ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/15 ojú ìwé 10-15
  • Gbogbo Wa Gbọ́dọ̀ Jíhìn fún Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbogbo Wa Gbọ́dọ̀ Jíhìn fún Ọlọ́run
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Áńgẹ́lì Yóò Jíhìn
  • Ọmọkùnrin Ọlọ́run Jíhìn
  • Àwọn Orílẹ̀-Èdè Jíhìn
  • Àwọn Àpẹẹrẹ Ìjíhìn Ara Ẹni
  • Ìjíhìn Nínú Ìjọ Kristẹni
  • Ǹjẹ́ Kí Jèhófà Lè Sọ Pé O Káre
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Kòṣeémáàní Làwa Kristẹni Jẹ́ Fún Ara Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Àwọn Orílẹ̀-Èdè “Á sì Wá Mọ̀ Pé Èmi Ni Jèhófà”
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/15 ojú ìwé 10-15

Gbogbo Wa Gbọ́dọ̀ Jíhìn fún Ọlọ́run

“Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—RÓÒMÙ 14:12.

1. Ààlà wo ni òmìnira Ádámù àti Éfà ní?

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù. Bí wọ́n tilẹ̀ rẹlẹ̀ sí àwọn áńgẹ́lì, ẹ̀dá olóye tí ó dáńgájíá láti ṣèpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu ni wọ́n. (Orin Dáfídì 8:4, 5) Síbẹ̀, òmìnira tí Ọlọ́run fún wọn yẹn, kì í ṣe ọlá àṣẹ láti fúnra wọn pinnu ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. Wọn yóò jíhìn fún Ẹlẹ́dàá wọn, ìjíhìn yìí sì ti nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn.

2. Ìjíhìn wo ni Jèhófà yóò béèrè fún láìpẹ́, èé sì ti ṣe?

2 Nísinsìnyí tí a ń sún mọ́ òtéńté ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí, Jèhófà yóò béèrè fún ìjíhìn lórí ilẹ̀ ayé. (Fi wé Róòmù 9:28.) Láìpẹ́, àwọn ènìyàn aláìwà-bí-Ọlọ́run yóò ní láti jíhìn fún Jèhófà Ọlọ́run fún bíba àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé jẹ́, pípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn run, àti ní pàtàkì, ṣíṣe inúnibíni sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.—Ìṣípayá 6:10; 11:18.

3. Ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀ wò?

3 Pẹ̀lú ìfojúsọ́nà amúnironújinlẹ̀ tí a dojú kọ yìí, ó dára kí a ronú lórí bí Jèhófà ṣe fi òdodo bá àwọn ẹ̀dá rẹ̀ lò ní ìgbà àtijọ́. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́, níhà ọ̀dọ̀ tiwa, láti jíhìn tí yóò ṣètẹ́wọ́gbà fún Ẹlẹ́dàá wa? Àwọn àpẹẹrẹ wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́, àwọn wo sì ni ó yẹ kí a yẹra láti fara wé?

Àwọn Áńgẹ́lì Yóò Jíhìn

4. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run yóò mú kí àwọn áńgẹ́lì jíhìn fún ìgbésẹ̀ wọn?

4 Àwọn ẹ̀dá Jèhófà tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì lọ́run yóò jíhìn fún un gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa náà yóò ti ṣe. Ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, àwọn áńgẹ́lì kan ṣàìgbọràn, ní yíyíra padà láti baà lè bá àwọn obìnrin lò pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá olómìnira ìwà híhù, àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí lè ṣe ìpinnu yìí, ṣùgbọ́n, wọ́n jíhìn fún Ọlọ́run. Nígbà tí àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn náà padà sí ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí, Jèhófà kò yọ̀ọ̀da fún wọn láti padà sí ipò wọn ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ọmọlẹ́yìn náà Júúdà sọ fún wa pé, a ti fi wọ́n “pa mọ́ de ìdájọ́ ọjọ́ ńlá náà pẹ̀lú àwọn ìdè ayérayé lábẹ́ òkùnkùn biribiri.”—Júúdà 6.

