ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 19-24
  • Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Kristi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Kristi
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Nínú Ìdílé
  • Nínú Ìjọ
  • Àwọn Alàgbà Ń Lo Òfin Kristi
  • Gbígbé ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Kristi
  • Òfin Kristi Wà Lẹ́nu Iṣẹ́!
  • Òfin Kristi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nínú Ìjọ Kristẹni (Apá Kejì Nínú Mẹ́rin)
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Wá Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Yìí
    Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká 2017-2018​—Tí Aṣojú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Máa Bá Wa Ṣe
  • Kí ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa Lónìí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 19-24

Gbígbé Ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Kristi

“Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kíní kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.”—GÁLÁTÍÀ 6:2.

1. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé òfin Kristi jẹ́ ipá alágbára tí ń ṣiṣẹ́ fún rere lónìí?

NÍ Rwanda, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ Hutu àti Tutsi fi ẹ̀mí ara wọn wewu láti dáàbò bo ara wọn lẹ́nì kíní kejì kúrò lọ́wọ́ ìpakúpa ẹ̀yà tí ó gba ilẹ̀ náà kan láìpẹ́ yìí. Àdánù tí ó dé bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kobe, Japan, tí wọ́n pàdánù àwọn mẹ́ḿbà ìdílé wọn nínú ìmìtìtì ilẹ̀ tí ń ṣèparun kó ìbànújẹ́ bá wọn gidigidi. Síbẹ̀, wọ́n lọ lọ́gán láti gba àwọn òjìyà míràn là. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àpẹẹrẹ tí ń mọ́kàn yọ̀ kárí ayé fi hàn pé òfin Kristi wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí. Ó jẹ́ ipá ìdarí tí ń ṣiṣẹ́ fún rere.

2. Báwo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ṣàìlóye òfin Kristi, báwo sì ni a ṣe lè mú òfin yẹn ṣẹ?

2 Lọ́wọ́ kan náà, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì nípa “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” líle koko ń ní ìmúṣẹ. Ọ̀pọ̀ ní “àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run,” ṣùgbọ́n “wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” (Tímótì Kejì 3:1, 5) Ní pàtàkì, nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìsìn wulẹ̀ jẹ́ oréfèé, kì í ṣe látọkàn wá. Ìyẹn ha jẹ́ nítorí pé ó ṣòro ju láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi bí? Rárá o. Jésù kì yóò fún wa ní òfin tí kò ṣeé tẹ̀ lé. Kirisẹ́ńdọ̀mù kò wulẹ̀ lóye òfin yẹn ni. Ó ti kùnà láti kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí yìí pé: “Ẹ máa bá a lọ ní ríru àwọn ẹrù ìnira ara yín lẹ́nì kíní kejì, kí ẹ sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ.” (Gálátíà 6:2) A ń “mú òfin Kristi ṣẹ” nípa ríru àwọn ẹrù ìnira ẹnì kíní kejì, kì í ṣe nípa fífara wé àwọn Farisí, kí a sì máa fi àìtọ́ dì kún ẹrù àwọn ará wa.

3. (a) Kí ni àwọn àṣẹ díẹ̀ tí ó wà nínú òfin Kristi? (b) Èé ṣe tí yóò fi ṣàìtọ́ láti parí èrò pé kò yẹ kí ìjọ Kristẹni ní ìlànà ju àṣẹ tí Kristi pa ní tààràtà?

