Ìbùkún Tàbí Ègún—Àwọn Àpẹẹrẹ fún Wa Lónìí
“Àwọn nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ láti máa ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn láti jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa ẹni tí òpin àwọn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan dé bá.”—KỌ́RÍŃTÌ KÌÍNÍ 10:11.
1. Àní bí ẹnì kan ṣe ń yẹ ohun èèlò kan wò, àyẹ̀wò wo ni ó yẹ kí a ṣe?
LÁBẸ́ ọ̀dà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ tí ojú kò tó, ohun èèlò àfirinṣe kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í dípẹtà. Ó lè pẹ́ díẹ̀ kí ìpẹtà náà tó wá sí ojútáyé. Lọ́nà tí ó jọra, ìṣarasíhùwà àti ìfẹ́ ọkàn ẹnì kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í díbàjẹ́ kí èyí tó yọrí sí àbájáde búburú tàbí kí àwọn ẹlòmíràn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe bọ́gbọ́n mu láti yẹ ohun èèlò kan wò bóyá ó ti ń dípẹtà, bẹ́ẹ̀ náà ni yíyẹ ọkàn-àyà wa wò fínnífínní àti títọ́jú rẹ̀ nígbà gbogbo lè pa ìwà títọ́ Kristẹni wa mọ́. Ní èdè míràn, a lè rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, a sì lè yẹra fún ègún àtọ̀runwá. Àwọn kan lè rò pé ìbùkún àti ègún tí a kà sórí Ísírẹ́lì ìgbàanì kò ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ fún àwọn tí wọ́n dojú kọ òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Jóṣúà 8:34, 35; Mátíù 13:49, 50; 24:3) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. A lè jàǹfààní gidigidi nínú àwọn àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí a ṣe tò ó lẹ́sẹẹsẹ nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí 10.
2. Kí ni Kọ́ríńtì Kìíní 10:5, 6 sọ nípa ìrírí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù?
2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lábẹ́ Mósè wéra pẹ̀lú àwọn Kristẹni lábẹ́ Kristi. (Kọ́ríńtì Kìíní 10:1-4) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Ísírẹ́lì ì bá ti wọ Ilẹ̀ Ìlérí, “Ọlọ́run kò fi ojú rere ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ hàn jáde lórí púpọ̀ jù lọ nínú wọn, nítorí a mú wọn balẹ̀ nínú aginjù.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Wàyí o àwọn nǹkan wọ̀nyí di àpẹẹrẹ fún wa, kí àwa má baà jẹ́ ẹni tí ń ní ìfẹ́ ọkàn sí àwọn ohun aṣeniléṣe, àní gẹ́gẹ́ bí àwọ́n ṣe ní ìfẹ́ ọkàn sí wọn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:5, 6) Inú ọkàn-àyà ni a ti ń mú ìfẹ́ ọkàn dàgbà, nítorí náà, a ní láti kọbi ara sí àwọn àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fúnni.
Ìkìlọ̀ Lòdì Sí Ìbọ̀rìṣà
3. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe dẹ́ṣẹ̀ ní ti ère ọmọ màlúù oníwúrà?
3 Ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ ni pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe di abọ̀rìṣà, bí àwọn kan nínú wọ́n ti ṣe; gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti gbádùn ara wọn.’” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:7) Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ yìí jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n yí padà sí ọ̀nà Íjíbítì, tí wọ́n sì ya òrìṣà ọmọ màlúù oníwúrà. (Ẹ́kísódù, orí 32) Ọmọlẹ́yìn náà Sítéfánù fi ìṣòro abẹ́nú tí ó wà níbẹ̀ hàn pé: “Àwọn baba-ńlá wa kọ̀ láti jẹ́ onígbọràn sí i [Mósè, aṣojú Ọlọ́run], ṣùgbọ́n wọ́n sọ́gọ rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan wọ́n sì padà sí Íjíbítì nínú ọkàn-àyà wọn, wọ́n wí fún Áárónì pé, ‘Ṣe àwọn ọlọ́run fún wa láti ṣíwájú wa. Nítorí Mósè yìí, tí ó mú wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, àwa kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.’ Nítorí náà wọ́n ṣe ọmọ màlúù kan ní ọjọ́ wọnnì wọ́n sì mú ẹbọ wá fún òrìṣà náà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” (Ìṣe 7:39-41) Ṣàkíyèsí pé “nínú ọkàn-àyà wọn,” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníwà wíwọ́ náà gbin ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ tí ó yọrí sí ìbọ̀rìṣà sọ́kàn. “Wọ́n ṣe ọmọ màlúù . . . wọ́n sì mú ẹbọ wá fún òrìṣà náà.” Ní àfikún sí i, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ara wọn nínú àwọn iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” Orin ń dún, wọ́n ń kọrin, wọ́n ń jó, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu. Ó hàn gbangba pé, ìbọ̀rìṣà náà fani mọ́ra, ó sì gbádùn mọ́ni.
