ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/1 ojú ìwé 10-14
  • ‘Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nítorí Èmi Jẹ́ Mímọ́’

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • ‘Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nítorí Èmi Jẹ́ Mímọ́’
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ísírẹ́lì Ṣe ní Ìsopọ̀ Pẹ̀lú Orísun Ìjẹ́mímọ́
  • Ìdí Tí Jèhófà Ṣe Fi Ísírẹ́lì Bú
  • Ọkàn-Àyà Mímọ́ Gaara Ń Ṣamọ̀nà sí Ìjọsìn Mímọ́ Gaara
  • Ìpèníjà—Láti Kojú Àwọn Àìlera Wa
  • Báwo Ni A Ṣe Lè Wà Ní Mímọ́?
  • “Kí Ẹ̀yin Fúnra Yín Di Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • “Èmi Jèhófà Ọlọ́run Yín Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/1 ojú ìwé 10-14

‘Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́ Nítorí Èmi Jẹ́ Mímọ́’

“Kí ẹ̀yin kí ó jẹ́ mímọ́: nítorí pé Èmi OLÚWA Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.” —LÉFÍTÍKÙ 19:2.

1. Àwọn díẹ̀ wo ni ayé kà sí ẹni mímọ́?

PÚPỌ̀ jù lọ nínú àwọn ìsìn pàtàkì ayé ní àwọn tí wọ́n kà sí ẹni mímọ́. A sábà máa ń ka Ìyá Teresa obìnrin olókìkí ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ní Íńdíà sí ẹni mímọ́ nítorí ẹ̀mí ìfarajìn onífara-ẹni-rúbọ tí ó ní fún àwọn tálákà. A pe póòpù ní “Bàbá Mímọ́.” Àwọn onísìn Kátólíìkì kan ka olùdásílẹ̀ àjọ ìgbòkègbodò Kátólíìkì òde òní, Opus Dei, José María Escrivá, sí “àwòṣe fún ìjẹ́mímọ́.” Ìsìn Híńdù ní àwọn olùkọ́ ìsìn, tàbí àwọn ẹni mímọ́ tirẹ̀. A bọ̀wọ̀ fún Gandhi gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́. Ìsìn Búdà ní àwọn ọkùnrin mímọ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé tirẹ̀, ìsìn Ìsìláàmù sì ní wòlíì mímọ́ tirẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni ó túmọ̀ sí gan-an láti jẹ́ mímọ́?

2, 3. (a) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ náà, “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́,” túmọ̀ sí? (b) Àwọn ìbéèrè díẹ̀ wo ni ó yẹ láti dáhùn?

2 Ọ̀rọ̀ náà, “mímọ́,” ni a túmọ̀ sí níní “1. . . . ìsopọ̀ pẹ̀lú agbára àtọ̀runwá; jíjẹ́ ẹni mímọ́ ọlọ́wọ̀. 2. Ẹni tí a kà sí jíjọ́sìn tàbí jíjúbà fún tàbí ẹni tí a rò pé ó yẹ ní jíjọ́sìn tàbí jíjúbà fún . . . 3. Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ètò ìgbékalẹ̀ ìsìn tàbí ètò ìgbékalẹ̀ tẹ̀mí tí ó ní ìlànà ìwà rere gíga tàbí tí kò gba gbẹ̀rẹ́ . . . 4. Ohun tí a tọ́ka sí tàbí tí a yà sọ́tọ̀ fún ète ti ìsìn.” Nínú àyíká ọ̀rọ̀ Bíbélì, ìjẹ́mímọ́ túmọ̀ sí “mímọ́ tónítóní tàbí àìlábàwọ́n ní ti ìsìn; ìjẹ́mímọ́ ọlọ́wọ̀.” Ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ìtọ́kasí náà, Insight on the Scriptures, “[ọ̀rọ̀] Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, qoʹdhesh, gbé èrò ìyàsọ́tọ̀, ìyàsọ́tọ̀ gédégbé, tàbí ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run, . . . ipò ìyàsọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run yọ.”a

3 A pàṣẹ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti jẹ́ mímọ́. Òfin Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín: nítorí náà ni kí ẹ̀yin kí ó ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ́ mímọ́; nítorí pé mímọ́ ni Èmi.” Ta ni Orísun ìjẹ́mímọ́? Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìpé ṣe lè jẹ́ mímọ́? Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo sì ni a lè rí kọ́ fún ara wa lónìí nínú ìpè Jèhófà fún ìjẹ́mímọ́?—Léfítíkù 11:44.

