“Máa Fi Ire Ṣẹ́gun Ibi”
“Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” —RÓÒMÙ 12:21.
1. Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé a lè ṣẹ́gun ibi?
ǸJẸ́ ó ṣeé ṣe láti má juwọ́ sílẹ̀ fáwọn tó ń ta ko ìsìn tòótọ́ lójú méjèèjì? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti borí àwọn nǹkan tó fẹ́ fà wá padà sínú ayé táwọn èèyàn kò ti ṣèfẹ́ Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ ni, ni ìdáhùn sáwọn ìbéèrè méjèèjì wọ̀nyí! Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Nítorí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Róòmù ni. Ó kọ̀wé pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” (Róòmù 12:21) Bá a bá gbọ́kàn lé Jèhófà tá a sì pinnu pé a ò ní jẹ́ kí ayé ṣẹ́gun wa, ìwà ibi wọn kò ní borí wa. Síwájú sí i, gbólóhùn náà, máa “ṣẹ́gun ibi” fi hàn pé a lè borí ibi tá a bá ń bá a nìṣó láti máa gbógun tì í. Kìkì àwọn tí kò bá wà lójúfò mọ́ tí wọ́n sì dáwọ́ ìjà dúró ni ayé búburú yìí àti Sátánì Èṣù, tó jẹ́ ẹni ibi tó ń ṣàkóso ayé, máa ṣẹ́gun wọn.—1 Jòhánù 5:19.
2. Kí nìdí tí a ó fi gbé àwọn nǹkan kan tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Nehemáyà yẹ̀ wò?
2 Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún ṣáájú ìgbà ayé Pọ́ọ̀lù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó ń gbé nílùú Jerúsálẹ́mù fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa gbígbógun ti ibi. Nehemáyà ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run tá à ń wí yìí, kì í ṣe pé ó kojú àtakò àwọn èèyànkéèyàn nìkan ni, àmọ́ ó tún fi ire ṣẹ́gun ibi. Àwọn ìṣòro wo ló dójú kọ? Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí? Báwo la ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ rẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká jíròrò àwọn nǹkan díẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Nehemáyà.a
3. Àárín àwọn wo ni Nehemáyà gbé, ohun ńlá wo ló sì gbé ṣe?
3 Ààfin Atasásítà ọba Páṣíà ni Nehemáyà ti ń ṣiṣẹ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn aláìgbàgbọ́ ni Nehemáyà ń gbé, kò ‘dáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan’ ayé ìgbà yẹn. (Róòmù 12:2) Nígbà tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ nílẹ̀ Júdà, ó fi ìgbésí ayé ọlọ́lá tó ń gbé sílẹ̀, ó rìnrìn àjò kan tí kò rọrùn lọ sílùú Jerúsálẹ́mù, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ títún ògiri ìlú náà mọ, èyí tó jẹ́ iṣẹ́ bàǹtàbanta. (Róòmù 12:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gómìnà ìlú Jerúsálẹ́mù ni Nehemáyà, ojoojúmọ́ ló ń ṣíṣẹ́ àṣekára pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tirẹ̀ “láti ìgbà tí ọ̀yẹ̀ [bá] ti là títí di ìgbà tí ìràwọ̀ [bá] yọ.” Nípa báyìí, láàárín oṣù méjì péré, iṣẹ́ náà parí pátápátá! (Nehemáyà 4:21; 6:15) Àṣeyọrí ńlá gbáà lèyí jẹ́, nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ yẹn ń lọ lọ́wọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí onírúurú àtakò. Àwọn wo ló ń ṣàtakò sí Nehemáyà, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣàtakò rẹ̀?
