ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/1 ojú ìwé 15-20
  • “Kí Ẹ̀yin Fúnra Yín Di Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Ẹ̀yin Fúnra Yín Di Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín”
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbésí Ayé Mímọ́, Iye Owó Mímọ́
  • Ìwà Mímọ́ Nínú Ìdílé
  • Ìjẹ́mímọ́ àti Àwọn Mẹ́ḿbà Ìdílé Wa Tí Wọ́n Jẹ́ Aláìgbàgbọ́
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Nínú Ìjọ?
  • Ìjẹ́mímọ́ Wa Ha Ń Fara Hàn Ní Àdúgbò Wa Bí?
  • Ìjẹ́mímọ́ ní Ibi Iṣẹ́ àti ní Ilé Ẹ̀kọ́
  • ‘Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nítorí Èmi Jẹ́ Mímọ́’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ẹ Máa Wà Ní Mímọ́ Nínú Ìbẹ̀rù Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/1 ojú ìwé 15-20

“Kí Ẹ̀yin Fúnra Yín Di Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín”

“Ní ìbámu pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ tí ó pè yín, kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín, nítorí a kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí tí èmi jẹ́ mímọ́.’”—PÉTÉRÙ KÌÍNÍ 1:15, 16.

1. Èé ṣe tí Pétérù fi ké sí àwọn Kristẹni láti jẹ́ mímọ́?

ÈÉ ṢE tí àpọ́sítélì Pétérù fi fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó wà lókè yìí? Nítorí pé ó rí i pé ó pọn dandan fún Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti dáàbò bo èrò àti ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti lè mú wọn wa ní ìbámu pẹ̀lú ìjẹ́mímọ́ Jèhófà. Nípa báyìí, ṣáájú ọ̀rọ̀ tí ó wà lókè yìí, ó sọ pé: “Ẹ mú èrò inú yín gbara dì fún ìgbòkègbodò, ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré . . . Gẹ́gẹ́ bí onígbọràn ọmọ, ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́ ọkàn tí ẹ ti ní tẹ́lẹ̀ rí nínú àìmọ̀kan yín.”—Pétérù Kìíní 1:13, 14.

2. Èé ṣe tí àwọn ìfẹ́ ọkàn wa fi jẹ́ aláìmọ́ kí á tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?

2 Ìfẹ́ ọkàn wa tẹ́lẹ̀ rí jẹ́ aláìmọ́. Èé ṣe? Nítorí pé púpọ̀ nínú wa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ayé ṣáájú kí a tó tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Kristẹni. Pétérù mọ èyí nígbà tí ó kọ̀wé láìfọ̀rọ̀ bọpo bọyọ̀ pé: “Nítorí àkókò tí ó ti kọjá lọ ti tó fún yín láti fi ṣe ìfẹ́ inú àwọn orílẹ̀-èdè nígbà tí ẹ ń tẹ̀ síwájú nínú àwọn ìṣe ìwà àìníjàánu, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, àṣejù nídìí ọtí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, ìfagagbága ọtí mímu, àti àwọn ìbọ̀rìṣà tí ó lòdì sí òfin.” Àmọ́ ṣáá o, Pétérù kò dárúkọ àwọn ìṣe àìmọ́ tí o jẹ́ ti ayé òde òní, níwọ̀n bí a kò ti mọ̀ wọ́n nígbà yẹn.—Pétérù Kìíní 4:3, 4.

3, 4. (a) Báwo ni a ṣe lè ṣẹ́gun àwọn ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́? (b) Àwọn Kristẹni ha ní láti tẹ èrò ìmọ̀lára wọn rì bí? Ṣàlàyé.

3 O ha ṣàkíyèsí pé àwọn ìfẹ́ ọkàn wọ̀nyí jẹ́ èyí tí ń fa ẹran ara, agbára ìmòye, àti èrò ìmọ̀lára mọ́ra bí? Nígbà tí a bá jẹ́ kí ìwọ̀nyí borí, nígbà náà èrò àti ìgbésẹ̀ wa yóò fi tìrọ̀rùntìrọ̀rùn di aláìmọ́. Èyí ṣàpèjúwe ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ kí agbára ìmọnúúrò ṣàkóso àwọn ìgbésẹ̀ wa. Pọ́ọ̀lù sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Nítorí náà mo pàrọwà fún yín nípasẹ̀ ìyọ́nú Ọlọ́run, ẹ̀yin ará, láti fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.”—Róòmù 12:1, 2.