4, 5. Àṣà ìbọ̀rìṣà wo ni a ní láti yẹra fún?
4 Lọ́nà kan, Íjíbítì amápẹẹrẹṣẹ—ayé Sátánì—ń jọ́sìn eré ìnàjú. (Jòhánù Kìíní 5:19; Ìṣípayá 11:8) Ó ń sọ àwọn òṣèré orí ìtàgé, àwọn olórin, àti àwọn olókìkí eléré ìdárayá, títí kan ijó wọn, orin wọn, èrò wọn nípa àkókò ìtura àti àkókò fàájì di òrìṣà. A ti dẹ àwọn kan wò láti ri ara wọn bọnú eré ìnàjú nígbà tí wọ́n ṣì ń jẹ́wọ́ pé àwọn ń jọ́sìn Jèhófà. Nígbà tí ọ̀ràn bá di pé kí a bá Kristẹni kan wí fún ìwà àìtọ́, ipò rẹ̀ nípa tẹ̀mí tí ó ti di aláìlera ni a sábà lè tọpasẹ̀ rẹ̀ dé mímú ọtí líle, ijó jíjó, àti ṣíṣe fàájì ní àwọn ọ̀nà kan tí ó lè ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kísódù 32:5, 6, 17, 18) Àwọn eré ìnàjú kan gbámúṣé, wọ́n sì ń gbádùn mọ́ni. Síbẹ̀, lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú orin ayé, ijó, sinimá, àti fídíò ń mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara dídíbàjẹ́ wá.
5 Àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í juwọ́ sílẹ̀ fún ìjọsìn òrìṣà. (Kọ́ríńtì Kejì 6:16; Jòhánù Kìíní 5:21) Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ṣọ́ra gidigidi kí a má ṣe sọ eré ìnàjú oníbọ̀rìṣà di bárakú, àti fífi ara wa wewu àwọn àbáyọrí búburú ti dídi ẹni tí ó rí ara bọnú ṣíṣe fàájì ní ọ̀nà ti ayé. Bí a bá fi ara wa fún agbára ìdarí ayé, ìfẹ́ ọkàn àti ìwà aṣeniléṣe lè wọnú èrò inú àti ọkàn-àyà wa láìfura. Bí a kò bá ṣàtúnṣe, ìwọ̀nyí lè yọrí sí ‘mímú wa balẹ̀ nínú aginjù’ ètò ìgbékalẹ̀ Sátánì nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
6. Ìgbésẹ̀ rere wo ni a ní láti gbé ní ti eré ìnàjú?
6 Gẹ́gẹ́ bíi Mósè nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ ère ọmọ màlúù oníwúrà, ohun tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” ń sọ ni pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó wà ní ìhà ti OLÚWA, kí ó tọ̀ mí wá.” Gbígbé ìgbésẹ̀ rere láti fi hàn pé a dúró gbọn-ingbọn-in fún ìjọsìn tòótọ́ lè gba ẹ̀mí là. Mósè ẹ̀yà Léfì gbégbèésẹ̀ kíá mọ́sá láti palẹ̀ agbára ìdarí tí ń rẹni nípò wálẹ̀ mọ́ kúrò pátápátá. (Mátíù 24:45-47; Ẹ́kísódù 32:26-28) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò eré ìnàjú, orin, fídíò, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tí o yàn. Bí ó bá lè sọni dìbàjẹ́ ní àwọn ọ̀nà kan, mú ìdúró rẹ fún Jèhófà. Pẹ̀lú gbígbára lé Ọlọ́run tàdúràtàdúrà, ṣe ìyípadà nínú eré ìnàjú àti orin tí o yàn, kí o sì pa àwọn nǹkan tí ó lè ṣèpalára nípa tẹ̀mí run, àní gẹ́gẹ́ bí Mósè pàápàá ṣe pa ère ọmọ màlúù oníwúrà run.—Ẹ́kísódù 32:20; Diutarónómì 9:21.
