ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 14-19
  • Òfin Kristi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Òfin Kristi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Májẹ̀mú Tuntun
  • Òfin Tí Í Ṣe Ti Òmìnira
  • Jésù àti Àwọn Farisí
  • Òfin Kristi Ha Gbọ̀jẹ̀gẹ́ Bí?
  • Kirisẹ́ńdọ̀mù Sọ Òfin Kristi Dìbàjẹ́
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àṣìṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù
  • Òfin Tí Ó Wà Ṣáájú Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • “Òfin Jèhófà Pé”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 14-19

Òfin Kristi

‘Èmi wà lábẹ́ òfin sí Kristi.’—KỌ́RÍŃTÌ KÌÍNÍ 9:21.

1, 2. (a) Báwo ni à bá ti dènà ọ̀pọ̀ àṣìṣe aráyé? (b) Kí ni Kirisẹ́ńdọ̀mù kùnà láti kọ́ láti inú ìtàn Ìsìn Àwọn Júù?

“ÀWỌN ènìyàn àti ìjọba kò tí ì fìgbà kan rí kọ́ ohunkóhun láti inú ìtàn, tàbí gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ìlànà tí wọ́n rí fà yọ nínú rẹ̀.” Ohun tí ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany, sọ nìyẹn. Ní tòótọ́, a ti ṣàpèjúwe àwọn ìgbésẹ̀ inú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bíi “ọ̀wọ́ ìgbésẹ̀ òmùgọ̀,” tí ó kún fún ọ̀wọ́ àṣìṣe àti yánpọnyánrin kíkóni nírìíra, èyí tí à bá ti dènà ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ bí ó bá jẹ́ pé aráyé ti múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá.

2 A fún kíkọ̀ jálẹ̀ kan náà láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá ní àfiyèsí nínú ìjíròrò òfin àtọ̀runwá yìí. Jèhófà Ọlọ́run fi òfin tí ó sàn jù pàápàá dípò Òfin Mósè—òfin Kristi. Síbẹ̀, àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí wọ́n sọ pé àwọn ń kọ́ni ní òfin yìí, tí wọ́n sì ń sọ pé àwọn ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ ti kùnà láti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìwà ẹ̀gọ̀ tí ó kọjá sísọ tí àwọn Farisí ń hù. Nípa bẹ́ẹ̀, Kirisẹ́ńdọ̀mù ti lọ́ òfin Kristi po, wọ́n sì ti ṣì í lò gan-an gẹ́gẹ́ bí Ìsìn Àwọn Júù ti ṣe sí Òfin Mósè. Báwo ni ìyẹn ṣe rí bẹ́ẹ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí a jíròrò òfin yìí fúnra rẹ̀—ohun tí ó jẹ́, àwọn tí ó ń darí àti bí ó ṣe ń darí wọn, àti ohun tí ó mú kí ó yàtọ̀ sí Òfin Mósè. Lẹ́yìn náà, a óò ṣàyẹ̀wò bí Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ṣe ṣì í lò. Ǹjẹ́ kí a tipa báyìí kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìtàn, kí a sì jàǹfààní nínú rẹ̀!

Májẹ̀mú Tuntun

3. Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe nípa májẹ̀mú tuntun kan?

3 Yàtọ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run, ta ni ẹni náà tí ó lè mú Òfin tí ó pé pérépéré sunwọ̀n sí i? Májẹ̀mú Òfin Mósè pé pérépéré. (Orin Dáfídì 19:7) Láìka ìyẹn sí, Jèhófà ṣèlérí pé: “Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀, . . . tí èmi óò bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun. Kì í ṣe bíi májẹ̀mú náà tí èmi bá bàbá wọn dá.” Òfin Mẹ́wàá—òpómúléró nínú Òfin Mósè—ni a kọ sórí wàláà òkúta. Ṣùgbọ́n, Jèhófà sọ nípa ti májẹ̀mú tuntun náà pé: “Èmi óò fi òfin mi sí inú wọn, èmi óò sì kọ ọ́ sí àyà wọn.”—Jeremáyà 31:31-34.