4 Láti ṣe ìrúbọ mímọ́ sí Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kí agbára ìmọnúúrò borí, kì í ṣe èrò ìmọ̀lára. Ẹ wo bí ọ̀pọ̀ ti kó wọnú ìwà pálapàla tó nítorí pé wọ́n jẹ́ kí ìmọ̀lára darí ìwà wọn! Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé a óò tẹ èrò ìmọ̀lára wa rì; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, báwo ni à bá ṣe lè fi ìdùnnú hàn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà? Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá fẹ́ mú èso tẹ̀mí jáde dípò àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara, nígbà náà a gbọ́dọ̀ mú kí èrò inú wá bá ọ̀nà ìrònú Kristi mu.—Gálátíà 5:22, 23; Fílípì 2:5.

Ìgbésí Ayé Mímọ́, Iye Owó Mímọ́

5. Èé ṣe tí àìní fún ìjẹ́mímọ́ fi jẹ Pétérù lọ́kàn?

5 Èé ṣe tí ìjẹ́mímọ́ Kristẹni fi jẹ Pétérù lọ́kàn tó bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó mọ iye owó mímọ́ tí a ti san láti ra aráyé onígbọràn padà. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀yín mọ̀ pé kì í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí ó lè díbàjẹ́, pẹ̀lú fàdákà tàbí wúrà, ni a fi dá yín nídè kúrò nínú irú ọ̀nà ètò ìwà yín aláìléso tí ẹ gbà nípasẹ̀ òfin àtọwọ́dọ́wọ́ láti ọwọ́ àwọn bàbá ńlá yín. Ṣùgbọ́n ó jẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí, àní ti Kristi.” (Pétérù Kìíní 1:18, 19) Bẹ́ẹ̀ ni, Orísun ìjẹ́mímọ́, Jèhófà Ọlọ́run, ti rán Ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo rẹ̀, “Ẹni Mímọ́,” wá sí ilẹ̀ ayé láti san ìràpadà tí yóò jẹ́ kí àwọn ènìyàn lè ní ipò ìbátan rere pẹ̀lú Ọlọ́run.—Jòhánù 3:16; 6:69; Ẹ́kísódù 28:36; Mátíù 20:28.

6. (a) Èé ṣe tí kò fi rọrùn fún wa láti lépa ìwà mímọ́? (b) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìwà wa wà ní mímọ́?

6 Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti mọ̀ pé kò rọrùn láti gbé ìgbésí ayé mímọ́ nígbà tí a wà nínú ayé Sátánì tí ó díbàjẹ́. Ó ń dẹkùn sílẹ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́, tí wọ́n ń gbìyànjú láti máa bá a yí nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan rẹ̀. (Éfésù 6:12; Tímótì Kìíní 6:9, 10) Pákáǹleke iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ti àtakò ìdílé, ti ìfiniṣẹlẹ́yà ní ilé ẹ̀kọ́, àti ti agbára ìdarí látọ̀dọ̀ ojúgbà ń mú kí níní ipò tẹ̀mí tí ó lágbára ṣe pàtàkì fún ẹnì kan láti pa ìjẹ́mímọ́ mọ́. Ìyẹ́n tẹnu mọ́ ipa ṣíṣe kókó tí ìdákẹ́kọ̀ọ́ ara ẹni wa àti lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni wa déédéé ń kó. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé: “Máa di àpẹẹrẹ àwòṣe àwọn ọ̀rọ̀ afúnninílera mú tí ìwọ́ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ó wà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (Tímótì Kejì 1:13) A ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ afúnninílera wọ̀nyẹn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ nínú ìwà wa lójoojúmọ́ nínú ọ̀pọ̀ onírúurú ipò.