Bí Ísírẹ́lì Ṣe ní Ìsopọ̀ Pẹ̀lú Orísun Ìjẹ́mímọ́

4. Báwo ni a ṣe fi àpẹẹrẹ ìjẹ́mímọ́ Jèhófà hàn ní Ísírẹ́lì?

4 Gbogbo ohun tí ó ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìjọsìn Ísírẹ́lì sí Jèhófà Ọlọ́run ní a gbọ́dọ̀ kà sí mímọ́, kí a sì lò ó lọ́nà bẹ́ẹ̀. Èé ṣe ti ìyẹ́n fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti orísun ìjẹ́mímọ́. Ìròyìn Mósè nípa kíkọ́ àgọ́ mímọ́ àti fífi aṣọ bò ó àti ṣíṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ parí pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Wọ́n sì ṣe àwo adé mímọ́ náà ní kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, ìkọ̀wé bíi fífín èdìdì àmì, MÍMỌ́ SÍ OLÚWA.” A lẹ àwo tí ń dán yinrin yìí mọ ara láwàní àlùfáà àgbà, èyí sì ń fi hàn pé a yà á sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn tí ó ní ìjẹ́mímọ́ àrà ọ̀tọ̀. Bí wọ́n ti ń rí àmì tí a lẹ̀ yìí tí ń kọ mọ̀nà nínú ìmọ́lẹ̀ oòrùn, a ń rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí nípa ìjẹ́mímọ́ Jèhófà.—Ẹ́kísódù 28:36; 29:6; 39:30.

5. Báwo ní a ṣe lè ka àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìpé sí mímọ́?

5 Ṣùgbọ́n báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè di mímọ́? Kìkì nípa ipò ìbátan tímọ́tímọ́ wọn pẹ̀lú Jèhófà àti ìjọsìn mímọ́ gaara wọn sí i ni. Wọ́n nílò ìmọ̀ pípéye nípa “Ẹni Mímọ́ Jù Lọ” kí wọ́n baà lè jọ́sìn rẹ̀ ní ìjẹ́mímọ́, ní mímọ́ tónítóní ní ti ara àti ní ti ẹ̀mí. (Òwe 2:1-6; 9:10, NW) Nítorí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti jọ́sìn Ọlọ́run pẹ̀lú ojúlówó ìsúnniṣe àti ọkàn-àyà mímọ́ gaara. Ìjọsìn alágàbàgebè èyíkéyìí yóò kó Jèhófà nírìíra.—Òwe 21:27.

Ìdí Tí Jèhófà Ṣe Fi Ísírẹ́lì Bú

6. Báwo ni àwọn Júù ní ọjọ́ Málákì ṣe lo tábìlì Jèhófà?

6 Irú ìjọsìn akóninírìíra bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn kedere nígbà tí wọ́n fi àìnífẹ̀ẹ́ ọkàn mú gbàrọgùdù ẹbọ, tí ó lábùkù wá sí tẹ́ḿpìlì. Nípasẹ̀ wòlíì rẹ̀, Málákì, Jèhófà fi àwọn ìrúbọ gbàrọgùdù wọn bú pé: “Èmi kò ní inú dídùn sí i yín, ni Olúwa àwọn ọmọ ogún wí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò gba ọrẹ kan lọ́wọ́ yín. . . . Nítorí ẹ̀yín ti sọ ọ́ di àìmọ́, nínú èyí tí ẹ wí pé, Tábìlì Olúwa di àìmọ́; àti èso rẹ̀, àní oúnjẹ rẹ̀ ni ohun ẹ̀gàn. Ẹ̀yín wí pẹ̀lú pé, Wò ó agara kí ni èyí! ẹ̀yín ṣítìímú sí i, ni Olúwa àwọn ọmọ ogún wí; ẹ̀yín sì mú èyí tí ó ya, àti arọ, àti olókùnrùn wá; báyìí ni ẹ̀yín mú ọrẹ wá: èmi óò ha gba èyí lọ́wọ́ yín? ni Olúwa wí.”—Málákì 1:10, 12, 13.

7. Àwọn ìgbésẹ̀ àìmọ́ wo ni àwọn Júù gbé ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa?