4. (a) Ísírẹ́lì wo ni májẹ̀mú tuntun náà ní nínú? (b) Àwọn mìíràn wo yàtọ̀ sí Ísírẹ́lì tẹ̀mí ni ó wà lábẹ́ òfin Kristi?

4 Àwọn wo ni a óò mú wọnú májẹ̀mú tuntun yìí? Dájúdájú, kì í ṣe “ilé Ísírẹ́lì,” ní ti ara, tí ó kọ Alárinà májẹ̀mú yìí sílẹ̀. (Hébérù 9:15) Kàkà bẹ́ẹ̀, “Ísírẹ́lì” tuntun yìí yóò jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí. (Gálátíà 6:16; Róòmù 2:28, 29) Lẹ́yìn náà, “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè, tí àwọn pẹ̀lú yóò fẹ́ láti jọ́sìn Jèhófà, yóò dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kékeré yìí, ti àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn. (Ìṣípayá 7:9, 10; Sekaráyà 8:23) Bí wọn kò tilẹ̀ kópa nínú májẹ̀mú tuntun náà, òfin yóò de àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. (Fi wé Léfítíkù 24:22; Númérì 15:15.) Gẹ́gẹ́ bí “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan,” gbogbo wọn gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti kọ̀wé yóò wà “lábẹ́ òfin sí Kristi.” (Jòhánù 10:16; Kọ́ríńtì Kìíní 9:21) Pọ́ọ̀lù pe májẹ̀mú tuntun yìí ní “májẹ̀mú . . . tí ó dára jù.” Èé ṣe? Ìdí kan ni pé, a gbé e karí ìlérí tí ó ní ìmúṣẹ dípò gbígbé e karí òjìji àwọn ohun tí ń bọ̀.—Hébérù 8:6; 9:11-14.

5. Kí ni ète májẹ̀mú tuntun náà, èé sì ti ṣe tí yóò fi kẹ́sẹ járí?

5 Kí ni ète májẹ̀mú yìí? Ó jẹ́ láti pèsè orílẹ̀-èdè àwọn ọba àti àlùfáà láti bù kún aráyé. (Ẹ́kísódù 19:6; Pétérù Kìíní 2:9; Ìṣípayá 5:10) Májẹ̀mú Òfin Mósè kò fìgbà kan rí pèsè orílẹ̀-èdè yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, nítorí pé Ísírẹ́lì lápapọ̀ ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì sọ àǹfààní wọn nù. (Fi wé Róòmù 11:17-21.) Bí ó ti wù kí ó rí, ó dájú pé májẹ̀mú tuntun náà yóò kẹ́sẹ járí, nítorí pé ó ní í ṣe pẹ̀lú òfin tí ó yàtọ̀ pátápátá. Àwọn ọ̀nà wo ni ó gbà yàtọ̀?

Òfin Tí Í Ṣe Ti Òmìnira

6, 7. Báwo ni òfin Kristi ṣe fúnni ní òmìnira tí ó pọ̀ ju bí Òfin Mósè ṣe fúnni lọ?

6 Léraléra, a so òfin Kristi pọ̀ mọ́ òmìnira. (Jòhánù 8:31, 32) A tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí “òfin àwọn ẹni òmìnira” àti “òfin pípé náà tí í ṣe ti òmìnira.” (Jákọ́bù 1:25; 2:12) Àmọ́ ṣáá o, gbogbo òmìnira láàárín ẹ̀dá ènìyàn ní ààlà. Síbẹ̀, òfin yìí fúnni ní òmìnira tí ó ga fíìfíì ju ti aṣáájú rẹ̀, Òfin Mósè, lọ. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?

