ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 144
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Sísun Òkú?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Sísun Òkú?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Àṣìlóye táwọn èèyàn sábà máa ń ní nípa sísun òkú
  • Ṣó Dáa Kí Wọ́n Máa Fi Iná Sun Òkú Èèyàn?
    Jí!—2009
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Padà Di Erùpẹ̀ Báwo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2009
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 144
Ohun tí wọ́n ń da eérú òkú sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ fọ́tò ẹni tó kú

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Sísun Òkú?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì ò fún wa ní ìtọ́ni kan pàtó lórí ọ̀rọ̀ fífi iná sun òkú. Kò sí òfin kankan nínú Bíbélì tó dá lórí sísin òkú tàbí fífi iná sun ún.

Àmọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tí wọ́n sin òkú èèyàn wọn. Bí àpẹẹrẹ, Ábúráhámù sapá gidigidi kó lè ra ibi tó máa sin òkú Sérà ìyàwó rẹ̀ sí.​—Jẹ́nẹ́sísì 23:2-20; 49:29-32.

Bíbélì tún mẹ́nu ba àwọn olóòótọ́ èèyàn tó sun òkú àwọn míì nínú iná. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọ̀tá pa Sọ́ọ̀lù ọba Ísírẹ́lì àti mẹ́ta nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sójú ogun, ilẹ̀ àwọn ọ̀tá ni wọ́n kú sí, wọn ò sì palẹ̀ òkú wọn mọ́. Nígbà táwọn olóòótọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ jagunjagun gbọ́, wọ́n lọ gbé òkú Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọ rẹ̀ kúrò níbẹ̀, wọ́n dáná sun àwọn òkú náà, wọ́n sì fi iyẹ̀pẹ̀ bò wọ́n mọ́lẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 31:8-13) Bíbélì jẹ́ ká rí i pé ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ṣe sí àwọn òkú náà rí ìtẹ́wọ́gbà.​—2 Sámúẹ́lì 2:4-6.

Àṣìlóye táwọn èèyàn sábà máa ń ní nípa sísun òkú

Àṣìlóye: Nǹkan ẹ̀sín ni téèyàn bá dáná sun òkú.

Òtítọ́: Bíbélì sọ pé àwọn tó bá kú máa pa dà di erùpẹ̀, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn tí òkú kan bá ti jẹrà. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Tí wọ́n bá dáná sun òkú, ṣe ló máa jẹ́ kó tètè di eérú, tàbí erùpẹ̀, dípò kó kọ́kọ́ jẹrà.

Àṣìlóye: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn tí kò rí ojúure Ọlọ́run nìkan ni wọ́n máa ń dáná sun òkú wọn.

Òtítọ́: Wọ́n dáná sun òkú àwọn èèyàn kan tí wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, bí Ákánì àti ìdílé rẹ̀. (Jóṣúà 7:25) Àmọ́ ìyẹn kàn wáyé bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ohun tí òfin sọ pé kí wọ́n máa ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ nìyẹn. (Diutarónómì 21:22, 23) Bá a ṣe sọ ṣáájú, wọ́n dáná sun òkú àwọn kan tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, bíi Jónátánì tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba.

Àṣìlóye: Tí wọ́n bá dáná sun òkú ẹnì kan, Ọlọ́run ò ní lè jí i dìde.

Òtítọ́: Tó bá dọ̀rọ̀ àjíǹde àwọn òkú, kò sí òkú tí Ọlọ́run ò lè jí dìde, ì báà jẹ́ èyí tí wọ́n sin, èyí tí wọ́n dáná sun, èyí tó bómi lọ tàbí tí ẹran igbó jẹ. (Ìfihàn 20:13) Kò ná Olódùmarè ní nǹkan kan láti dá ara tuntun fún ẹni náà.​—1 Kọ́ríńtì 15:35, 38.

Bá A Ṣe Lè Pinnu Bóyá Ká Sun Òkú Tàbí Ká Sin Ín

Tó o bá fẹ́ pinnu ohun tó o lè ṣe sí òkú ẹnì kan, gbé àwọn kókó yìí yẹ̀ wò.

  • Ohun tí olóògbé fẹ́. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa bí àwọn mọ̀lẹ́bí ẹnì kan tó kú ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni tí onítọ̀hún fún wọn kó tó kú nípa bóun ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe òkú òun.​—Jẹ́nẹ́sísì 50:4, 5; Ẹ́kísódù 13:19.

  • Àṣà ìbílẹ̀. Àṣà ìbílẹ̀ sábà máa ń nípa lórí ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe sí òkú. (Jòhánù 19:40) Bí àpẹẹrẹ, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ṣe làwọn èèyàn máa ń sin òkú torí ohun tó wọ́pọ̀ nìyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 49:31; 1 Sámúẹ́lì 28:3) Bẹ́ẹ̀ náà, lóde òní, àwọn èèyàn lè pinnu láti tẹ̀ lé àṣà ilẹ̀ wọn tó bá dọ̀rọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe sí òkú, tó bá ṣáà ti jẹ́ pé àwọn àṣà náà ò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

  • Ohun tí òfin sọ. Bíbélì rọ̀ wá pe ká máa ṣègbọràn sí àwọn aláṣẹ. (Róòmù 13:1) Láwọn àdúgbò kan, àwọn aláṣẹ máa ń ṣòfin nípa bó ṣe yẹ kí èèyàn ṣe òkú. Bí àpẹẹrẹ, tó bá dọ̀rọ̀ sísun òkú, àwọn aláṣẹ kan ṣòfin pé ó níbi tí wọ́n lè da eérú òkú náà sí.

  • Bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára àwọn míì. Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká máa wá ire àwọn ẹlòmíì. (Fílípì 2:4) Tá a bá fẹ́ pinnu ohun tá a máa ṣe sí òkú ẹnì kan, a lè ronú lórí àwọn ìbéèrè yìí: Ojú wo làwọn mọ̀lẹ́bí yòókù fi wo ká dáná sun òkú náà tàbí ká sin ín? Ojú wo làwọn aráàlú fi ń wo irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́