ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 10/1 ojú ìwé 3-4
  • A Gbọ́dọ̀ Lálàá

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Gbọ́dọ̀ Lálàá
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lílá Àlá
  • Ṣé Ìsọfúnni Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Àlá Jẹ́?
    Jí!—2001
  • Rírí Oorun Tó Pọ̀ Tó Sùn
    Jí!—2004
  • Àlá Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
    Jí!—2014
  • Àlá Ha Lè Sọ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 10/1 ojú ìwé 3-4

A Gbọ́dọ̀ Lálàá

ÌWỌ ha máa ń lálàá bí? Kò lè mú ìjiyàn wá láti gbà pé o ń ṣe bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí gbogbo wa pátá ti máa ń lálàá nígbà tí a bá sùn, àní bí a bá tilẹ̀ ń sọ pé a kì í ṣe bẹ́ẹ̀. A ti fojú díwọ̀n rẹ̀ pé, ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àlá tí a ń lá ni a kì í rántí. Èwo ni ìwọ rántí? Ní ti gidi, kìkì àwọn tí a ń rántí ni àwọn tí a lá kété kí a tó jí.

Àwọn olùṣèwádìí àlá ti rí i pé, orun jẹ́ ìgbésẹ̀ oníṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé tí ó máa ń wọra jù lọ ní àwọn wákàtí díẹ̀ àkọ́kọ́, tí ó sì máa ń dín kù sí i bí àkókò ti ń lọ. A máa ń lálàá ní pàtàkì láàárín àkókò ti ojú fi ń yí bíríbírí, tí a ń pè ní oorun ojú yíyí bíríbírí. Èyí ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé oorun àìyí bíríbírí ojú. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àyípo oorun àìyí bíríbírí ojú àti ojú yíyí bíríbírí ń wáyé fún nǹkan bí 90 ìṣẹ́jú, àwọn àyípo wọ̀nyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà márùn-ún tàbí mẹ́fà láàárín òru, tí èyí tí ó kẹ́yìn yóò sì ṣẹlẹ̀ kété kí a tó jí.

Ó jẹ́ àṣìṣe láti ronú pé ọpọlọ rẹ kì í ṣiṣẹ́ tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí o bá sùn. A ti rí i pé, ọpọlọ ń ṣiṣẹ́ nínú àlá ju bí ó ṣe ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ìgbà tí ẹnì kan kò bá sùn, àyàfi àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ kan tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ọpọlọ, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àfiyèsí àti agbára ìrántí. Àwọn wọ̀nyí ni ó dà bí ẹni pé wọn ń sinmi nígbà oorun ojú yíyí bíríbírí. Ṣùgbọ́n ní gbogbogbòò, àwọn sẹ́ẹ̀lì inú ọpọlọ máa ń fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí èkíní kejì láìdáwọ́ dúró.

Ọpọlọ wa jẹ́ ohun àgbàyanu dídíjú nínú ara ènìyàn, tí ó ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ohun ẹ̀dá ìpilẹ̀ tí ń gbé ìsọfúnni tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún sí igba tàbí ọ̀ọ́dúnrún jáde ní ìṣẹ́jú àáyá kan. Iye ẹ̀dá ìpilẹ̀ tí ń bẹ nínú ọpọlọ ẹ̀dá ènìyàn kan ṣoṣo ju iye ènìyàn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé lọ. Àwọn olùṣèwádìí kan fojú díwọ̀n pé, ó ní ẹ̀dá ìpilẹ̀ tí ó tó 20 bílíọ̀nù sí ohun tí ó lé ní 50 bílíọ̀nù. Ìdíjú rẹ̀ jẹ́rìí sí ohun tí akọ̀wé Bíbélì nì, Dáfídì, sọ nípa ara ẹ̀dá ènìyàn pé: “Èmi óò yín ọ; nítorí tẹ̀rùtẹ̀rù àti tìyanutìyanu ni a dá mi: ìyanu ni iṣẹ́ rẹ.”—Orin Dáfídì 139:14.