7 Ohun kan ni pé, kò sí ẹni tí a bí lábẹ́ òfin Kristi. Irú àwọn kókó abájọ bí ẹ̀yà ìran, àti ibi tí a ti bíni kò ṣe pàtàkì. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń yàn láti inú ọkàn wọn ní fàlàlà láti tẹ́wọ́ gba àjàgà ìgbọ́ràn sí òfin yìí. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rí i pé ó jẹ́ àjàgà onínúure, ẹrù fífúyẹ́. (Mátíù 11:28-30) Ó ṣe tán, a pète pẹ̀lú pé kí Òfin Mósè kọ́ ènìyàn pé ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, àti pé ó nílò ẹbọ ìràpadà kan ní kánjúkánjú láti rà á padà. (Gálátíà 3:19) Òfin Kristi kọ́ni pé Mèsáyà ti wá, ó fi ìwàláàyè rẹ̀ san iye ìràpadà náà, ó sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti di òmìnira kúrò lọ́wọ́ ìnilára bíbani lẹ́rù tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú mú wá! (Róòmù 5:20, 21) Láti lè jàǹfààní, a ní láti “lo ìgbàgbọ́” nínú ìrúbọ yẹn.—Jòhánù 3:16.

8. Kí ni òfin Kristi ní nínú, ṣùgbọ́n èé ṣe tí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ kò fi béèrè fún híhá ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìlànà òfin sórí?

8 ‘Lílo ìgbàgbọ́’ wé mọ́ gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi. Ìyẹn kan ṣíṣègbọràn sí gbogbo àṣẹ Kristi. Èyí ha túmọ̀ sí híhá ọgọ́rọ̀ọ̀rún òfin àti ìlànà sórí bí? Rárá o. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mósè, alárinà májẹ̀mú láéláé, kọ Òfin Mósè sílẹ̀, Jésù, Alárinà májẹ̀mú tuntun, kò kọ òfin kan ṣoṣo sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ó gbé ìgbésí ayé òfin yìí. Nípasẹ̀ ọ̀nà ìwàláàyè rẹ̀ pípé lórí ilẹ́ ayé, ó fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún gbogbo ènìyàn láti tẹ̀ lé. (Pétérù Kìíní 2:21) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí a fi tọ́ka sí ìjọsìn àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ọ̀nà Náà.” (Ìṣe 9:2; 19:9, 23; 22:4; 24:22) Lójú wọn, ìgbésí ayé Kristi fi àpẹẹrẹ òfin Kristi lélẹ̀. Láti fara wé Jésù jẹ́ láti ṣègbọ́ràn sí òfin yìí. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní fún un túmọ̀ sí pé, ní tòótọ́, a kọ òfin yìí sí ọkàn-àyà wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ tẹ́lẹ̀. (Jeremáyà 31:33; Pétérù Kìíní 4:8) Ara kì í sì í ni ẹni tí ó bá ń ṣègbọ́ràn nítorí ìfẹ́—ìdí mìíràn tí a fi lè pe òfin Kristi ní “òfin àwọn ẹni òmìnira.”

9. Kí ni lájorí òfin Kristi, ọ̀nà wo sì ni òfin yìí gbà ní àṣẹ tuntun kan nínú?

9 Bí ìfẹ́ bá ṣe pàtàkì nínú Òfin Mósè, òun gan-an ni lájorí òfin Kristẹni. Nípa báyìí, òfin Kristi ní àṣẹ tuntun kan nínú—àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ sí ẹnì kíní kejì. Wọ́n gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ní in; ó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 13:34, 35; 15:13) Nítorí náà, a lè sọ pé òfin Kristi tilẹ̀ fi ìṣàkóso Ọlọ́run hàn lọ́nà gíga lọ́lá ju bí Òfin Mósè ti ṣe lọ. Bí ìwé ìròyìn yìí ti sọ ṣáájú pé: “Ìṣàkóso Ọlọ́run jẹ́ àkóso nípasẹ̀ Ọlọ́run; Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́; nítorí náà ìṣàkóso Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso nípasẹ̀ ìfẹ́.”