7 Ọlọ́run lo Málákì láti fi àṣà èké àwọn Júù bú, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn àlùfáà ń fi àpẹẹrẹ búburú lélẹ̀, ìwà wọn kò sì jẹ́ mímọ́ lọ́nàkọnà. Ní títẹ̀ lé ipò aṣáájú yẹn, àwọn ènìyàn náà gba gbẹ̀rẹ́ nínú ìlànà wọn, àní débi kíkọ àwọn ìyàwó wọn pàápàá sílẹ̀, nítorí kí wọ́n baà lè fẹ́ àwọn ọmọge abọ̀rìṣà láya. Málákì kọ̀wé pé: “Olúwa ti ṣe ẹlẹ́rìí láàárín ìwọ àti láàárín aya èwe rẹ, ẹni tí ìwọ́ ti ń hùwà ẹ̀tànb sí: bẹ́ẹ̀ ni ẹgbẹ́ rẹ ni òún sáà ń ṣe, àti aya májẹ̀mú rẹ. . . . Ẹ tọ́jú ẹ̀mí yín, kí ẹ má sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni hùwà ẹ̀tàn sí aya èwe rẹ̀. Nítorí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, òún kórìíra ìkọ̀sílẹ̀.”—Málákì 2:14-16.

8. Báwo ni ojú ìwòye òde òní nípa ìkọ̀sílẹ̀ ti ṣe nípa lórí àwọn kan nínú ìjọ Kristẹni?

8 Lóde òní, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ìkọ̀sílẹ̀ ti ṣeé ṣe lọ́nà rírọrùn, iye ìkọ̀sílẹ̀ ti ròkè lálá. Àní, ó ti nípa lórí ìjọ Kristẹni pàápàá. Dípò wíwá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà láti ṣẹ́pá àwọn ohun ìdènà, kí wọ́n sì gbìyànjú láti mú kí ìgbéyàwó wọ́n yọrí sí rere, àwọn kan ti tètè kọ alábàáṣègbéyàwó wọn sílẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, a fi àwọn ọmọ sílẹ̀ láti jìyà èrò ìmọ̀lára lọ́nà gíga.—Mátíù 19:8, 9.

9, 10. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a ronú nípa ìjọsìn wa sí Jèhófà?

9 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i lókè, lójú ìwòye ipò tẹ̀mí bíbani nínú jẹ́ ní ọjọ́ Málákì, Jèhófà láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, dẹ́bi fún ìjọsìn Júdà tí ó jẹ́ oréfèé, ó sì fi hàn pé òun yóò tẹ́wọ́ gba ìjọsìn mímọ́ gaara nìkan ṣoṣo. Kò ha yẹ kí èyí mú wa ronú nípa ìjójúlówó ìjọsìn wa sí Jèhófà Ọlọ́run, Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé, Orísun ìjẹ́mímọ́ tòótọ́ bí? Àwá ha ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Ọlọ́run ní tòótọ́ bí? Àwá ha pa ara wa mọ́ ní ipò tẹ̀mí tí ó mọ́ tónítóní bí?

10 Èyí kò túmọ̀ sí pé a ní láti jẹ́ pípé, èyí tí kò ṣeé ṣe, tàbí pé a ní láti fi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn. Ṣùgbọ́n, ó túmọ̀ sí pé Kristẹni kọ̀ọ̀kán ní láti jọ́sìn Ọlọ́run dé gbogbo ibi tí agbára rẹ̀ mọ, ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò olúkúlùkù. Èyí ń tọ́ka sí ìjójúlówó ìjọsìn wa. Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ wa ní láti jẹ́ gbogbo èyí tí a lè ṣe—iṣẹ́ ìsìn mímọ́. Báwo ní a ṣe lè ṣàṣeparí ìyẹn?—Lúùkù 16:10; Gálátíà 6:3, 4.

Ọkàn-Àyà Mímọ́ Gaara Ń Ṣamọ̀nà sí Ìjọsìn Mímọ́ Gaara

11, 12. Níbo ni ìwà àìmọ́ ti ń bẹ̀rẹ̀?