3 Òfin Kristi ní gbogbo àṣẹ Kristi Jésù nínú—ì báà jẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni, mímú kí ojú mọ́ gaara, kí ó sì mú ọ̀nà kan, ṣíṣiṣẹ́ láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú aládùúgbò wa, tàbí mímú ìwà àìmọ́ kúrò nínú ìjọ. (Mátíù 5:27-30; 18:15-17; 28:19, 20; Ìṣípayá 2:14-16) Ní tòótọ́, ó di dandan fún àwọn Kristẹni láti pa gbogbo àṣẹ tí ó wà nínú Bíbélì mọ́, tí a fún àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Kò tán síbẹ̀ o. Ètò àjọ Jèhófà, títí kan ìjọ kọ̀ọ̀kan, ní láti gbé àwọn ìlànà àti ọ̀nà ìgbàṣe nǹkan tí ó pọn dandan kalẹ̀, kí ó ba lè ṣeé ṣe láti pa ìwà létòlétò tí ó dára mọ́. (Kọ́ríńtì Kìíní 14:33, 40) Họ́wù, kò tilẹ̀ lè ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni láti pàdé pọ̀, bí wọn kò bá ní àwọn ìlànà nípa ìgbà tí wọn yóò máa ṣe irú àwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀, ibi tí wọn yóò ti máa ṣe wọ́n, àti bí wọn yóò ṣe máa ṣe wọ́n! (Hébérù 10:24, 25) Fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà bíbọ́gbọ́n mu tí àwọn tí a fún ní ọlá àṣẹ nínú ètò àjọ náà gbé kalẹ̀ tún jẹ́ apá kan mímú òfin Kristi ṣẹ.—Hébérù 13:17.

4. Kí ni ipá asúnniṣiṣẹ́ ti ń bẹ lẹ́yìn ìjọsìn mímọ́ gaara?

4 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í jẹ́ kí ìjọsìn wọn di ìtòlẹ́sẹẹsẹ òfin tí kò nítumọ̀. Wọn kò ṣiṣẹ́ sin Jèhófà kìkì nítorí pé àwọn kan tàbí ètò àjọ kan sọ fún wọn pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ ni ipá tí ń sún wọn láti jọ́sìn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ Kristi sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (Kọ́ríńtì Kejì 5:14, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé, NW) Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ́nì kíní kejì. (Jòhánù 15:12, 13) Ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ ni ìpìlẹ̀ òfin Kristi, ó sì sọ ọ́ di dandan fún àwọn Kristẹni, tàbí ó ń sún wọn ṣiṣẹ́ níbi gbogbo, nínú ìdílé àti nínú ìjọ. Ẹ jẹ́ kí a wo bí ó ṣe rí bẹ́ẹ̀.

Nínú Ìdílé

5. (a) Báwo ni àwọn òbí ṣe lè mú ìfẹ́ Kristi ṣẹ nínú ilé? (b) Kí ni àwọn ọmọ ń fẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn, àwọn ohun ìdènà wo sì ni àwọn òbí kan gbọ́dọ̀ ṣẹ́pá kí wọ́n ba lè pèsè rẹ̀?

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Nígbà tí ọkọ bá fara wé Kristi, tí ó sì fi ìfẹ́ àti òye bá aya rẹ̀ lò, ó ń mú apá pàtàkì nínú òfin Kristi ṣẹ. Síwájú sí i, Jésù fi ìfẹ́ni hàn ní gbangba fún àwọn ọmọdé, ní gbígbé wọn sí apá rẹ̀, ní gbígbé ọwọ́ lé wọn, àti ní sísúre fún wọn. (Máàkù 10:16) Àwọn òbí tí wọ́n ń mú òfin Kristi ṣẹ pẹ̀lú máa ń fi ìfẹ́ni hàn fún àwọn ọmọ wọn. Ní tòótọ́, àwọn òbí kan wà tí wọ́n rí i pé ó ṣòro láti fara wé àpẹẹrẹ Jésù lórí èyí. Àwọn kan kì í lè fi ìmọ̀lára wọn hàn ní ti ẹ̀dá. Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe jẹ́ kí irú èrò bẹ́ẹ̀ dí yín lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ tí ẹ ní fún àwọn ọmọ yín hàn sí wọn! Kìkì kí ẹ̀yin nìkan mọ̀ pé ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ yín kò tó. Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ mọ̀ ọ́n. Wọn kì yóò sì mọ̀ ọ́n, àyàfi bí ẹ bá wá ọ̀nà láti fi ìfẹ́ yín hàn.—Fi wé Máàkù 1:11.

6. (a) Àwọn ọmọ ha nílò ìlànà òbí bí, èé ṣe tí o sì fi dáhùn bẹ́ẹ̀? (b) Kí ni ìdí ìpìlẹ̀ fún ìlànà agboolé, tí àwọn ọmọ ní láti lóye? (d) Àwọn ewu wo ni a ń yẹra fún nígbà tí òfin Kristi bá gbilẹ̀ nínú agboolé?