Jésù àti Àwọn Farisí

10. Báwo ni ẹ̀kọ́ Jésù ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn Farisí?

10 Nígbà náà, kò yani lẹ́nu pé Jésù forí gbárí pẹ̀lú àwọn aṣáájú ìsìn Júù ọjọ́ rẹ̀. “Ofin pípé . . . tí í ṣe ti òmìnira” jìnnà sí ọkàn àwọn akọ̀wé àti Farisí bí ojú ti jìnnà símú. Wọ́n gbìyànjú láti fi àwọn ìlànà àtọwọ́dá darí àwọn ènìyàn. Ẹ̀kọ́ wọ́n ń nini lára, ó ń dáni lẹ́jọ́, kò sì ṣeni láǹfààní. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí èyí, ẹ̀kọ́ Jésù ń gbéni ró lọ́nà gíga lọ́lá, ó sì ń ṣeni láǹfààní! Ó já fáfá, ó sì bójú tó àìní àti àníyàn àwọn ènìyàn gan-an. Ó kọ́ni lọ́nà rírọrùn àti pẹ̀lú ojúlówó ìmọ̀lára, ní lílo àwọn àkàwé láti inú ìgbésí ayé ojoojúmọ́, ó sì ń ṣàyọlò láti inú ọlá àṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nípa báyìí, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀kọ́ Jésù dé inú ọkàn-àyà wọn!

11. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé Òfin Mósè ni à bá ti fi òye àti àánú lò?

11 Dípò fífi àwọn ìlànà kún Òfin Mósè, Jésù fi hàn bí àwọn Júù ì bá ti máa lo Òfin yẹn látẹ̀yìn wá—pẹ̀lú òye àti àánú. Fún àpẹẹrẹ, rántí ìgbà tí obìnrin tí ó ní ìṣàn ẹ̀jẹ̀ tọ̀ ọ́ wá. Ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Mósè, ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn yóò di aláìmọ́, nítorí èyí, kò yẹ kí ó dara pọ̀ mọ́ ogunlọ́gọ̀ ènìyàn rárá! (Léfítíkù 15:25-27) Ṣùgbọ́n ó ń fi ìgbékútà wá ìmúláradá tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi gba àárín ogunlọ́gọ̀ náà kọjá, tí ó sì fi ọwọ́ kan ẹ̀wù àwọ̀lékè Jésù. Ìṣàn ẹ̀jẹ̀ náà dáwọ́ dúró lọ́gán. Òun ha bá a wí nítorí rírú Òfin bí? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, òun lóye ipò àìnírètí rẹ̀, ó sì fi àṣẹ títóbi jù lọ nínú Òfin náà hàn—ìfẹ́. Pẹ̀lú ẹ̀mí ìfọ̀rànrora ẹni wò, ó sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn rẹ aronilára gógó.”—Máàkù 5:25-34.

Òfin Kristi Ha Gbọ̀jẹ̀gẹ́ Bí?

12. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a ronú pé Kristi gbọ̀jẹ̀gẹ́? (b) Kí ni ó fi hàn pé ṣíṣe ọ̀pọ̀ òfin ń ṣamọ̀nà sí ṣíṣe ọ̀pọ̀ ìyẹ̀sílẹ̀?

12 Nígbà náà, a ha ní láti parí èrò pé, òfin Kristi gbọ̀jẹ̀gẹ́ nítorí pé ó ‘jẹ́ ti òmìnira,’ nígbà tí ó sì jẹ́ pé, ó kéré tán, àwọn Farisí, pẹ̀lú gbogbo òfin àtẹnudẹ́nu wọ́n, fi ìwà àwọn ènìyàn mọ sáàárín àwọn ààlà aláìgbọ̀jẹ̀gẹ́? Rárá o. Ètò òfin lónìí fi hàn pé lọ́pọ̀ ìgbà, bí òfin bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn ṣe ń rí ọ̀nà yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ tó.a Ní ọjọ́ Jésù, sísọ òfin àwọn Farisí di púpọ̀ fún wíwá ọ̀nà láti yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ níṣìírí, ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àfaraṣe má fọkàn ṣe tí kò ní ìfẹ́ nínú, àti fífi òdodo ara ẹni hàn lóde láti bo ìwà ìbàjẹ́ tí ń bẹ nínú mọ́lẹ̀.—Mátíù 23:23, 24.