11 Jésù kọ́ni ní kedere pé, ohun tí ẹnì kán bá sọ, tí ó sì ṣe yóò fi ohun tí ó wà nínú ọkàn-àyà rẹ̀ hàn gbangba. Jésù sọ fún àwọn Farisí olódodo lójú ara wọn, síbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ pé: “Ẹ̀yin àmújáde ọmọ paramọ́lẹ̀, báwo ni ẹ̀yín ṣe lè sọ àwọn ohun rere, nígbà tí ẹ jẹ́ ẹni burúkú? Nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” Lẹ́yìn náà, ó fi hàn pé ìwà búburú ń bẹ̀rẹ̀ láti inú èrò búburú tí ó wà nínú ọkàn-àyà, tàbí ẹni inú lọ́hùn-ún. Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ń jáde láti ẹnu jáde wá láti inú ọkàn-àyà, àwọn ohun wọnnì sì ní ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin. Fún àpẹẹrẹ, láti inú ọkàn-àyà ni àwọn ìgbèrò burúkú ti ń wá, ìṣìkàpànìyàn, panṣágà, àgbèrè, olè jíjà, àwọn èké gbólóhùn ẹ̀rí, àwọn ọ̀rọ̀ òdì. Ìwọ̀nyí ni àwọn ohun tí ń sọ ènìyàn di ẹlẹ́gbin.”—Mátíù 12:34; 15:18-20.

12 Èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìgbésẹ̀ àìmọ́ kì í ṣàdéédéé wáyé tàbí ṣẹlẹ̀ láìnídìí. Wọ́n jẹ́ ìyọrísí èrò tí ń sọni di ẹlẹ́gbin tí ó ti fara sin nínú ọkàn-àyà—ìfẹ́ ọkàn ìkọ̀kọ̀, ó sì lè jẹ́ ìfọkànyàwòrán. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lè sọ pé: “Ẹ̀yín gbọ́ pé a wí i pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Lọ́nà míràn, àgbèrè àti panṣágà ti ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà ṣáájú kí ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tó wáyé. Lẹ́yìn náà, nígbà tí àyíká ipò bá fàyè gbà á, èrò àìmọ́ yóò di ìwà àìmọ́. Àgbèrè, panṣágà, ìbálòpọ̀ tí a gbé gbòdì, olè jíjà, ọ̀rọ̀ òdì, àti ìpẹ̀yìndà di ìyọrísí tí ó hàn kedere.—Mátíù 5:27, 28; Gálátíà 5:19-21.

13. Kí ni àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nípa bí èrò àìmọ́ ṣe lè yọrí sí ìgbésẹ̀ àìmọ́?

13 A lè ṣàpèjúwe èyí ní onírúurú ọ̀nà. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ilé tẹ́tẹ́ ń pọ̀ sí i bíi bàbà èṣùá, ní títipa báyìí mú àǹfààní títa tẹ́tẹ́ pọ̀ sí i. A lè dẹni wò láti yíjú sí ohun tí ó dà bí ojútùú yìí láti yanjú ìṣòro ìṣúnná owó ẹni. Ìrònú tí ń tanni jẹ́ lè sún arákùnrin kan láti kọ àwọn ìlànà rẹ̀ tí ó gbé karí Bíbélì sílẹ̀ tàbí láti ṣàbùlà wọn.c Nínú ọ̀ràn míràn, níní àwòrán arùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lárọ̀ọ́wọ́tó, bóyá nípasẹ̀ tẹlifíṣọ̀n, fídíò, kọ̀m̀pútà, tàbí ìwé, lè sún Kristẹni kan sínú ìwà àìmọ́. Kìkì ohun tí yóò ṣe ni kí ó ṣàìnáání ìhámọ́ra rẹ̀ nípa tẹ̀mí, kí ó sì tó ṣẹ́jú pẹ́, yóò ti ṣubú sínú ìwà pálapàla. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀ràn tí ó pọ̀ jù lọ, yíyọ̀ tẹ̀rẹ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ láti inú èrò inú. Bẹ́ẹ̀ ni, nínú irú ipò bí ìwọ̀nyí, ọ̀rọ̀ Jákọ́bù ní ìmúṣẹ pé: “Olúkúlùkù ni a ń dán wò nípa fífà á jáde àti ríré e lọ láti ọwọ́ ìfẹ́ ọkàn òun fúnra rẹ̀. Lẹ́yìn náà ìfẹ́ ọkàn náà, nígbà tí ó bá ti lóyún, a bí ẹ̀ṣẹ̀.”—Jákọ́bù 1:14, 15; Éfésù 6:11-18.

