Ǹjẹ́ Kí Jèhófà Lè Sọ Pé O Káre
“Rántí mi Ọlọ́run mi, . . . Rántí mi, Ọlọ́run mi, fún rere.”—NEHEMÁYÀ 13:22, 31.
1. Kí ní ń ran àwọn tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run lọ́wọ́ láti lè jíhìn àtàtà fún Jèhófà?
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jèhófà ní gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò láti jíhìn àtàtà fún un. Èé ṣe? Nítorí pé wọ́n ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí apá kan ètò àjọ rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. Ó ti ṣí àwọn ète rẹ̀ payá fún wọn, ó sì ti fún wọn ní ìrànlọ́wọ́ àti òye inú nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Orin Dáfídì 51:11; 119:105; Kọ́ríńtì Kìíní 2:10-13) Ní gbígbé àwọn àyíká ipò àrà ọ̀tọ̀ wọ̀nyí yẹ̀ wò, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ ké sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé láti jíhìn fún un nípa ara wọn, fún ohun tí wọ́n jẹ́ àti fún ohun tí wọ́n fi okun àti ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣàṣeparí.
2. (a) Ní àwọn ọ̀nà wo ni Nehemáyà gbà jíhìn tí ó dára nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run? (b) Ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wo ni Nehemáyà fi parí ìwé Bíbélì tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀?
2 Ọkùnrin kan tí ó jíhìn tí ó dára nípa ara rẹ̀ fún Ọlọ́run ni Nehemáyà, agbọ́tí Atasásítà (Longimanus), Ọba Páṣíà. (Nehemáyà 2:1) Nehemáyà di gómìnà àwọn Júù, ó sì tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́ lójú àwọn ọ̀tá àti ewu. Pẹ̀lú ìtara fún ìjọsìn tòótọ́, ó mú Òfin Ọlọ́run ṣẹ, ó sì dàníyàn nípa àwọn tí a ni lára. (Nehemáyà 5:14-19) Nehemáyà rọ àwọn Léfì láti sọ ara wọn di mímọ́ nígbà gbogbo, kí wọ́n máa ṣọ́ ẹnubodè, kí wọn sì ya ọjọ́ Sábáàtì sí mímọ́. Nígbà náà, ó lè gbàdúrà pé: “Rántí mi Ọlọ́run mi nítorí èyí pẹ̀lú kí o sì dá mi sí gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ.” Pẹ̀lúpẹ̀lù, lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, Nehemáyà mú ìwé onímìísí àtọ̀runwá rẹ̀ wá sí ìparí pẹ̀lú ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ náà pé: “Rántí mi, Ọlọ́run mi, fún rere.”—Nehemáyà 13:22, 31.
3. (a) Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàpèjúwe ẹnì kan tí ń ṣe rere? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni ríronú lórí ìwà Nehemáyà lè mú kí a bi ara wa?
3 Ẹni tí ń hùwà rere jẹ́ oníwà funfun, yóò sì máa hùwà àìlábòsí tí yóò ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní. Irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni Nehemáyà jẹ́. Ó ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àti ìtara ńláǹlà fún ìjọsìn tòótọ́. Ní àfikún sí i, ó mọrírì àwọn àǹfààní rẹ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, ó sì jíhìn àtàtà nípa ara rẹ̀ fún Jèhófà. Ríronú lórí ìwà rẹ̀ lè mú kí a bi ara wa pé, ‘Ojú wo ni mo fi ń wo àwọn àǹfààní àti ẹrù iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún mí? Irú ìjíhìn wo ni mò ń ṣe nípa ara mi fún Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi?’
Ìmọ̀ Ń Mú Kí A Jíhìn
4. Iṣẹ́ àṣẹ wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí sì ni àwọn tí wọ́n “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” yóò ṣe?
4 Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní iṣẹ́ àṣẹ yìí: “Ẹ lọ kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Wọn yóò sọni di ọmọ ẹ̀yìn nípa kíkọ́ wọn. Àwọn tí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kọ́, tí wọ́n sì “ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” yóò ṣe batisí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Ìṣe 13:48; Máàkù 1:9-11) Ìfẹ́ wọn láti pa gbogbo ohun tí ó ti pa láṣẹ mọ́ yóò wá láti ọkàn-àyà wọn. Wọn yóò dorí ṣíṣe ìyàsímímọ́ nípa gbígba ìmọ̀ pípéye ti Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àti fífi í sílò.—Jòhánù 17:3.