13. Èé ṣe tí òfin Kristi fi yọrí sí ìlànà gíga jù ní ti ìwà híhù ju ìwé àkójọ òfin èyíkéyìí?

13 Ní ìyàtọ̀ pátápátá, òfin Kristi kò fàyè gba irú ìrònú bẹ́ẹ̀. Ní tòótọ́, ṣíṣègbọràn sí òfin tí a gbé ka orí ìfẹ́ Jèhófà, tí a sì ṣègbọràn sí nípa fífara wé ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ tí Kristi ní fún àwọn ẹlòmíràn máa ń yọrí sí ìlànà ìwà híhù tí ó ga fíìfíì ju bí yóò ti rí ní títẹ̀ lé ìwé àkójọ òfin. Ìfẹ́ kì í wá ọ̀nà ìyẹ̀sílẹ̀; ó ń pa wá mọ́ kúrò nínú ṣíṣe ohun eléwu tí àkójọ òfin lè ṣàìkà léèwọ̀ ní tààràtà. (Wo Mátíù 5:27, 28.) Nípa báyìí, òfin Kristi yóò sún wa láti ṣe nǹkan fún àwọn ẹlòmíràn—láti fi ọ̀làwọ́, aájò àlejò, àti ìfẹ́, hàn—ní àwọn ọ̀nà tí kò sí òfin àpilẹ̀ṣe tí ó lè mú wa ṣe bẹ́ẹ̀.—Ìṣe 20:35; Kọ́ríńtì Kejì 9:7; Hébérù 13:16.

14. Ipa wo ni gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi ní lórí ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?

14 Títí dé ìwọ̀n tí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi dé, ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ gbádùn àyíká ọlọ́yàyà, onífẹ̀ẹ́, tí ó bọ́, dé àyè kan, kúrò lọ́wọ́ ẹ̀mí ìrònú tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún, adánilẹ́jọ́, àti alágàbàgebè tí ó gbalé gbòde nínú àwọn sínágọ́ọ́gù ní àkókò náà. Ó ní láti jẹ́ pé àwọn mẹ́ḿbà ìjọ tuntun wọ̀nyí mọ̀ ní tòótọ́ pé àwọn ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú “òfin àwọn ẹni òmìnira”!

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìsapá àkọ́kọ́ tí Sátánì ṣe láti sọ ìjọ Kristẹni dìbàjẹ́?

15 Ṣùgbọ́n, Sátánì hára gàgà láti sọ ìjọ Kristẹni dìbàjẹ́ láti inú wá, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dìbàjẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ nípa àwọn ọkùnrin bí ìkookò tí wọn yóò “sọ àwọn ohun àyídáyidà,” tí wọn yóò sì ni agbo Ọlọ́run lára. (Ìṣe 20:29, 30) Ó ní láti bá àwọn Onísìn Júù jiyàn, àwọn tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ìsìnrú lábẹ́ Òfin Mósè, tí a ti múṣẹ nínú Kristi, dípò òmìnira aláàlà ti òfin Kristi. (Mátíù 5:17; Ìṣe 15:1; Róòmù 10:4) Lẹ́yìn tí èyí tí ó kẹ́yìn nínú àwọn àpọ́sítélì kú, kò sí ìdènà lòdì sí irú ìpẹ̀yìndà bẹ́ẹ̀ mọ́. Nítorí náà, ìwà ìbàjẹ́ wá búrẹ́kẹ.—Tẹsalóníkà Kejì 2:6, 7.

