ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/15 ojú ìwé 2-7
  • Gbogbo Ìsìn Ni Inú Ọlọ́run Ha Dùn Sí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Ìsìn Ni Inú Ọlọ́run Ha Dùn Sí Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Fi Èso Wọn Dá Wọn Mọ̀
  • Ìdí fún Ìṣọ́ra
  • Ṣàyẹ̀wò Èso Náà
  • Àkókò fún Ìgbésẹ̀ Onípinnu
  • Ìjọsìn Tó Ní Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
    Òpin Ìsìn Èké Sún Mọ́lé!
  • Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ǹjẹ́ Gbogbo Ẹ̀sìn ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/15 ojú ìwé 2-7

Gbogbo Ìsìn Ni Inú Ọlọ́run Ha Dùn Sí Bí?

O ha rò pé gbogbo ìsìn ni inú Ọlọ́run dùn sí bí? Ó ṣeé ṣe pé, ó kéré tán, dé ìwọ̀n àyè kan, gbogbo ìsìn tí o mọ̀ ní ń fún ìwà rere níṣìírí. Ṣùgbọ́n, ìyẹn ha tó láti mú inú Ọlọ́run dùn bí?

ÀWỌN kan máa ń sọ pé, ‘Ṣáà ti fi òótọ́ inú jọ́sìn, inú Ọlọ́run yóò sì dùn. Gbogbo ìsìn ni ó dára.’ Fún àpẹẹrẹ, ìsìn Bahai ti tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye yìí débi mímú ìsìn mẹ́sàn-án tí ó ṣe pàtàkì jù lọ lágbàáyé wọnú ìgbàgbọ́ rẹ̀. Àwùjọ ìsìn yìí ronú pé gbogbo ìwọ̀nyí pilẹ̀ṣẹ̀ látọ̀runwá àti pé, wọ́n jẹ́ onírúurú ẹ̀ka òtítọ́ kan ṣoṣo. Báwo ni èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?

Síwájú sí i, o lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe kàyéfì nípa bí ìsìn kan ṣe lè dùn mọ́ Ọlọ́run nínú nígbà tí ó bá ń pàṣẹ fún àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ láti ri gáàsì aséniléèémí mọ́lẹ̀ ní ibi tí èrò ń gbà, kí ó baà lè pa ọ̀pọ̀ ènìyàn. A ti fẹ̀sùn ìyẹn kan àwùjọ ìsìn kan ní Japan. Àbí inú Ọlọ́run ha dùn sí ìsìn tí ń mú kí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ fọwọ́ ara wọn pa ara wọn bí? Ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọlẹ́yìn aṣáájú ìsìn náà, Jim Jones.

Bí a bá wẹ̀yìn padà sí ìgbà àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, a lè béèrè pé, Inú Ọlọ́run ha lè dùn sí àwọn ìsìn bí, nígbà tí wọ́n bá ń súnná sógun, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Ogun Ọgbọ̀n Ọdún, tí a jà láti ọdún 1618 sí 1648? Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, The Universal History of the World, ti sọ, ìforígbárí ìsìn yẹn láàárín àwọn onísìn Kátólíìkì àti Pùròtẹ́sítáǹtì jẹ́ “ọ̀kan lára àwọn ogun tí ó tí ì burú jù lọ nínú ìtàn Europe.”

Ogun Ìsìn tí a jà láti ọrúndún kọkànlá sí ìkẹtàlá pẹ̀lú yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ bíbani lẹ́rù. Fún àpẹẹrẹ, nínú Ogun Ìsìn àkọ́kọ́, àwọn tí wọ́n pe ara wọn ní ajagun Kristẹni pa àwọn Mùsùlùmí àti àwọn Júù tí ń gbé Jerúsálẹ́mù nípakúpa.

Ronú pẹ̀lú, nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹtàlá, tí ó sì gba nǹkan bíi 600 ọdún. A dá ẹgbẹẹgbẹ̀rún lóró, a sì dáná sun wọ́n látàrí àṣẹ àwọn aṣáájú ìsìn. Nínú ìwé rẹ̀, Vicars of Christ—The Dark Side of the Papacy, Peter De Rosa sọ pé: “Lórúkọ póòpù, [àwọn olùwádìí láti gbógun ti àdámọ̀] ni wọ́n jẹ̀bi àtakò gbígbóná janjan jù lọ, tí ó ń bá a nìṣó, tí a tí ì ṣe sí iyì ẹ̀dá ènìyàn nínú ìtàn ìran [aráyé].” De Rosa sọ nípa ọmọ ẹgbẹ́ Dominic náà, Torquemada ti Sípéènì, tí í ṣe olùwádìí láti gbógun ti àdámọ̀ pé: “A yàn án sípò ní ọdún 1483, ó sì ṣàkóso fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún gẹ́gẹ́ bí òṣìkà agbonimọ́lẹ̀. Àwọn tí ó pa ju 114,000 lọ, tí ó sì dáná sun 10,220 lára wọn.”