6 Lọ́wọ́ kan náà, àwọn ọmọ nílò ààlà, èyí tí ó túmọ̀ sí pé àwọn òbí ní láti gbé ìlànà kalẹ̀, wọ́n sì ní láti mú kí a pa ìlànà wọ̀nyí mọ́ nígbà míràn nípasẹ̀ ìbáwí. (Hébérù 12:7, 9, 11) Síbẹ̀síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ ní ìṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé láti rí ìdí ìpìlẹ̀ fún àwọn ìlànà wọ̀nyí pé: àwọn òbí wọn nífẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ ni ìdí tí ó dára jù lọ tí wọ́n fi ní láti ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn. (Éfésù 6:1; Kólósè 3:20; Jòhánù Kìíní 5:3) Góńgó àwọn òbí tí ń lo ìfòyemọ̀ jẹ́ láti kọ́ àwọn èwe láti lo “agbára ìmọnúúrò” wọn kí àwọn fúnra wọn baà lè ṣe ìpinnu tí ó yè kooro lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. (Róòmù 12:1; fi wé Kọ́ríńtì Kìíní 13:11.) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò yẹ kí ìlànà pọ̀ jù tàbí kí ìbáwí lè koko jù. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21; Éfésù 6:4) Nígbà tí òfin Kristi bá gbilẹ̀ nínú agboolé, kì í sí àyè fún ìbáwí tí a ń fúnni pẹ̀lú ìbínú tí a kò ṣàkóso, tàbí ọ̀rọ̀ aṣa tí ń pani lára. Nínú irú ilé bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ máa ń nímọ̀lára ààbò àti ìgbéniró, a kì í dẹrù pa wọ́n, tàbí rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.—Fi wé Orin Dáfídì 36:7.

7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì fi ń pèsè àpẹẹrẹ nígbà tí ó bá dórí gbígbé ìlànà kalẹ̀ nínú ilé?

7 Àwọn kan tí wọ́n ti ṣèbẹ̀wò sí àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé sọ pé wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere ní ti wíwà déédéé lórí ọ̀ràn ìlànà fún ìdílé. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà ni ó wà níbẹ̀, irú àwọn ilé iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ wà gẹ́gẹ́ bí ìdílé.a Iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì pọ̀, ó sì ń béèrè fún àwọn ìlànà mélòó kan—dájúdájú ju ti ìdílé kan tí ó mọ níwọ̀n lọ. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn alàgbà tí ń mú ipò iwájú ní àwọn ibi ìdarí ilé Bẹ́tẹ́lì, àwọn ọ́fíìsì, àti àwọn ilé iṣẹ́ ń sakun láti lo òfin Kristi. Wọ́n wò ó pé iṣẹ́ àyànfúnni wọn kì í ṣe láti ṣètò iṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti gbé ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí, àti “ayọ̀ Olúwa” pẹ̀lú lárugẹ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. (Nehemáyà 8:10) Nítorí náà, wọ́n ń sakun láti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tí ó dára, tí ó sì ń fúnni níṣìírí, wọ́n sì ń làkàkà láti jẹ́ afòyebánilò. (Éfésù 4:31, 32) Abájọ tí a fi mọ àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì fún ẹ̀mí aláyọ̀ wọn!

Nínú Ìjọ

8. (a) Kí ni ó yẹ kí ó má fìgbà gbogbo jẹ́ góńgó wa nínú ìjọ? (b) Lábẹ́ àwọn àyíká ipò wo ni àwọn kan ti béèrè fún ìlànà, tàbí tí wọ́n ti gbìyànjú láti ṣe ìlànà?