7. Báwo ni a ṣe lè dáàbò bo ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ?
7 Báwo ni a ṣe lè gbéjà ko dídípẹtà ọkàn-àyà? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọntaápọn, kí a sì jẹ́ kí òtítọ́ rẹ̀ wọnú èrò inú àti ọkàn-àyà wa ṣinṣin. (Róòmù 12:1, 2) Kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ tún máa sọ ọ́, a ní láti máa lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. (Hébérù 10:24, 25) Lílọ sí ìpàdé láti mú ìjókòó gbóná lásán ni a lè fi wé kíkun ohun tí ó ti ń dípẹtà lọ́dà. Èyí lè mú kí a dán gbinrin fun ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n kò yanjú ìṣòro tí ó wà lábẹ́nú. Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa ìmúrasílẹ̀, ṣíṣàṣàrò, àti lílọ́wọ́ ní ti gidi nínú ìpàdé, a lè fi tagbáratagbára ṣí ìpẹtà náà tí ó lè wà ní ibi kọ́lọ́fín ọkàn-àyà ìṣàpẹẹrẹ wa dànù. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yóò sì fún wa lókun láti fara da àdánwò ìgbàgbọ́, kí a sì “yè kooro ni gbogbo ọ̀nà.”—Jákọ́bù 1:3, 4; Òwe 15:28.
Ìkìlọ̀ Lòdì Sí Àgbèrè
8-10. (a) Àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ wo ni a tọ́ka sí ní Kọ́ríńtì Kìíní 10:8? (b) Báwo ni a ṣe lè fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí ní Mátíù 5:27, 28 sílò lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní?
8 Nínú àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù fúnni tẹ̀ lé e, a gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe fi àgbèrè ṣèwàhù, bí àwọn kan nínú wọ́n ti ṣe àgbèrè, kìkì láti ṣubú, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún nínú wọn ní ọjọ́ kan ṣoṣo.”a (Kọ́ríńtì Kìíní 10:8) Àpọ́sítélì náà ń tọ́ka sí àkókò náà, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹrí ba fún àwọn ọlọ́run èké, tí wọ́n sì ṣe “panṣágà pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Móábù.” (Númérì 25:1-9) Ìwà pálapàla takọtabo ń ṣekú pani! Fífàyè gba ìrònú àti ìfẹ́ ọkàn nínú ìwà pálapàla láti máa bá a nìṣó láìṣàkóso rẹ̀ dà bíi fífàyè gba “dídípẹtà” ọkàn-àyà. Jésù wí pé: “Ẹ̀yín gbọ́ pé a wí i pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:27, 28.
9 Ìyọrísí ìrònú tí ń rẹni nípò wálẹ̀ tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn ní ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà jẹ́rìí sí àbájáde “wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2) Tún rántí pé, ọ̀kan nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbani nínú jẹ́ jù lọ nínú ìgbésí ayé Ọba Dáfídì ni a súnná sí nípa bíbá a nìṣó ní wíwo obìnrin lọ́nà àìtọ́. (Sámúẹ́lì Kejì 11:1-4) Ní òdìkejì, Jóòbù, ọkùnrin olódodo náà tí ó ti láya sílé ‘bá ojú rẹ̀ dá májẹ̀mú pé òun kì yóò tẹjú mọ́ wúńdíá,’ ó sí tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún ìwà pálapàla, ó sì fi hàn pé òún jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́. (Jóòbù 31:1-3, 6-11) A lè fi ojú wé fèrèsé ọkàn-àyà. Láti inú ọkàn-àyà dídíbàjẹ́ sì ni àwọn ohun búburú ti ń jáde wá.—Máàkù 7:20-23.