Kirisẹ́ńdọ̀mù Sọ Òfin Kristi Dìbàjẹ́

16, 17. (a) Ọ̀nà wo ni ìwà ìbàjẹ́ gbà fara hàn nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù? (b) Báwo ni òfin Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe gbé ojú ìwòye òdì nípa ìbálòpọ̀ lárugẹ?

16 Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú Ìsìn Àwọn Júù, ìwà ìbàjẹ́ pín sí oríṣiríṣi nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Òun pẹ̀lú di ẹran ìjẹ fún àwọn ẹ̀kọ́ èké àti ìwà pálapàla. Gbogbo ìsapá rẹ̀ láti dáàbò bo agbo kúrò lọ́wọ́ agbára ìdarí láti òde sì sábà máa ń yọrí sí ìpalára fún ohunkóhun tí ó ṣẹ́kù nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. Àwọn òfin tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún tí kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu gbèrú.

17 Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti mú ipò iwájú ní ṣíṣe ọ̀pọ̀ jaburata òfin ṣọ́ọ̀ṣì. Ní pàtàkì, a lọ́ àwọn òfin wọ̀nyí po lórí àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ìbálòpọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Sexuality and Catholicism, ṣe sọ, ṣọ́ọ̀ṣì gba ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì ti Sítóíkì wọlé, èyí tí a fura sí pé ó kún fún gbogbo oríṣi adùn. Ṣọ́ọ̀ṣì náà fi kọ́ni pé gbogbo adùn ìbálòpọ̀, títí kan ti ìbátan ìgbéyàwó tí ó bójú mu, jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. (Fi wé ìyàtọ̀ Òwe 5:18, 19.) Wọ́n sọ pé ọmọ bíbí nìkan ni ìbálòpọ̀ wà fún, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nípa báyìí, ṣọ́ọ̀ṣì dẹ́bi fún irú ọ̀nà májòóyún-ó-dúró èyíkéyìí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo, nígbà míràn tí ó máa ń béèrè fún títọrọ ìdáríjì fún ọ̀pọ̀ ọdún. Síwájú sí i, a kà á léèwọ̀ fún ẹgbẹ́ àlùfáà láti ṣègbéyàwó, òfin tí ó ti yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbálòpọ̀ tí kò tọ́, títí kan bíbá àwọn ọmọdé ṣèṣekúṣe.—Tímótì Kìíní 4:1-3.

18. Kí ni ó jẹ yọ láti inú mímú òfin ṣọ́ọ̀ṣì pọ̀ sí i?

18 Bí àwọn òfin ṣọ́ọ̀ṣì ti ń pọ̀ sí i, wọ́n ṣètò wọn jọ sínú ìwé. Àwọn ìwé wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí sọ Bíbélì di àdììtú, wọ́n sì ta á yọ. (Fi wé Mátíù 15:3, 9.) Gẹ́gẹ́ bí Ìsìn Àwọn Júù, Ìsìn Kátólíìkì kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwé tí kì í ṣe ti ìsìn, wọ́n sì ka ọ̀pọ̀ nínú rẹ̀ sí ewu. Láìpẹ́, ojú ìwòye yìí lọ ré kọjá ìkìlọ̀ Bíbélì tí ó bọ́gbọ́n mu lórí ọ̀ràn náà. (Oníwàásù 12:12; Kólósè 2:8) Jerome, òǹkọ̀wé ṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa polongo pé: “Olúwa, bí mo bá tún ní ìwé ayé lẹ́ẹ̀kan sí i, tàbí bí mo bá tún kà wọ́n, mo ti sẹ́ ọ.” Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí i yiiri àwọn ìwé wò—àní àwọn tí ó dá lórí kókó ọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ ti ayé pàápàá. Nípa báyìí, wọ́n ṣe lámèyítọ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, Galileo, nítorí kíkọ̀wé pé ayé ń yí oòrùn po. Rírin kinkin tí ṣọ́ọ̀ṣì rin kinkin pé òun ni ọlá àṣẹ tí ó kẹ́yìn lórí ohun gbogbo—àní lórí ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà pàápàá—lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn wá ṣiṣẹ́ láti jin ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì lẹ́sẹ̀.