5, 6. Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye Jákọ́bù 4:17? Ṣàkàwé bí a ṣe lè fi í sílò.
5 Bí ìmọ̀ wa nípa Ìwé Mímọ́ bá ṣe jinlẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wa yóò ṣe jinlẹ̀ tó. Lọ́wọ́ kan náà, ìjíhìn wa fún Ọlọ́run yóò pọ̀ sí i. Jákọ́bù 4:17 sọ pé: “Bí ẹni kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́ síbẹ̀ tí kò sì ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” Ó ṣe kedere pé, gbólóhùn yìí jẹ́ ìparí èrò ohun tí ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán nípa fífọ́nnu dípò gbígbára lé Ọlọ́run pátápátá. Bí ẹnì kan bá mọ̀ pé òun kò lè ṣàṣeparí ohunkóhun láìsí ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ṣùgbọ́n tí kò hùwà lọ́nà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ni èyí jẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ Jákọ́bù tún lè tọ́ka sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àìka-nǹkan-sí. Fún àpẹẹrẹ, nínú òwe àkàwé Jésù nípa àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, a dá àwọn ewúrẹ́ lẹ́bi, kì í ṣe fún ìwà búburú, bí kò ṣe fún àìran àwọn arákùnrin Kristi lọ́wọ́.—Mátíù 25:41-46.
6 Ìtẹ̀síwájú nípa tẹ̀mí ti ọkùnrin kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní kò tó nǹkan, ó hàn gbangba pé àìjáwọ́ nínú sìgá mímu ni ó fà á, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé kò yẹ kí òun máa ṣe bẹ́ẹ̀. Alàgbà kan ní kí ó ka Jákọ́bù 4:17. Lẹ́yìn ṣíṣàlàyé lórí ìjẹ́pàtàkì ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, alàgbà náà wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò tí ì ṣe batisí, ìwọ yóò jíhìn, ìwọ nìkan ni yóò sì ru ẹrù ìpinnu rẹ.” Ó dùn mọ́ni pé, ọkùnrin náà hùwà padà lọ́nà rere, ó dẹ́kun sìgá mímu, kò sì pẹ́ púpọ̀ tí ó fi tóótun fún batisí ní àmì ìṣàpẹẹrẹ ìyàsímímọ́ rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run.
A Óò Jíhìn fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
7. Ọ̀nà kan wo ni a lè gbà fi ìmoore wa hàn fún “ìmọ̀ Ọlọ́run”?
7 Ìfẹ́ àtọkànwá wa yẹ kí ó jẹ́ láti mú inú Ẹlẹ́dàá wa dùn. Ọ̀nà kan láti fi ìmoore wa hàn fún “ìmọ̀ Ọlọ́run” ni láti ṣe iṣẹ́ àṣẹ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi. Èyí pẹ̀lú jẹ́ ọ̀nà kan láti fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò wa. (Òwe 2:1-5; Mátíù 22:35-40) Bẹ́ẹ̀ ni, ìmọ̀ wa nípa Ọlọ́run béèrè pé a óò jíhìn fún un, a sì ní láti ka àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́la.
8. Báwo ni a ṣe lè sọ pé Pọ́ọ̀lù nímọ̀lára pé òun yóò jíhìn fún Ọlọ́run nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé títẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà tọkàntọkàn àti ṣíṣègbọràn sí i ń yọrí sí ìgbàlà, nígbà tí kíkọ̀ ọ́ sílẹ̀ lè mú ìparun wá. (Tẹsalóníkà Kejì 1:6-8) Nítorí náà ó mọ̀ pé òun yóò jíhìn fún Jèhófà fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun. Ní tòótọ́, Pọ́ọ̀lù àti àwọn olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mọrírì iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹra fún mímú kí àwọn ènìyàn ronú pé àwọn ń rí owó nínú rẹ̀. Ní àfikún sí i, ọkàn-àyà Pọ́ọ̀lù sún un láti sọ pé: “Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere, kì í ṣe ìdí kankan fún mi lati ṣògo, nítorí àìgbọdọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, ègbé ni fún mi bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—Kọ́ríńtì Kìíní 9:11-16.