Àmọ́ ṣáá o, kì í ṣe àwọn ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù nìkan ni ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Nínú ìwé rẹ̀, Pensées, ọlọ́gbọ́n èrò orí, ọmọ ilẹ̀ Faransé, Blaise Pascal sọ pé: “Àwọn ènìyàn kì í fi tọkàntọkàn àti tayọ̀tayọ̀ ṣe búburú tó bí ìgbà tí wọ́n bá ṣe é láti inú ìdálójú ìgbàgbọ́ ìsìn.”

A Fi Èso Wọn Dá Wọn Mọ̀

Láti ojú ìwòye Ọlọ́run, títẹ́wọ́ gba ìsìn kan kò sinmi lórí kókó abájọ kan ṣoṣo. Kí ìsìn kan baà lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un, ẹ̀kọ́ rẹ̀ àti ìgbòkègbodò rẹ̀ gbọ́dọ̀ bá òtítọ́ Ọ̀rọ̀ alákọsílẹ̀ rẹ̀, Bíbélì, mu. (Orin Dáfídì 119:160; Jòhánù 17:17) Èso ìjọsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí gbọ́dọ̀ bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà Ọlọ́run mu.

Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù Kristi tọ́ka sí i pé àwọn wòlíì èké yóò wà, tí wọn yóò máa sọ pé wọ́n ń ṣojú fún Ọlọ́run. Jésù wí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn wòlíì èké tí ń wá sọ́dọ̀ yín nínú ìbora àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọ́n jẹ́ ọ̀yánnú ìkookò. Nípa àwọn èso wọn ni ẹ̀yin yóò fi dá wọn mọ̀. Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti inú ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti inú òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò níláárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò níláárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. Gbogbo igi tí kò ń mú èso àtàtà jáde ni a óò ké lulẹ̀ tí a óò sì sọ sínú iná. Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ̀yin yóò fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.” (Mátíù 7:15-20) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé a ní láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí. A lè rò pé Ọlọ́run àti Kristi tẹ́wọ́ gba aṣáájú ìsìn kan tàbí àwùjọ ìsìn kan, ṣùgbọ́n ó lè jẹ́ pé àṣìṣe ní a ń ṣe.

Ìdí fún Ìṣọ́ra

Bí ìsìn kan tilẹ̀ sọ pé òun ní ìfọwọ́sí Ọlọ́run, tí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ sì ń ka àwọn àyọkà láti inú Bíbélì, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó jẹ́ irú ìjọsìn tí inú Ọlọ́run dùn sí. Àwọn aṣáájú rẹ̀ tilẹ̀ lè ṣe àwọn ohun tí ń wúni lórí tí yóò fi dà bíi pé Ọlọ́run ń tipasẹ̀ wọn ṣiṣẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, ìsìn náà ṣì lè jẹ́ èké, tí kì í mú èso tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà jáde. Àwọn pidánpidán àlùfáà ará Íjíbítì ti ọjọ́ Mósè ṣe àwọn nǹkan tí ń wúni lórí, ṣùgbọ́n dájúdájú, Ọlọ́run kò tẹ́wọ́ gbà wọ́n.—Ẹ́kísódù 7:8-22.

Lónìí gẹ́gẹ́ bíi ti àtijọ́, ọ̀pọ̀ ìsìn ń gbé èrò àti ọgbọ́n èrò orí ẹ̀dá ènìyàn lárugẹ, dípò rírọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ ohun tí Ọlọ́run pè ní òtítọ́. Nígbà náà, ìkìlọ̀ Bíbélì náà ní pàtàkì bá a mu pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹni kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ọgbọ́n èrò orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.

Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ nípa èso rere àti búburú, Jésù wí pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ inú ìjọba àwọn ọ̀run, bí kò ṣe ẹni náà tí ń ṣe ìfẹ́ inú Bàbá mi tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò wá jẹ́wọ́ fún wọn dájúdájú pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.”—Mátíù 7:21-23.