19. Báwo ni ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ṣe gbé ìlànà bóo fẹ́ bóo kọ̀, tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún lárugẹ?

19 Ṣíṣe ìlànà ti ṣọ́ọ̀ṣì gbilẹ̀ ní ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, níbi tí àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé yìí láti gbé ìgbésí ayé asẹ́ra-ẹni. Ọ̀pọ̀ jù lọ ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti Kátólíìkì rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ “Ìlànà Ti Benedict Mímọ́.” Abbot [olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn (ọ̀rọ̀ kan tí a rí fà yọ láti inú èdè Árámáíkì fún “bàbá”)] ní ń ṣàkóso pẹ̀lú ọlá àṣẹ pátápátá. (Fi wé Mátíù 23:9.) Bí ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan bá rí ẹ̀bùn gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀, olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn ni yóò pinnu bóyá ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé yẹn tàbí ẹlòmíràn kan ni yóò gbà á. Yàtọ̀ sí dídẹ́bi fún sísọ ọ̀rọ̀ rírùn, ìlànà kan ka gbogbo ọ̀rọ̀ ṣákálá àti àwàdà léèwọ̀, ní sísọ pé: “Kò sí ọmọ ẹ̀yìn tí ó gbọ́dọ̀ sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.”

20. Kí ni ó fi hàn pé Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì pẹ̀lú jẹ́ ògbóǹkangí nínú gbígbé ìlànà bóo fẹ́ bóo kọ̀, tí kò bá àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ mu kalẹ̀?

20 Ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì, tí ó wọ́nà láti ṣàtúnṣe àṣejù aláìbá àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ mu ti Ìsìn Kátólíìkì, di ògbóǹkangí láìpẹ́ lọ́nà kan náà ní gbígbé àwọn ìlànà bóo fẹ́ bóo kọ̀, tí kò ní ìpìlẹ̀ nínú òfin Kristi kalẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, aṣáájú alátùn-ún-ṣe, John Calvin, di ẹni tí a wá ń pè ní “aṣòfin Ṣọ́ọ̀ṣì tí a tún ṣe.” Ó ṣàkóso Geneva pẹ̀lú ọ̀pọ̀ yanturu ìlànà kò dúró gbẹ́jọ́, tí àwọn “Alàgbà” ń mú ṣẹ, àwọn ẹni tí “ipò iṣẹ́ wọ́n,” gẹ́gẹ́ bí Calvin ti sọ, “jẹ́ láti bójú tó ìwàláàyè gbogbo ènìyàn.” (Fi wé ìyàtọ̀ Kọ́ríńtì Kejì 1:24.) Ṣọ́ọ̀ṣì darí àwọn ilé èrò, ó sì ṣàkóso irú kókó ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí a fàyè gbà. Ìyà tí ó gbópọn wà fún ṣíṣe láìfí, bíi kíkọ orin tí kò fi ọ̀wọ̀ hàn, tàbí ijó jíjó.b

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Àṣìṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù

21. Kí ni ó ti jẹ́ àpapọ̀ àbájáde ìtẹ̀sí Kirisẹ́ńdọ̀mù láti ‘ré kọjá àwọn ohun tí a kọ̀wé rẹ̀’?

21 Gbogbo ìlànà àti òfin wọ̀nyí ha ti ṣiṣẹ́ láti dáàbò bo Kirisẹ́ńdọ̀mù kúrò lọ́wọ́ ìwà ìbàjẹ́ bí? Òdìkejì pátápátá ni ó jẹ́! Lónìí, Kirisẹ́ńdọ̀mù ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ sí ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀ya ìsìn, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn tí ó le koko ré kọjá ààlà títí dé orí àwọn tí ó gbọ̀jẹ̀gẹ́ lọ́nà tí ó lé kenkà. Lọ́nà kan tàbí òmíràn, gbogbo wọ́n ti ‘ré kọjá àwọn ohun tí a kọ̀wé rẹ̀,’ ní fífàyè gba èrò ènìyàn láti ṣàkóso agbo, kí ó sì jin òfin àtọ̀runwá lẹ́sẹ̀.—Kọ́ríńtì Kìíní 4:6.