4. Kí làwọn ọ̀tá Nehemáyà ní lọ́kàn?
4 Àwọn tó dìídì ń ṣàtakò yìí ni Sáńbálátì, Tobáyà, àti Géṣémù, tí wọ́n jẹ́ èèyàn pàtàkì, ibi tí wọ́n ń gbé kò sì jìnnà sílẹ̀ Júdà. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run ni wọ́n, “ó dà bí ohun tí ó burú lójú wọn pé [Nehemáyà] wá láti wá ohun rere fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” (Nehemáyà 2:10, 19) Àwọn ọ̀tá Nehemáyà ṣáà fẹ́ rí i dájú pé àwọn dá ètò ògiri mímọ tí Nehemáyà ń ṣe dúró, kódà wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣe ibi. Ǹjẹ́ Nehemáyà yóò ‘jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun òun’?
“Ó Bínú, Ó sì Fara Ya Gidigidi”
5, 6. (a) Kí làwọn ọ̀tá Nehemáyà ṣe nígbà tí wọ́n rí i pé iṣẹ́ mímọ ògiri náà ń tẹ̀ síwájú? (b) Kí nìdí táwọn ọ̀tá Nehemáyà kò fi lè kó o láyà jẹ?
5 Nehemáyà kò bẹ̀rù rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tún ògiri Jerúsálẹ́mù mọ.” Àwọn náà sì dáhùn pé: ‘A ó mọlé.’ Nehemáyà wá sọ pé: “Wọ́n fún ọwọ́ wọn lókun fún iṣẹ́ rere náà,” àmọ́ àwọn alátakò “bẹ̀rẹ̀ sí fi wá ṣẹ̀sín, wọ́n sì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wa pé: ‘Kí ni ohun tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ọba ni ẹ̀yin ń ṣọ̀tẹ̀ sí?’” Nehemáyà kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn tí wọ́n ń sọ àtàwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án dẹ́rù ba òun. Ó sọ fáwọn alátakò náà pé: “Ọlọ́run ọ̀run ni Ẹni tí yóò yọ̀ǹda àṣeyọrí sí rere fún wa, àti pé àwa fúnra wa, tí a jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, yóò dìde, a ó sì mọlé.” (Nehemáyà 2:17-20) Nehemáyà pinnu láti máa bá “iṣẹ́ rere náà” lọ.
6 Ọ̀kan lára àwọn alátakò yẹn, ìyẹn Sáńbálátì wá “bínú, ó sì fara ya gidigidi,” ó sì túbọ̀ ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ń fi wọ́n ṣẹ̀sín pé: “Kí ni àwọn Júù ahẹrẹpẹ ń ṣe?” “Wọn yóò ha mú àwọn òkúta sọ jí láti inú òkìtì pàǹtí?” Tobáyà náà dara pọ̀ mọ́ ọn, ó ní: “Bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gùn ún, dájúdájú, yóò wó ògiri òkúta wọn lulẹ̀.” (Nehemáyà 4:1-3) Kí ni Nehemáyà ṣe?
7. Kí ni Nehemáyà ṣe nígbà táwọn ọ̀tá rẹ̀ ń fẹ̀sùn kàn án?
7 Nehemáyà kò ka yẹ̀yẹ́ tí wọ́n ń fi òun ṣe sí. Ó pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, kò sì gbìyànjú láti gbẹ̀san. (Léfítíkù 19:18) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ fún Jèhófà ó sì gbàdúrà pé: “Gbọ́, ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí a ti di ẹni ìfojú-tín-ín-rín; dá ẹ̀gàn wọn padà sórí wọn.” (Nehemáyà 4:4) Nehemáyà fọkàn tán ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé: “Tèmi ni ẹ̀san, àti ẹ̀san iṣẹ́.” (Diutarónómì 32:35) Bákan náà, Nehemáyà àtàwọn èèyàn rẹ̀ “ń mọ ògiri náà nìṣó.” Wọn ò jẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́. Àní sẹ́, “gbogbo ògiri náà pátá ni a sì mọ pọ̀ mọ́ra títí lọ dé ìdajì gíga rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń bá a lọ láti ní ọkàn-àyà fún iṣẹ́ ṣíṣe.” (Nehemáyà 4:6) Àwọn ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ wọ̀nyẹn kò lè dá iṣẹ́ ògiri mímọ́ náà dúró rárá! Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nehemáyà?
8. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nehemáyà nígbà táwọn ọ̀tá bá ń fẹ̀sùn èké kàn wá? (b) Sọ ìrírí kan tó o ní tàbí tó o gbọ́ tó fi hàn pé ó bọ́gbọ́n mu láti má ṣe gbẹ̀san.
8 Lọ́jọ́ òní, àwọn alátakò nílé ìwé, níbi iṣẹ́, tàbí nínú ìdílé wa pàápàá, lè máa sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ sí wa kí wọ́n sì máa fẹ̀sùn èké kàn wá. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, fífi ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti kojú irú àwọn ẹ̀sùn èké bẹ́ẹ̀. Ìlànà ọ̀hún ni pé: ‘Ìgbà dídákẹ́ jẹ́ẹ́ wà.’ (Oníwàásù 3:1, 7) Nítorí náà, bíi ti Nehemáyà, a ò ní sọ̀rọ̀ burúkú padà sí wọn. (Róòmù 12:17) A ó tọ Ọlọ́run lọ nínú àdúrà, a ó sì fọkàn tán ẹni tó mú un dá wa lójú pé: “Èmi yóò san ẹ̀san.” (Róòmù 12:19; 1 Pétérù 2:19, 20) Lọ́nà yẹn, a ò ní jẹ́ káwọn alátakò dí wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run tó yẹ ká ṣe lọ́jọ́ òní, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Nígbàkigbà tá a bá ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, tá ò jẹ́ kí àtakò dí wa lọ́wọ́, ńṣe là ń fi hàn pé irú ẹ̀mí tí Nehemáyà ní làwa náà ní.
‘Dájúdájú Àwa Yóò Pa Yín’
9. Irú àtakò wo làwọn ọ̀tá Nehemáyà gbé dìde sí i, kí ni Nehemáyà sì ṣe?
9 Nígbà táwọn tó ń ta ko ìjọsìn tòótọ́ nígbà ayé Nehemáyà gbọ́ pé “títún ògiri Jerúsálẹ́mù ṣe ti tẹ̀ síwájú,” wọ́n mú idà wọn “láti wá bá Jerúsálẹ́mù jà.” Lójú àwọn Júù yẹn, ó dà bí ẹni pé kò sírètí. Àwọn ará Samáríà wà níhà àríwá, àwọn ọmọ Ámónì wà níhà ìlà oòrùn, àwọn Lárúbáwá wà níhà gúúsù, àwọn ará Áṣídódì sì wà níhà ìwọ̀ oòrùn. Àwọn ọ̀tá wá yí Jerúsálẹ́mù ká; ó sì dà bíi pé kò sọ́nà àbáyọ fáwọn tó ń mọ ògiri náà! Kí ni wọ́n máa ṣe? Nehemáyà sọ pé: “A gbàdúrà sí Ọlọ́run wa.” Àwọn ọ̀tá náà halẹ̀ pé: “Dájúdájú, àwa yóò . . . pa wọ́n, a ó sì fi òpin sí iṣẹ́ náà.” Ohun tí Nehemáyà wá ṣe ni pé, ó tún yan iṣẹ́ dídáàbòbo ìlú náà fáwọn tó ń mọ ògiri yẹn, “ti àwọn ti idà wọn, aṣóró wọn àti ọrun wọn.” Lóòótọ́, lójú èèyàn, àwọn Júù tí wọ́n kéré gan-an yìí kò lè ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tí wọ́n pọ̀ jù wọ́n lọ fíìfíì yẹn, àmọ́ Nehemáyà rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ má fòyà . . . Jèhófà Ẹni ńlá tí ń múni kún fún ẹ̀rù ni kí ẹ fi sọ́kàn yín.”—Nehemáyà 4:7-9, 11, 13, 14.
10. (a) Kí ló fà á tí nǹkan ṣàdédé yí padà láàárín àwọn ọ̀tá Nehemáyà? (b) Kí làwọn ohun tí Nehemáyà ṣe?