9. Gbèsè pàtàkì wo ni àwọn Kristẹni jẹ?
9 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ olùṣèyásímímọ́ fún Jèhófà, ‘àìgbọdọ̀máṣe wà lórí wa láti polongo ìhìn rere.’ Ó jẹ́ iṣẹ́ àṣẹ wa láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. A tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ yẹn nígbà tí a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run. (Fi wé Lúùkù 9:23, 24.) Síwájú sí i, a ní gbèsè kan láti san. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Èmi jẹ́ ajigbèsè sí àwọn Gíríìkì àti àwọn Aláìgbédè, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn òpònú: nítorí náà ìháragàgà wà ní ìhà ọ̀dọ̀ mi láti polongo ìhìn rere pẹ̀lú fún ẹ̀yin tí ẹ wà ní Róòmù.” (Róòmù 1:14, 15) Pọ́ọ̀lù jẹ́ ajigbèsè nítorí pé ó mọ̀ pé ojúṣe òun ni láti wàásù kí àwọn ènìyàn baà lè gbọ́ ìhìn rere náà, kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Tímótì Kìíní 1:12-16; 2:3, 4) Nítorí náà, ó ṣakitiyan láti mú iṣẹ́ àṣẹ rẹ̀ ṣẹ àti láti san gbèsè tí ó jẹ àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwa pẹ̀lú ní irú gbèsè bẹ́ẹ̀ láti san. Wíwàásù Ìjọba jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti fi ìfẹ́ wa hàn fún Ọlọ́run, fún Ọmọkùnrin rẹ̀, àti fún àwọn aládùúgbò wa.—Lúùkù 10:25-28.
10. Kí ni àwọn kan ti ṣe láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i?
10 Ọ̀nà kan tí a lè gbà jíhìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run ni láti lo agbára wa láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò. Láti ṣàkàwé: Àwọn ènìyàn láti ọ̀pọ̀ àwùjọ orílẹ̀-èdè ti ń rọ́ tìrítìrí wá sí Britain ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Láti mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ó lé ní 800 (àwọn alákòókò kíkún oníwàásù Ìjọba) àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún Ẹlẹ́rìí ń kọ́ onírúurú èdè. Èyí ti yọrí sí ipa ìsúnniṣe àtàtà kan fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Aṣáájú ọ̀nà kan tí ń kọ́ kíláàsì èdè Chinese kan wí pé: “N kò ronú rẹ̀ rí pé n óò kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ní èdè mi, kí wọn baà lè ṣàjọpín òtítọ́ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lọ́nà yìí. Ó mú inú mi dùn jọjọ!” Ìwọ ha lè mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i lọ́nà kan náà bí?
11. Kí ni ó yọrí sí, nígbà tí Kristẹni kan jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà?
11 Ní gbogbo ọ̀nà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa yóò ṣe ohun tí a lè ṣe láti gba ẹnì kan tí omi ń gbè lọ là. Lọ́nà kan náà, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń hára gàgà láti lo agbára wọn láti jẹ́rìí ní gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀. Láìpẹ́ yìí, Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ obìnrin jókòó lẹ́bàá obìnrin kan nínú bọ́ọ̀sì, ó sì bá a sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́. Nítorí pé ohun tí ó gbọ́ ru ìmọ̀lára rẹ̀ sókè, obìnrin náà béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Ẹlẹ́rìí náà sọ̀kalẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì náà, obìnrin náà rọ̀ ọ́ pé kí ó kúkú wà sí ilé òun, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé òun ṣì ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ẹlẹ́rìí náà gbà. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bẹ̀rẹ̀, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, obìnrin náà di akéde Ìjọba tí kò tí ì ṣe batisí. Láìpẹ́, ó ti ń fúnra rẹ̀ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́fà nínú ilé. Ẹ wo irú èrè amóríyágágá tí èyí jẹ́ fún lílo agbára ẹni nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba!