10 Bí a bá fi ọ̀rọ̀ Jésù sílò, a kò ní gba ìrònú tí kò tọ́ láyè nípa wíwo àwòrán tí ń ru ìbálòpọ̀ takọtabo sókè tàbí nípa fífi àwọn ìrònú ìwà pálapàla sọ́kàn nípa Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, alábàáṣiṣẹ́pọ̀, tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn. A kò lè ṣí ìpẹtà kúrò nípa wíwulẹ̀ fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ gbá ìpẹtà náà kúrò. Nítorí náà, má ṣe fọwọ́ dẹngbẹrẹ gbá èrò àti ìtẹ̀sí ìwà pálapàla kúrò bí ẹni pé wọn kò ṣe ìpalára kankan. Gbé ìgbésẹ̀ lílágbára láti mú ìfẹ́ fún ìwà pálapàla kúrò ní ọkàn rẹ. (Fi wé Mátíù 5:29, 30.) Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́ ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí irú nǹkan bí ìwà pálapàla takọtabo, ‘ìrunú Ọlọ́run ń bọ̀’ gẹ́gẹ́ bí ègún rẹ̀. Nítorí náà a ní láti “sọ” àwọn ẹ̀yà ara wa “di òkú” sí àwọn nǹkan wọ̀nyí.—Kólósè 3:5, 6.
Ìkìlọ̀ Lòdì sí Ìráhùn Ẹlẹ́mìí Ọ̀tẹ̀
11, 12. (a) Ìkìlọ̀ wo ni a fúnni ní Kọ́ríńtì Kìíní 10:9, ìṣẹ̀lẹ̀ wo sì ni ó tọ́ka sí? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù nípa lórí wa?
11 Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí a má ṣe dán Jèhófà wò, bí àwọn kan nínú wọ́n ti dán an wò, kìkì láti ṣègbé nípasẹ̀ àwọn ejò.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:9) Nígbà tí wọ́n ń fẹsẹ̀ rìn nínú aginjù nítòsí ibodè Édómù, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “bá Ọlọ́run àti Mósè sọ̀ pé, Èé ṣe tí ẹ̀yín fi mú wa gòkè láti Íjíbítì jáde wá láti kú ní aginjù? nítorí pé àkàrà kò sí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí omi; oúnjẹ fútẹ́fútẹ́ yìí sì sú ọkàn wa,” mánà tí a pèsè lọ́nà ìyanu. (Númérì 21:4, 5) Rò ó wò ná! Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀nyẹn ń ‘bá Ọlọ́run wí,’ ní pípe ìpèsè rẹ̀ ní oúnjẹ fútẹ́fútẹ́!
12 Nípa ìráhùn wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń dán sùúrù Jèhófà wò. A kò fawọ́ ìbáwí sẹ́yìn, nítorí Jèhófà rán àwọn ejò olóró sáàárín wọn, oró ejò sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn náà ronú pìwà dà, tí Mósè sì bá wọn bẹ̀bẹ̀, a mú ìyọnu náà wá sí òpin. (Númérì 21:6-9) Dájúdájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ní láti ṣiṣẹ́ bí ìkìlọ̀ fún wa láti má ṣe fi ẹ̀mí ọ̀tẹ̀ ráhùn, ní pàtàkì sí Ọlọ́run àti ìṣètò ìṣàkóso àtọ̀runwá rẹ̀.
Ìkìlọ̀ Lòdì Sí Ìkùnsínú
13. Kí ni Kọ́ríńtì Kìíní 10:10 kìlọ̀ fún wa lòdì sí, kí sì ni ọ̀tẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?
13 Nígbà tí ó ń fúnni ní àpẹẹrẹ rẹ̀ tí ó kẹ́yìn ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nínú aginjù, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe jẹ́ oníkùnsínú, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn kan nínú wọ́n ti kùn, kìkì láti ṣègbé láti ọwọ́ apanirun.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:10) Ọ̀tẹ̀ dìde nígbà tí Kórà, Dátánì, àti Ábírámù, àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn hùwà lọ́nà tí kò bá ìlànà ìṣàkóso Ọlọrun mu, tí wọ́n sì pe ọlá àṣẹ Mósè àti Áárónì níjà. (Númérì 16:1-3) Lẹ́yìn ìparun àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí i kùn. Èyí jẹ́ nítorí pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, ìparun àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà kò tọ́. Númérì 16:41 sọ pé: “Ṣùgbọ́n ní ijọ́ kejì gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kùn sí Mósè àti sí Áárónì, wí pé, Ẹ̀yín pa àwọn ènìyàn OLÚWA.” Nítorí ṣíṣe lámèyítọ́ ọ̀nà tí a gbà ṣèdájọ́ ní àkókò yẹn, àrùn ńlá láti ọ̀run pa 14,700 ọmọ Ísírẹ́lì.—Númérì 16:49.