5. Ìṣubú wo ni Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ nírìírí rẹ̀, báwo sì ni a óò ṣe yanjú ìjíhìn fún ìṣọ̀tẹ̀ wọn?

5 Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyí, tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù, ní Sátánì Èṣù gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso wọn. (Mátíù 12:24-26) Áńgẹ́lì búburú yìí ṣọ̀tẹ̀ sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ó sì pé ẹ̀tọ́ ipò ọba aláṣẹ Jèhófà níjà. Sátánì sún àwọn òbí wa àkọ́kọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀, èyí sì yọrí sí ikú wọn nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-7, 17-19) Bí Jèhófà tilẹ̀ fàyè gba Sátánì láti wọnú ààfin ọ̀run fún sáà kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, ìwé Ìṣípayá nínú Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí àkókò bá tó lójú Ọlọ́run, a óò lé olubi ẹ̀dá yìí sí sàkáání ilẹ̀ ayé. Ẹ̀rí fi hàn pé èyí ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí Jésù Kristi gba agbára Ìjọba ní ọdún 1914. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Èṣù àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò lọ sí ìparun àìnípẹ̀kun. Pẹ̀lú yíyanjú ọ̀ràn ipò ọba aláṣẹ pátápátá, a óò ti yanjú ìjíhìn fún ìṣọ̀tẹ̀ lọ́nà tí ó tọ́.—Jóòbù 1:6-12; 2:1-7; Ìṣípayá 12:7-9; 20:10.

Ọmọkùnrin Ọlọ́run Jíhìn

6. Ojú wo ni Jésù fi ń wò ìjíhìn rẹ̀ fún Bàbá rẹ̀?

6 Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Jésù Kristi, fi lélẹ̀ fún wa! Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé alábàádọ́gba Ádámù, Jésù ní inú dídùn sí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó tún yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fún mímú tí a mú kí ó jíhìn fún títẹ̀ lé òfin Jèhófà. Nípa rẹ̀, onísáàmù náà sọ tẹ́lẹ̀ lọ́nà tí ó bá a mu pé: “Inú mi dùn láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run mi, ní tòótọ́, òfin rẹ ń bẹ ní àyà mi.”—Orin Dáfídì 40:8; Hébérù 10:6-9.

7. Nígbà tí ó ń gbàdúrà nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ ku ọ̀la, èé ṣe tí Jésù fi sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú Jòhánù 17:4, 5?

7 Láìka àtakò oníkòórìíra tí Jésù nírìírí rẹ̀ sí, ó ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì di ìwà títọ́ mú lórí òpó igi ìdálóró. Ó tipa bẹ́ẹ̀ san iye owó ìràpadà láti ra aráyé padà kúrò nínú àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani tí Ádámù dá. (Mátíù 20:28) Nítorí náà, nígbà tí ọjọ́ ikú rẹ̀ ku ọ̀la, Jésù lè fi ìgbọ́kànlé gbàdúrà pé: “Mo ti yìn ọ́ lógo ní ilẹ̀ ayé, ní píparí iṣẹ́ tí ìwọ ti fún mi láti ṣe. Nítorí náà nísinsìnyí ìwọ, Bàbá, ṣe mí lógo lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara rẹ pẹ̀lú ògo tí mo ti ní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:4, 5) Jésù lè bá Bàbá rẹ̀ ọ̀run sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nítorí pé, ó yege ìdánwò ìjíhìn, Ọlọ́run sì tẹ́wọ́ gbà á.

8. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé a gbọ́dọ̀ jíhìn nípa ara wa fún Jèhófà Ọlọ́run? (b) Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

8 Ní ìyàtọ̀ sí ọkùnrin pípé náà Jésù Kristi, aláìpé ni wá. Síbẹ̀, àwa yóò jíhìn fún Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wí pé: “Èé ṣe tí ìwọ ń dá arákùnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èé ṣe tí ìwọ tún ń fojú tẹ́ḿbẹ́lú arákùnrin rẹ? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Ọlọ́run; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘“Bí èmi ti wà láàyè,” ni Jèhófà wí, “gbogbo eékún yóò tẹ̀ba fún mi, gbogbo ahọ́n yóò sì ṣe ìjẹ́wọ́fihàn ní gbangba wálíà fún Ọlọ́run.”’ Nítorí bẹ́ẹ̀, nígbà náà, olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:10-12) Kí àwa baà lè ṣe bẹ́ẹ̀, kí a sì rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ fún wa ní ẹ̀rí ọkàn àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí, Bíbélì, láti darí wa nínú ohun tí a ń sọ àti ohun tí a ń ṣe. (Róòmù 2:14, 15; Tímótì Kejì 3:16, 17) Títẹ́wọ́ gba àǹfààní kíkún ti àwọn ìpèsè nípa tẹ̀mí tí Jèhófà ń ṣe àti títẹ̀ lé ẹ̀rí ọkàn wa tí a fi Bíbélì kọ́, yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (Mátíù 24:45-47) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà, tàbí ipá ìṣiṣẹ́, jẹ́ orísun mìíràn fún okun àti ìtọ́sọ́nà. Bí a bá hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìdarí ẹ̀mí mímọ́ àti ìtọ́sọ́nà ẹ̀rí ọkàn wa tí a fi Bíbélì dá lẹ́kọ̀ọ́, a ń fi hàn pé a ‘ka Ọlọ́run sí,’ ẹni tí a gbọ́dọ̀ jíhìn gbogbo ìgbésẹ̀ wa fún.—Tẹsalóníkà Kìíní 4:3-8; Pétérù Kìíní 3:16, 21.

Àwọn Orílẹ̀-Èdè Jíhìn

9. Àwọn wo ni àwọn Édómù, kí sì ni ó ṣẹlẹ̀ sí wọn nítorí bí wọ́n ṣe bá Ísírẹ́lì lò?

9 Jèhófà mú kí àwọn orílẹ̀-èdè jíhìn. (Jeremáyà 25:12-14; Sefanáyà 3:6, 7) Gbé ìjọba Édómù ìgbàanì yẹ̀ wò, tí ó wà ní gúúsù Òkun Òkú àti àríwá Ìyawọlẹ̀ Omi Aqaba. Àwọn Édómù jẹ́ àwọn Semite, tí wọ́n bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ísọ̀, ọmọ-ọmọ Ábúráhámù, ni babańlá àwọn Édómù, wọn kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gba “ọ̀nà òpópó ọba” ní ilẹ̀ Édómù kọjá, nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Númérì 20:14-21) Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, kèéta àwọn Édómù sí Ísírẹ́lì di ìkórìíra tí kò ṣeé tù lójú. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn Édómù ní láti jíhìn fún rírọ̀ tí wọ́n rọ àwọn ará Bábílónì láti pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. (Orin Dáfídì 137:7) Ní ọ̀rùndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Bábílónì lábẹ́ Ọba Nábónídọ́sì ṣẹ́gun Édómù, ó sì di ahoro, gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti pàṣẹ.—Jeremáyà 49:20; Ọbadáyà 9-11.

10. Báwo ni àwọn Móábù ṣe hùwà sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, báwo sì ni Ọlọ́run ṣe mú kí Móábù jíhìn?