12. Báwo ni a ṣe lè lo agbára wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà gbígbéṣẹ́?
12 A lè lo agbára wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́ nínú pápá nípa lílo àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé olójú ewé 192 náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Nígbà tí yóò fi di April ọdún 1996, Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fọwọ́ sí títẹ ìwé Ìmọ̀ jáde ní èdè tí ó lé ní 140, a sì ti tẹ 30,500,000 ẹ̀dà rẹ̀ ní èdè 111 nígbà yẹn. A kọ ìwé yìí pẹ̀lú ète ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ète rẹ̀ dé àyè tí ó tó fún wọn láti ṣe ìyàsímímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe batisí. Níwọ̀n bí àwọn akéde Ìjọba kì yóò ti máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan náà fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn sí i tàbí kí wọ́n fi kún ìpín wọn nínú iṣẹ́ ilé dé ilé àti apá mìíràn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Ìṣe 5:42; 20:20, 21) Ní mímọ̀ pé àwọn yóò jíhìn fún Ọlọ́run, wọ́n darí àfiyèsí àwọn ènìyàn sí ìkìlọ̀ àtọ̀runwá. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 33:7-9) Ṣùgbọ́n ohun tí ó jẹ wọ́n lógún jù lọ ni láti bọlá fún Jèhófà, kí wọ́n sì ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìhìn rere náà ní àkókò kúkúrú tí ó kù fún ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí.
Jíjíhìn Àtàtà Gẹ́gẹ́ Bí Ìdílé
13. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ìdílé tí a ń ṣe déédéé?
13 Gbogbo ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ìdílé tí ń tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni tòótọ́ ni yóò jíhìn fún Ọlọ́run, nítorí náà wọ́n ní láti “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú,” kí wọ́n sì ‘dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.’ (Hébérù 6:1-3; Pétérù Kìíní 5:8, 9) Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀, tí wọ́n sì ti ṣe batisí ní láti parí ìmọ̀ wọn nínú Ìwé Mímọ́, nípa wíwá sí àwọn ìpàdé déédéé àti nípa kíka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni mìíràn. Ó yẹ kí àwọn ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tí a ń ṣe déédéé pẹ̀lú, nítorí èyí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan láti ‘wà lójúfò, láti dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, láti máa bá a nìṣó bí ọkùnrin, láti di alágbára ńlá.’ (Kọ́ríńtì Kìíní 16:13) Bí o bá jẹ́ olórí agboolé kan, ìwọ ní pàtàkì yóò jíhìn fún Ọlọ́run fún àtirí i pé o bọ́ ìdílé rẹ ní àbọ́yó nípa tẹ̀mí. Gan-an gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ nípa ti ara tí ń ṣara lóore ti ń mú kí ìlera ní ti ẹ̀dá sunwọ̀n sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe nílò oúnjẹ yanturu nípa tẹ̀mí tí ó ń wá déédéé, bí ìwọ àti ìdílé rẹ yóò bá jẹ́ “onílera nínú ìgbàgbọ́.”—Títù 1:13.
14. Kí ni ẹ̀rí tí ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì kan tí a kọ́ dáradára jẹ́ yọrí sí?
14 Bí àwọn ọmọ bá wà nínú agboolé rẹ, Ọlọ́run yóò sọ pé o káre fún fífún wọn ní ìtọ́ni yíyè kooro nípa tẹ̀mí. Irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ yóò ṣàǹfààní fún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣàǹfààní fún ọmọdébìnrin Ísírẹ́lì náà tí àwọn ará Síríà mú ní àkókò wòlíì Ọlọ́run nì, Èlíṣà. Ó di ìránṣẹ́bìnrin aya adẹ́tẹ̀ nì, Náámánì, tí í ṣe ọ̀gágun àwọn ará Síríà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọdébìnrin náà kéré, ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé: “Olúwa mi ì bá wà níwájú wòlíì tí ń bẹ ní Samáríà! ní tòótọ́ òun ì bá wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Nítorí ẹ̀rí tí ó jẹ́, Náámánì gbéra lọ sí Ísírẹ́lì, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ó fara mọ́ ìdarí Èlíṣà láti wẹ̀ nígbà méje nínú Odò Jọ́dánì, ẹ̀tẹ̀ ara rẹ̀ sì wẹ̀ dànù. Ní àfikún sí i, Náámánì di olùjọ́sìn Jèhófà. Ẹ wo bí ìyẹn yóò ti morí ọmọbìnrin yẹn yá gágá tó!—Àwọn Ọba Kejì 5:1-3, 13-19.
15. Èé ṣe tí ó fi ṣe pàtàkì fún àwọn òbí láti fún àwọn ọmọ wọn ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ àtàtà nípa tẹ̀mí? Ṣàkàwé.