10 Wàyí o, nǹkan ṣàdédé yí padà? Àwọn ọ̀tá náà dáwọ́ àtakò wọn dúró. Kí nìdí? Nehemáyà sọ pé: ‘Ọlọ́run tòótọ́ mú ète wọn já sí pàbó.’ Àmọ́ Nehemáyà mọ̀ pé àwọn ọ̀tá yẹn ṣì tún lè gbógun dìde. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lo ọgbọ́n, ó yí ọ̀nà táwọn tó ń mọ ògiri náà ń gbà ṣiṣẹ́ padà. Látìgbà náà lọ, “olúkúlùkù ni ọwọ́ rẹ̀ kan dí fún iṣẹ́ nígbà tí ọwọ́ kejì di ohun ọṣẹ́ mú.” Nehemáyà tún yan ọkùnrin kan tí “yóò fun ìwo” láti jẹ́ káwọn tó ń ṣiṣẹ́ náà mọ̀ bó bá ṣẹlẹ̀ pé àwọn ọ̀tá gbógun dé. Olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, Nehemáyà fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ọlọ́run wa fúnra rẹ̀ yóò jà fún wa.” (Nehemáyà 4:15-20) Èyí fún àwọn tó ń mọ ògiri náà níṣìírí gan-an ó sì tún jẹ́ kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ bó bá ṣẹlẹ̀ pé wàhálà yọjú, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ wọn lọ. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn yìí?
11. Kí ló ń jẹ́ káwọn Kristẹni tòótọ́ lè kojú ibi láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, báwo ni wọ́n sì ṣe ń fi ire ṣẹ́gun ibi?
11 Nígbà míì, àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń dojú kọ àtakò tó gbóná janjan. Àní sẹ́, láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn alátakò tó rorò máa ń pọ̀ gan-an wọ́n sì máa ń lágbára gan-an. Tá a bá fojú tèèyàn wò ó, ó dá bíi pé àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn kò lè ṣẹ́gun rárá. Síbẹ̀, ó dá àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn lójú pé ‘Ọlọ́run yóò jà fún wọn.’ Àní sẹ́, àwọn tí wọ́n ń rí inúnibíni nítorí ìgbàgbọ́ wọn ti rí i léraléra pé Jèhófà ń dáhùn àdúrà àwọn, ó sì ń “mú ète” àwọn ọ̀tá tó lágbára “já sí pàbó.” Kódà láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, àwọn Kristẹni máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè máa wàásù ìhìn rere náà nìṣó. Gẹ́gẹ́ báwọn tó mọ ògiri nílùú Jerúsálẹ́mù ṣe yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ wọn padà, bẹ́ẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ń lo ọgbọ́n, wọ́n máa ń yí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣiṣẹ́ ìwàásù wọn padà nígbà táwọn èèyàn bá ń ṣenúnibíni sí wọn. Àmọ́ ṣá o, wọn kì í lo ohun ìjà ti ara. (2 Kọ́ríńtì 10:4) Kódà, bí wọ́n tilẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ wọn pé wọ́n máa ṣe wọ́n bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣojú, ìyẹn kì í mú kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ ìwàásù wọn dúró. (1 Pétérù 4:16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nígboyà yẹn máa ń “fi ire ṣẹ́gun ibi.”
“Wá, Jẹ́ Kí A Pàdé Pọ̀”
12, 13. (a) Ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo làwọn alátakò Nehemáyà dá? (b) Kí nìdí tí Nehemáyà fi kọ̀ láti lọ nígbà táwọn ọ̀tá rẹ̀ ní kó wá pàdé àwọn?
12 Lẹ́yìn táwọn ọ̀tá Nehemáyà rí i pé báwọn ṣe ń gbéjà kò ó ní tààràtà yẹn kò ṣiṣẹ́, wọ́n wá lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti máa ṣe àtakò. Kódà, wọ́n gbìyànjú ọ̀nà mẹ́ta. Kí làwọn ọ̀nà mẹ́ta náà?
