“Kọ́ Wa Bí A Ṣe Ń Gbàdúrà”
“OLÚWA, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yin Jésù Kristi ló sọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ yìí. (Lúùkù 11:1) Ní kedere, ọmọ ẹ̀yìn tí a kò dárúkọ náà jẹ́ ọkùnrin kan tí ó ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún àdúrà. Bákan náà lónìí, àwọn olùjọsìn tòótọ́ mọrírì ìjẹ́pàtàkì rẹ̀. Ó ṣe tán, àdúrà ni ọ̀nà tí Ẹni Gíga Jù Lọ ní gbogbo àgbáyé fi ń gbọ́ wa! Sì ronú èyí wò ná! ‘Olùgbọ́ àdúrà’ náà ń fún àlámọ̀rí àti àníyàn wa ní àfiyèsí ara ẹni. (Orin Dáfídì 65:2) Ní pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ, nípasẹ̀ àdúrà, a ń fi ọpẹ́ àti ìyìn fún Ọlọ́run.—Fílípì 4:6.
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀rọ̀ náà, “kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà,” gbé àwọn ìbéèrè pàtàkì dìde. Jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni àwọn onírúurú ìsìn ń lo láti tọ Ọlọ́run lọ. Ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́ ha wà láti gbàdúrà bí? Láti lè dáhùn rẹ̀, jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wo díẹ̀ nínú àwọn àṣà gbígbajúmọ̀ ti ìsìn, tí ó ní àdúrà nínú. A óò darí àfiyèsí sí àwọn tí ń ṣẹlẹ̀ ní Latin America.
Ère àti “Àwọn Ẹni Mímọ́ Alátìlẹyìn”
Ní gbogbogbòò, àwọn orílẹ̀-èdè Latin America fara jìn fún ìsìn. Fún àpẹẹrẹ, jákèjádò Mexico, ẹnì kan lè rí àṣà gbígbajúmọ̀ ti gbígbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́ alátìlẹyìn.” Ní tòótọ́, ó jẹ́ àṣà ní àwọn ìlú àwọn ará Mexico láti ní “àwọn ẹni mímọ́ alátìlẹyìn” tí wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ fún ní àwọn ọjọ́ kan pàtó. Àwọn Kátólíìkì ará Mexico tún ń gbàdúrà sí ọ̀pọ̀ onírúurú ère. Ṣùgbọ́n, ohun tí olùjọsìn bá fẹ́ béèrè ni ó ń pinnu “ẹni mímọ́” tí yóò ké sí. Bí ẹnì kán bá ń wá alábàáṣègbéyàwó, ó lè tan àbẹ́là fún Anthony “Mímọ́.” Ẹnì kan tí ó fẹ́ rìnrìn àjò nínú ohun ìrìnnà lè fi ara rẹ̀ lé Christopher “Mímọ́” lọ́wọ́, alátìlẹyìn àwọn arìnrìn àjò, pàápàá ti àwọn tí ń wọkọ̀.
Ṣùgbọ́n, níbo ni irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀ ti pilẹ̀? Ìtán fi hàn pé nígbà tí àwọn ará Sípéènì dé sí Mexico, wọ́n rí i pé àwọn olùgbé ibẹ̀ fara jìn pátápátá fún ìjọsìn àwọn ọlọ́run kèfèrí. Nínú ìwe rẹ̀ Los Aztecas, Hombre y Tribu (Aztecs, Ọkùnrin Náà àti Ẹ̀yà Ìran), Victor Wolfgang von Hagen sọ pé: “Àwọn ọlọ́run ara ẹní wà, irúgbìn kọ̀ọ̀kán ní ọlọ́run tirẹ̀, ìgbòkègbodò kọ̀ọ̀kán ní ọlọ́run tàbí abo-ọlọ́run tirẹ̀, àní ìṣekúpa-ara-ẹní ní ọ̀kan. Yacatecuhtli ni ọlọ́run àjọ́sìnfún ti àwọn oníṣòwò. Nínú ayé tí ó ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run yìí, gbogbo ọlọ́run ni ó ní ìtẹ̀sí àti ipa iṣẹ́ tí a fi hàn kedere.”