Lílá Àlá

Ní àwọn wákàtí tí a kò sùn, òye ìmọ̀lára wa márààrún ń fi ìsọfúnni àti àwòrán ránṣẹ́ sí ọpọlọ wa láìdáwọ́ dúró, ṣùgbọ́n nígbà tí a bá sùn ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Ọpọlọ ń rí àwòrán láti inú ara rẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́ òye ìmọ̀lára wa márààrún. Nítorí náà, ohun tí a ń rí nínú àlá àti ìgbésẹ̀ tí a ń gbé nínú wọn, nígbà míràn wulẹ̀ dà bí ìràn-ǹ-rán. Èyí ń mú kí ó jọ pé a lè ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ títẹ òfin àdánidá lójú, irú bí fífò bíi Peter Pan tàbí ṣíṣubú láti orí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àpáta láìfarapa. Àkókò lè yí padà, kí a rí ìgbà àtijọ́ bí ìgbà ìsinsìnyí. Tàbí bí a bá ń gbìyànjú láti sá lọ, ó lè dà bíi pé a kò lè ṣàkóso ìrìn wà—ẹsẹ̀ wa kò fẹ́ ṣe bí a ṣe fẹ́. Àwọn èrò lílágbára àti ìrírí tí a lè ní ní àwọn wákàtí tí a kò sùn, ní ti gidi, lè nípa lórí àlá wa. Kò rọrùn fùn ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti nírìírí àwọn ìwà burúkú tí ń kó jìnnìjìnnì báni, nígbà ogun, láti gbàgbé wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kan kò lè gbàgbé ìmọ̀lára bí ọ̀daràn kan ṣe kọlù wọ́n. Irú àwọn ìrírí tí ń dà wá láàmú bẹ́ẹ̀ nígbà tí a kò sùn lè jẹ yọ nínú àlá wa, kí ó sì fa àlá burúkú. Àwọn nǹkan tí ń sábà ṣẹlẹ̀ sí wa tí ọkàn wa sì máa ń ronú lé lórí nígbà tí a bá fẹ́ sùn lè ṣẹ́ yọ nínú àlá wa.

Nígbà mìíràn, bí a bá ń gbìyànjú láti yanjú ìṣòro kan, ojútùú rẹ̀ máa ń wá nígbà tí a bá sùn. Èyí lè fi hàn pé kì í ṣe gbogbo oorun ní ó wé mọ́ àlá. Apá kan nínú rẹ̀ jẹ́ ríronú.

Ìwé kan nípa àlá àti ọpọlọ wa sọ pé: “Iṣẹ́ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ tí ọpọlọ ń ṣe nígbà tí a bá sùn kì í ṣe lílá àlá bí kò ṣe ríronú. Ríronú nígbà oorun kò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìtànjẹ ọpọlọ, kì í sì í ṣe ohun àjèjì. Ó jẹ́ ohun tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ti gidi sẹ́yìn tàbí tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́la, lọ́pọ̀ ìgbà kì í sì í runi sókè, kì í ṣe ohun tí a lè finú mòye, ó sì sábà ń jẹ́ àròtúnrò.”

Àwọn kan rò pé ohun tí wọ́n rí nínú àlá wọn ní ìhìn iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún wọn. Kí wọn baà lè mọ ìtumọ̀ awọn àlá wọn, wọ́n máa ń tọ́jú ìwé kékeré kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn wọn, kí wọn baà lè kọ àlá náà sínú rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá jí. Nípa ìwúlò àwọn ìwé tí ń gbìyànjú láti fún àwọn àmì àlá nítumọ̀, ìwé náà, The Dream Game, láti ọwọ́ Ann Faraday, sọ pé: “Ìwé àlá tí o ń wo inú rẹ̀ fún ìtumọ̀ ohun tí ó rí nínú àlá àti àmì àlá kò wúlò, ì báà jẹ́ ti àbáláyé tàbí èyí tí a gbé ka àbá èrò orí ìfìṣemọ̀rònú ti òde òní.”

Níwọ̀n bí ó ti dà bíi pé inú ọpọlọ ni àlá ti pilẹ̀, kò bọ́gbọ́n mu láti ronú pé wọ́n ní ìhìn iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún wa. Ó yẹ kí a kà wọ́n sí iṣẹ́ tí ọpọlọ máa ń ṣe, tí ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìlera tí ó jí pépé.

Ṣùgbọ́n àwọn tí ń sọ pé àwọn lálàá pé mọ̀lẹ́bí kan tàbí ọ̀rẹ́ kan kú, tí wọ́n sì gbọ́ lọ́jọ́ kejì pé onítọ̀hún ti kú ńkọ́? Ìyẹn kò ha fi hàn pé àlà lè sọ nípa ọjọ́ ọ̀la bí? Nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e, a óò gbé ohun tí ó wà lẹ́yìn àwọn àlá alásọtẹ́lẹ̀ yẹ̀ wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́