15 Kò rọrùn láti tọ́ àwọn ọmọ tí yóò bẹ̀rù Ọlọ́run dàgbà nínú ayé aláìníwàrere, tí ó wà lábẹ́ agbára Sátánì yìí. (Jòhánù Kìíní 5:19) Ṣùgbọ́n, láti kékeré Tímótì ni ìyá rẹ̀ àgbà, Lọ́ìsì, àti ìyá rẹ̀, Yùníìsì, ti ṣàṣeyọrí nínú kíkọ́ ọ ní Ìwé Mímọ́. (Tímótì Kejì 1:5; 3:14, 15) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, mímú wọn lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé, àti lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn mímú wọn dání nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ìwọ yóò jíhìn nípa rẹ̀ fún Ọlọ́run. Kristẹni kan ní Wales, tí ó wà láàárín 80 ọdún sí 90 ọdún nísinsìnyí, rántí pé ní kùtùkùtù àwọn ọdún 1920, bàbá rẹ̀ mú un lọ́wọ́ nígbà tí ó ń fẹsẹ̀ rin kìlómítà 10 lórí òkè kan (ìrìn 20 kìlómítà ní àlọ àti àbọ̀) láti pín ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì fún àwọn ará abúlé tí ó wà ní àfonífojì kejì. Ó fi ìmoore sọ pé: “Àkókò tí a ń fẹsẹ̀ rìn yẹn ni bàbá gbin òtítọ́ sí mi lọ́kàn.”
Àwọn Alàgbà Ń Jíhìn—Lọ́nà Wo?
16, 17. (a) Àwọn àǹfààní wo ni àwọn agbà ọkùnrin adàgbàdénú nípa tẹ̀mí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì gbádùn? (b) Ní ìfiwéra pẹ̀lú ipò tí ó wà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, èé ṣe tí a fi ń béèrè ohun púpọ̀ sí i lọ́wọ́ àwọn Kristẹni alàgbà lónìí?
16 Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà, Sólómọ́nì, wí pé: “Adé ògo ni orí ewú, bí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Ṣùgbọ́n kì í ṣe ọjọ́ orí nìkan ní ń mú kí ọkùnrin kan tóótun fún ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Àwọn àgbà ọkùnrin tí wọ́n dàgbà dénú nípa tẹ̀mí ní Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ àti òṣìṣẹ́ olóyè fún ṣíṣèdájọ́ àti rírí i pé àlàáfíà wà, pé nǹkan ń lọ létòlétò, àti pé ìlera nípa tẹ̀mí ń bẹ. (Diutarónómì 16:18-20) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀ràn rí nínú ìjọ Kristẹni, a ń béèrè ohun púpọ̀ sí i lọ́wọ́ àwọn alàgbà bí òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti ń sún mọ́lé. Èé ṣe?
17 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ‘àwọn ènìyàn àyànfẹ́’ tí Ọlọ́run dá nídè kúrò ní Íjíbítì ìgbàanì. Níwọ̀n bí wọ́n ti rí Òfin náà gbà nípasẹ̀ alárinà wọn, Mósè, a bí àwọn àtọmọdọ́mọ wọn sínú orílẹ̀-èdè kan tí a yà sí mímọ́, wọ́n sì di ojúlùmọ̀ àwọn ìlànà Jèhófà. (Diutarónómì 7:6, 11) Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, kò sí ẹnikẹ́ni tí a bí sínú irú orílẹ̀-èdè tí a yà sí mímọ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ ní ìfiwéra ni ó sì dàgbà nínú ìdílé oníwà-bí-Ọlọ́run, tí wọ́n mọ òtítọ́ Ìwé Mímọ́ dunjú. Ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ‘rìn nínú òtítọ́’ nílò ìtọ́ni lórí bí wọn yóò ṣe gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́. (Jòhánù Kẹta 4) Nítorí náà, ẹ wo irú ẹrù iṣẹ́ bàǹtà-banta tí èyí gbé lé àwọn alàgbà olùṣòtítọ́ léjìká, bí wọ́n ṣe ń “di àpẹẹrẹ àwòṣe àwọn ọ̀rọ̀ afúnninílera mú,” tí wọ́n sì ń ran àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́wọ́!—Tímótì Kejì 1:13, 14.
