ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 8/15 ojú ìwé 30-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Máa Bá Yín Lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Kí Ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Túmọ̀ Sí Fún Ọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • “Àwa Yóò Bá Yín Lọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • “Ẹ̀mí Fúnra Rẹ̀ Ń Jẹ́rìí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 8/15 ojú ìwé 30-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Fún àwọn ọdún mélòó kan, ìròyìn fi hàn pé iye àwọn tí ń ṣàjọpín ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí ti pọ̀ díẹ̀ sí i. Èyí ha fi hàn pé a ti fi ẹ̀mí mímọ́ yan ọ̀pọ̀ ẹni tuntun sí i bí?

A ní ìdí rere láti gbà gbọ́ pé iye 144,000 àwọn Kristẹni ẹni-àmì-òróró ti pé láti àwọn ẹ̀wádún sẹ́yìn.

Ní Ìṣe 2:1-4, a kà nípa àwọn ẹni àkọ́kọ́ nínú àwùjọ kéréje yẹn pé: “Wàyí o bí ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ń lọ lọ́wọ́ gbogbo wọ́n wà pa pọ̀ ní ibì kan náà, lójijì ariwo kan sì dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bíi ti atẹ́gùn alágbára líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bíi ti iná sì di rírí fún wọn a sì há wọn káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.”

Lẹ́yìn ìyẹn, Jèhófà yan àwọn mìíràn, ó sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. A fi ẹgbẹẹgbẹ̀rún kún wọn ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìsìn Kristẹni gan-an. Ní àkókò tiwa, nígbà Ìṣe Ìrántí, olùbánisọ̀rọ̀ sábà máa ń pe àfiyèsí sí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní Róòmù 8:15-17, tí ó mẹ́nu bà á pé àwọn ẹni-àmì-òróró “gba ẹ̀mí ìsọdọmọ.” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé ẹ̀mí mímọ́ tí wọ́n gbà ‘ń jẹ́rìí pẹ̀lú ẹ̀mí wọn pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, àwọn ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.’ Àwọn tí ó ní ẹ̀mí tí ń yanni yìí ní tòótọ́, mọ̀ ọ́n dájúdájú. Kì í ṣe ìdàníyàn lásán tàbí ìrònú ní ti èrò ìmọ̀lára àti ojú ìwòye tí kò jóòótọ́ nípa ara wọn.

A lóye pé ìpè ti ọ̀run yìí ń bá a nìṣó jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà Sànmánì Ojú Dúdú, àkókò ti lè wà nígbà tí iye àwọn ẹni-àmì-òróró kéré jọjọ.a Nígbà tí a fi ìdí ìsìn Kristẹni tòótọ́ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní apá ìparí ọ̀rúndún tí ó kọjá, a pe àwọn mìíràn sí i, a sì yàn wọ́n. Ṣùgbọ́n, ó dà bí ẹni pé láàárín àwọn ọdún 1930, iye 144,000 náà ti pé ní ti gidi. Nípa bẹ́ẹ̀, àwùjọ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn. Jésù pe irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní “àwọn àgùntàn míràn,” tí wọ́n ṣọ̀kan nínú ìjọsìn pẹ̀lú àwọn ẹni-àmì-òróró gẹ́gẹ́ bí agbo kan tí a tẹ́wọ́ gbà.—Jòhánù 10:14-16.

Òkodoro òtítọ́ láti àwọn ẹ̀wádún sẹ́yìn fi hàn pé ìpè àwọn ẹni-àmì-òróró ti parí, Jèhófà sì ń bù kún “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí wọ́n ní ìrètí láti la “ìpọ́njú ńlá náà” já. (Ìṣípayá 7:9, 14) Fún àpẹẹrẹ, níbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tí a ṣe ní 1935, tí 63,146 pésẹ̀ sí, àwọn tí ó ṣàjọpín àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìkéde wọn ní gbangba pé wọ́n jẹ́ ẹni-àmì-òróró jẹ́ 52,465. Ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, tàbí ní 1965, iye àwọn tí ó pésẹ̀ jẹ́ 1,933,089, nígbà tí àwọn tí ó ṣàjọpín dín kù sí 11,550. Ọgbọ̀n ọdún mìíràn lẹ́yìn náà, ní 1995, àwọn tí ó pésẹ̀ fò sókè sí 13,147,201, ṣùgbọ́n kìkì 8,645 ni ó ṣàjọpín búrẹ́dì àti wáìnì. (Kọ́ríńtì Kìíní 11:23-26) Ó ṣe kedere pé bí àwọn ẹ̀wádún ti ń kọjá, iye àwọn tí ń kéde ní gbangba pé wọ́n jẹ́ ara àṣẹ́kù náà ti dín kù jọjọ—nǹkan bíi 52,400 ní 1935; 11,500 ní 1965; 8,600 ní 1995. Ṣùgbọ́n, a ti bù kún àwọn tí ó ní ìrètí ti orí ilẹ̀ ayé, iye wọ́n sì ti pọ̀ sí i ní yanturu.

Ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn tí a tẹ̀ jáde jẹ́ ti ọdún 1995, ó sì fi àwọn olùṣàjọpín 28 hàn ju ti ọdún tí ó ṣáájú rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn olùṣàjọpín ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tí ó pésẹ̀ dín kù. Bí a bá gbé gbogbo rẹ̀ yẹ̀ wò, pé àwọn díẹ̀ sí i yàn láti ṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ kò yẹ kí ó dààmú wa. Láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn kan, àní àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí pàápàá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín lójijì. Nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, wọ́n lóye pé èyí jẹ́ àṣìṣe. Àwọn kan ti mọ̀ pé àwọ́n ṣàjọpín láti inú fífi èrò ìmọ̀lára hùwà padà lábẹ́ yálà másùnmáwo ti ara tàbí ti èrò orí. Ṣùgbọ́n, wọ́n wá mọ̀ ní tòótọ́ pé, a kò pè wọ́n sí ìye ti ọ̀run. Wọ́n béèrè fún ẹ̀mí ìfàánúgbatẹnirò tí Ọlọ́run ní. Wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa ṣiṣẹ́ sìn ín gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni àtàtà, adúróṣinṣin, tí ó ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.

Kò sí ìdí fún ẹnikẹ́ni nínú wa láti dààmú bí ẹnì kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàjọpín nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ tàbí tí ó ṣíwọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Yálà a ti fi àmì òróró yan ẹnì kan ní ti gidi, tí a sì ti pè é sí ìyè ti ọ̀run tàbí bóyá a kò yàn án, kò kàn wá rárá. Rántí ìmúdánilójú Jésù tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ pé: “Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà, mo sì mọ àwọn àgùntàn mi.” Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti mú un dáni lójú, Jèhófà mọ àwọn tí ó ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ tẹ̀mí. A ní ìdí gbogbo láti gbà gbọ́ pé iye àwọn ẹni-àmì-òróró yóò máa dín kù sí i bí ọjọ́ ogbó àti èèṣì ti ń fòpin sí ìwàláàyè wọn ti orí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, àní bí àwọn ẹni-àmì-òróró ní tòótọ́ yìí ti ń jẹ́ olùṣòtítọ́ títí dójú ikú, ní fífojú sọ́nà fún adé ìyè, àwọn àgùntàn míràn, tí wọ́n ti fọ aṣọ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, lè máa fojú sọ́nà fún líla ìpọ́njú ńlá tí ó sún mọ́lé já.—Tímótì Kejì 4:6-8; Ìṣípayá 2:10.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ilé Ìṣọ́, March 15, 1965 (Gẹ̀ẹ́sì), ojú ìwé 191, 192.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́