13 Àkọ́kọ́, àwọn ọ̀tá Nehemáyà gbìyànjú láti tàn án. Wọ́n sọ fún un pé: “Wá, jẹ́ kí a pàdé pọ̀ nípasẹ̀ àdéhùn ní àwọn abúlé pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Ónò.” Àárín ìlú Jerúsálẹ́mù àti Samáríà ni Ono wà. Àwọn ọ̀tá náà sọ pé kí Nehemáyà pàdé àwọn ní agbedeméjì yìí káwọn lè yanjú aáwọ̀ náà. Ká ní Nehemáyà fẹ́, ó lè ronú pé: ‘Ìyẹn mà bọ́gbọ́n mu o. Ó dára ká jọ sọ̀rọ̀ ju ká máa bára wa jà lọ.’ Àmọ́ Nehemáyà kọ̀. Ó sì ṣàlàyé ìdí, ó ní: “Wọ́n ń pète-pèrò láti ṣe ìpalára fún mi.” Ó mọ ète tí wọ́n ń pa, kò sì jẹ́ kí wọ́n rí òun tàn jẹ. Ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ fáwọn alátakò rẹ̀ pé: “Èmi kò . . . lè sọ̀ kalẹ̀ wá. Èé ṣe tí iṣẹ́ náà yóò fi dúró nígbà tí mo bá ṣíwọ́ kúrò lẹ́nu rẹ̀, tí mo sì sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín?” Gbogbo ọgbọ́n táwọn ọ̀tá dá láti rí Nehemáyà mú ló já sásán. Iṣẹ́ mímọ ògiri náà ló gbájú mọ́.—Nehemáyà 6:1-4.
14. Kí ni Nehemáyà ṣe nípa àwọn tó ń fẹ̀sùn èké kàn án?
14 Èkejì, àwọn ọ̀tá Nehemáyà bẹ̀rẹ̀ sí í tan irọ́ kálẹ̀. Wọ́n fẹ̀sùn èké kan Nehemáyà pé ó “ń pète-pèrò láti ṣọ̀tẹ̀” sí Atasásítà Ọba. Ni wọ́n bá tún sọ fún Nehemáyà lẹ́ẹ̀kan sí i pé: “Jẹ́ kí a jọ fikùnlukùn.” Àmọ́ Nehemáyà tún kọ̀, nítorí ó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọ̀tá náà. Nehemáyà ṣàlàyé pé: “Gbogbo wọn ń gbìyànjú láti mú wa fòyà, wọ́n ń wí pé: ‘Ọwọ́ wọn yóò rọ jọwọrọ kúrò lẹ́nu iṣẹ́ náà tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ṣe é.’” Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Nehemáyà jẹ́ káwọn ọ̀tá rẹ̀ mọ̀ pé irọ́ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan òun, ó sọ fún wọn pé: ‘Irú ohun tí ẹ̀ ń sọ kò ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n láti inú ọkàn-àyà ẹ̀yin fúnra yín ni ẹ ti ń hùmọ̀ wọn.’ Ìyẹn nìkan kọ́, Nehemáyà yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, ó gbàdúrà pé: “Fún ọwọ́ mi lókun.” Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, òun yóò borí ètekéte yìí òun yóò sì máa bá iṣẹ́ mímọ ògiri náà lọ.—Nehemáyà 6:5-9.
15. Ìmọ̀ràn wo ni wòlíì èké kan gba Nehemáyà, kí sì nìdí tí Nehemáyà kò fi tẹ̀ lé ìmọ̀ràn náà?