18. Irú ìrànlọ́wọ́ wo ni àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ ṣe tán láti fúnni, èé sì ti ṣe?
18 Ọmọ kékeré kan tí ó ń kọ́ àtirìn lè rìn tàgétàgé, kí ó sì ṣubú. Kò nímọ̀lára ààbò, ó sì nílò ìrànlọ́wọ́ òbí àti ìfọkànbalẹ̀. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan tí ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà lè rìn tàgétàgé, kí ó sì ṣubú nípa tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pàápàá rí i pé ó pọn dandan láti jìjàkadì láti ṣe ohun tí ó tọ́ tàbí ohun rere lójú Ọlọ́run. (Róòmù 7:21-25) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run ní láti máa fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ti ṣìnà ṣùgbọ́n tí wọ́n ronú pìwà dà ní tòótọ́ ní ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́. Nígbà tí àwọn alàgbà ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ obìnrin olùṣèyàsímímọ́ kan, tí ó sì ti ṣe àṣìṣe ńláǹlà, ó sọ níṣojú ọkọ rẹ̀ olùṣèyàsímímọ́ pé: “Mo mọ̀ pé ẹ óò yọ mí lẹ́gbẹ́!” Ṣùgbọ́n ó bú sẹ́kún pẹ̀lú omijé lójú nígbà tí a sọ fún un pé, àwọn alàgbà fẹ́ mọ ìrànlọ́wọ́ tí àwọn lè ṣe láti dá ipò tẹ̀mí ìdílé náà padà. Ní mímọ̀ pé àwọn gbọ́dọ̀ jíhìn, àwọn alàgbà náà láyọ̀ láti ran onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí ó bá ronú pìwà dà lọ́wọ́.—Hébérù 13:17.
Máa Bá A Nìṣó Ní Jíjíhìn Àtàtà
19. Báwo ni a ṣe lè máa bá a nìṣó ní jíjíhìn àtàtà nípa ara wa fún Ọlọ́run?
19 Àwọn alàgbà ìjọ àti àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní láti máa bá a nìṣó ní jíjíhìn àtàtà nípa ara wọn fún Jèhófà. Èyí ṣeé ṣe bí a bá dìrọ̀ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí a sì ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Òwe 3:5, 6; Róòmù 12:1, 2, 9) Ó yẹ kí àwa ní pàtàkì máa ṣoore fún àwọn wọnnì tí wọ́n jẹ́ ìbátan wa nínú ìgbàgbọ́. (Gálátíà 6:10) Ṣùgbọ́n, ìkórè ṣì pọ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ sì ni àwọn òṣìṣẹ́ jẹ́ síbẹ̀síbẹ̀. (Mátíù 9:37, 38) Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a máa ṣoore fún àwọn ẹlòmíràn nípa fífi taápọntaápọn pòkìkí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Jèhófà yóò sọ pé a káre, bí a bá mú ìyàsímímọ́ wa ṣẹ, tí a bá ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tí a sì fi ìṣòtítọ́ pòkìkí ìhìn rere náà.
20. Kí ni a rí kọ́ láti inú gbígbé ìwà Nehemáyà yẹ̀ wò?
20 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní níní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa. (Kọ́ríńtì Kìíní 15:58) Ó sì dára kí a ronú nípa Nehemáyà, tí ó tún odi Jerúsálẹ́mù kọ́, tí ó mú Òfin Ọlọ́run ṣẹ, tí ó sì fi tìtaratìtara gbé ìjọsìn tòótọ́ lárugẹ. Ó gbàdúrà pé kí Jèhófà Ọlọ́run rántí òun fún ohun rere tí òun ti ṣe. Ǹjẹ́ kí o fẹ̀rí hàn pé ìwọ pẹ̀lú jẹ́ olùfọkànsin Jèhófà, kí òun sì lè sọ pé o káre.
Kí Ni Àwọn Ìdáhùn Rẹ?
◻ Àpẹẹrẹ wo ni Nehemáyà fi lélẹ̀?
◻ Èé ṣe tí ìmọ̀ yóò fi mú kí a jíhìn fún Ọlọ́run?
◻ Báwo ni a ṣe lè jíhìn tí ó ṣè ìtẹ́wọ́gbà fún Jèhófà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
◻ Kí ni àwọn ìdílé lè ṣe láti jíhìn àtàtà fún Ọlọ́run?
◻ Báwo ni àwọn Kristẹni alàgbà ṣe ń jíhìn?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, a lè jíhìn àtàtà fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Àwọn ọmọ rẹ ha dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́ bíi ti ọmọdébìnrin kékeré ará Ísírẹ́lì nínú ilé Náámánì bí?