8 Nínú ìjọ, ó jẹ́ góńgó wa bákan náà láti gbé ara wa ró lẹ́nì kíní kejì nínú ẹ̀mí ìfẹ́. (Tẹsalóníkà Kìíní 5:11) Nítorí náà, gbogbo Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣe dì kún ẹrù ìnira àwọn ẹlòmíràn nípa gbígbìyànjú láti gbé èrò tiwọn kani lórí, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ́ ti ìpinnu ara ẹni. Nígbà míràn, àwọn kán máa ń kọ̀wé sí Watch Tower Society ní bíbéèrè fún ìlànà lórí àwọn ọ̀ràn bí ojú ìwòye tí ó yẹ kí wọ́n ní nípa àwọn fíìmù, ìwé, àní àwọn ohun ìṣeré kan pàtó. Síbẹ̀, Society kò ní ọlá àṣẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ fínnífínní, kí wọ́n sì ṣe ìpinnu lórí wọn. Nínú ọ̀ràn púpọ̀ jù lọ, ìwọ̀nyí máa ń jẹ́ ọ̀ràn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí tí olórí ìdílé yẹ kí ó pinnu, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn ìlànà Bíbélì. Àwọn mìíràn máa ń fẹ́ sọ àwọn àbá àti ìtọ́sọ́nà Society di ìlànà. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àtàtà kan wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, March 15, 1996, tí ń fún àwọn alàgbà níṣìírí láti máa ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sọ́dọ̀ àwọn mẹ́ḿbà ìjọ déédéé. Ète rẹ̀ ha jẹ́ láti gbé àwọn ìlànà kalẹ̀ bí? Rárá o. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ó ṣeé ṣe fún láti tẹ̀ lé àwọn àbá náà rí ọ̀pọ̀ àǹfààní, kò ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà kan láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lọ́nà kan náà, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1995, kìlọ̀ nípa bíbu iyì àkókò batisí kù nípa ṣíṣe àṣejù, irú bíi pípe àpèjẹ tí a kò ṣàkóso tàbí ṣíṣe ìyanfanda ìjagunmólú. Àwọn kan ti ki àṣejù bọ ìmọ̀ràn onírònújinlẹ̀ yìí, tí wọ́n tilẹ̀ ṣe ìlànà pàápàá pé fífi káàdì ìṣírí ráńṣẹ́ nígbà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò tọ́!

9. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì pé kí a yẹra fún líle koko jù àti dídá ara wa lẹ́nì kíní kejì lẹ́jọ́?

9 Ronú pẹ̀lú pé, bí “òfin tí ó jẹ́ ti òmìnira” yóò bá gbilẹ̀ láàárín wa, a gbọ́dọ̀ gbà pé kì í ṣe gbogbo ẹ̀rí ọkàn Kristẹni ni ó rí bákan náà. (Jákọ́bù 1:25) Ó ha yẹ kí á bínú bí àwọn ènìyàn bá ṣe yíyàn tí kò tẹ ìlànà Ìwé Mímọ́ lójú? Rárá o. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wa yóò fa ìyapa. (Kọ́ríńtì Kìíní 1:10) Pọ́ọ̀lù, nígbà tí ó ń kìlọ̀ fún wa nípa ṣíṣe ìdájọ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ ẹni, sọ pé: “Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú. Ní tòótọ́, a óò mú un dúró, nítorí Jèhófà lè mú un dúró.” (Róòmù 14:4) A wà nínú ewu mímú Jèhófà bínú, bí a bá ń sọ̀rọ̀ sí ara wa lórí àwọn ọ̀ràn tí ó yẹ kí a fi sílẹ̀ fún ẹ̀rí ọkàn ẹnì kọ̀ọ̀kan.—Jákọ́bù 4:10-12.

10. Àwọn wo ni a yàn láti bójú tó ìjọ, báwo sì ni ó ṣe yẹ kí a tì wọ́n lẹ́yìn?

10 Ẹ jẹ́ kí á rántí pẹ̀lú pé, a yan àwọn alàgbà láti bójú tó agbo Ọlọ́run. (Ìṣe 20:28) Wọ́n wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Ó yẹ kí a lómìnira láti tọ̀ wọ́n lọ fún ìmọ̀ràn, nítorí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì mọ ohun tí a ti jíròrò nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Watch Tower Society ní àmọ̀dunjú. Nígbà tí àwọn alàgbà bá rí ìwà tí ó ṣeé ṣe kí ó ṣamọ̀nà sí títẹ àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ lójú, wọ́n ń fi àìṣojo fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó yẹ. (Gálátíà 6:1) Àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ń tẹ̀ lé òfin Kristi nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́ àgùntàn ọ̀wọ́n wọ̀nyí, tí wọ́n ń mú ipò iwájú láàárín wọn.—Hébérù 13:7.

