ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 137
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣé èèyàn aláìpé lè jẹ́ mímọ́?
  • Ṣé ẹni tó jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run lè di aláìmọ́?
  • Àwọn èrò tí kò tọ́ nípa jíjẹ́ mímọ́
  • “Ẹ Gbọ́dọ̀ Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń wo Ohun Mímọ́ Ni Ìwọ Náà Fi Ń wò ó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Èmi Jèhófà Ọlọ́run Yín Jẹ́ Mímọ́”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Dida Ẹmi Mimọ Mọyatọ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 137
Mósè ní níbi igi kékeré ẹlẹ́gùn-ún tó ń jó

Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Jẹ́ Mímọ́?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Kí nǹkan jẹ́ mímọ́ túmọ̀ sí pé kó má ní àbàwọ́n kankan. Ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “mímọ́” wá látinú ọ̀rọ̀ náà “yà sọ́tọ̀.” Torí náà, wọn kì í lo nǹkan tó bá jẹ́ mímọ́ nílòkulò, ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n máa fi ń mú un, pàápàá jù lọ torí pé kò dọ̀tí, ó sì rí nigín-nigín.

Ọlọ́run lẹni mímọ́ jù lọ, kò sì sẹ́ni tó mọ́ tó o. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ẹnì kankan tí ó jẹ́ mímọ́ bí Jèhófà.”a (1 Sámúẹ́lì 2:2) Fún ìdí yìí, Ọlọ́run nìkan ló lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè di mímọ́.

A lè pe ohunkóhun tó bá tan mọ́ Ọlọ́run ní “mímọ́,” pàápàá jù lọ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa:

  • Àwọn ibi mímọ́: Nígbà tí Mósè wà ní ẹ̀gbẹ́ igbó tó ń jó, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí ìwọ dúró sí.”​—Ẹ́kísódù 3:2-5.

  • Àpéjọpọ̀ mímọ́: Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì máa ń lọ sáwọn “àpéjọpọ̀ mímọ́” láti jọ́sìn Jèhófà.​—Léfítíkù 23:37.

  • Ohun èlò mímọ́: Àwọn nǹkan tó wà nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù tí wọ́n ń lò fún ìjọsìn Ọlọ́run nígbà yẹn ni wọ́n ń pè ní, “nǹkan èlò mímọ́.” (1 Àwọn Ọba 8:4) Àwọn èèyàn kì í fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn nǹkan yẹn, síbẹ̀ kì í ṣe pé wọ́n ń jọ́sìn wọn.b

Ṣé èèyàn aláìpé lè jẹ́ mímọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ fáwọn Kristẹni pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:16) Lóòótọ́, kò sí bí àwa èèyàn aláìpé ṣe lè jẹ́ mímọ́ pátápátá bí Ọlọ́run. Àmọ́ ẹni tó bá ń tẹ̀lé àwọn òfin Ọlọ́run máa jẹ́ ẹni “mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà” lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 12:1) Ó máa hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe ẹni tó bá fẹ́ jẹ́ mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, irú eni yẹn á máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: “Kí ẹ ta kété sí àgbèrè,” àtèyí tó sọ pé: “Kí ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú di mímọ́ nínú gbogbo ìwà yín.”​—1 Tẹsalóníkà 4:3; 1 Pétérù 1:15.

Ṣé ẹni tó jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run lè di aláìmọ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ́nì kan ò bá tẹ̀lé àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́, Ọlọ́run ò ní ka ẹni yẹn sí mímọ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn “ará mímọ́” ni Pọ́ọ̀lù kọ ìwé Hébérù sí, síbẹ̀ ó tún kìlọ̀ fún wọn pé “ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́” tó ń yani “kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè” lè dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú wọn.​—Hébérù 3:1, 12.

Àwọn èrò tí kò tọ́ nípa jíjẹ́ mímọ́

Èrò tí kò tọ́: Téèyàn bá máa jẹ́ mímọ́, ó gbọ́dọ̀ máa fìyà jẹ ara rẹ̀.

Òtítọ́: Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kéèyàn máa fi ìyà jẹ ara rẹ̀ tàbí kó máa fi nǹkan du ara rẹ̀ lọ́nà tó burú, kò ní ìtẹ́wọ́gbà lójú Ọlọ́run. (Kólósè 2:23) Dípò ìyẹn, Ọlọ́run fẹ́ ká máa gbádùn ohun rere. “Kí olúkúlùkù ènìyàn máa jẹ, kí ó sì máa mu ní tòótọ́, kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”​—Oníwàásù 3:13.

Èrò tí kò tọ́: Tẹ́nì kan ò bá ṣègbéyàwó, ó máa túbọ̀ jẹ́ mímọ́.

Òtítọ́: Kò burú tí Kristẹni kan bá pinnu pé òun ò ní ṣègbéyàwó, àmọ́ ìyẹn kọ́ ló máa sọ ọ́ di ẹni mímọ́ lójú Ọlọ́run. Lóòótọ́ ó lè ṣeé ṣe fún ẹni tó kò ṣègbéyàwó láti sin Ọlọ́run láìsí ìpínyà ọkàn. (1 Kọ́ríńtì 7:32-34) Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn tó ṣègbéyàwó náà lè jẹ́ Mímọ́. Ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣe ìgbéyàwó, ìyẹn Pétérù.​—Mátíù 8:14; 1 Kọ́ríńtì 9:5.

Ibo lọ̀rọ̀ náà “Bíbélì Mímọ́” ti wá?

Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ni wọ́n ti ń pe gbogbo ìwé tí Ọlọ́run mí sí ní “Bíbélì Mímọ́” tàbí “Ìwé Mímọ́.” Ìdí tí wọ́n fi ń pè é bẹ́ẹ̀ rèé:

  • Ibi tó ti wá. “Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”​—2 Pétérù 1:21.

  • Ohun tó wà nínú rẹ̀. “Àṣẹ Jèhófà mọ́, ó ń mú kí ojú mọ́lẹ̀. Ìbẹ̀rù Jèhófà mọ́ gaara, ó wà títí láé.”​—Sáàmù 19:8, 9.

Fún àwọn ìdí yìí, Bíbélì jẹ́ mímọ́. Ó yàtọ̀ pátápátá sáwọn ìwé míì, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀ péye, ó sì wúlò fún ìjọsìn Ọlọ́run.

a Jèhófà ni orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́. Ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa “mímọ́” àti “ìjẹ́mímọ́” nígbà tó bá mẹ́nu ba orúkọ yẹn.

b Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò yẹ ká máa jọ́sìn àwọn nǹkan èlò tí wọ́n lò nínú ìjọsìn Ọlọ́run láyé àtijọ́.​—1 Kọ́ríńtì 10:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́