15 Ẹ̀kẹta, àwọn ọ̀tá Nehemáyà lo ọ̀dàlẹ̀ èèyàn kan, ìyẹn Ṣemáyà tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, pé kó gbìyànjú láti mú Nehemáyà rú Òfin Ọlọ́run. Ṣemáyà sọ fún Nehemáyà pé: “Jẹ́ kí a jọ pàdé nípasẹ̀ àdéhùn ní ilé Ọlọ́run tòótọ́, láàárín tẹ́ńpìlì, sì jẹ́ kí a ti àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì; nítorí wọ́n ń wọlé bọ̀ láti wá pa ọ́.” Ṣemáyà sọ pé àwọn kan fẹ́ wá pa Nehemáyà àti pé ó lè bọ́ lọ́wọ́ ikú bó bá sá pa mọ́ sínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ Nehemáyà kì í ṣe àlùfáà. Yóò dẹ́ṣẹ̀ bó bá lọ sá pa mọ́ sínú ilé Ọlọ́run. Ǹjẹ́ Nehemáyà yóò rú Òfin Ọlọ́run kó bàa lè dá ẹ̀mí rẹ̀ sí? Ó wá fún Ṣemáyà lésì pé: “Ta ni ó sì wà tí ó dà bí èmi tí ó lè wọnú tẹ́ńpìlì, kí ó sì wà láàyè? Èmi kì yóò wọ̀ ọ́!” Kí nìdí tí Nehemáyà kò fi kó sínú páńpẹ́ tí wọ́n dẹ sílẹ̀ fún un? Nítorí ó mọ̀ pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ísírẹ́lì bíi tòun ni Ṣemáyà, “kì í ṣe Ọlọ́run ni ó rán an.” Ó ṣe tán, wòlíì tòótọ́ kò ní gbà á nímọ̀ràn pé kó rú Òfin Ọlọ́run. Lọ́tẹ̀ yìí náà, Nehemáyà kò jẹ́ káwọn ẹni ibi tó ń ṣàtakò ṣẹ́gun òun. Èyí mú kó lè sọ láìpẹ́ sí àkókò yẹn pé: “Nígbà tí ó ṣe, ògiri náà parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n Élúlì, ní ọjọ́ méjì-lé-láàádọ́ta.”—Nehemáyà 6:10-15; Númérì 1:51; 18:7.
16. (a) Báwo ló ṣe yẹ ká ṣe sáwọn ọ̀rẹ́ èké, àwọn tó ń fẹ̀sùn èké kàn wá, àtàwọn èké arákùnrin? (b) Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o kò ní ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ rẹ nílé, níléèwé, tàbí níbi iṣẹ́?
16 Bíi ti Nehemáyà, àwa náà lè dojú kọ àwọn alátakò tí wọ́n lè máa ṣe bí ọ̀rẹ́, wọ́n sì lè jẹ́ àwọn tó ń fẹ̀sùn èké kàn wá, tàbí àwọn èké arákùnrin. Àwọn kan lè sọ pé ká pàdé àwọn ní agbedeméjì, ká sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. Wọ́n lè gbìyànjú láti sọ fún wa pé, tí a bá tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a lè máa wá nǹkan tayé ká sì tún máa sin Jèhófà lákòókò kan náà. Àmọ́ o, nítorí pé Ìjọba Ọlọ́run la fi ṣáájú nígbèésí ayé wa, a ò ní tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọn. (Mátíù 6:33; Lúùkù 9:57-62) Àwọn alátakò tún máa ń tan ẹ̀sùn èké kálẹ̀ nípa wa. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, wọ́n máa ń sọ pé ewu la jẹ́ fún Ìjọba, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe fẹ̀sùn kan Nehemáyà pé ó ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba. A ti jàre àwọn ẹ̀sùn kan tí wọ́n fi kàn wá láwọn ilé ẹjọ́. Àmọ́ ibi yòówù kí ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa já sí, àdúrà wa ni pé kí Jèhófà bójú tó àwọn ọ̀ràn náà níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ọkàn wa sì balẹ̀ pé yóò dáhùn àdúrà wa. (Fílípì 1:7) Àtakò tún lè wá látọ̀dọ̀ àwọn tó ń ṣe bí ẹni pé olùjọ́sìn Jèhófà ni wọ́n. Bí ẹnì kan tó jẹ́ Júù ṣe gbìyànjú láti mú kí Nehemáyà rú Òfin Ọlọ́run kí Nehemáyà bàa lè dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, bẹ́ẹ̀ làwọn tí wọ́n ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí tẹ́lẹ̀ rí àmọ́ tí wọ́n ti di apẹ̀yìndà ṣe lè gbìyànjú láti mú ká ṣe ohun tí Ọlọ́run kò fẹ́, lọ́nà kan tàbí òmíràn. Àmọ́ ṣá o, a kì í gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn apẹ̀yìndà nítorí a mọ̀ pé pípa òfin Ọlọ́run mọ́ ló máa mú ka ní ìgbàlà kì í ṣe rírú òfin Ọlọ́run! (1 Jòhánù 4:1) Dájúdájú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a lè ṣẹ́gun ibi èyíkéyìí.