Àwọn Alàgbà Ń Lo Òfin Kristi

11. Báwo ni àwọn alàgbà ṣe ń lo òfin Kristi nínú ìjọ?

11 Àwọn alàgbà ń hára gàgà láti mú òfin Kristi ṣẹ nínú ìjọ. Wọ́n ń mú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere náà, wọ́n ń kọ́ni láti inú Bíbélì, kí wọ́n baà lè dé inú ọkàn-àyà àti, gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́, ẹni pẹ̀lẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ fún “àwọn ọkàn tí ó soríkọ́.” (Tẹsalóníkà Kìíní 5:14) Wọ́n ń yẹra fún ìṣarasíhùwà tí kì í ṣe ti Kristẹni tí ń wáyé nínú ọ̀pọ̀ jáǹtírẹrẹ ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ní tòótọ́, ayé yìí ń bàjẹ́ lọ lọ́nà yíyára kánkán, àti gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, àwọn alàgbà lè ṣàníyàn nítorí ìjọ; ṣùgbọ́n wọ́n ń wà déédéé bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ lórí irú àníyàn bẹ́ẹ̀.—Kọ́ríńtì Kejì 11:28.

12. Nígbà tí Kristẹni kan bá tọ alàgbà kan lọ fún ìrànwọ́, báwo ni alàgbà náà ṣe lè dáhùn padà?

12 Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni kan lè fẹ́ láti wá ìrànlọ́wọ́ alàgbà kan lórí ọ̀ràn pàtàkì kan tí àwọn ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ ní tààràtà kò kárí tàbí tí ó béèrè fún mímú kí àwọn ìlànà Kristẹni tí ó yàtọ̀ síra wà déédéé. Bóyá wọ́n ti fún un ní ìgbéga tí owó rẹ̀ pọ̀ sí i, níbi iṣẹ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹrù iṣẹ́ gíga sí i. Tàbí aláìgbàgbọ́ kan tí ó jẹ́ bàbá ọ̀dọ́ Kristẹni kan lè máa béèrè àwọn nǹkan lọ́wọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ tí ó lè nípa lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, àwọn alàgbà ń yẹra fún fífúnni ní èrò ara ẹni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lè ṣí Bíbélì, kí ó sì ran ẹni náà lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ìlànà tí wọ́n tan mọ́ ọn. Ó lè lo ìwé Watch Tower Publications Index, bí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó, láti ṣàwárí ohun tí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” náà ti sọ lórí kókó ẹ̀kọ́ náà nínú àwọn ojú ewé Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn. (Mátíù 24:45) Bí Kristẹni náà lẹ́yìn náà bá ṣe ìpinnu tí ó dà bí ẹni pé kò bọ́gbọ́n mu lójú alàgbà náà ń kọ́? Bí ìpinnu náà kò bá ré àwọn ìlànà tàbí òfin Bíbélì kọjá ní tààràtà, Kristẹni náà yóò rí i pé alàgbà náà mọ̀ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀, ní mímọ pé “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” Ṣùgbọ́n, Kristẹni náà gbọ́dọ̀ rántí pé, “ohun yòó wù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú.”—Gálátíà 6:5, 7.

13. Dípò fífúnni ní ìdáhùn tààràtà sí àwọn ìbéèrè tàbí fífúnni ní èrò ara wọn, èé ṣe tí àwọn alàgbà fi ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ọ̀ràn?

13 Èé ṣe tí alàgbà onírìírí fi ń gbégbèésẹ̀ lọ́nà yìí? Ó kéré tán, fún ìdí méjì ni. Lákọ̀ọ́kọ́, Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ kan pé òun kì í ṣe ‘ọ̀gá lórí ìgbàgbọ́ wọn.’ (Kọ́ríńtì Kejì 1:24) Bí alàgbà náà ti ń ran arákùnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti ronú lórí Ìwé Mímọ́, kí ó sì ṣe ìpinnu tí a gbé karí ìmọ̀, òun ń ṣe àfarawé ìṣarasíhùwà Pọ́ọ̀lù. Ó mọ̀ pé ọlá àṣẹ òun ní ààlà, gan-an gẹ́gẹ́ bí Jésù ti mọ̀ pé ọlá àṣẹ tòun ní ààlà. (Lúùkù 12:13, 14; Júúdà 9) Lọ́wọ́ kan náà, àwọn alàgbà ń fi ìmúratán pèsè ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tí ń ranni lọ́wọ́, tí ó ṣe tààràtà pàápàá, níbi tí a bá ti nílò rẹ̀. Ìkejì, ó ń dá Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Oúnjẹ líle jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí ó dàgbà dénú, ti àwọn wọnnì tí wọ́n tipasẹ̀ lílò kọ́ agbára ìmòye wọn láti fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Hébérù 5:14) Nítorí náà, láti dàgbà dénú, a ní láti lo agbára ìwòye wa, kì í ṣe láti máa fìgbà gbogbo gbára lé ẹnì kan láti pinnu fún wa. Bí alàgbà náà ti ń fi bí a ti í ronú lórí Ìwé Mímọ́ han Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó ń ràn án lọ́wọ́ lọ́nà yìí láti tẹ̀ síwájú.

