Padà Di Erùpẹ̀ Báwo?
“ERÙPẸ̀ sá ni ìwọ, ìwọ óò sì padà di erùpẹ̀.” Nígbà tí ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù, gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, ó mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. A mú un jáde láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, yóò sì padà di erùpẹ̀ lásán. Yóò kú nítorí ó ti ṣàìgbọràn sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7, 15-17; 3:17-19.
Bíbélì fi hàn pé erùpẹ̀ ní a fi dá ènìyàn. Ó tún sọ pé: “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” (Ìsíkíẹ̀lì 18:4; Orin Dáfídì 103:14) Ikú ti mú ìbànújẹ́ wá bá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn, ó sì ti gbé ìbéèrè dìde léraléra lórí pípalẹ̀ òkú mọ́.
Àwọn Àṣà Àtijọ́ àti Ti Ìsinsìnyí
Báwo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ìgbàanì ṣe ń palẹ̀ òkú mọ́? Ní àwọn ojú ewé àkọ́kọ́ rẹ̀, Bíbélì mẹ́nu kan onírúurú ọ̀nà tí a ń gbà palẹ̀ òkú mọ́, títí kan sísìnkú sínú ilẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 35:8) A sin babańlá, Ábúráhámù, àti ìyàwó rẹ̀, Sárà, títí kan ọmọkùnrin wọn, Aísíìkì àti ọmọ-ọmọ wọn, Jékọ́bù, sínú ihò Mákípẹ́là. (Jẹ́nẹ́sísì 23:2, 19; 25:9; 49:30, 31; 50:13) A sin àwọn onídàájọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Gídéónì àti Sámúsìnì ‘sí ibojì àwọn bàbá wọn.’ (Àwọn Onídàájọ́ 8:32; 16:31) Èyí fi hàn pé àwọn ènìyàn Ọlọ́run ìgbàanì fẹ́ràn níní ibi sàréè ti ìdílé. Nígbà tí Jésù Kristi kú ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, a tẹ́ òkú rẹ̀ sínú ibojì òkúta, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́. (Mátíù 27:57-60) Nígbà náà, ní gbogbogbòò, a ń sin òkú ènìyàn sínú ilẹ̀, tàbí gbé e sínú ibojì. Èyí ṣì jẹ́ àṣà ní ibi tí ó pọ̀ jù lọ yíká ilẹ̀ ayé.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní àwọn apá ibì kan lágbàáyé lónìí, àìtó ilẹ̀ àti owó gegere tí ilẹ̀ ń náni ń mú kí ó túbọ̀ ṣòro láti rí ilẹ̀ ìsìnkú. Nítorí náà, àwọn kan ń ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà míràn tí a ń gbà palẹ̀ òkú mọ́.
Fífọ́n eérú kiri lẹ́yìn dídáná sun òkú deérú, ti ń wọ́pọ̀ sí i. Nísinsìnyí, ní England, a ń palẹ̀ àwọn òkú tí ó tó nǹkan bí ìdá 40 nínú ọgọ́rùn-ún mọ́ lọ́nà yìí. Ní Sweden, níbi tí a ti ń dáná sun èyí tí ó ju ìdá 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń di olóògbé ní àwọn ìlú ńlá di eérú, a ṣètò àwọn igbó kan fún fífọ́n eérú sí. Ní Shanghai àti ní àwọn ìlú ńlá etíkun mélòó kan ní China, àwọn ìjọba ìlú ńlá ń ṣonígbọ̀wọ́ fífọ́n eérú lọ́pọ̀ yanturu sórí òkun lọ́pọ̀ ìgbà nínú ọdún.
Níbo ni a lè fọ́n eérú sí? Kì í ṣe ibikíbi ṣáá. Àwọn kan lè bẹ̀rù pé fífọ́n eérú léwu fún àyíká. Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, ewu ṣíṣeé ṣe èyíkéyìí pé kí àrùn bẹ́ sílẹ̀ nítorí dídáná sun òkú deérú kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Ní àwọn itẹ́ kan ní England àti àwọn ọgbà ìrántí ní United States, a ya àwọn agbègbè eléwéko títẹ́ rẹrẹ tàbí àwọn ọgbà òdòdó sọ́tọ̀ fún fífọ́n eérú sí. Àmọ́ ṣáá o, àwọn Kristẹni ń ṣàníyàn ní pàtàkì nípa ojú ìwòye Ìwé Mímọ́ nípa dídáná sun òkú deérú àti fífọ́n eérú.
