Ìbùkún Tàbí Ègún—Yíyàn kan Wà!
“Èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè.”—DIUTARÓNÓMÌ 30:19.
1. Agbára wo ni a fi jíǹkí ẹ̀dá ènìyàn?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ṣètò wa—ẹ̀dá ènìyàn ìṣẹ̀dá rẹ̀ olóye—láti jẹ́ ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, tí yóò jíhìn fún ìgbésẹ̀ rẹ̀. A kò dá wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ adáṣiṣẹ́, tàbí ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì, ṣùgbọ́n, a nawọ́ àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe yíyàn sí wa. (Sáàmù 100:3) Àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́—Ádámù àti Éfà—lómìnira láti yan ipa ọ̀nà ìgbésẹ̀ wọn, wọ́n sì jíhìn fún Ọlọ́run fún yíyàn tí wọ́n ṣe.
2. Yíyàn wo ni Ádámù ṣe, kí sì ni ó yọrí sí?
2 Ẹlẹ́dàá náà ti pèsè ìbùkún àìlópin ní yanturu lórí párádísè ilẹ̀ ayé kan fún ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn. Èé ṣe tí a kò fi tí ì mú ète yẹn ṣẹ síbẹ̀síbẹ̀? Nítorí pé Ádámù ṣe yíyàn tí kò tọ́. Jèhófà ti pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé: “Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ kí ó máa jẹ: Ṣùgbọ́n nínú igi ìmọ̀ rere àti búburú nì, ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé ní ọjọ́ tí ìwọ́ bá jẹ nínú rẹ̀ kíkú ni ìwọ óò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Bí Ádámù bá ti yàn láti ṣègbọràn, à bá ti bù kún fún àwọn òbí wa àkọ́kọ́. Àìgbọràn mú ikú wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:6, 18, 19) Nítorí bẹ́ẹ̀, a tàtaré ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sórí gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù.—Róòmù 5:12.
A Mú Kí Ìbùkún Ṣeé Ṣe
3. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fúnni ní ìdánilójú pé ète rẹ̀ fún aráyé yóò ní ìmúṣẹ?
3 Jèhófà Ọlọ́run gbé ọ̀nà kan kalẹ̀ nípasẹ̀ èyí tí a óò fi mú ète rẹ̀ fún bíbùkún aráyé ṣẹ nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Òun fúnra rẹ̀ sọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa Irú Ọmọ kan, ní sísọ àsọtẹ́lẹ̀ ní Édẹ́nì pé: “Èmi óò sì fi ọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà, àti sáàárín irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀: òun óò fọ́ ọ ní orí, ìwọ óò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Lẹ́yìn èyí, Ọlọ́run ṣèlérí pé, ìbùkún yóò tipasẹ̀ Irú Ọmọ yìí, àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù, wá sórí aráyé onígbọràn.—Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18.
4. Ètò wo ni Jèhófà ṣe láti bù kún aráyé?
4 Jésù Kristi ni Irú Ọmọ ìlérí ìbùkún yẹn. Nípa ipa iṣẹ́ Jésù nínú ìṣètò Jèhófà fún bíbùkún aráyé, Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Àwọn aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ wọnnì tí wọ́n ṣègbọràn sí Ọlọ́run, tí wọ́n sì jàǹfààní ìtóye ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi yóò gbádùn ìbùkún. (Ìṣe 4:12) Ìwọ yóò ha yan ìgbọràn àti ìbùkún bí? Àìgbọràn yóò yọrí sí ohun kan tí ó yàtọ̀ pátápátá.
Ègún Ńkọ́?
5. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ègún”?
5 Ègún ni òdìkejì ìbùkún. Ọ̀rọ̀ náà “ègún” túmọ̀ sí fífi ẹnì kan bú tàbí fífi ẹnì kan ré. Ọ̀rọ̀ Hébérù náà qela·lahʹ ni a rí láti inú orísun ọ̀rọ̀ ìṣe náà qa·lalʹ, tí ó túmọ̀ sí “fúyẹ́” ní olówuuru. Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá lò ó ní ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ, ó túmọ̀ sí láti ‘fi ẹnì kan ré’ tàbí láti ‘ṣàìka ẹnì kan sí.’—Léfítíkù 20:9; Sámúẹ́lì Kejì 19:43.
6. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo tí ó kan Èlíṣà ni ó ṣẹlẹ̀ nítòsí Bétélì?
6 Gbé àpẹẹrẹ amúnijígìrì ti ìgbésẹ̀ kíá mọ́sá kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ègún yẹ̀ wò. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Èlíṣà, wòlíì Ọlọ́run, ṣe ń ti Jẹ́ríkò lọ sí Bétélì. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Bí ó sì ti ń gòkè lọ ní ọ̀nà, àwọn ọmọ kéékèèké jáde láti ìlú wá, wọ́n sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì wí fún un pé, Gòkè lọ, apárí! gòkè lọ, apárí! Ó sì yí padà, ó sì wò wọ́n, ó sì fi wọn bú ní orúkọ Oluwa. Abo béárì méjì sì jáde láti inú igbó wá, wọ́n sì fa méjìlélógójì ya nínú wọn.” (Àwọn Ọba Kejì 2:23, 24) A kò ṣí ohun tí Èlíṣà sọ ní pàtó payá, nígbà tí ó sọ ègún yẹn nípa fífi àwọn ọmọdé tí ń fi í ṣẹlẹ́yà ré. Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu yẹn ní ìyọrísí nítorí pé a sọ ọ́ ní orúkọ Jèhófà láti ẹnu wòlíì Ọlọ́run tí ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run.
7. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ tí ó fi Èlíṣà ṣẹlẹ́yà, èé sì ti ṣe?
7 Ó dà bíi pé ìdí pàtàkì fún ìfiniṣẹlẹ́yà náà ni pé, Èlíṣà wọ aṣọ oyè tí wọ́n mọ̀ mọ Èlíjà, àwọn ọmọdé náà kò sì fẹ́ rí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbapò wòlíì náà sojú rárá. (Àwọn Ọba Kejì 2:13) Láti lè dáhùn ìpèníjà jíjẹ́ tí ó jẹ́ agbapò Èlíjà àti láti lè kọ́ àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí àti àwọn òbí wọn ní ọ̀wọ̀ tí ó yẹ fún wòlíì Jèhófà, Èlíṣà fi àwọn ènìyànkénìyàn tí ń fi í ṣe ẹlẹ́yà náà ré ní orúkọ Ọlọ́run Èlíjà. Jèhófà fi hàn pé òún tẹ́wọ́ gba Èlíṣà gẹ́gẹ́ bí wòlíì rẹ̀ nípa mímú kí abo béárì méjì ti inú igbó jáde wá, kí ó sì fa 42 lára àwọn afiniṣẹ̀sín wọ̀nyẹn ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ onípinnu nítorí àìlọ́wọ̀ rárá wọn fún ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ tí ó ń lò lórí ilẹ̀ ayé nígbà yẹn.
8. Kí ni àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì gbà láti ṣe, pẹ̀lú ìfojúsọ́nà wo sì ni?
8 Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi irú ìwà àìlọ́wọ̀ kan náà hàn fún ìṣètò Ọlọ́run. Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: Ní ọdún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà fi ojú rere hàn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa dídá wọn nídè kúrò ní oko ẹrú Íjíbítì bí ẹni pé ‘wọ́n wà ní apá ìyẹ́ idì.’ Kété lẹ́yìn náà, wọ́n jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Kíyè sí bí ìgbọràn ṣe ní ìsopọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rírí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Jèhófà sọ nípasẹ̀ Mósè pé: “Bí ẹ̀yin bá fẹ́ gba ohùn mi gbọ́ ní tòótọ́, tí ẹ óò sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin óò jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo ènìyàn lọ: nítorí gbogbo ayé ni ti èmi.” Lẹ́yìn náà, àwọn ènìyàn náà dáhùn padà lọ́nà rere, ní sísọ pé: “Gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLÚWA wí ni àwa óò ṣe.” (Ẹ́kísódù 19:4, 5, 8; 24:3) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún un, àwọn sì ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò yọrí sí ìbùkún ńláǹlà.