Ṣàyẹ̀wò Èso Náà

Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, ó ṣe pàtàkì láti wo èso ìsìn kan kí a tó parí èrò pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà á. Fún àpẹẹrẹ, ìsìn náà ha ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú bí? Lẹ́yìn náà, ṣàkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí a kọ sílẹ̀ nínú Jákọ́bù 4:4 pé: “Ẹni yòó wù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” Síwájú sí i, Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tòótọ́ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Ìsìn tí ó dára lójú Ọlọ́run kì í lọ́wọ́ nínú ìṣèlú ayé yìí, èyí tí ó “wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà,” ẹ̀dá ẹ̀mí àìleèrí náà, Sátánì Èṣù. (Jòhánù Kìíní 5:19) Kàkà bẹ́ẹ̀, ìsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí ń fi ìdúróṣinṣin ṣalágbàwí Ìjọba rẹ̀ tí ó wà lábẹ́ Jésù Kristi, ó sì ń polongo ìhìn rere nípa ìjọba ọ̀run.—Máàkù 13:10.

Ọlọ́run ha tẹ́wọ́ gba ìsìn kan, bí ó bá ń ṣalágbàwí àìgbọràn sí àṣẹ ìjọba bí? Ìdáhùn náà ṣe kedere bí a bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Máa bá a lọ ní rírán wọn létí láti wà ní ìtẹríba àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àkóso àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso, láti gbara dì fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (Títù 3:1) Àmọ́ ṣáá o, Jésù fi hàn pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní láti “san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Máàkù 12:17.

Ká sọ pé ìsìn kan ń fún kíkópa nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè níṣìírí. Pétérù Kìíní 3:11 rọ̀ wá láti “ṣe ohun rere” àti láti ‘wá àlàáfíà kí a sì lépa rẹ̀.’ Báwo ni inú Ọlọ́run ṣe lè dùn sí ìsìn kan, bí àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ bá ń ní ìfẹ́ inú láti pa àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wọn ní orílẹ̀-èdè míràn nígbà ogun? Àwọn mẹ́ḿbà ìsìn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí máa ń ṣàfihàn ànímọ́ rẹ̀ gíga jù lọ—ìfẹ́. Jésù sì wí pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ìfẹ́ yẹn kò ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ìkórìíra oníkà tí a ń fún níṣìírí nínú ogun àwọn orílẹ̀-èdè.

Ìsìn tòótọ́ ń yí àwọn arógunyọ̀ ènìyàn padà sí àwọn olùfẹ́ àlàáfíà. A sàsọtẹ́lẹ̀ èyí nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Wọn óò fi idà wọn rọ ọ̀bẹ píláù, wọn óò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé; orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.” (Aísáyà 2:4) Dípò sísọ àwọn ọ̀rọ̀ ìkórìíra jáde, àwọn tí ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ ń pa àṣẹ náà mọ́ pé: “Ìwọ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Mátíù 22:39.

Àwọn tí ń ṣe ìsìn tòótọ́ ń làkàkà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ti Jèhófà Ọlọ́run, ní kíkọ̀ láti gbá ọ̀nà ìgbésí ayé oníwà pálapàla mú lò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kínla! Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo ènìyàn kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣe ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dàpọ̀, tàbí àwọn olè, tàbí àwọn oníwọra ènìyàn, tàbí àwọn ọ̀mùtípara, tàbí àwọn olùkẹ́gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀ ohun tí àwọn kan lára yín sì ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́, ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.”—Kọ́ríńtì Kìíní 6:9-11.

Àkókò fún Ìgbésẹ̀ Onípinnu

Ó ṣe pàtàkì láti fòye mọ ìyàtọ̀ láàárín ìjọsìn èké àti ìsìn tòótọ́. Nínú ìwé Bíbélì náà, Ìṣípayá, a tọ́ka sí ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé gẹ́gẹ́ bí “Bábílónì Ńlá,” aṣẹ́wó ìṣàpẹẹrẹ “tí àwọn ọba ilẹ̀ ayé bá ṣe àgbèrè.” Ó jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, ó sì mú ife oníwúrà kan “tí ó kún fún àwọn ohun ìríra àti àwọn ohun àìmọ́ àgbèrè rẹ̀” dání. (Ìṣípayá 17:1-6) Kò sí ohunkóhun nípa rẹ̀, tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà.

Àkókò nìyí fún ìgbésẹ̀ onípinnu. Sí àwọn ènìyàn olóòótọ́ inú tí wọ́n ṣì wà nínú Bábílónì Ńlá, Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́ nawọ́ ìkésíni yìí jáde pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn mi, bí ẹ kò bá fẹ́ ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, bí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ rẹ̀.”—Ìṣípayá 18:4.

