Àlá Ha Lè Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Bí?
LÁTI ìgbà ìjímìjí, ni aráyé ti ní ọkàn ìfẹ́ jíjinlẹ̀ nínú àlá. Àwọn ará Íjíbítì ṣe àwọn ìwé kíkún rẹ́rẹ́ fún ìtumọ̀ àlá, àwọn ará Bábílónì sì ní àwọn olùtúmọ̀ àlá wọn. Láàárín àwọn Gíríìkì, àṣà wọn ni kí àwọn aláìsàn sùn sí ojúbọ Asclepius, kí wọ́n lè gba ìtọ́ni lórí ìlera lójú àlá. Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, Artemidorus ṣe ìwé kan nínú èyí tí ó ti fún àwọn àmì àlá ní ìtumọ̀. Ọ̀pọ̀ ìwé tí ó jẹ mọ́ ọn tí a ṣe lẹ́yìn náà ni a gbé karí ìwé rẹ̀. Títí di ọjọ́ òní, a ti ń sapá láti túmọ̀ àlá, ṣùgbọ́n wọ́n ha fúnni ní òye inú nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la ní tòótọ́ bí?
Kí wọ́n baà lè ní ìjẹ́pàtàkì ọjọ́ ọ̀la, ipá gíga jù lọ kan ní láti ní agbára ìdarí lórí wọn. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ nínú èyí tí Ọlọ́run ti fúnni ní irú ipá bẹ́ẹ̀. Ó mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn kan tí kò jọ́sìn rẹ̀ lálàá alásọtẹ́lẹ̀. Ní tòótọ́, Jóòbù 33:14-16 sọ pé: “Ọlọ́run sọ̀rọ̀ . . . nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tí oorun ìjìkà bá kun ènìyàn lọ, ní ìsùn yẹ́ẹ́ lórí ibùsùn. Nígbà náà ní í ṣí etí ènìyàn.”
Ọlọ́run ṣe èyí nínú ọ̀ràn Fáráò ará Íjíbítì ní ọjọ́ Jósẹ́fù, ẹni tí ó gbé ayé ní ohun tí ó lé ní 1,700 ọdún ṣááju Sànmánì Tiwa. A rí àlá Fáráò nínú Jẹ́nẹ́sísì 41:1-7, àti ní ẹsẹ 25 sí 32, Jósẹ́fù túmọ̀ rẹ̀ pé ó ń sọ nípa ọdún méje ‘ọ̀pọ̀ tí yóò wà ní ilẹ̀ Íjíbítì,’ tí ọdún méje ìyàn yóò sì tẹ̀ lé e. Jósẹ́fù ṣàlàyé fún Fáráò pé: “Ohun tí Ọlọ́run ń bọ̀ wá ṣe, ó ti fi hàn fún Fáráò.” (Jẹ́nẹ́sísì 41:28) Àlá náà jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ti gidi.
Ọba àwọn ará Bábílónì kan tí ó tayọ lọ́lá ní ìrírí tí ó fara jọ ọ́. Nebukadinésárì lálàá kan tí ó dà á lọ́kàn rú gidigidi, ṣùgbọ́n kò lè rántí rẹ̀. Nítorí náà, ó ké sí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ rẹ̀ láti sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún òun. Èyí jẹ́ ohun àbéèrèfún tí kò ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe.—Dáníẹ́lì 2:1-11.
Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mú kí ọba lá àlá náà, Ó mú kí wòlíì Dáníẹ́lì rọ́ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún un. Dáníẹ́lì 2:19 sọ pé: “Nígbà náà a fi àṣírí náà hàn fún Dáníẹ́lì ní ìran ní òru.” Dáníẹ́lì fi ògo fún Ọlọ́run nítorí àlá yìí pé: “Àṣírí tí ọba ń béèrè, àwọn ọlọgbọ́n, àwọn oṣó, àwọn amòye, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ, kò lè fi hàn fún ọba. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn, ẹni tí ó sì fi hàn fún Nebukadinésárì ohun tí ń bọ̀ wá ṣe ní ìkẹyìn ọjọ́.”—Dáníẹ́lì 2:27, 28.
Nígbà míràn, Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìtọ́ni nípasẹ̀ àlá, nígbà míràn, ó sì máa ń mú ojú rere àtọ̀runwá rẹ̀ dá wọn lójú tàbí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye bí òun ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Nínú ọ̀ràn Jékọ́bù, Ọlọ́run fi hàn pé òun tẹ́wọ́ gbà á nípasẹ̀ àlá.—Jẹ́nẹ́sísì 48:3, 4.