Kí Ni Ojú Ìwòye Ìwé Mímọ́?
Nínú ìkéde kan lòdì sí “ọba Bábílónì” wòlíì Aísáyà wí pé: “Ìwọ ní a gbé sọnù kúrò níbi ibojì rẹ.” (Aísáyà 14:4, 19) A ha ní láti fi fífọ́n eérú wé irú ìtẹ́nilógo bẹ́ẹ̀ bí? Rárá o, nítorí a kò tọ́ka sí dídáná sun òkú deérú tàbí fífọ́n eérú rẹ̀.
Jésù Kristi sọ nípa àjíǹde àwọn òkú lórí ilẹ̀ ayé, tí yóò wáyé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rúndún rẹ̀, nígbà tí ó wí pé: “Gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi] wọn yóò sì jáde wá.” (Jòhánù 5:28, 29) Bí ó ti wù kí ó rí, a fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ míràn nípa àjíǹde pé, ibojì kan pàtó kò pọn dandan láti jí ẹnì kan dìde. Ìṣípayá 20:13 sọ pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú wọnnì tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú ati Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú wọnnì tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.” Nítorí náà, kì í ṣe ibi tí tàbí bí ẹnì kan ṣe “padà di erùpẹ̀” ni ó ṣe pàtàkì. Kàkà bẹ́ẹ̀, bóyá Ọlọ́run rántí rẹ̀, tí ó sì jí i dìde ni ó ṣe pàtàkì. (Jóòbù 14:13-15; fi wé Lúùkù 23:42, 43.) Dájúdájú, Jèhófà kò nílò àwọn ibojì mèremère láti ràn án lọ́wọ́ láti rántí àwọn ènìyàn. Dídáná sun òkú deérú kò dènà àjíǹde ẹnì kan. Bí a bá sì fọ́n eérú pẹ̀lú ìsúnniṣe títọ́, tí kò sì sí ayẹyẹ ìsìn èké, kì yóò ṣàìbá Ìwé Mímọ́ mu.
Àwọn tí ó bá pinnu láti fọ́n eérú gbọ́dọ̀ kíyè sí òfin orílẹ̀-èdè. Yóò tún bá a mu wẹ́kú fún wọn láti ronú nípa ìmọ̀lára àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ àti àwọn ẹlòmíràn. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò ṣe rere láti kíyè sára kí lílo òmìnira wọn, tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, nínú ọ̀ràn yìí má baà mú ẹ̀gàn bá orúkọ rere tí àwọn Kristẹni ń jẹ́. Èyí ṣe pàtàkì gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí òfin ti fàyè gba dídáná sun òkú deérú, ṣùgbọ́n tí a kò tí ì tẹ́wọ́ gbà á ní kíkún ládùúgbò. Àmọ́ ṣáá o, Kristẹni kan yóò yẹra fún àwọn ààtò tàbí àṣà èyíkéyìí tí a gbé karí ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn.
Òmìnira Kíkún Kúrò Lọ́wọ́ Sàréè Kẹ̀!
Àwọn kan tí ń ṣalágbàwí fífọ́n eérú sọ pé ó túmọ̀ sí òmìnira kúrò lọ́wọ́ sísinni sí sàréè. Ṣùgbọ́n, ohun tí yóò mú ìtúsílẹ̀ títóbi jù lọ wá ni ìmúṣẹ ìlérí Bíbélì náà pé, “gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a óò sọ di asán.”—Kọ́ríńtì Kìíní 15:24-28.
Èyí túmọ̀ sí pé sàréè, ibojì, àní dídáná sun òkú deérú àti fífọ́n eérú, yóò di àwọn nǹkan àtijọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, ikú kì yóò sí mọ́. Lábẹ́ ìmísí àtọ̀runwá, àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo gbọ́ ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wá wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, òun yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Òun yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Gbogbo èyí yóò wáyé nígbà tí a bá mú ikú tí ń pa ẹ̀dá ènìyàn, tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kúrò, lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Nígbà yẹn, aráyé onígbọràn kì yóò dojú kọ ìfojúsọ́nà ti pípadà di erùpẹ̀.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀nà tí ó wọ́pọ̀ tí a ń gbà palẹ̀ òkú mọ́
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Fífọ́n eérú níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Òkun Sagami, ní Japan
[Credit Line]
Ìyọ̀ọ̀da onínúure ti Koueisha, Tokyo