Jíjọ tí àwọn ọlọ́run wọ̀nyí jọ “àwọn ẹni mímọ́” Kátólíìkì gba àfiyèsí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí àwọn ajagunṣẹ́gun ará Sípéènì gbìyànjú láti “sọ” àwọn ọmọ ìbílẹ̀ “di Kristẹni,” àwọn wọ̀nyí wulẹ̀ yí ìtúúbá wọn fún àwọn òrìṣà wọn padà sọ́dọ̀ “àwọn ẹni mímọ́” ṣọ́ọ̀ṣì ni. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal mọ gbòǹgbò abọgibọ̀pẹ̀ ti ìsìn àwọn Kátólíìkì tí a ń ṣe ní àwọn apá ibì kan ní Mexico ní àmọ̀jẹ́wọ́. Ó sọ pé ní agbègbè kan, ọ̀pọ̀ jù lọ lára “àwọn ẹni mímọ́” 64 tí àwọn tí ń gbé ibẹ̀ ń bọ̀wọ̀ fún jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú “àwọn ọlọ́run pàtó kan ti Mayan.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ṣàlàyé pé, “ìdè ìgbọ́kànlé pẹ́kípẹ́kí ń bẹ láàárín ẹni mímọ́ àti àwọn tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, . . . ìdè tí ó jẹ́ pé, dípò dídín ipò ìbátan pẹ̀lú Kristi àti Ọlọ́run kù, ńṣe ni ó bù kún un, tí ó sì mú un jinlẹ̀.” Ṣùgbọ́n báwo ni ìdè kan tí ó ṣe kedere pé ó jẹ́ àmì ìbọ̀rìṣà ṣe lè mú ipò ìbátan ẹnì kan pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́ náà jinlẹ̀ sí i? Àwọn àdúrà tí a gbà sí irú “àwọn ẹni mímọ́” bẹ́ẹ̀ ha lè dùn mọ́ Ọlọ́run nínú ní ti gidi bí?
Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà
Àṣà míràn tí ó tún gbajúmọ̀ wé mọ́ lílo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà. Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Diccionario Enciclopédico Hispano-Americano (Ìwe Gbédègbẹ́yọ̀ Atúmọ̀ Ède Hispanic-America), ṣàpèjúwe ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà gẹ́gẹ́ bí “àpapọ̀ àádọ́ta tàbí àádọ́jọ wóró ìlẹ̀kẹ̀ tí a sín sínú okùn, tí a sì fi àwọn wóró ìlẹ̀kẹ̀ ńlá mìíràn pín sí mẹ́wàá mẹ́wàá, tí a sì fi àgbélébùú tí wóró ìlẹ̀kẹ̀ mẹ́ta ṣáájú rẹ̀ so ẹnu rẹ̀ pa pọ̀.”
Ní ṣíṣàlàyé bí a ti ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà náà, ìtẹ̀jáde Kátólíìkì kán sọ pé: “Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà Mímọ́ jẹ́ oríṣi àdúrà àfẹnusọ àti àkọ́sórí nípa àwọn ohun Àdììtú ìràpadà wa. Ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni ó ní. Ìpín kan ní nínú, kíka Àdúrà Olúwa lẹ́ẹ̀kan, Mo Kí Ọ Màríà mẹ́wàá, àti Ògo ni fún Baba lẹ́ẹ̀kan. A máa ń ṣàṣàrò lórí ohun àdììtú kan nígbà kíka ìpín kọ̀ọ̀kan.” Àwọn ohun àdììtú náà jẹ́ àwọn ìgbàgbọ́, tàbí ẹ̀kọ́, tí àwọn Kátólíìkì ní láti mọ̀, tí ó ní í ṣe nínú ọ̀ràn yìí pẹ̀lú ìwàláàyè, ìjìyà, àti ikú Kristi Jésù.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Fífi ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà gbàdúrà bẹ̀rẹ̀ ní ìjímìjí nínú ìsìn Kristẹni nígbà Sànmánì Agbedeméjì, ṣùgbọ́n ó tàn kálẹ̀ ní kìkì àwọn ọdún 1400 àti 1500.” Ìsìn Kátólíìkì nìkan ni ó ha ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà bí? Rárá. Ní ti gidi, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopedia of Religion and Religions, sọ pé: “Ohun ti a gbọ́ ni pé ọwọ́ àwọn onísìn Búdà ni àwọn ọmọlẹ́yìn Mòhámẹ́ẹ̀dì ti gba Ìlẹ̀kẹ̀ Àdúrà, àwọn Kristẹni sì gbà á lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Mòhámẹ́ẹ̀dì nígbà Ogun Ìsìn.”
Àwọn kan jiyàn pé a wulẹ̀ ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà fún ìránnilétí ni, nígbà tí a bá nílò àwọn àdúrà àgbàtúngbà. Ṣùgbọ́n inú Ọlọ́run ha dùn sí lílò ó bí?
A kò ní láti méfòó tàbí jiyàn lórí ìbójúmu tàbí ìlẹ́sẹ̀nílẹ̀ irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀. Jésù fi ọlá àṣẹ dáhùn ẹ̀bẹ̀ náà láti kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí a ti ń gbàdúrà. Ohun tí ó sọ yóò la àwọn òǹkàwé kan lóye, ó sì ṣeé ṣe kí ó ya àwọn kan lẹ́nu.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn onísìn Kátólíìkì sábà máa ń lo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà. Níbo ni wọ́n ti ṣẹ̀ wá?