Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
◼ Ki ni “rere” ti apọsiteli Pọọlu ko le ṣe, gẹgẹ bi a ti mẹnukan an ni Roomu 7:19?
Ni ipilẹ, Pọọlu ntọka si ailagbara rẹ̀ lati ṣe gbogbo awọn ohun rere ti a tò lẹsẹẹsẹ sinu Ofin Mose. Iyẹn ko ṣeeṣe fun Pọọlu ati gbogbo awọn ẹlomiran, papọ pẹlu wa, nitori aipe ati ipo ẹṣẹ. Ṣugbọn ko si idi lati sọ ireti nù. Ẹbọ Kristi ṣí ọna silẹ fun idariji Ọlọrun ati iduro rere pẹlu Rẹ̀.
Romu 7:19 (NW) ka pe: “Nitori rere ti mo nfẹ emi ko ṣe e, ṣugbọn buburu ti emi ko fẹ ni ohun ti mo nṣe bi aṣa.” Ayika ọrọ naa fihan pe Pọọlu ni ipilẹṣẹ nsọrọ nipa “rere” ni itumọ ohun ti a là lẹsẹẹsẹ ninu Ofin. Ni ẹsẹ 7 oun ti sọ pe: “Ofin ha jẹ ẹṣẹ bi? Ki eyiini maṣe ri bẹẹ lae! Niti gidi emi ki ba ti mọ ẹṣẹ bi kò bá sí ti Ofin; ati pẹlu, fun apẹẹrẹ, emi ki ba ti mọ ojukokoro bi Ofin kò ba ti wi pe: ‘Iwọ ko gbọdọ ṣojukokoro.’” Bẹẹni, Ofin mu un ṣe kedere pe niwọn igba ti wọn ko ti le pa a mọ́ patapata, gbogbo eniyan jẹ ẹlẹṣẹ.
Pọọlu nbaa lọ lati mẹnukan an pe oun “walaaye nigba kan laisi ofin.” Nigba wo ni iyẹn rí bẹẹ? O dara, nigba ti o wa ni abẹ́nú Aburahamu ṣaaju ki Jehofa to pese Ofin naa (Roomu 7:9; fiwe Heberu 7:9, 10) Bi o tilẹ jẹ pe Aburahamu jẹ alaipe, Ofin naa ni a ko tii fifunni, nitori naa oun ni a kò ranleti ipo ẹṣẹ rẹ̀ nipa kikuna lati pa ọgọọrọ awọn aṣẹ mọ́. Iyẹn ha tumọsi pe ni gbàrà ti a fi Ofin naa funni ti a si fi aipe eniyan han jade, o mu awọn iyọrisi buburu jade? Bẹẹkọ. Pọọlu nbaa lọ pe: “Nipa bẹẹ, Ofin, ni tirẹ, jẹ mimọ, aṣẹ sì jẹ mimọ ati ododo ati daradara.”—Roomu 7:12, NW.
Ṣakiyesi pe Pọọlu ṣapejuwe Ofin gẹgẹ bi “mimọ” ati “rere.” Ni awọn ẹsẹ ti o tẹle e, o ṣalaye pe “ohun ti o dara”—Ofin—mu un ṣe kedere pe oun jẹ́ ẹlẹṣẹ kan, ẹṣẹ yii si mu un yẹ fun iku. Pọọlu kọwe pe: “Nitori rere ti mo nfẹ emi ko ṣe e, ṣugbọn buburu ti emi ko fẹ ni ohun ti mo nṣe bi aṣa. Nisinsinyi, bi o ba jẹ pe ohun ti emi ko fẹ ni ohun ti mo nṣe, ẹni ti nṣe e kii ṣe emi mọ, bikoṣe ẹṣẹ ti ngbe inu mi.”—Roomu 7:13-20, NW.
Ninu ayika ọrọ yii, nigba naa, kii ṣe pe Pọọlu nsọrọ nipa iwarere iṣeun ni gbogbogboo, tabi ni kukuru awọn iṣe oninuure. (Fiwe Iṣe 9:36; Roomu 13:3.) Oun tọka ni pataki si ṣiṣe (tabi ṣiṣaiṣe) awọn ohun ti o ṣe deedee pẹlu Ofin rere ti Ọlọrun. Ni iṣaaju oun ti fi itara ṣe isin awọn Juu ati—bi a ba fiwe awọn ẹlomiran—o jẹ “alailẹbi.” Sibẹ, ani bi o tilẹ jẹ pe ninu ọkan rẹ̀ oun ti jẹ ẹru afitọkantọkan ṣiṣẹ si Ofin rere yẹn, oun sibẹ ko de oju iwọn ni kikun. (Filipi 3:4-6, NW) Ofin naa fi awọn ọpa idiwọn pipe ti Ọlọrun han, ni fifihan apọsiteli naa pe ninu ẹran-ara rẹ̀ oun ṣì jẹ ẹru si ofin ẹṣẹ sibẹ ati nipa bayii a da a lẹbi iku. Bi o ti wu ki o ri, Pọọlu le kun fun ọpẹ pe nipa ẹbọ Kristi a polongo oun ni olododo—ti a gbala kuro ninu ofin ẹṣẹ ati abajade ti o yẹ, idalẹbi si iku.—Roomu 7:25.
Awọn Kristẹni lonii ko si labẹ Ofin Mose, nitori a ti kan an mọ òpó igi idaloro. (Roomu 7:4-6; Kolose 2:14) Sibẹ a ṣe daradara lati mọ daju pe kii ṣe akojọ ofin ti o nira ti a ko nilati fiyesi. Bẹẹkọ, ní ipilẹ Ofin naa dara. A tipa bayii ni idi lati ka awọn iwe Bibeli ti o ni Ofin naa ninu ati lati mọ ohun ti o beere lọwọ Isirẹli. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika aye yoo maa ṣe eyi laipẹ, ni titẹle Bibeli kika wọn ọsọọsẹ.
Gẹgẹ bi a ti nka Ofin naa, o yẹ ki a ronu siwa sẹhin lori awọn ilana ti o wa labẹ oniruuru awọn ilana ofin ati lori awọn anfaani ti awọn eniyan Ọlọrun jere gẹgẹ bi wọn ti gbiyanju lati tẹle awọn aṣẹ rere wọnni. A nilati mọriri, pẹlu, pe a jẹ alaipe a ko si le tẹle ohun rere ti a kọ́ lati inu Ọrọ Ọlọrun patapata. Ṣugbọn nigba ti a njijakadi lodi si ofin ẹṣẹ, awa le yọ lori ifojusọna jijẹ ẹni ti a gbà silẹ nipasẹ ifisilo ẹbọ Kristi fun wa.