Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
A Ń Bá A Nìṣó Láti Wàásù Òtítọ́ Bíbélì ní Ireland
NÍ ÀWỌN ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè dídùn-ún wò náà, Ireland, ti di ohun àpéwò nítorí rúkèrúdò tí ó gadabú. Lọ́wọ́ kan náà, àwọn ará Ireland ti dáhùn padà lọ́nà rere sí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí ń fúnni nírètí, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú tọ̀ wọ́n wá. Àwọn ìrírí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí láti Ireland, jẹ́rìí sí èyí.
■ Ní Dublin, ọ̀kan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọmọdébìnrin rẹ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ẹnu ọ̀nà sí ẹnu ọ̀nà. Wọ́n pàdé obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Cathy, ẹni tí àwọn ọmọ rẹ̀ púpọ̀ mú kí ọwọ́ rẹ̀ dí gidigidi. Ẹlẹ́rìí náà béèrè bí ọmọbìnrin òun, tí ń kọ́ bí a ṣe ń wàásù, bá lè ṣàjọpín ìhìn iṣẹ́ ṣókí pẹ̀lú rẹ̀. Cathy gbà bẹ́ẹ̀, ọmọdébìnrin náà sì gbé ọ̀rọ̀ tí ó ṣe kedere, tí ó sì mọ́yán lórí kalẹ̀. Òótọ́ inú àti ọ̀wọ̀ tí ọmọ kékeré náà ní wú Cathy lórí, ó sì tẹ́wọ́ gba ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì tí a fi lọ̀ ọ́.
Lẹ́yìn náà, Cathy ronú lórí ìmúrasílẹ̀ rere àti ìwà ọmọlúwàbí tí àlejò rẹ̀ kékeré náà ní. Ó wí pé: “Orí mi wú pé ọmọbìnrin kékeré kan lè ṣàjọpín irú ìhìn iṣẹ́ fífani mọ́ra bẹ́ẹ̀ láìpe àfiyèsí sí ara rẹ̀. Mo pinnu pé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún ṣèbẹ̀wò, n óò fetí sílẹ̀ sí wọn.”
Kò pẹ́ púpọ̀, Cathy ṣí lọ sí ìlú kékeré kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn Ireland, nítòsí ààlà ìjọba ìbílẹ̀ Cork àti Kerry. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn rẹ̀, ó sì pè wọ́n wọlé. Ó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé nínú Bíbélì, ó sì ń wá sí àwọn ìpàdé ìjọ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ nísinsìnyí. Cathy dúpẹ́ púpọ̀ fún ojúlówó ìfẹ́ ọkàn tí ọmọdébìnrin náà ní láti ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú rẹ̀.
■ Ní agbègbè Tullamore, àwọn Ẹlẹ́rìí jíròrò Bíbélì pẹ̀lú obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jean, fún ohun tí ó ju ọdún méje lọ. Nígbà míràn yóò fi ọkàn ìfẹ́ hàn, yóò sì tẹ́wọ́ gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n nígbà míràn ọkàn ìfẹ́ rẹ̀ yóò dín kù. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frances àti olùbákẹ́gbẹ́ rẹ̀ kàn sí Jean, wọ́n bá a ní ipò tí kò fara rọ rárá. Ẹlẹ́rìí náà ròyìn pé: “Ohun yòó wù kí a sọ, inú ṣáà ń bí i ni. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó ní kí a kóra wa jáde, ó sì pa ìlẹ̀kùn rẹ̀ dé gbàgà.”
Frances ṣe kàyéfì bí ìbẹ̀wò míràn kò bá ní mú irú ìhùwàsí kan náà lọ́wọ́. Frances ronú pé: ‘Bóyá kò tilẹ̀ yẹ kí a máa kàn sí i mọ́ níwọ̀n bí kò ti ní ọkàn ìfẹ́ gidi nínú ìhìn iṣẹ́ náà mọ́.’ Ṣùgbọ́n, ó jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Thomas, ọkọ̀ rẹ̀ sí ní ẹ̀mí nǹkan yóò dára. Ìgbà tí wọ́n tún padà lọ sí agbègbè náà, wọ́n tún kàn sí Jean. Ara rẹ̀ yá mọ́ wọn, ó sì tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀dá ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Àwọn ìbẹ̀wò mìíràn tí wọ́n ṣe tún gbádùn mọ́ni, Thomas àti Frances sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé déédéé.
Kí ni ó fa ìyípadà náà? Jean ṣàlàyé pé, nígbà tí òun hùwà àìlọ́wọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí, ṣe ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, àti pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ dé láti ilé ìwòsàn ni. Nítorí fífún ọmọ jòjòló náà lọ́mú àti fífi oúnjẹ nu àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà díẹ̀, oorun wákàtí kan àti ààbọ̀ ni òun ń sùn lóru. Jean sọ pé: “Ń kò nífẹ̀ẹ́ sí sísọ̀rọ̀ nípa ìsìn nígbà yẹn rárá.”
Láàárín oṣù méjì, Jean ti ń wá sí gbogbo ìpàdé ìjọ, àti láàárín oṣù mẹ́rin, ó ti ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Oṣù mẹ́wàá lẹ́yìn ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣe ìrìbọmi. Wàyí o, ìrírí ti Jean alára ń ràn án lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó wí pé: “Bí mo bá bá ẹnì kan tí ń hùwà àìlẹ́kọ̀ọ́ pàdé, mo máa ń gbìyànjú láti gba tirẹ̀ rò. Mo máa ń fi í sọ́kàn. Bóyá ipò nǹkan lè yí padà nígbà tí n óò bá fi padà wá; ìmọ̀lára rẹ̀ ti lè yí padà, kí ó sì túbọ̀ tẹ́tí sílẹ̀.”