10 Nǹkan kò sàn ju èyí lọ fún Móábù. Ìjọba Móábù wà ní àríwá Édómù àti ìlà oòrùn Òkun Òkú. Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn Móábù kó fi aájò àlejò hàn sí wọn, ẹ̀rí fi hàn pé kìkì búrẹ́dì àti omi tí wọ́n fún wọn jẹ́ nítorí èrè tí wọn yóò rí jẹ. (Diutarónómì 23:3, 4) Bálákì, Ọba Móábù, bẹ wòlíì Báláámù lọ́wẹ̀ láti fi Ísírẹ́lì bú, a sì lo àwọn obìnrin Móábù láti ti àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sínú ìwà pálapàla àti ìbọ̀rìṣà. (Númérì 22:2-8; 25:1-9) Àmọ́ ṣáá o, Jèhófà kíyè sí ìkórìíra tí Móábù ní sí Ísírẹ́lì. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀, àwọn ará Bábílónì sọ Móábù dahoro. (Jeremáyà 9:25, 26; Sefanáyà 2:8-11) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run mú kí Móábù jíhìn.

11. Bí àwọn ìlú wo ni Móábù àti Ámónì ṣe dà, kí sì ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn nípa ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí?

11 Kì í ṣe Móábù níkan, ṣùgbọ́n Ámónì pẹ̀lú tún jíhìn fún Ọlọ́run. Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú Móábù yóò dà bíi Sódómù, àti àwọn ọmọ Ámónì bíi Gòmórà, bíi títàn wèrèpè, àti bí ihò iyọ̀, àti ìdahoro títí láé.” (Sefanáyà 2:9) A pa ilẹ̀ Móábù àti Ámónì run, àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run. Gẹ́gẹ́ bí Ẹgbẹ́ Onímọ̀ Ìtàn Ilẹ̀ Ayé ti London ti sọ, àwọn aṣèwádìí sọ pé àwọn ti rí ọ̀gangan Sódómù àti Gòmórà tí a pa run, ní etíkun ìlà oòrùn Òkun Òkú. Ẹ̀rí èyíkéyìí tí ó ṣeé gbára lé tí a lè rí láìpẹ́ nípa èyí, yóò wulẹ̀ ti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lẹ́yìn ni, pé Jèhófà Ọlọ́run yóò mú kí ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí pẹ̀lú jíhìn.—Pétérù Kejì 3:6-12.

12. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ísírẹ́lì ní láti jíhìn fún Ọlọ́run fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí ni a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àṣẹ́kù Júù?

12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti ṣe ojú rere sí Ísírẹ́lì lọ́nà gíga, ó ní láti jíhìn fún Ọlọ́run nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí Jésù wá sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ọ̀pọ̀ jù lọ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Kìkì àṣẹ́kù ni ó lo ìgbàgbọ́, tí ó sì di ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Pọ́ọ̀lù lo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan fún àṣẹ́kù Júù nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Aísáyà ké jáde nípa Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè dà bí iyanrìn òkun, àṣẹ́kù kékeré ni a óò gbà là. Nítorí Jèhófà yóò béèrè fún ìjíhìn lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀ yóò sì ké e kúrú.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, gan-an gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti wí ní ìgbà ìṣáájú pé: ‘Bí kì í bá ṣe pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ì bá ti dà gẹ́gẹ́ bí Sódómù gan-an, à bá sì ti ṣe wá gẹ́gẹ́ bí Gòmórà gan-an.’” (Róòmù 9:27-29; Aísáyà 1:9; 10:22, 23) Àpọ́sítélì náà fúnni ní àpẹẹrẹ ti 7,000 ní àkókò Èlíjà, tí wọn kò tẹrí ba fún Báálì, lẹ́yìn náà ni ó wí pé: “Nítorí náà, ní ọ̀nà yìí, ní àsìkò ìsinsìnyí pẹ̀lú àṣẹ́kù kékeré kan ti fara hàn ní ìbámu pẹ̀lú yíyàn nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí.” (Róòmù 11:5) Olúkúlùkù àwọn tí yóò fúnra wọn jíhìn fún Ọlọ́run ni wọ́n para pọ̀ jẹ́ àṣẹ́kù yẹn.