14. Báwo ni ọ̀pọ̀ ti ṣe kọ́fẹ padà láti inú ìwà àìmọ́ wọn?

14 Ó múni láyọ̀ pé, ọ̀pọ̀ Kristẹni tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ láìmọ̀-ọ́nmọ̀ fi ìrònúpìwàdà tòótọ́ hàn, ó sì ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà láti mú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Àní lẹ́yìn-ọ-rẹyìn, orí ọ̀pọ̀ tí a yọ lẹ́gbẹ́ nítorí àìronúpìwàdà wálé, a sì gbà wọ́n padà sínú ìjọ. Wọ́n wá mọ bí Sátánì ṣe fi tìrọ̀rùntìrọ̀rùn borí wọn nígbà tí wọ́n gba èrò àìmọ́ láyè láti ta gbòǹgbò nínú ọkàn-àyà wọn.—Gálátíà 6:1; Tímótì Kejì 2:24-26; Pétérù Kìíní 5:8, 9.

Ìpèníjà—Láti Kojú Àwọn Àìlera Wa

15. (a) Èé ṣe tí a fi gbọ́dọ̀ kojú àwọn àìlera wa? (b) Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn àìlera wa ní àmọ̀jẹ́wọ́?

15 A gbọ́dọ̀ sapá láti mọ ohun tí ọkàn-àyà wá jẹ́ ní tòótọ́. Àwá ha múra tán láti kojú àwọn àìlera wa, kí a gbà pé a ní wọn, lẹ́yìn náà kí a ṣiṣẹ́ láti ṣẹ́gun wọn bí? Àwá ha fẹ́ láti béèrè lọ́wọ́ aláìlábòsí ọ̀rẹ́ kan nípa bí a ṣe lè sunwọ̀n sí i, lẹ́yìn náà, kí a sì fetí sí ìmọ̀ràn bí? Láti wà ní mímọ́, a gbọ́dọ̀ ṣẹ́pá àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wa. Èé ṣe? Nítorí pé Sátánì mọ àìlera wa. Yóò lo àwọn ọgbọ́n àyínìke ètekéte rẹ̀ láti fà wá sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà àìmọ́. Nípasẹ̀ ìwà àrékérekè rẹ̀, ó ń gbìyànjú láti yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kí a má baà wà ní mímọ́, kí a sì wúlò fún ìjọsìn Jèhófà mọ́.—Jeremáyà 17:9; Éfésù 6:11; Jákọ́bù 1:19.

16. Àwọn òfin wo ni ó ń forí gbárí nínú Pọ́ọ̀lù?

16 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní àdánwò àti ìdánwò tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́rìí sí i nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Róòmù pé: “Mo mọ̀ pé nínú mi, èyíinì ni, nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀; nítorí agbára ìlèdàníyàn wà pẹ̀lú mi, ṣùgbọ́n agbára ìlèṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ kò sí. Nítorí rere tí mo dàníyàn ni èmi kò ṣe, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò dàníyàn ni èmí fi ń ṣèwàhù. . . . Ní ti gidi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí nínú àwọn ẹ̀yà ara mi òfin mìíràn tí ń bá òfin èrò inú mi jagun tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.”—Róòmù 7:18-23.

17. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe jagunmólú nínú ìjàkadì rẹ̀ pẹ̀lú àìlera?

17 Wàyí o, kókó pàtàkì nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé ó gbà pé òún ní àìlera. Bí ó tilẹ̀ gbà pé òún ní wọn, ó lè sọ pé: “Ní ti gidi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni [tẹ̀mí] tí mo jẹ́ ní inú.” Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ ohun rere, ó sì kórìíra ohun búburú. Síbẹ̀ ó ṣì ní ìjà láti jà, ìjà kan náà tí gbogbo wa ní láti jà—lòdì sí Sátánì, ayé, àti ẹran ara. Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè ṣẹ́gun nínú ìjà náà láti wà ní mímọ́, ní yíya ara wa sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí àti ìrònú rẹ̀?—Kọ́ríńtì Kejì 4:4; Éfésù 6:12.

Báwo Ni A Ṣe Lè Wà Ní Mímọ́?