À Ń Wàásù Ìhìn Rere Láìfi Ibi Pè
17, 18. (a) Kí lohun tí Sátánì àtàwọn aṣojú rẹ̀ fẹ́ ṣe? (b) Kí ni ìwọ́ pinnu láti ṣe, kí sì nìdí?
17 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àwọn arákùnrin Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé: ‘Wọ́n ṣẹ́gun Sátánì nítorí ọ̀rọ̀ ìjẹ́rìí wọn.’ (Ìṣípayá 12:11) Nítorí náà, wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun Sátánì, ẹni tó pilẹ̀ ibi. Ìdí nìyẹn tí Sátánì kò fi dáwọ́ dúró láti máa gbéjà ko àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” nípa gbígbé àtakò dìde sí wọn!—Ìṣípayá 7:9; 12:17.
18 Bá a ṣe rí i, oríṣiríṣi ọ̀nà ni àtakò lè gbà wá, ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé, tàbí káwọn ọ̀tá máa halẹ̀ pé àwọ́n á ṣe wá ní jàǹbá, tàbí kó jẹ́ pé ọ̀nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ló máa gbà wá. Ọ̀nà yòówù kó gbà wá, ohun kan ṣoṣo ni Sátánì ní lọ́kàn, ìyẹn ni láti dá iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe dúró. Àmọ́, yóò kùnà pátápátá nítorí pé bíi ti Nehemáyà ayé ọjọ́un, àwọn èèyàn Ọlọ́run ti pinnu láti “máa fi ire ṣẹ́gun ibi.” Wọ́n á máa ṣe bẹ́ẹ̀ nípa bíbá a nìṣó láti máa wàásù ìhìn rere náà títí Jèhófà yóò fi sọ pé iṣẹ́ náà ti parí!—Máàkù 13:10; Róòmù 8:31; Fílípì 1:27, 28.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí dáadáa, ka Nehemáyà 1:1-4; 2:1-6, 9-20; 4:1-23; 6:1-15.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àtakò wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run dojú kọ láyé ọjọ́un, táwọn Kristẹni lọ́jọ́ òní náà sì ń dojú kọ?
• Kí lohun náà gan-an táwọn ọ̀tá Nehemáyà ní lọ́kàn, kí sì làwọn ọ̀tá Ọlọ́run lọ́jọ́ òní náà ní lọ́kàn?
• Báwo la ṣe ń bá a nìṣó láti máa fi ire ṣẹ́gun ibi lónìí?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn ẹ̀kọ́ tá a rí nínú ìwé Nehemáyà
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ń dojú kọ
• ìfiniṣẹ̀sín
• ìhàlẹ̀
• ẹ̀tàn
Ìtànjẹ máa ń wá látọ̀dọ̀
• àwọn ọ̀rẹ́ èké
• àwọn tó ń fẹ̀sùn èké kàn wá
• àwọn èké arákùnrin
Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń ṣẹ́gun ibi nípa
• ṣíṣàì jáwọ́ nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé fún wọn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Nehemáyà àtàwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ̀ mọ ògiri Jerúsálẹ́mù bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dojú kọ àtakò tó le gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń wàásù ìhìn rere láìbẹ̀rù