Bí o bá fẹ́ láti ṣe ìsìn tí inú Ọlọ́run dùn sí, èé ṣe tí o kò fi túbọ̀ dojúlùmọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣáàtì tí ó bá ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí rìn ṣètòlẹ́sẹẹsẹ díẹ̀ lára àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, àti àwọn ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n ní. Ṣàyẹ̀wò Bíbélì rẹ láti rí i bí ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́ bá wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wádìí láti mọ̀ bóyá ìsìn wọn ń mú irú èso tí ìwọ yóò fojú sọ́nà fún lọ́dọ̀ ìjọsìn tòótọ́ jáde. Bí o bá rí i pé ó ń ṣe bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti ṣàwárí ìsìn tí inú Ọlọ́run dùn sí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

OHUN TÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ GBÀ GBỌ́

ÌGBÀGBỌ́ ÌPÌLẸ̀ ÌWÉ MÍMỌ́

Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run Ẹ́kísódù 6:3; Orin Dáfídì 83:18

Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Jòhánù 17:17; Tímótì Kejì 3:16, 17

Jésù Kristi jẹ́ Mátíù 3:16, 17; Jòhánù 14:28

Ọmọkùnrin Ọlọ́run

Aráyé kò dédé súyọ, Jẹ́nẹ́sísì 1:27; 2:7

ṣùgbọ́n a dá wọn ni

Ikú ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ nítorí Róòmù 5:12

ẹ̀ṣẹ̀ ènìyàn àkọ́kọ́

Ọkàn kò sí mọ́ nígbà ikú Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4

Hẹ́ẹ̀lì jẹ́ sàréè aráyé Jóòbù 14:13; Ìṣípayá 20:13,

ní gbogbogbòò King James Version

Àjíǹde ni ìrètí tí ó wà Jòhánù 5:28, 29; 11:25;

fún àwọn òkú Ìṣe 24:15

Kristi fi ìwàláàyè rẹ̀ lórí Mátíù 20:28; Pétérù Kìíní 2:24;

ilẹ̀ ayé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà Jòhánù Kìíní 2:1, 2

fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn

A gbọ́dọ̀ darí àdúrà sí Mátíù 6:9; Jòhánù 14:6, 13, 14

Jèhófà nìkan ṣoṣo nípasẹ̀ Kristi

A gbọ́dọ̀ ṣègbọ́ràn sí òfin Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 10

Bíbélì lórí ìwà híhù

A kò gbọdọ̀ lo ère nínú ìjọsìn Ẹ́kísódù 20:4-6;

Kọ́ríńtì Kìíní 10:14

A gbọ́dọ̀ yẹra fún ìbẹ́mìílò Diutarónómì 18:10-12;

Gálátíà 5:19-21

A kò gbọdọ̀ gba ẹ̀jẹ̀ sára Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4; Ìṣe 15:28, 29

Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tòótọ́ ń ya Jòhánù 15:19; 17:16;

ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára ayé Jákọ́bù 1:27; 4:4

Àwọn Kristẹni ń jẹ́rìí, ní Aísáyà 43:10-12;

pípolongo ìhìn rere náà Mátíù 24:14; 28:19, 20

Batisí nípa ìrìbọmi pátápátá Máàkù 1:9, 10; Jòhánù 3:22;

ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ sí Ìṣe 19:4, 5

Ọlọ́run hàn

Orúkọ oyè ti ìsìn kò bá Jóòbù 32:21, 22; Mátíù 23:8-12

Ìwé Mímọ́ mu

A ń gbé ní “ìgbà ìkẹyìn” Dáníẹ́lì 12:4; Mátíù 24:3-14;

Tímótì Kejì 3:1-5

Wíwà níhìn-ín Mátíù 24:3; Jòhánù 14:19;

Kristi kò ṣeé fojú rí Pétérù Kìíní 3:18

Sátánì ni alákòóso ayé yìí, Jòhánù 12:31; Jòhánù Kìíní 5:19

tí a kò lè fojú rí

Ọlọ́run yóò pa ètò ìgbékalẹ̀ Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 16:14, 16;

àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí run 18:1-8

Ìjọba Ọlọ́run lábẹ́ Kristi yóò Aísáyà 9:6, 7; Dáníẹ́lì 7:13, 14;

ṣàkóso ilẹ̀ ayé ní òdodo Mátíù 6:10

“Agbo kékeré” kan yóò ṣàkóso Lúùkù 12:32; Ìṣípayá 14:1-4; 20:4

pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run

Àwọn mìíràn tí Ọlọ́run fọwọ́ sí Lúùkù 23:43; Jòhánù 3:16;

yóò gba ìyè ayérayé lórí Ìṣípayá 21:1-4

párádísè ilẹ̀ ayé kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

A pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún nígbà Ìwádìí Láti Gbógun Ti Àdámọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn Ogun Ìsìn yọrí sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ bíbani lẹ́rù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Èso rere ìsìn tòótọ́ ni a fi ń mọ̀ ọ́n

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 2]

Ẹ̀yìn ìwé: Garo Nalbandian

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́