18. Báwo ni a ṣe lè wà ní mímọ́?

18 Ọwọ́ ẹni kì í tẹ ìjẹ́mímọ́ nípa gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ tàbí kíkẹ́ ara ẹni bàjẹ́. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóò máa wí àwíjàre nítorí ìwà rẹ̀ ṣáá ni, yóò sì gbìyànjú láti gbé ẹ̀bi rẹ̀ ka ibòmíràn. Bóyá a nílò láti kọ́ bí a ti í jíhìn fún ìgbésẹ̀ ẹni, kí a má sì ṣe dà bí àwọn kan tí wọ́n ń ṣàwáwí pé ilẹ̀ lẹrù amúkùn-ún àwọ́n ti wọ́ wá nítorí ipò àtilẹ̀wá ìdílé tàbí apilẹ̀ àbùdá. Gbòǹgbò ọ̀ràn náà ń bẹ nínú ọkàn-àyà olúkúlùkù. Òún ha nífẹ̀ẹ́ òdodo bí? Ó ha ń yán hànhàn fún ìjẹ́mímọ́ bí? Ó ha fẹ́ ìbùkún Ọlọ́run bí? Onísáàmù mú àìní fún ìjẹ́mímọ́ ṣe kedere nígbà tí ó sọ pé: “Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere; máa wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ yín wà láìsí àgàbàgebè. Ẹ fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú, ẹ dìrọ̀ mọ́ ohun rere.”—Orin Dáfídì 34:14; 97:10; Róòmù 12:9.

19, 20. (a) Báwo ní a ṣe lè gbé èrò inú wa ró? (b) Kí ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbéṣẹ́ ní nínú?

19 A lè “dìrọ̀ mọ́ ohun rere” bí a ba ń wo ọ̀ràn bí Jèhófà ṣe ń wò ó, tí a bá sì ní èrò inú Kristi. (Kọ́ríńtì Kìíní 2:16) Báwo ni a ṣe ń ṣàṣeparí èyí? Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣàṣàrò déédéé nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ẹ wo bí a ti ń fúnni ní ìmọ̀ràn yìí lóòrèkóòrè tó! Ṣùgbọ́n a ha ń fi ọwọ́ dan-indan-in mú un bí? Fún àpẹẹrẹ, o ha ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìròyìn yìí ní tòótọ́ bí, ní wíwo àwọn ẹsẹ Bíbélì, ṣáájú kí o tó wá sí ìpàdé bí? Bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìkẹ́kọ̀ọ́, kì í ṣe wíwulẹ̀ fàlà sábẹ́ àwọn àpólà ọ̀rọ̀ mélòó kan nínú ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan ni a ń sọ. A lè wo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan gààràgà, kí a sì fàlà sí i láàárín nǹkan bí ìṣẹ́jú 15. Ìyẹ́n ha túmọ̀ sí pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà bí? Ní ti gidi, ó lè gba wákàtí kan tàbí méjì láti kẹ́kọ̀ọ́ kí a sì gba àǹfààní tẹ̀mí tí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan ń fúnni sínú.

20 Bóyá, a ní láti ṣàkóso ara wa láti pa tẹlifíṣọ̀n tì fún wákàtí díẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí a sì pọkàn pọ̀ ní ti gidi sórí ìjẹ́mímọ́ ara ẹni wa. Ìkẹ́kọ̀ọ́ wa déédéé ń gbé wa ró nípa tẹ̀mí, ní mímú èrò inú wa ṣiṣẹ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó tọ́—àwọn ìpinnu tí ń ṣamọ̀nà sí “àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà.”—Pétérù Kejì 3:11; Éfésù 4:23; 5:15, 16.

21. Ìbéèrè wo ni ó kù láti dáhùn?

21 Ìbéèrè tí ó wà níbẹ̀ nísinsìnyí ni pé, nínú pápá ìgbòkègbodò àti ìwà míràn wo ni àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni ti lè jẹ́ mímọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti jẹ́ mímọ́? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò fọ̀rọ̀ lọ ìrònú wa.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Iṣẹ́ ìtọ́kasí onídìpọ̀ méjì yìí ní a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

b Fún àgbéyẹ̀wò tí ó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́ nípa ohun tí “ẹ̀tàn” túmọ̀ sí, wo Jí!, February 8, 1994, ojú ìwé 21, “Irú Ìkọ̀sílẹ̀ Wo Ni Ọlọrun Kórìíra?”

c Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìdí tí tẹ́tẹ́ títa fi jẹ́ ìwà àìmọ́, wo Jí!, August 8, 1994, ojú ìwé 14 àti 15, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Báwo ni a ṣe dá Orísun ìjẹ́mímọ́ mọ̀ yàtọ̀ ní Ísírẹ́lì?

◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ní ìjọsìn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jẹ́ aláìmọ́ ní ọjọ́ Málákì?

◻ Níbo ni ìwà àìmọ́ ti ń bẹ̀rẹ̀?

◻ Láti jẹ́ mímọ́, kí ni a gbọ́dọ̀ gbà pé a ní?

◻ Báwo ni a ṣe lè wà ní mímọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́