Ìwà Mímọ́ Nínú Ìdílé

7. Báwo ni ó ṣe yẹ kí ìjẹ́mímọ́ nípa lórí ìgbésí ayé ìdílé wa?

7 Nígbà tí Pétérù ṣàyọlò Léfítíkù 11:44, ó lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, haʹgi·os, tí ó túmọ̀ sí, “yà sọ́tọ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì tipa bẹ́ẹ̀, yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀.” (An Expository Dictionary of New Testament Words, láti ọwọ́ W. E. Vine) Báwo ni ó ṣe yẹ kí èyí nípa lórí wa nínú ìgbésí ayé ìdílé Kristẹni wa? Dájúdájú, ó gbọ́dọ̀ túmọ̀ sí pé a ní láti gbé ìgbésí ayé ìdílé wa karí ìfẹ́, nítorí “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (Jòhánù Kìíní 4:8) Ìfẹ́ onífara-ẹni-rúbọ ni ohun tí ń mú kí ipò ìbátan láàárín tọkọtaya àti láàárín òbí àti àwọn ọmọ dán mọ́rán.—Kọ́ríńtì Kìíní 13:4-8; Éfésù 5:28, 29, 33; 6:4; Kólósè 3:18, 21.

8, 9. (a) Nígbà míràn, kí ni ipò tí ó máa ń dìde láàárín ilé Kristẹni? (b) Ìmọ̀ràn yíyè kooro wo ni Bíbélì fúnni lórí ọ̀ràn yìí?

8 A lè ronú pé fífi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn yóò ṣàdéédéé wá nínú ìdílé Kristẹni ni. Síbẹ̀, a ní láti gbà pé ìfẹ́ kì í fi ìgbà gbogbo jọba dé ìwọ̀n tí ó yẹ nínú àwọn ilé Kristẹni kan. Ó lè dà bíi pé a ń fi ìfẹ́ náà hàn nígbà tí a bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣùgbọ́n ẹ wo bí ó ti rọrùn tó fún ìjẹ́mímọ́ wa láti jó rẹ̀yìn nínú ilé. Nígbà náà, lójijì a lè gbàgbé pé aya náà ṣì jẹ́ Kristẹni arábìnrin wa síbẹ̀ tàbí pé ọkọ náà jẹ́ arákùnrin kan náà (bóyá tí ó sì jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà) tí ó dà bíi pé a bọ̀wọ̀ fún ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. A gbaná jẹ, ìjiyàn gbígbóná janjan sì lè dìde. Àní ọ̀pá ìdiwọ̀n méjì lè rá pálá wọnú ìgbésí ayé wa. Kì í ṣe ipò ìbátan ọkọ àti aya bíi ti Kristi mọ́, bí kò ṣe ipò ìbátan ọkùnrin kan àti obìnrin kan ṣáá, tí wọ́n jọ tẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan náà. Wọ́n gbàgbé pé àyíká ipò tí ó jẹ́ mímọ́ ní láti wà nínú ilé. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ bí àwọn ènìyàn ayé. Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó nígbà náà pé kí ọ̀rọ̀ rírùn, tí ń gúnni bẹ̀rẹ̀ sí í ti ẹnu jáde!—Òwe 12:18; fi wé Ìṣe 15:37-39.

9 Bí ó ti wù kí ó rí, Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn pé: “Kí àsọjáde jíjẹrà [Gíríìkì, loʹgos sa·prosʹ, “èdè tí ń sọni di ẹlẹ́gbin,” tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláìmọ́] má ṣe ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní náà bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” Ìyẹ́n sì tọ́ka sí gbogbo àwọn olùgbọ́ nínú ilé, títí kan àwọn ọmọ.—Éfésù 4:29; Jákọ́bù 3:8-10.