Àwọn Àpẹẹrẹ Ìjíhìn Ara Ẹni

13. Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí Kéènì nígbà tí Ọlọ́run ní kí ó jíhìn fún pípa Ébẹ́lì arákùnrin rẹ̀?

13 Bíbélì fúnni ní ọ̀pọ̀ ìjíhìn ara ẹni tí a ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run. Gbé àpẹẹrẹ àkọ́bí ọmọkùnrin Ádámù, Kéènì, yẹ̀ wò. Òun àti arákùnrin rẹ̀ Ébẹ́lì rúbọ sí Jèhófà. Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì, ṣùgbọ́n kò tẹ́wọ́ gba ti Kéènì. Nígbà tí a pè é láti jíhìn fún pípa arákùnrin rẹ̀ lọ́nà òǹrorò, Kéènì fi ẹ̀mí òṣónú sọ fún Ọlọ́run pé: “Èmi í ṣe olùtọ́jú arákùnrin mi bí?” Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a lé Kéènì dà nù sí “ilẹ̀ Nódì, níhà ìlà oòrùn Édẹ́nì.” Kò fi ìrònúpìwàdà àtọkànwá kankan hàn fún ìwà ọ̀daràn rẹ̀, kìkì ìyà tí ó tọ́ sí i nìkan ni ó dùn ún.—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-16.

14. Báwo ni a ṣe ṣàkàwé ìjíhìn ara ẹni fún Ọlọ́run nínú ọ̀ràn àlùfáà àgbà náà Élì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀?

14 A tún ṣàkàwé ìjíhìn ara ẹni fún Ọlọ́run nínú ọ̀ràn àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì, Élì. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, Hófínì àti Fíníhásì, ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà olùṣekòkáárí, ṣùgbọ́n “wọ́n jẹ̀bi àìṣèdájọ́ òdodo sí àwọn ènìyàn, àti àìlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, àti pé wọ́n kò ta kété sí ìwà ibi kankan,” ni Josephus òpìtàn sọ. Àwọn “ọmọ Bélíálì” wọ̀nyí kò mọ Jèhófà, wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwà àìlọ́wọ̀ fún ibi mímọ́, wọ́n sì jẹ̀bi ìwà pálapàla tí ó burú lékenkà. (Sámúẹ́lì Kìíní 1:3; 2:12-17, 22-25) Gẹ́gẹ́ bí bàbá wọn àti àlùfáà àgbà Ísírẹ́lì, Élì ní ẹrù iṣẹ́ láti fìyà jẹ wọ́n, ṣùgbọ́n ó wulẹ̀ fi ọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ bá wọn wí. Élì ‘bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Jèhófà lọ.’ (Sámúẹ́lì Kìíní 2:29) Ẹ̀san ké lórí ilé Élì. Àwọn ọmọkùnrin méjèèjì àti bàbá wọn kú ní ọjọ́ kan náà, ìlà àlùfáà wọn sì parẹ́ ráúráú lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. A tipa bẹ́ẹ̀ yanjú ìjíhìn náà.—Sámúẹ́lì Kìíní 3:13, 14; 4:11, 17, 18.

15. Èé ṣe tí a fi san èrè fún ọmọkùnrin Ọba Sọ́ọ̀lù, Jónátánì?

15 Ọmọkùnrin Ọba Sọ́ọ̀lù, Jónátánì, fi àpẹẹrẹ tí ó yàtọ̀ látòkè délẹ̀ lélẹ̀. Kété lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, “ọkàn Jónátánì sì fà mọ́ ọkàn Dáfídì,” wọ́n sì dá májẹ̀mú ọ̀rẹ́. (Sámúẹ́lì Kìíní 18:1, 3) Ó ṣeé ṣe pé, Jónátánì ti fòye mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ti fi Sọ́ọ̀lù sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìtara rẹ̀ alára fún ìjọsìn tòótọ́ kò yingin. (Sámúẹ́lì Kìíní 16:14) Ìmọrírì Jónátánì fún ọlá àṣẹ tí Ọlọ́run fún Dáfídì kò fìgbà kan rí yẹ̀. Jónátánì mọ ìjíhìn rẹ̀ fún Ọlọ́run, Jèhófà sì san èrè fún un fún ìgbésẹ̀ rẹ̀ tí ó lọ́lá, nípa rírí i dájú pé, ìlà ìdílé rẹ̀ kò parẹ́ fún ọ̀pọ̀ ìran.—Kíróníkà Kìíní 8:33-40.