9, 10. Nígbà tí Mósè wà lórí Òke Sínáì, kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
9 Ṣùgbọ́n, kí ó tó di pé ‘Ọlọ́run fi ìka rẹ̀’ gbẹ́ àwọn ìpìlẹ̀ ìlànà ìgbàgbọ́ inú àdéhùn yẹn sórí òkúta, ègún àtọ̀runwá pọn dandan. (Ẹ́kísódù 31:18) Èé ṣe tí wọ́n fi yẹ fún irú àbájáde bíbani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀? Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ha ti fi ìfẹ́ ọkàn wọn hàn láti ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ bí? Bẹ́ẹ̀ ni, nínú ọ̀rọ̀ wọ́n fẹ́ ìbùkún, ṣùgbọ́n, nípa ìgbésẹ̀ wọn, wọ́n yàn láti gba ègún.
10 Láàárín sáà 40 ọjọ́ tí Mose fi wà lórí Òke Sínáì, tí ó ń gba Òfin Mẹ́wàá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò mú ìlérí wọn ìṣáájú láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ṣẹ. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé, Mósè pẹ́ láti sọ̀kalẹ̀ ti orí òkè wá, àwọn ènìyàn kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ Áárónì, wọ́n sì wí fún un pé, Dìde, dá òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa lọ; bí ó ṣe ti Mósè yìí ni, ọkùnrin nì tí ó mú wa gòkè láti ilẹ̀ Íjíbítì wá, àwa kò mọ ohun tí ó ṣe é.” (Ẹ́kísódù 32:1) Àpẹẹrẹ ìwà àìlọ́wọ̀ míràn nìyí tí a hù sí ẹ̀dá ènìyàn aṣojú tí Jèhófà ń lò nígbà yẹn láti ṣáájú àwọn ènìyàn rẹ̀, kí ó sì darí wọn. A tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sínú fífara wé àwọn ará Íjíbítì abọ̀rìṣà, wọ́n sì jẹ èrè bíbani lẹ́rù, nígbà tí nǹkan bí 3,000 nínú wọn ti ojú idà ṣubú ní ọjọ́ kan ṣoṣo.—Ẹ́kísódù 32:2-6, 25-29.
Sísọ Ìbùkún àti Gígégùn-ún
11. Àwọn ìtọ́ni wo tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìbùkún àti ègún ni Jóṣúà tẹ̀ lé?
11 Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí ó pé 40 ọdún tí Ísírẹ́lì ti ń rìn nínú aginjù, Mósè to àwọn ìbùkún tí wọn yóò ká lẹ́sẹẹsẹ, bí wọ́n bá yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Ó tún to àwọn ègún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò jìyà rẹ̀ bí wọ́n bá yàn láti ṣàìgbọràn sí Jèhófà. (Diutarónómì 27:11–28:10) Kété lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jóṣúà tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Mósè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìbùkún àti ègún wọ̀nyí. Ẹ̀yà mẹ́fà ti Ísírẹ́lì dúró sí ìsàlẹ̀ Òke Ébálì, àwọn mẹ́fà yòókù sì wà ní iwájú Òke Gérísímù. Àwọn ọmọ Léfì dúró sí àfonífojì tí ó wà láàárín òkè méjèèjì. Ó hàn gbangba pé, àwọn ẹ̀yà tí wọ́n wà ní iwájú Òke Ébálì wí pé “Àmín” sí ègún, tàbí èpè, tí a kà ní dídojú kọ ìhà ọ̀dọ̀ wọn. Àwọn yòókù dáhùn padà sí ìbùkún tí àwọn ọmọ Léfì kà ní dídojú kọ ìhà ọ̀dọ̀ wọn ní ẹsẹ̀ Òke Gérísímù.—Jóṣúà 8:30-35.
12. Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ègún tí àwọn ọmọ Léfì gé?
12 Kí a sọ pé o ń gbọ́ tí àwọn ọmọ Léfì ń sọ pé: “Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yá ère gbígbẹ́ tàbí dídá, ìríra sí OLÚWA, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà, tí ó sì gbé e kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí kò fi bàbá tàbí ìyá rẹ̀ pè. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó ṣí ààlà ẹnì kejì rẹ̀ kúrò. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó ṣi afọ́jú ní ọ̀nà. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó ń yí ìdájọ́ àlejò po, àti ti aláìníbaba, àti ti opó. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó bá aya bàbá rẹ̀ dà pọ̀, nítorí tí ó tú aṣọ bàbá rẹ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó bá ẹranko dà pọ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó bá arábìnrin rẹ̀ dà pọ̀, tí í ṣe ọmọbìnrin bàbá rẹ̀, tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó bá ìyá aya rẹ̀ dà pọ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó lu ẹnì kejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí ó gba [àbẹ̀tẹ́lẹ̀] láti pa aláìṣẹ̀. . . . Ègún ni fún ẹni tí kò dúró sí gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí láti ṣe wọ́n.” Lẹ́yìn ègún kọ̀ọ̀kan, àwọn ẹ̀yà tí ó wà ní iwájú Òke Ébálì sọ pé, “Àmín.”—Diutarónómì 27:15-26.
13. Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, báwo ni ìwọ yóò ṣe sọ àwọn ìbùkún kan tí àwọn ọmọ Léfì sọ?
13 Wàyí o, kí a sọ pé o ń gbọ́ tí àwọn tí ó wà ní iwájú Òke Gérísímù ń fèsì sí ìbùkún kọ̀ọ̀kan ní gbígbóhùn sókè, bí àwọn ọmọ Léfì ti ń wí pé: “Ìbùkún ni fún ọ ní ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko. Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ, àti ìbísí màlúù rẹ, àti ọmọ àgùntàn rẹ. Ìbùkún ni fún agbọ̀n rẹ àti fún ọpọ́n ìpo àkàrà rẹ. Ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá wọlé, ìbùkún ni fún ọ nígbà tí ìwọ bá jáde.”—Diutarónómì 28:3-6.
14. Kí ni yóò mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ìbùkún gbà?
14 Kí ni yóò mú kí wọ́n rí ìbùkún wọ̀nyí gbà? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Bí ìwọ bá fara balẹ̀ gbọ́ ohùn OLÚWA Ọlọ́run rẹ, láti máa kíyè sí àtiṣe àṣẹ rẹ̀ gbogbo tí mo pa fún ọ ní òní, ǹjẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò gbé ọ ga ju gbogbo orílẹ̀-èdè ayé lọ: Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí yóò sì ṣẹ sórí rẹ, yóò sì bá ọ, bí ìwọ́ bá fetí sí ohùn OLÚWA Ọlọ́run rẹ.” (Diutarónómì 28:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbọràn sí Ọlọ́run ni kọ́kọ́rọ́ náà sí gbígbádùn ìbùkún àtọ̀runwá. Ṣùgbọ́n àwa lónìí ńkọ́? Àwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan yóò ha yan ìbùkún àti ìyè nípa bíbá a nìṣó láti máa “gbọ́ ohùn OLÚWA” bí?—Diutarónómì 30:19, 20.
Títúbọ̀ Wò Ó Fínnífínní
15. Kókó wo ni a tẹnu mọ́ nínú ìbùkún tí a kọ sílẹ̀ nínú Diutarónómì 28:3, báwo sì ni a ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀?
