̀, nípa ríru ìmọ̀lára àwọn èrò sókè àti nípa rírí i dájú pé ìmọ̀lára gbogbo wọn pátá ló ru sókè, orin lè ra wọ́n níyè, ó lè jẹ́ kí wọ́n gbàgbéra ní ìṣẹ́jú yẹn, ìyẹn ni wàhálà fi máa ń bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn èèyàn lágbo ijó.” Òótọ́ kúkú lọ̀rọ̀ yìí, pàápàá táa bá ronú nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lágbo orin rọ́ọ̀kì, táwọn èèyàn á wá ya ewèlè kalẹ̀.
Nítorí náà, kí orin má bàa sọ èrò inú àti ọkàn wa dìbàjẹ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gan-an nípa irú orin táa ń gbọ́. Báwo la ṣe lè lo ìṣọ́ra? Àpilẹ̀kọ tí a óò fi kádìí ìjíròrò yìí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Orin máa ń jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ láti jó