22. Èé ṣe tí àbùkù Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi túmọ̀ sí òpin òfin Kristi?

22 Bí ó ti wù kí ó rí, ìtàn òfin Kristi kì í ṣe ti oníbànújẹ́. Jèhófà Ọlọ́run kì yóò gba ènìyàn lásán láyè láti pa òfin àtọ̀runwá rẹ́. Òfin Kristẹni wà lẹ́nu iṣẹ́ ní pẹrẹu lónìí láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́, àwọn wọ̀nyí sì ní àǹfààní ńlá náà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò itú tí Ìsìn Àwọn Júù àti Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi òfin àtọ̀runwá pa, ó dára kí a béèrè pé, ‘Báwo ni a ṣe lè gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi bí a ti ń yẹra fún ìdẹkùn fífi èrò ènìyàn àti àwọn ìlànà tí ń jin ìtumọ̀ gidi tí òfin àtọ̀runwá ní lẹ́sẹ̀, sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dìbàjẹ́? Ojú ìwòye wíwà déédéé wo ni ó yẹ kí òfin Kristi gbìn sínú wa lónìí?’ Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Farisí ní pàtàkì ni ó fa oríṣi Ìsìn Àwọn Júù tí ó wà lónìí, nítorí náà, kò yani lẹ́nu pé síbẹ̀ Ìsìn Àwọn Júù ṣì ń wá ọ̀nà láti yẹ púpọ̀ nínú àwọn ìkálọ́wọ́kò Sábáàtì tí ó fi kún un sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, olùbẹ̀wò kan sí ilé ìwòsàn àwọn Júù ní ọjọ́ Sábáàtì lè rí i pé ẹ̀rọ agbéni-ròkè-rodò máa ń dúró fúnra rẹ̀ ní àjà kọ̀ọ̀kan kí àwọn èrò baà lè yẹra fún ṣíṣe “iṣẹ́” ẹ̀ṣẹ̀, ti títẹ bọ́tìnnì ẹ̀rọ agbéni-ròkè-rodò náà. Àwọn dókítà kan tí wọ́n jẹ́ Júù ń fi tàdáwà tí yóò parẹ́ láàárín ọjọ́ díẹ̀ kọ àwọn ìwé àmọ̀ràn egbòogi wọn. Èé ṣe? Mishnah ka kíkọ̀wé sí “iṣẹ́,” ṣùgbọ́n ó túmọ̀ “kíkọ̀wé” gẹ́gẹ́ bíi kíkọ àmì tí yóò wà pẹ́ títí sílẹ̀.

b Servetus, ẹni tí ó bu ẹnu àtẹ́ lu díẹ̀ nínú ojú ìwòye Calvin ní ti ẹ̀kọ́ ìsìn ni a dáná sun lórí òpó igi gẹ́gẹ́ bí aládàámọ̀.

Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?

◻ Kí ni lájorí òfin Kristi?

◻ Báwo ni ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Jésù ṣe yàtọ̀ sí ti àwọn Farisí?

◻ Báwo ni Sátánì ṣe lo ẹ̀mí ṣíṣe ìlànà tí kò ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún láti sọ Kirisẹ́ńdọ̀mù dìbàjẹ́?

◻ Kí ni díẹ̀ lára agbára ìdarí rere tí gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi ní?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jésù fi òye àti àánú lo Òfin Mósè

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́