10. Báwo ni ìmọ̀ràn lórí ìjẹ́mímọ́ ṣe kan àwọn ọmọ?

10 Wàyí o, ìlànà yìí lórí ìjẹ́mímọ́ kan àwọn ọmọ pẹ̀lú nínú ìdílé Kristẹni. Ẹ wo bí ó ti rọrùn fún wọn tó láti ti ilé ẹ̀kọ́ dé, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ̀tẹ̀ àti aláìlọ́wọ̀ tí àwọn ojúgbà wọn nínú ayé ń sọ! Ẹ̀yin ọmọ, ẹ má ṣe tẹ̀ síhà ìṣarasíhùwà tí àwọn ọmọdékùnrin aláìlẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ṣè àfojúdi sí wòlíì Jèhófà fi hàn, tí àwọn ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú, asọ̀rọ̀ òdì bá dọ́gba lónìí. (Àwọn Ọba Kejì 2:23, 24) Má ṣe jẹ́ kí èdè àwọn ọmọọ̀ta tí wọ́n ya òkú ọ̀lẹ tàbí tí wọn kò bìkítà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò fi lè lo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bójú mu, sọ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ di ẹlẹ́gbin. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ọ̀rọ̀ ẹnu wá gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, tí ó lárinrin, tí ń gbéni ró, tí ó jẹ́ onínúure, tí a sì “fi iyọ̀ dùn.” Ó gbọ́dọ̀ fi wá hàn yàtọ̀ sí àwọn ènìyàn míràn.—Kólósè 3:8-10; 4:6.

Ìjẹ́mímọ́ àti Àwọn Mẹ́ḿbà Ìdílé Wa Tí Wọ́n Jẹ́ Aláìgbàgbọ́

11. Èé ṣe tí jíjẹ́ mímọ́ kò fi túmọ̀ sí jíjẹ́ olódodo lójú ara ẹni?

11 Bí a ti ń fi tọkàntọkàn gbìyànjú láti fi ìjẹ́mímọ́ ṣèwàhù, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ó lẹ́mìí ìlọ́lájù, a kò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ olódodo lójú ara wa, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń bá àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ lò. Ìwà onínúure ti Kristẹni wa yẹ kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́, ó kéré tán, láti rí i pé a yàtọ̀ lọ́nà tí ń ṣàǹfààní, pé a mọ bí a ti í fi ìfẹ́ àti ìyọ́nú hàn, àní gẹ́gẹ́ bí ará Samáríà rere ti inú àkàwé Jésù ti ṣe.—Lúùkù 10:30-37.

12. Báwo ni àwọn Kristẹni ọkọ tàbí aya ṣe lè mú kí òtítọ́ túbọ̀ fa alábàáṣègbéyàwó wọn mọ́ra?

12 Pétérù tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìṣarasíhùwà yíyẹ sí àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wa tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́, nígbà tí ó kọ̀wé sí àwọn Kristẹni aya pé: “Ní irú ọ̀nà kan náà, ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó baà lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí jíjẹ́ tí wọ́n ti jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” Kristẹni aya (tàbí ọkọ pàápàá) lè mú kí òtítọ́ túbọ̀ fa alábàáṣègbéyàwó kan tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́ra, bí ìwà rẹ̀ bá mọ́, tí ó jẹ́ olùgbatẹnirò, tí ó sì ń bọ̀wọ̀ fúnni. Èyí túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ mọwọ́ yí padà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìṣàkóso Ọlọ́run, kí ó má baà ṣàìnáání alábàáṣègbéyàwó náà tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́ tàbí pa á tì.a—Pétérù Kìíní 3:1, 2.

13. Báwo ni àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà míràn ṣe lè ran àwọn aláìgbàgbọ́ ọkọ lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́?

13 Àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lè ṣèrànwọ́ nígbà míràn nípa dídojúlùmọ̀ aláìgbàgbọ́ ọkọ náà nípa jíjẹ́ ẹni tí ń kóni mọ́ra. Lọ́nà yìí, ó lè rí i pé ẹ̀dá bíi ti àwọn ènìyàn yòókù ni àwọn Ẹlẹ́rìí, wọ́n yááyì, wọ́n sì ní ọkàn ìfẹ́ nínú ọ̀pọ̀ nǹkan, títí kan àwọn ọ̀ràn tí kò jẹ mọ́ Bíbélì. Nínú ọ̀ràn kan, alàgbà kan fi ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú iṣẹ́ ẹja pípa tí ọkọ kan ń ṣe. Ó ti tó láti fa ojú rẹ̀ mọ́ra. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ọkọ yẹn di arákùnrin tí a batisí. Nínú ọ̀ràn míràn, aláìgbàgbọ́ ọkọ kan ní ọkàn-ìfẹ́ nínú ẹyẹ canary. Àwọn alàgbà kò jẹ́ kó sú wọn. Ọ̀kan nínú wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹyẹ náà kí ó baà lè jẹ́ pé nígbà míràn tí ó bá pàdé ọkùnrin náà, yóò lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lórí ohun ọ̀sìn tí ọkọ yẹn fẹ́ràn jù lọ! Nígbà náà, láti jẹ́ mímọ́ kò túmọ̀ sí jíjẹ́ aláìlè-tẹ̀-síhìn-ín-sọ́hùn-ún tàbí jíjẹ́ olójú ìwòye kan ṣoṣo.—Kọ́ríńtì Kìíní 9:20-23.