Nígbà tí Jósẹ́fù, bàbá tí ó gba Jésù ṣọmọ, rí i pé Màríà ti fẹ́ra kù, ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Nígbà náà ni ó gba ìtọ́ni nínú àlá láti má ṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Mátíù 1:20 sọ pé: “Lẹ́yìn tí ó ti fara balẹ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí, wò ó! áńgẹ́lì Jèhófà fara hàn án nínú àlá, ó wí pé: ‘Jósẹ́fù, ọmọkùnrin Dáfídì, má ṣe fòyà láti mú Màríà aya rẹ sí ilé, nítorí èyíinì tí òun lóyún rẹ̀ sínú jẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.’” Lẹ́yìn náà, a kì í nílọ̀ nínú àlá pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà fara han Jósẹ́fù nínú àlá, ó wí pé: ‘Dìde, mú ọmọ kékeré náà àti ìyá rẹ̀ kí o sì sá lọ sí Íjíbítì.’”—Mátíù 2:13.
Àwọn Àlá Tí Kò Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá
Òkodoro òtítọ́ náà pé títúmọ̀ àlá wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí kì í ṣe ènìyàn Ọlọ́run fi hàn pé a kò lè ka àlá ní gbogbogbòò sí ohun tí ń ṣí ọjọ́ ọ̀la payá lọ́nà tí ó ṣeé gbára lé. Ní ọjọ́ Jeremáyà, wòlíì Ọlọ́run, àwọn èké wòlíì ń sọ pé: “Mo lá àlá! mo lá àlá!” (Jeremáyà 23:25) Èrò wọn jẹ́ láti ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà sínú ríronú pé, Ọlọ́run ń tipasẹ̀ wọn sọ̀rọ̀. Nípa àwọn àlá wọ̀nyí, a mí sí Jeremáyà láti sọ pé: “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí pé, Ẹ má ṣe jẹ́ kí àwọn wòlíì yín tí ó wà láàárín yín àti àwọn aláfọ̀sẹ yín tàn yín jẹ, kí ẹ má sì fetí sí àlá yín tí ẹ̀yin lá. Nítorí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún yín ní orúkọ mi: . . . ni Olúwa wí.”—Jeremáyà 29:8, 9.
Níwọ̀n bí àwọn èké wòlíì wọ̀nyí ti jẹ́ “aláfọ̀ṣẹ,” àwọn ipá ẹ̀mí búburú ti ní láti lo agbára ìdarí lórí àlá wọn fún ète títan àwọn ènìyàn jẹ. Ohun kan náà ni ohun tí a kọ sínú Sekaráyà 10:2 fi hàn pé: “Àwọn òrìṣà ti ń sọ̀rọ̀ asán, àwọn aláfọ̀ṣẹ sì ti rí èké, wọ́n sì ti rọ́ èké, wọ́n ń tù mí ní inú lásán.”
Èṣù ni olórí atannijẹ, tí ó ti lo àwọn aṣáájú ìsìn fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún láti fi èké sọ pé, Ọlọ́run ti tipasẹ̀ ìran àti àlá bá wọn sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn èké wòlíì ní ọjọ́ Jeremáyà àti Sekaráyà ti wí. Nípa irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, òǹkọ̀wé Bíbélì tí a mí sí, Júúdà, kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní pé: “Àwọn ènìyàn kan báyìí ti yọ́ wọlé, àwọn tí Ìwé Mímọ́ ti yàn kalẹ̀ láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn fún ìdájọ́ yìí, àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí wọ́n ń sọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa di àwáwí fún ìwà àìníjàánu tí wọ́n sì já sí èké sí Ẹnì kan ṣoṣo náà tí ó ni wá tí ó sì jẹ́ Olúwa wa, Jésù Kristi.” Ó wí pé, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ‘fi àwọn àlá kẹ́ra bàjẹ́,’ kí a sọ ọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Júúdà 4, 8.
Yiiri Àwọn Ohun Tí A Bá Sọ Wò
Ẹnì kan lè sọ pé Ọlọ́run bá òun sọ̀rọ̀ nínú àlá tàbí pé àlá òun nípa ọjọ́ ọ̀la ṣẹ, síbẹ̀ ìyẹn kì í ṣe ìdí tí ó tó láti gbà á gbọ́, kí a sì máa tẹ̀ lé e láìgbé ohun tí ó sọ yẹ̀ wò. Kíyè sí ìtọ́ni tí a kọ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí a rí nínú Diutarónómì 13:1-3, 5 pé: “Bí wòlíì kan bá hù láàárín rẹ, tàbí alálàá kan, tí ó sì fi àmì tàbí iṣẹ́ ìyanu kan hàn ọ́. Tí àmì náà tàbí iṣẹ́ ìyanu náà tí ó sọ fún ọ bá ṣẹ, wí pé, Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ lé ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn, tí ìwọ kò tí ì mọ̀ rí, kí a sì máa sìn wọ́n; Ìwọ kò gbọdọ̀ fetí sí ọ̀rọ̀ wòlíì náà, tàbí alálàá náà: . . . Àti wòlíì náà, tàbí alálàá náà, ni kí ẹ̀yin kí ó pa.” Ọlọ́run yọ̀ọ̀da kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ èké, gẹ́gẹ́ bí ìdánwò ìṣòtítọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.