15 Ẹ jẹ́ kí a ronú lórí àwọn ìbùkún kan pàtó tí ọmọ Ísírẹ́lì kan yóò gbádùn fún ṣíṣègbọràn sí Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, Diutarónómì 28:3 sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọ ní ìlú, ìbùkún ni fún ọ ní oko.” Rírí ìbùkún Ọlọ́run gbà kò sinmi lórí ibi tí ẹnì kán wà tàbí iṣẹ́ tí a yàn fún un. Àwọn àyíká ipò lè gbé ẹnì kan dè, bóyá nítorí pé wọ́n ń gbé ní agbègbè tí wọn kò ti rí jájẹ tàbí orílẹ̀-èdè tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Àwọn mìíràn lè yán hànhàn láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà ní ibòmíràn. Àwọn Kristẹni ọkùnrin kan lè rẹ̀wẹ̀sì nítorí pé a kò tí ì yàn wọ́n sípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ. Nígbà míràn, àwọn obìnrin Kristẹni máa ń bọkàn jẹ́ nítorí pé wọn kò sí ní ipò lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì. Síbẹ̀, gbogbo ẹni tí ‘ó bá fara balẹ̀ gbọ́ ohùn Jèhófà, tí ó sì ń ṣe ohun tí ó ń béèrè’ ni a óò bù kún nísinsìnyí àti títí láé fáàbàdà.
16. Báwo ni ètò àjọ Jèhófà ṣe ń nírìírí ìlànà Diutarónómì 28:4 lónìí?
16 Diutarónómì 28:4 sọ pé: “Ìbùkún ni fún ọmọ inú rẹ, àti èso ilẹ̀ rẹ, àti irú ohun ọ̀sìn rẹ, àti ìbísí màlúù rẹ, àti ọmọ àgùntàn rẹ.” Ọ̀nà tí a gbà lo ọ̀rọ̀-arọ́pò-orúkọ ẹlẹ́yọ ẹnì kan náà ní èdè Hébérù, tí a túmọ̀ sí “rẹ” fi hàn pé, èyí yóò jẹ ìrírí tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tí ó bá jẹ́ onígbọràn yóò ní. Àwọn onígbọràn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí ńkọ́? Ìbísí jákèjádò ayé àti ìmúgbòòrò tí ń lọ lọ́wọ́ nínú ètò àjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìyọrísí ìbùkún Ọlọ́run lórí ìsapá aláápọn àwọn olùpòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà tí wọ́n lé ní 5,000,000. (Máàkù 13:10) Ìrètí náà sì dájú pé ìbísí ńláǹlà ṣì wà níwájú nítorí pé, ó lé ní 13,000,000 tí wọ́n wá síbi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní 1995. Ìwọ́ ha ń gbádùn àwọn ìbùkún Ìjọba bí?
Yíyàn Tí Ísírẹ́lì Ṣe Yàtọ̀
17. Kí ìbùkún tàbí ègún ‘bá’ ẹnì kan sinmi lórí kí ni?
17 Ní ti gidi, òjò ìbùkún yóò rọ̀ sórí ọmọ Ísírẹ́lì kan tí ó bá jẹ́ onígbọràn. A ṣèlérí pé: “Gbogbo ìbùkún wọ̀nyí yóò sì ṣẹ sórí rẹ, yóò sì bá ọ.” (Diutarónómì 28:2) Lọ́nà kan náà, a sọ nípa ègún pé: “Gbogbo ègún wọ̀nyí yóò ṣẹ sórí rẹ, yóò sì bá ọ.” (Diutarónómì 28:15) Bí o bá jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kan ní ìgbàanì, ṣe ìbùkún ni yóò ‘bá’ ọ ni tàbí ègún? Ìyẹn ì bá ti sinmi lórí bóyá o ṣègbọràn sí Ọlọ́run tàbí ó ṣàìgbọràn sí i.
18. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ti ṣe yẹra fún ègún?