Báwo Ni A Ṣe Lè Jẹ́ Mímọ́ Nínú Ìjọ?

14. (a) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì fi ń jin ìjọ lẹ́sẹ̀? (b) Báwo ni a ṣe lè dènà ìdẹkùn Sátánì?

14 Sátánì Èṣù jẹ́ abanijẹ́, nítorí pé orúkọ Gíríìkì fún Èṣù, di·aʹbo·los, túmọ̀ sí “afẹ̀sùnkanni” tàbí “abanijẹ́.” Ìbanijẹ́ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn iṣẹ́ tí ó mọ̀ dunjú, ó sì ń gbìyànjú láti lò ó nínú ìjọ. Òfófó ni ọ̀nà tí ó fẹ́ràn jù lọ. Àwá ha ń jẹ́ kí ó tàn wá jẹ́ sínú ìwà àìmọ́ yìí bí? Báwo ni ìyẹ́n ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Nípa dídá òfófó sílẹ̀, nípa sísọ ọ́ fún ẹlòmíràn, tàbí nípa fífetí sí i. Òwe ọlọgbọ́n sọ pé: “Onírìkíṣí ènìyàn máa ń dá asọ̀ sílẹ̀, abanijẹ́ sì máa ń ya àwọn ojúlùmọ̀ nípa.” (Òwe 16:28, NW) Kí ni ẹ̀rọ̀ òfófó àti ìbanijẹ́? A gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ọ̀rọ̀ ẹnu wá máa ń gbéni ró nígbà gbogbo, kí a sì gbé e karí ìfẹ́. Bí a bá n wo ìwà funfun ti àwọn ará wa, dípò ìwà abèṣe ti a rò pé wọ́n ní, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wa yóò gbádùn mọ́ni, yóò sì jẹ́ tẹ̀mí. Rántí pé ṣíṣe lámèyítọ́ rọrùn. Ẹni tí ó sì ń ṣòfófó fún ọ nípa àwọn ẹlòmíràn lè ṣòfófó fún àwọn ẹlòmíràn nípa rẹ pẹ̀lú!—Tímótì Kìíní 5:13; Títù 2:3.

15. Kí ni àwọn ànímọ́ bíi ti Kristi tí yóò ṣèrànwọ́ láti mú kí gbogbo àwọn tí ń bẹ nínú ìjọ wà ní mímọ́?

15 Láti mú kí ìjọ wà ní mímọ́, gbogbo wá ní láti ní èrò inú Kristi, a sì mọ̀ pé ìfẹ́ ni olórí ànímọ́ rẹ̀. Nípa báyìí, Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Kólósè nímọ̀ràn láti ní ìyọ́nú gẹ́gẹ́ bíi Kristi pé: “Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ . . . , ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kíní kejì . . . Yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.” Lẹ́yìn náà, ó fi kún un pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ jẹ́ kí àlàáfíà Kristi máa ṣàkóso nínú ọkàn-àyà yín.” Dájúdájú, pẹ̀lú ẹ̀mí ìdáríjì yìí, a lè pa ìṣọ̀kan àti ìjẹ́mímọ́ ìjọ mọ́.—Kólósè 3:12-15.

Ìjẹ́mímọ́ Wa Ha Ń Fara Hàn Ní Àdúgbò Wa Bí?

16. Èé ṣe tí ìjọsìn mímọ́ wa fi ní láti jẹ́ ìjọsìn aláyọ̀?

