ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 7/1 ojú ìwé 9
  • “Èmi Jèhófà Ọlọ́run Yín Jẹ́ Mímọ́”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Èmi Jèhófà Ọlọ́run Yín Jẹ́ Mímọ́”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Mímọ́, Mímọ́, Mímọ́ Ni Jèhófà”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • “Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • “Kí Ẹ̀yin Fúnra Yín Di Mímọ́ Nínú Gbogbo Ìwà Yín”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 7/1 ojú ìwé 9

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Èmi Jèhófà Ọlọ́run Yín Jẹ́ Mímọ́”

Léfítíkù Orí 19

“MÍMỌ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 4:8) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni Bíbélì fi jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, ìyẹn sì fi hàn pé kò lábàwọ́n, ó sì mọ́ tónítóní látòkè délẹ̀. Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́nàkọnà; ẹnikẹ́ni ò sì lè fi ẹ̀ṣẹ̀ sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin lọ́nà èyíkéyìí. Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé àwa èèyàn aláìpé ò lè ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́ lọ́nà tó ga jù lọ ni? Rárá o! Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tó máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ látinú ìwé Léfítíkù orí 19.

Jèhófà sọ fún Mósè pé kó “bá gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sọ̀rọ̀.” Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pátá sì làwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ tẹ̀ lé e ń bá wí. Ọ̀rọ̀ wo ló fẹ́ kí Mósè báwọn sọ? Ọlọ́run ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kí o sì wí fún wọn pé, ‘Kí ẹ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi Jèhófà Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.’” (Ẹsẹ 2) Ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa hùwà mímọ́. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé , “Kí ẹ jẹ́,” fi hàn pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fẹ́, àmọ́ ṣe ló pàṣẹ fún wọn. Ṣóhun tó ju agbára àwọn èèyàn yẹn lọ ni Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe ni?

Kíyè sí pé torí káwọn èèyàn yẹn lè mọ ìdí tí wọ́n fi gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ ni Jèhófà fi mẹ́nu kan ìjẹ́mímọ́ tiẹ̀, kì í ṣe torí pé ó fẹ́ kí wọ́n jẹ́ mímọ́ gan-an bíi tòun. Lọ́rọ̀ kan, kì í ṣe pé Jèhófà ń sọ fáwọn olùjọsìn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé ní Ísírẹ́lì pé kí wọ́n jẹ́ mímọ́ gan-an bíi tòun. Ìyẹn ò lè ṣeé ṣe. Kò sẹ́ni tó mọ́ tó Jèhófà, torí òun ni “Ẹni Mímọ́ Jù Lọ.” (Òwe 30:3) Àmọ́ torí pé Jèhófà jẹ́ mímọ́, ó retí pé káwọn ìránṣẹ́ òun náà jẹ́ mímọ́, ìyẹn dé ìwọ̀n tó bá ṣeé ṣe fún ẹ̀dá aláìpé. Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà máa fi hàn pé àwọn jẹ́ mímọ́?

Lẹ́yìn tí Jèhófà pàṣẹ pé káwọn èèyàn òun jẹ́ mímọ́, ó wá tipasẹ̀ Mósè sọ àwọn òfin tó kan gbogbo apá ìgbésí ayé wọn fún wọn. Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Jèhófà retí pé kó pa àwọn ìlànà ìwà híhù yìí mọ́: wọ́n gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fáwọn òbí wọn àtàwọn àgbàlagbà lọ́nà tó yẹ (ẹsẹ 3, 32); wọ́n gbọ́dọ̀ máa gba tàwọn adití, afọ́jú àti tàwọn akúṣẹ̀ẹ́ rò (ẹsẹ 9, 10, 14); wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́, wọn ò gbọ́dọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì wọn jẹ (ẹsẹ 11-13, 15, 35, 36); wọ́n sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn bí ara wọn. (ẹsẹ 18) Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá ń pa àwọn òfin yìí àtàwọn òfin míì tí Ọlọ́run fún wọn mọ́, wọ́n á lè “jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run [wọn] ní tòótọ́.”—Númérì 15:40.

Àṣẹ tí Jèhófà pa nípa ìjẹ́mímọ́ ti jẹ́ ká ní òye tó jinlẹ̀ dáadáa nípa ìrònú Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́. Ẹ̀kọ́ pàtàkì kan tá a ti rí kọ́ ni pé, tá a bá fẹ́ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti mú ara wa bá àwọn ìlànà ìwà mímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ mu. (1 Pétérù 1:15, 16) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yẹn, a máa gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ.—Aísáyà 48:17.

Àṣẹ tí Jèhófà pa pé ká jẹ́ mímọ́ tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà fọkàn tán àwa ìránṣẹ́ rẹ̀. Jèhófà ò fìgbà kankan retí pé ká ṣe ohun tó ju agbára wa lọ. (Sáàmù 103:13, 14) Ó mọ̀ pé àwa èèyàn tóun dá ní àwòrán ara òun ní agbára láti jẹ́ mímọ́ dé ìwọ̀n àyè kan. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Ṣé kò wù ẹ́ láti fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bó o ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run mímọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

A láwọn ànímọ́ tó lè jẹ́ ká jẹ́ mímọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́