18 Ní Diutarónómì 28:15-68, a to àbájáde àìgbọràn lẹ́sẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ègún. Àwọn kan jẹ́ òdìkejì rẹ́gí sí àwọn ìbùkún fún ìgbọràn tí a tó lẹ́sẹẹsẹ ní Diutarónómì 28:3-14. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì ká èso búburú ti ègún nítorí pé, wọ́n yàn láti lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké. (Ẹ́sírà 9:7; Jeremáyà 6:6-8; 44:2-6) Ẹ wo bí èyí ti bani nínú jẹ́ tó! Wọn ì bá ti yẹ irú àbájáde bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, nípa ṣíṣe yíyàn tí ó tọ́, ìyẹn ni ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà Jehofa tí ó gbámúṣe, tí ó sọ ohun tí ó jẹ́ rere àti búburú ní kedere. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lónìí ń ní ìrora àti ìbànújẹ́ nítorí pé, wọ́n yàn láti hùwà ní ìlòdì sí àwọn ìlànà Bíbélì nípa ṣíṣe ìsìn èké, lílọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla takọtabo, lílo òògùn tí kò bófin mu, fífi ọtí líle kẹ́ ara wọn bà jẹ́, àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní Ísírẹ́lì àti Júdà ìgbàanì, ṣíṣe irú yíyàn búburú bẹ́ẹ̀ ń yọrí sí àìrí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun àti ìrora ọkàn-àyà tí ó jẹ́ àfọwọ́fà.—Aísáyà 65:12-14.
19. Ṣàpèjúwe ipò tí Júdà àti Ísírẹ́lì gbádùn nígbà tí wọ́n yàn láti ṣègbọràn sí Jèhófà.
19 Kìkì ìgbà tí Ísírẹ́lì ṣègbọràn sí Jèhófà nìkan ni ìbùkún pọ̀ yamùrá, tí nǹkan sì tòrò minimini. Fún àpẹẹrẹ, nípa ọjọ́ Ọba Sólómọ́nì, a kà pé: “Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn tí ń bẹ ní etí òkun ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n sì ń ṣe àríyá. . . . Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé ní àlàáfíà, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà, ni gbogbo ọjọ́ Sólómọ́nì.” (Àwọn Ọba Kìíní 4:20-25) Àní ní àkókò Ọba Dáfídì pàápàá, tí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run gbógun dìde lọ́pọ̀lọpọ̀, orílẹ̀-èdè náà nímọ̀lára ìtìlẹ́yìn àti ìbùkún Jèhófà nígbà tí wọ́n yàn láti ṣègbọràn sí Ọlọ́run òtítọ́.—Sámúẹ́lì Kejì 7:28, 29; 8:1-15.
20. Ìgbọ́kànlé wo ni Ọlọ́run ní nínú ẹ̀dá ènìyàn?
20 Ìwọ yóò ha ṣègbọràn sí Ọlọ́run, àbí ìwọ yóò ṣàìgbọràn sí i? Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní yíyàn kan. Bí gbogbo wa tilẹ̀ ti ní ìtẹ̀sí ẹ̀ṣẹ̀ tí a jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù, a rí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ṣíṣe yíyàn gbà pẹ̀lú. Láìka Sátánì, ayé búburú yìí, àti àìpé wa sí, a lè ṣe yíyàn tí ó tọ́. Ní àfikún sí i, Ẹlẹ́dàá wa ní ìgbọ́kànlé pé, lójú gbogbo àdánwò àti ìdánwò, àwọn tí yóò ṣe yíyàn tí ó tọ́ yóò wà, kì í ṣe nínú ọ̀rọ̀ nìkan ṣùgbọ́n nínú ìṣe pẹ̀lú. (Pétérù Kìíní 5:8-10) Ìwọ yóò ha wà lára wọn bí?
21. Kí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀ lé e?
21 Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀ lé e, a óò lè fi àwọn àpẹẹrẹ àtẹ̀yìnwá wọn ìwà àti ìgbésẹ̀ wa wò. Ǹjẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fi ìmoore dáhùn padà sí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípasẹ̀ Mósè pé: “Èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ, nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè.”—Diutarónómì 30:19.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe mú kí ìbùkún ṣeé ṣe fún ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀?
◻ Kí ni ègún?
◻ Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ì bá ṣe rí ìbùkún gbà dípò ègún?
◻ Ìbùkún wo ni Ísírẹ́lì gbádùn fún ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì péjọ níwájú Òke Gérísímù àti Òke Ébálì
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.