16 Àwọn aládùúgbò wa ńkọ́? Ojú wo ni wọ́n fi ń wò wá? Àwá ha ń jẹ́ kí ìdùnnú òtítọ́ hàn lójú wa, tàbí a ha jẹ́ kí ó dà bí ẹrù wíwúwo bí? Bí a bá jẹ́ mímọ́ àní bí Jèhófà ti jẹ́ mímọ́, nígbà náà ó yẹ kí ó hàn gbangba nínú ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa. Ó yẹ kí ó ṣe kedere pé ìjọsìn mímọ́ wá jẹ́ ìjọsìn aláyọ̀. Èé ṣe tí ìyẹ́n fi yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ Ọlọ́run aláyọ̀, tí ń fẹ́ kí àwọn olùjọsìn rẹ̀ jẹ́ onídùnnú. Nípa báyìí, onísáàmù lè sọ nípa àwọn ènìyàn Jèhófà ní ìgbàanì pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn náà tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!” Àwá ha ń jẹ́ kí ayọ̀ yẹn hàn lójú wa bí? Àwọn ọmọ wa pẹ̀lú ha ń fi ìtẹ́lọ́rùn hàn nínú wíwà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àti ní àwọn àpéjọ bí?—Orin Dáfídì 89:15, 16; 144:15b, NW.

17. Kí ni a lè ṣe lọ́nà gbígbéṣẹ́ láti fi ìjẹ́mímọ́ wíwà déédéé hàn?

17 A tún lè fi ìjẹ́mímọ́ wa tí ó wà déédéé hàn nípasẹ̀ ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa àti jíjẹ́ onínú rere ládùúgbò. Nígbà míràn, ó máa ń pọn dandan fún àwọn aládùúgbò láti fọwọ́sowọ́pọ̀, bóyá láti mú kí àdúgbò wà ní mímọ́ tónítóní tàbí, bí ó ti máa ń rí ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, láti ṣèrànwọ́ láti mú kí ọ̀nà tàbí òpópónà sunwọ̀n sí i. Nípa báyìí, ìjẹ́mímọ́ wa lè fara hàn nínú bí a ti ń bójú tó ọgbà wa, àgbàlá wa, tàbí àwọn ohun ìní mìíràn. Bí pàǹtí bá wà nílẹ̀ káàkiri, tàbí bí àgbàlá wa bá dọ̀tí tàbí tí ó rí wúruwùru, bóyá tí àwókù ọkọ̀ wà níbẹ̀ tí àwọn èrò tí ń lọ, tí ń bọ̀ lè máa rí, a ha lè sọ pé a ń bọ̀wọ̀ fún àwọn aládùúgbò wa bí?—Ìṣípayá 11:18.

Ìjẹ́mímọ́ ní Ibi Iṣẹ́ àti ní Ilé Ẹ̀kọ́

18. (a) Kí ni ó jẹ́ ìṣòro fún àwọn Kristẹni lónìí? (b) Báwo ni a ṣe lè yàtọ̀ sí ayé?

18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní ìlú Kọ́ríńtì tí ó jẹ́ aláìmọ́ pé: “Nínú lẹ́tà mi mo kọ̀wé sí yín pé kí ẹ jáwọ́ dídara pọ̀ nínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbèrè, kò túmọ̀ sí pẹ̀lú gbogbo àwọn àgbèrè ayé yìí pátápátá tàbí àwọn oníwọra ènìyàn àti àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà tàbí àwọn abọ̀rìṣà. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ní ti gàsíkíá yóò ní láti jáde kúrò nínú ayé.” (Kọ́ríńtì Kìíní 5:9, 10) Ìṣòro ni èyí jẹ́ fún àwọn Kristẹni, tí wọ́n gbọ́dọ̀ dara pọ̀ lójoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn oníwà pálapàla tàbí aláìníwà. Èyí jẹ́ ìdánwò ńlá ti ìwà títọ́, ní pàtàkì, nínú ẹgbẹ́ àwùjọ tí a ti ń fún ìfìbálòpọ̀-fòòró-ẹni, ìwà ìbàjẹ́, àti àbòsí níṣìírí tàbí tí a gbà á láyè. Nínú ipò yìí, a kò lè fàyè gba dídẹ àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n wa kí a baà lè fara hàn fún àwọn tí ó wà ní àyíká wa pé “ẹ̀dá bíi ti àwọn ènìyàn yòókù ni wá.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwà Kristẹni wa tí ó jẹ́ ti onínúure, ṣùgbọ́n tí ó yàtọ̀ ní láti mú wa yàtọ̀ gedegbe lójú àwọn ènìyàn onífòyemọ̀, lójú àwọn tí wọ́n gbà pé àwọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì ń wá ohun tí ó sàn jù.—Mátíù 5:3; Pétérù Kìíní 3:16, 17.