14, 15. (a) Kí ni ọ̀kan lára ẹ̀ṣẹ̀ “àwọn ọkùnrin aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” tí wọ́n yọ́ wọnú ìjọ? (b) Kí ni a lè rí kọ́ nínú ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Kórà?
14 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, “àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” tí wọ́n yọ́ wọnú ìjọ Kristẹni fi hàn pé àwọn jẹ́ olùkọ́ èké àti akùnsínú. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí “ṣàìka ipò oluwa sí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ àwọn ẹni ògo tèébútèébú,” àwọn ẹni-àmì-òróró tí a fún ní ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó ìjọ nípa tẹ̀mí. Nípa àwọn apẹ̀yìndà aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run, ọmọlẹ́yìn náà, Júúdà, tún wí pé: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ oníkùnsínú, àwọn olùráhùn nípa ìpín-ìní wọn nínú ìgbésí ayé, wọ́n ń rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ ọkàn ti ara wọn.” (Júúdà 3, 4, 8, 16) Lónìí, àwọn kan di akùnsínú nítorí pé wọ́n yọ̀ọ̀da fún ìṣarasíhùwà dídípẹtà nípa tẹ̀mí láti dàgbà nínú ọkàn-àyà wọn. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ronú lórí kìkì àìpé àwọn wọnnì tí ó wà ní ipò àbójútó nínú ìjọ, wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí wọn. Kíkùn àti ríráhùn wọn tilẹ̀ lè nasẹ̀ dé ṣíṣe lámèyítọ́ àwọn ìtẹ̀jáde ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà.
15 Ó tọ́ láti béèrè àwọn ìbéèrè olóòótọ́ ọkàn nípa kókó ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́. Ṣùgbọ́n, bí a bá mú ìwà òdì dàgbà, èyí ti ń fi ara rẹ̀ hàn nínú ìjíròrò ìṣelámèyítọ́ láàárín agbo àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ńkọ́? Yóò dára kí a bi ara wa pé, ‘Ibo ni èyí yóò jálẹ̀ sí? Kì yóò ha sàn ju gidigidi láti dẹ́kun kíkún sínú, kí a sì gbàdúrà fún ọgbọ́n?’ (Jákọ́bù 1:5-8; Júúdà 17-21) Kórà àti àwọn ìsọ̀ǹgbè rẹ̀, tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọlá àṣẹ Mósè àti Áárónì, lè ti ní ìdálójú pé, ojú ìwòye àwọ́n gún régé débi tí wọn kò fi yẹ ète wọn wò. Àmọ́, wọ́n kùnà pátápátá. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kùn nípa ìparun Kórà àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ yòókù. Ẹ wo bí ó ti bọ́gbọ́n mu tó láti jẹ́ kí irú àwọn àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ sún wa láti yẹ ète wa wò, kí a lé kíkùn àti ríráhùn sọnù, kí a sì yọ̀ọ̀da kí Jèhófà tún wa ṣe!—Sáàmù 17:1-3.
Kẹ́kọ̀ọ́, Kí O Sì Gbádùn Ìbùkún
16. Kí ni kókó ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ní Kọ́ríńtì Kìíní 10:11, 12?
16 Lábẹ́ ìmísí Ọlọ́run, Pọ́ọ̀lù mú àkọsílẹ̀ àwọn ìhìn iṣẹ́ ìkìlọ̀ náà wa sí ìparí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú pé: “Wàyí o àwọn nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ láti máa ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn láti jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa ẹni tí òpin awọn ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan dé bá. Nítorí náà kí ẹni tí ó bá rò pé òún dúró kíyè sára kí ó má baà ṣubú.” (Kọ́ríńtì Kìíní 10:11, 12) Ǹjẹ́ kí a má ṣe fojú tín-ínrín ìdúró wa nínú ìjọ Kristẹni.