Dípò gbígba ohun tí àwọn afagbára idán lálàá sọ gbọ́ láìgbé e yẹ̀ wò, ipa ọ̀nà ọgbọ́n fún wa ni láti yiiri ohun tí wọ́n sọ wò, kí a lè yẹra fún dídi ẹni tí olórí atannijẹ tí a kò lè fojú rí náà ṣì lọ́nà, ẹni tí “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè yiiri wọn wò lọ́nà tí ó ṣeé gbára lé?
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a kọ sílẹ̀ ni ìtọ́sọ́nà wa àtọ̀runwá sí òtítọ́. Nípa rẹ̀, Jésù Kristi wí pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Nítorí náà, a gbà wá níyànjú nínu Jòhánù Kìíní 4:1 pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gba gbogbo àgbéjáde onímìísí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn àgbéjáde onímìísí wò láti rí i bóyá wọ́n pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, nítorí ọ̀pọ̀ wòlíì èké ti jáde lọ sínú ayé.” Nígbà tí a bá fara balẹ̀ fi wé Bíbélì, ohun tí wọ́n sọ, abà èrò orí wọn, àti ìgbésẹ̀ wọn yóò forí gbárí pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ọlá àṣẹ ní ti ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.
Ó ha lè jẹ́ pé àfọ̀ṣẹ tàbí àṣà ìbẹ́mìílò míràn ni alálàá náà tí ń sọ pé òun ní ìmọ̀ àrà ọ̀tọ̀ ń lò bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún un. “Kí a má ṣe rí nínú yín ẹnì kan tí . . . ń fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí alákìíyèsí ìgbà, tàbì aṣefàyà, tàbí àjẹ́, tàbí atujú, tàbí abá iwin gbìmọ̀, tàbí oṣó, tàbí abókùúlò. Nítorí pé gbogbo àwọn tí ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ìríra ni sí OLÚWA.”—Diutarónómì 18:10-12.
Bí ó bá sọ pé òun ní ọkàn kan tí kì í kú nínú ara òun, ó ń ta ko Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ó sọ kedere pé: “Ọkàn tí ó bá ṣẹ̀, òun óò kú.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:4) Ó ha ń gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ń wá ọmọ ẹ̀yìn fún ara rẹ̀ bí? Mátíù 23:12 kìlọ̀ pé: “Ẹni yòó wù tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò rẹ̀ sílẹ̀.” Ìṣe 20:30 sì kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé: “Láti àárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ọkùnrin yóò ti dìde wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.”
Ó ha ń ṣètìlẹyìn fún ìgbésẹ̀ oníwà ipá bí? Jákọ́bù 3:17, 18 dẹ́bi fún un pé: “Ọgbọ́n tí ó wá láti òkè á kọ́kọ́ mọ́ níwà, lẹ́yìn náà ó lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò, ó múra tán láti ṣègbọràn, ó kún fún àánú àti àwọn èso rere, kì í pa àwọn ààlà ìyàtọ̀ olójúsàájú, kì í ṣe àgàbàgebè. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, èso òdodo ni a ń fún irúgbìn rẹ̀ lábẹ́ àwọn ipò tí ó kún fún àlàáfíà fún àwọn wọnnì tí ń wá àlàáfíà.” Ó ha ń wá ọlá àṣẹ ìṣèlú tàbí ipò nínú ayé bí? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi í bú lọ́nà lílágbára, ní sísọ pé: “Ẹni yòó wù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” Bíbélì tipa báyìí táṣìírí ohun tí ó jẹ́ èké.—Jákọ́bù 4:4.
Bí ẹnì kan bá lálàá nípa ikú mẹ́ḿbà ìdílé kan tàbí ọ̀rẹ́ kan, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ nítorí pé ó ti ń dàníyàn nípa ẹni yìí. Pé ẹni náà ti lè kú ní òru ọjọ́ tí ó lálàá gan-an kò fi gbogbo ara jẹ́ ẹ̀rí pé, àlá náà jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀. Níbi tí a bá ti rí ọ̀kan irú àlá yìí tí ń ṣẹ, níbẹ̀ ni a ti ń rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún rẹ̀ tí kì í ṣẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run fi àwọn àlá ṣí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ alásọtẹ́lẹ̀ payá nígbà àtijọ́ àti láti fúnni ní ìtọ́ni nígbà tí a ń kọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílẹ̀, kò sí ìdí kankan fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí. Ọ̀rọ̀ alákọsílẹ̀ yẹn ní gbogbo ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí aráyé nílò ní àkókò yìí nínú, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sì kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún síwájú sí i ní ọjọ́ ọ̀la. (Tímótì Kejì 3:16, 17) Nítorí náà, a lè ní ìgbọ́kànlé pé àwọn àlá wa kì í ṣe ìfihàn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la, ṣùgbọ́n ó jẹ́ iṣẹ́ tí ó pọn dandan fún ọpọlọ láti jẹ́ kí èrò orí wa máa jí pépé.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí àlá Fáráò ṣe fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ hàn, bẹ́ẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe tan ìmọ́lẹ̀ sórí ọjọ́ ọ̀la wa