19. (a) Ìdánwò wo ni ẹ̀yin ọmọ ń ní ní ilé ẹ̀kọ́? (b) Kí ni àwọn òbí lè ṣe láti ti àwọn ọmọ wọn àti ìwà mímọ́ wọn lẹ́yìn?

19 Bákan náà, ọ̀pọ̀ ìdánwò ni àwọn ọmọ wa ń kojú ní ilé ẹ̀kọ́. Ẹ̀yin òbí ha ń ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ tí àwọn ọmọ yín ń lọ bí? Ẹ ha mọ irú àyíká ipò tí ó wà níbẹ̀ bí? Ẹ ha wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùkọ́ bí? Èé ṣe tí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí fi ṣe pàtàkì? Nítorí pé ní ọ̀pọ̀ ìlú ńlá kárí ayé, àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí di ibi tí ìwà ipá, oògùn líle, àti ìbálòpọ̀ gbalẹ̀ kan. Báwo ni àwọn ọmọ yín ṣe lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́, kí ìwà wọn sì wà ní mímọ́ bí wọn kò bá rí ẹ̀kún rẹ́rẹ́ ìtìlẹyìn onínúure àwọn òbí wọn gbà? Lọ́nà tí ó bá a mu, Pọ́ọ̀lù gba àwọn òbí nímọ̀ràn pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21) Ọ̀nà kan láti dá àwọn ọmọ lágara jẹ́ nípa kíkùnà láti lóye àwọn ìṣòro àti ìdánwò wọn ojoojúmọ́. Ìmúrasílẹ̀ fún àwọn ìdẹwò ní ilé ẹ̀kọ́ ń bẹ̀rẹ̀ láti inú àyíká ipò tẹ̀mí nínú ilé Kristẹni.—Diutarónómì 6:6-9; Òwe 22:6.

20. Èé ṣe tí ìjẹ́mímọ́ fi ṣe pàtàkì fún gbogbo wa?

20 Ní paríparí rẹ̀, èé ṣe tí ìjẹ́mímọ́ fi ṣe pàtàkì fún gbogbo wa? Ó jẹ́ nítorí pé ó jẹ́ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìkọlù ayé Sátánì àti ìrònú rẹ̀. Ó jẹ́ ìbùkún nísinsìnyí, yóò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la. Ó ń ṣèrànwọ́ láti mú ìyè tí yóò jẹ́ ìyè tòótọ́ nínú ayé tuntun òdodo dá wa lójú. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ Kristẹni tí ó wà déédéé, tí ó ṣeé sún mọ́, tí ó ṣeé bá sọ̀rọ̀ pọ́—kì í ṣe òǹrorò agbawèrèmẹ́sìn. Ní ṣókí, ó mú wa dà bíi Kristi.—Tímótì Kìíní 6:19.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i lórí ipò ìbátan ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ pẹ̀lú alábàáṣègbéyàwó tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́, wo Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1990, “Maṣe Ṣàìnáání Alábàáṣègbéyàwó Rẹ!” ojú ìwé 20 sí 22 àti November 1, 1988, ojú ìwé 24 àti 25, ìpínrọ̀ 20 sí 22.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Èé ṣe tí Pétérù fi rí i pé ó pọn dandan láti gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn lórí ìjẹ́mímọ́?

◻ Èé ṣe tí kò fi rọrùn láti gbé ìgbésí ayé mímọ́?

◻ Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti mú kí ìjẹ́mímọ́ sunwọ̀n sí i nínú ìdílé?

◻ Bí ìjọ yóò bá wà ní mímọ́, ìwà àìmọ́ wo ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún?

◻ Báwo ni a ṣe lè wà ní mímọ́ ní ibi iṣẹ́ àti ní ilé ẹ̀kọ́?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó yẹ kí a jẹ́ onídùnnú nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run àti nínú àwọn ìgbòkègbodò míràn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́