17. Bí a bá nímọ̀lára ète tí kò tọ́ nínú ọkàn-àyà wa, kí ni ó yẹ kí a ṣe?
17 Bí irin ṣe lè dípẹtà, bákan náà ni àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ti jogún ìtẹ̀sí láti ṣe búburú. (Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 5:12) Nítorí náà, a kò ní láti rẹ̀wẹ̀sì bí a bá nímọ̀lára ète tí kò tọ́ kan nínú ọkàn-àyà wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésẹ̀ onípinnu. Nígbà tí a bá fi irin sínú afẹ́fẹ́ gbangba ìta tàbí àyíká tí omiró ti lè dà sí i, kíákíá ni yóò dípẹtà. A ní láti yẹra fún ṣíṣí ara wa sílẹ̀ sí “afẹ́fẹ́” ayé Sátánì, pẹ̀lú eré ìnàjú arínilára rẹ̀, ìwà pálapàla rẹ̀ tí ó gbalé gbòde, àti ìtẹ̀sí òdì ti èrò inú rẹ̀.—Éfésù 2:1, 2.
18. Kí ni Jèhófà ti ṣe nípa ìtẹ̀sí búburú tí aráyé ní?
18 Jèhófà ti pèsè ọ̀nà gbígbógun ti ìtẹ̀sí búburú tí a jogún fún ìran ènìyàn. Ó fún wa ní Ọmọkùnrin bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, kí àwọn tí wọ́n bá lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ baà lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 3:16) Bí a bá tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí, tí a sì fi àkópọ̀ ìwà bíi ti Kristi hàn, a óò jẹ́ ìbùkún fún àwọn ẹlòmíràn. (Pétérù Kìíní 2:21) Ìbùkún àtọ̀runwá ni a óò sì rí gbà, kì í ṣe ègún.
19. Báwo ni a ṣe lè jàǹfààní nínú gbígbé àwọn àpẹẹrẹ Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò?
19 Bí àwa lónìí tilẹ̀ lè ṣe àṣìṣe bíi ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì, a ní odindi àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti tọ́ wa sọ́nà. Láti inú àwọn ojú ìwé rẹ̀ a ń kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe ń bá aráyé lò àti bí Jésù ṣe fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn, ‘ìgbéyọfihàn ògo Ọlọ́run àti àwòrán náà gẹ́lẹ́ ti wíwà Rẹ̀ gan-an.’ (Hébérù 1:1-3; Jòhánù 14:9, 10) Nípasẹ̀ àdúrà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ aláápọn nínú Ìwé Mímọ́, a lè ní “èrò inú ti Kristi.” (Kọ́ríńtì Kìíní 2:16) Nígbà tí a bá dojú kọ ìdánwò àti àdánwò ìgbàgbọ́ mìíràn, a lè jàǹfààní nínú gbígbé àwọn àpẹẹrẹ ìgbàanì ti inú Ìwé Mímọ́ yẹ̀ wò, ní pàtàkì àpẹẹrẹ gíga lọ́lá jù lọ ti Jésù Kristi. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a kì yóò ní láti nírìírí àbájáde ègún àtọ̀runwá. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò gbádùn ojú rere Jèhófà lónìí àti ìbùkún rẹ̀ títí láé.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni a ṣe lè fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò láti má ṣe di abọ̀rìṣà?
◻ Kí ni a lè ṣe láti kọbi ara sí ìkìlọ̀ àpọ́sítélì náà lòdì sí àgbèrè?
◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a yẹra fún ìkùnsínú àti ìráhùn?
◻ Báwo ni a ṣe lè rí ìbùkún àtọ̀runwá gbà, dípò ègún?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Bí a bá ń fẹ́ ìbùkún àtọ̀runwá, a gbọ́dọ̀ yẹra fún ìbọ̀rìṣà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àní bí a ṣe ní láti ṣí ìpẹtà kúrò, ẹ jẹ́ kí a gbé ìgbésẹ̀ rere láti mú ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ kúrò ní ọkàn-àyà wa