Ìjíhìn Nínú Ìjọ Kristẹni

16. Ta ni Títù, èé sì ti ṣe tí a fi lè sọ pé ó jíhìn tí ó dára nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run?

16 Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ rere nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jíhìn ara wọn lọ́nà rere. Fún àpẹẹrẹ, ará Gíríìsì kan ń bẹ tí ó jẹ́ Kristẹni, tí a ń pè ní Títù. A gbọ́ pé ó di Kristẹni nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ ti Pọ́ọ̀lù sí Kípírọ́sì. Níwọ̀n bí àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe láti Kípírọ́sì ti lè wà ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ìsìn Kristẹni ti lè dé erékùṣù náà kété lẹ́yìn ìgbà yẹn. (Ìṣe 11:19) Síbẹ̀síbẹ̀, Títù jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olùṣòtítọ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ Pọ́ọ̀lù. Ó bá Pọ́ọ̀lù àti Bánábà lọ nínú ìrìn àjò sí Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Tiwa, nígbà tí a yanjú ọ̀ràn pàtàkì nípa ìkọlà. Òkodoro òtítọ́ náà pé a kò kọ Títù nílà mú kí ìjiyàn Pọ́ọ̀lù tẹ̀wọ̀n sí i pé, kò yẹ kí àwọn tí a sọ di Kristẹni wà lábẹ́ Òfin Mósè. (Gálátíà 2:1-3) A jẹ́rìí sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ àtàtà tí Títù ṣe nínú Ìwé Mímọ́, Pọ́ọ̀lù pàápàá sì kọ lẹ́tà onímìísí àtọ̀runwá kan sí i. (Kọ́ríńtì Kejì 7:6; Títù 1:1-4) Ó hàn kedere pé, títí dé òpin ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, Títù ń bá a nìṣó ní jíjíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

17. Irú ìjíhìn wo ni Tímótì ṣe, báwo sì ni àpẹẹrẹ yìí ṣe lè nípa lórí wa?

17 Tímótì jẹ́ ẹlòmíràn tí ó ní ìtara, tí ó jíhìn tí ó ṣè ìtẹ́wọ́gbà nípa ara rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì ní àwọn ìṣòro ìlera díẹ̀, ó fi ‘ìgbàgbọ́ tí kò ní àgàbàgebè kankan’ hàn, ó sì ‘sìnrú pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù fún ìtẹ̀síwájú ìhìn rere.’ Nítorí náà, àpọ́sítélì náà sọ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní Fílípì pé: “Èmi kò ní ẹlòmíràn kankan tí ó ní ìtẹ̀sí ọkàn bíi [Tímótì] tí yóò fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ó jẹmọ́ yín.” (Tímótì Kejì 1:5; Fílípì 2:20, 22; Tímótì Kìíní 5:23) Lójú àwọn ìkù-díẹ̀-káà-tó ẹ̀dá ènìyàn àti àwọn àdánwò míràn, àwa pẹ̀lú lè ní ìgbàgbọ́ aláìlágàbàgebè, a sì lè jìhín tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà nípa ara wa fún Ọlọ́run.