14. Báwo ni àwọn adàgbàdénú ṣe lè fi hàn pé wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?

14 A lè ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run, nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, yóò darí ọkàn-àyà àwọn olùjọsìn tòótọ́. Nípa báyìí, àwọn Kristẹni adàgbàdénú máa ń dé inú ọkàn-àyà àwọn arákùnrin wọn, ní pípàrọwà fún wọn, gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe. (Kọ́ríńtì Kejì 8:8; 10:1; Fílémónì 8, 9) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo ní pàtàkì ni ó nílò kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin láti tọ́ wọn sọ́nà, kì í ṣe àwọn olódodo. (Tímótì Kìíní 1:9) Ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó sọ jáde, kì í ṣe ìfura tàbí àìnígbẹkẹ̀lé. Ó kọ̀wé sí ìjọ kan pé: “Àwa ní ìgbọ́kànlé nínú Olúwa nípa yín.” (Tẹsalóníkà Kejì 3:4) Ó dájú pé ìgbàgbọ́, ìgbẹ́kẹ̀lé, àti ìgbọ́kànlé Pọ́ọ̀lù ṣe bẹbẹ láti sún àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ṣiṣẹ́. Àwọn alàgbà àti alábòójútó arìnrìn àjò lónìí ní ìfojúsùn kan náà. Ẹ wo bí àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ti ń tuni lára tó, bí wọ́n ti ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣolùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run!—Aísáyà 32:1, 2; Pétérù Kìíní 5:1-3.

Gbígbé ní Ìbámu Pẹ̀lú Òfin Kristi

15. Kí ni àwọn ìbéèrè díẹ̀ tí a lè bí ara wa láti mọ̀ bóyá a ń lo òfin Kristi nínú ipò ìbátan wa pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa?

15 Gbogbo wa ní láti ṣàyẹ̀wò ara wa déédéé láti rí i bóyá a ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi, tí a sì ń gbé e lárugẹ. (Kọ́ríńtì Kejì 13:5) Ní ti gidi, gbogbo wa lè jàǹfààní nípa bíbéèrè pé: ‘Mo ha ń gbéni ró tàbí mo ha jẹ́ aṣelámèyítọ́ bí? Mo ha wà déédéé tàbí mo ha jẹ́ aláṣejù? Mo ha ń gba ti àwọn ẹlòmíràn rò tàbí tèmi ni mo máa ń fẹ́ kí ó ṣẹ?’ Kristẹni kan kì í gbìyànjú láti pàṣẹ ìgbésẹ̀ tí arákùnrin rẹ̀ gbọ́dọ̀ gbé àti èyí tí kò gbọdọ̀ gbé lórí ọ̀ràn tí Bíbélì kò kárí ní pàtó.—Róòmù 12:1; Kọ́ríńtì Kìíní 4:6.

16. Báwo ni a ṣe lè ran àwọn tí ó ní ojú ìwòye òdì nípa ara wọn lọ́wọ́, ní títipa báyìí mú apá pàtàkì nínú òfin Kristi ṣẹ?

16 Ní àwọn àkókò líle koko wọ̀nyí, ó ṣe pàtàkì fún wa láti máa wá ọ̀nà láti fún ara wa níṣìírí lẹ́nì kíní kejì. (Hébérù 10:24, 25; fi wé Mátíù 7:1-5.) Nígbà tí a bá wo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, àwọn ànímọ́ rere wọn kò ha ṣe pàtàkì púpọ̀ fún wa ju àìlera wọn bí? Lójú Jèhófà, ẹnì kọ̀ọ̀kan ni ó ṣe iyebíye. Lọ́nà tí kò múni láyọ̀, kì í ṣe gbogbo ènìyàn ní ń nímọ̀lára lọ́nà yẹn, àní nípa ara wọn pàápàá. Ọ̀pọ̀ máa ń rí kìkì àṣìṣe àti àìpé ara wọn. Láti fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ níṣìírí—àti àwọn ẹlòmíràn—a ha lè gbìyànjú láti bá ẹnì kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ ní ìpàdé kọ̀ọ̀kan, ní jíjẹ́ kí wọ́n mọ ìdí tí a fi mọrírì wíwá wọn, àti ipa pàtàkì tí wọ́n ń kó nínú ìjọ bí? Ẹ wo ìdùnnú tí ó jẹ́ láti mú ẹrù ìnira wọn fúyẹ́ lọ́nà yìí, kí a sì tipa báyìí mú òfin Kristi ṣẹ!—Gálátíà 6:2.

Òfin Kristi Wà Lẹ́nu Iṣẹ́!

17. Àwọn ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wo ni o ti rí i pé òfin Kristi wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ìjọ rẹ?

17 Òfin Kristi wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni. A ń rí i lójoojúmọ́—nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ́ ẹni bá ń fi ìháragàgà ṣàjọpín ìhìn rere náà, nígbà tí wọ́n bá ń tu ara wọn lẹ́nì kíní kejì nínú, tí wọ́n sì ń fún ara wọn lẹ́nì kíní kejì níṣìírí, nígbà tí wọ́n bá ń jìjàkadì láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà láìka àwọn ìṣòro tí ó lè koko jù lọ sí, nígbà tí àwọn òbí bá ń làkàkà láti tọ́ àwọn ọmọ wọn láti fẹ́ràn Jèhófà pẹ̀lú ọkàn-àyà onídùnnú, nígbà tí àwọn alábòójútó bá ń fi ìfẹ́ àti ọ̀yàyà kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ríru agbo sókè láti ní ìtara tí ń jó fòfò láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà títí láé. (Mátíù 28:19, 20; Tẹsalóníkà Kìíní 5:11, 14) Nígbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa bá ń lo òfin Kristi nínú ìgbésí ayé wa, ẹ wo bí ọkàn-àyà Jèhófà ti ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó! (Òwe 23:15) Ó ń fẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn òfin pípé rẹ̀ wà láàyè títí láé. Nínú Párádísè tí ń bọ̀, a óò rí àkókò kan nígbà tí aráyé yóò jẹ́ pípé, àkókò kan láìsí àwọn arúfin, àti àkókò kan nígbà tí gbogbo èrò ọkàn wa yóò wà lábẹ̀ àkóso. Ẹ wo èrè ológo tí ó jẹ́ láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú òfin Kristi!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú àwọn ilé bẹ́ẹ̀ kò dà bí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti Kirisẹ́ńdọ̀mù. Kò sí àwọn “olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn,” tàbí “àwọn bàbá,” ní èrò ìtumọ̀ ìyẹn níbẹ̀. (Mátíù 23:9) A ń bọ̀wọ̀ fún àwọn arákùnrin tí wọ́n ṣeé fa ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ìlànà kan náà tí ń darí àwọn alàgbà ní ń darí iṣẹ́ ìsìn wọn.

Kí Ni Èrò Rẹ?

◻ Èé ṣe tí Kirisẹ́ńdọ̀mù kò fi lóye òfin Kristi?

◻ Báwo ní a ṣe lè lo òfin Kristi nínú ìdílé?

◻ Láti lo òfin Kristi nínú ìjọ, kí ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún, kí sì ni a gbọ́dọ̀ ṣe?

◻ Báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ṣègbọràn sí òfin Kristi nínú ìbálò wọn pẹ̀lú ìjọ?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ohun tí ọmọ rẹ nílò jù lọ ni ìfẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ẹ wo bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn wa onífẹ̀ẹ́ ti ń tuni lára tó!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́