18. Ta ni Lìdíà, ẹ̀mí wo sì ni ó fi hàn?

18 Obìnrin tí ń ṣèfẹ́ Ọlọ́run ni Lìdíà jẹ́, ẹni tí ó hàn gbangba pé ó jíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run. Òun àti agboolé rẹ̀ wà nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́ tí ó di Kristẹni ní Europe nítorí ìgbòkègbodò Pọ́ọ̀lù ní Fílípì ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa. Ará Tíátírà ni, ó sì ṣeé ṣe kí Lìdíà jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù, ṣùgbọ́n àwọn Júù lè kéré níye ní Fílípì, kí ó máà sì sí sínágọ́gù níbẹ̀. Òun àti àwọn obìnrin olùfọkànsìn míràn ń pàdé ní etí odò kan nígbà ti Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ̀rọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, Lìdíà di Kristẹni, ó sì yí Pọ́ọ̀lù àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lérò padà láti dé sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. (Ìṣe 16:12-15) Aájò àlejò tí Lìdíà ṣe, ṣì wà gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ títayọ ti àwọn Kristẹni tòótọ́.

19. Nípa àwọn ìwà rere wo ni Dọ̀káàsì fi jíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run?

19 Dọ̀káàsì jẹ́ obìnrin mìíràn tí ó jíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà tí ó kú, Pétérù lọ sí Jópà ní fífèsì sí àrọwà àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí ń gbé ibẹ̀. Àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n pàdé Pétérù “mú un lọ sí ìyẹ̀wù òkè; gbogbo àwọn opó sì wá síwájú rẹ̀ wọ́n ń sunkún wọ́n sì ń fi ọ̀pọ̀ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ati ẹ̀wù àwọ̀lékè hàn sójú táyé èyí tí Dọ́káàsì ti máa ń ṣe nígbà tí ó wà pẹ̀lú wọn.” A mú Dọ́káàsì padà wá sí ìyè. Ṣùgbọ́n, kìkì ẹ̀mí ìṣoore rẹ̀ nìkan ni a óò ha fi máa rántí rẹ̀ bí? Rárá o. Ó jẹ́ “ọmọ ẹ̀yìn,” ó sì dájú pé ó fúnra rẹ̀ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Bákan náà, àwọn obìnrin Kristẹni lónìí ‘ń pọ̀ gidigidi nínú àwọn iṣẹ́ rere àti àwọn ẹ̀bùn àánú.’ Inú wọn sì tún dùn láti nípìn-ín nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.—Ìṣe 9:36-42; Mátíù 24:14; 28:19, 20.

20. Àwọn ìbéèrè wo ni a lè bi ara wa?

20 Bíbélì fi hàn ní kedere pé, àwọn orílẹ̀-èdè àti olúkúlùkù gbọ́dọ̀ jíhìn fún Olúwa Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, Jèhófà. (Sefanáyà 1:7) Bí a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, nígbà náà, a lè bi ara wa pé, ‘Ojú wo ni mo fi ń wo àwọn àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún mi? Irú ìjíhìn wo ni èmi ń ṣe nípa ara mi fún Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi?’

Kí Ni Àwọn Ìdáhùn Rẹ?

◻ Báwo ni ìwọ yóò ṣe fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì àti Ọmọkùnrin Ọlọ́run jíhìn fún Jèhófà?

◻ Àwọn àpẹẹrẹ Bíbélì wo ni ó fi hàn pé Ọlọ́run yóò mú kí àwọn orílẹ̀-èdè jíhìn?

◻ Kí ni Bíbélì sọ nípa ìjíhìn ara ẹni fún Ọlọ́run?

◻ Àwọn ènìyàn wo nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì, ni wọ́n jíhìn àtàtà fún Jèhófà Ọlọ́run?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jésù Kristi jíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Bàbá rẹ̀ ọ̀run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Bíi Dọ̀káàsì, àwọn Kristẹni obìnrin lónìí ń jíhìn tí ó dára nípa ara wọn fún Jèhófà Ọlọ́run

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Ikú Ébẹ́lì/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́