Ìgbàṣọmọ—Èé Ṣe, Báwo Sì Ni?
ÈÉ ṢE tí iye àwọn ọmọ tí wọ́n ń gbà ṣọmọ ní Britain fi lọ sílẹ̀ gẹ̀rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ní 20 ọdún tí ó kọjá? Ìdí méjì ni àwọn ènìyàn sọ pé ó fà á—wíwà tí ìṣẹ́yún tí ó bófin mu wà fàlàlà àti títẹ́wọ́ gbà tí àwọn ènìyàn ń tẹ́wọ́ gba kí ìyá kan máa dá ọmọ rẹ̀ tọ́jú láìsí ọkọ. Nísinsìnyí, àwọn ènìyàn ń wo ìdílé olóbìí kan gẹ́gẹ́ bí ìpèníjà kan tí ènìyàn lè kojú pẹ̀lú àṣeyọrí nínú àwùjọ òde òní.
Bí ó ti wù kí ó rí, ní kìkì nǹkan bí 100 ọdún sẹ́yìn, nǹkan yàtọ̀. Nígbà tí ọmọkùnrin ọ̀gá Polly, ìyá Edgar Wallace, ọmọ Gẹ̀ẹ́sì tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé nípa ìtàn ìwà ọ̀daràn, fún un lóyún, ó lọ, ó sì bí ọmọ rẹ̀ ní bòńkẹ́lẹ́. Ọmọ ọjọ́ mẹ́sàn-án ni Edgar nígbà tí agbẹ̀bí ṣètò pé kí ìyàwó George Freeman, aláàárù kan ní ọjà Billingsgate tí wọ́n ti ń ta ẹja ní London, máa tọ́jú rẹ̀. Àwọn ìdílé Freeman ti ní ọmọ mẹ́wàá fúnra wọn tẹ́lẹ̀, Edgar sì dàgbà di ẹni tí wọ́n wá mọ̀ sí Dick Freeman. Polly ń san owó déédéé láti ṣètìlẹ́yìn fún títọ́jú ọmọ rẹ̀, baba ọmọ náà kò sì mọ̀ pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀ pé òún ní ọmọ kan.
Lónìí, nígbà tí wọn kò bá fẹ́ àwọn ọmọ kan, àwọn aláṣẹ ìjọba lọ́pọ̀ ìgbà máa ń tẹ́wọ́ gba bùkátà wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ni wọ́n máa ń gbé lọ sí ilé ìtọ́jú nítorí pé wọ́n nílò ààbò kí wọ́n má baà ṣe wọ́n ní ìṣekúṣe tàbí nítorí pé wọ́n ní àléébù ti ara tàbí tí wọ́n ya dìndìnrìn. Àwọn tí ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ogun sọ di ọmọ òrukàn àti àwọn ọmọ tí a bí nítorí ìfipábánilòpọ̀ ló sábà máa ń mú kí iye àwọn ọmọ tí ń ké fún ìfẹ́ni àti ààbò òbí—lọ́rọ̀ kan ṣáá, ìgbàṣọmọ, pọ̀ sí i.
Láti Gba Ọmọ Sọmọ Tàbí Láti Má Ṣe Gbà Á?
Gbígba ọmọ ṣọmọ kì í ṣe ohun tí ó rọrùn rárá, kì í sì í ṣe ohun tí ó lọ́gbọ́n nínú láti ṣe ìpinnu oníwàǹwára nígbà tí o bá ń ronú nípa rẹ̀. Bí ọmọ rẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ kú, yóò jẹ́ ohun tí ó dára jù láti dúró títí fi di ìgbà tí ọkàn rẹ yóò fúyẹ́ tàbí tí ìbànújẹ́ náà yóò tán lọ́kàn rẹ kí o tó ṣe ìpinnu pátápátá nípa gbígba ọmọ ṣọmọ. Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn tọkọtaya tí wọ́n sọ fún pé wọn kò lè rọ́mọ bí.
Olúkúlùkù ọmọ ló ní ànímọ́ àjogúnbá tirẹ̀. Ẹnu máa ń ya àwọn òbí lọ́pọ̀ ìgbà nípa ìfẹ́ ọkàn lílágbára tí àwọn ọmọ tiwọn fúnra wọn ní, àmọ́ ó ṣòro láti mọ ohun tí ọpọlọ àti ìmí ẹ̀dùn ọmọ kan yóò dà ní ọjọ́ iwájú bí ènìyàn kò bá mọ ohun tí àwọn òbí rẹ̀ jẹ́.
Ìwọ́ ha jẹ́ ẹni tí ó fi ìníyelórí tí ó pọ̀ sórí àṣeyọrí ní ti ẹ̀kọ́ ìwé bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni yóò ṣe rí lára rẹ bí ọmọ ọlọ́mọ kan tí o gbà ṣọmọ bá já ọ kulẹ̀? Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ kan tí ó ya dìndìnrìn tàbí tí ó lábùkù ara yóò jẹ́ ìpèníjà kan tí o lè bá gbé bí?
Àwọn òṣìṣẹ́ tí ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹ̀ka ìgbàṣọmọ tàbí àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re ìjọba yóò bèèrè irú àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́wọ́ rẹ kí o tó tọrùn bọ̀ ọ́. Ohun tí ó jẹ àwọn lógún jù lọ ni ààbò àti ayọ̀ ọmọ náà.
Bí O Bá Pinnu Ìgbàṣọmọ . . .
Gbogbo orílẹ̀-èdè ló ní àwọn òfin àti ìlànà ìgbàṣọmọ tirẹ̀ tí ó yẹ kí ènìyàn fara balẹ̀ yẹ̀ wò. Ní Britain, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ẹgbẹ́ ìgbàṣọmọ ló wà, wọ́n sì sábà máa ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọba ilẹ̀ wọn. Gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ló ní àwọn òfin tiwọn.
Ohun tí ó tilẹ̀ gbajúmọ̀ jù lọ ní Britain ni àwọn àríyá ìgbàṣọmọ, níbi tí àwọn òbí lọ́la bíi mélòó kan ti lè dara pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ tí wọ́n wà nílẹ̀ fún ìgbàṣọmọ, láìsí ìmí ẹ̀dùn ọkàn tí ó sábà máa ń wà bí ó bá jẹ́ pé ọmọ kan sí òbí kan ni. Àyíká títuni lára náà ń mú kí ó rọrùn fún àwọn òbí lọ́la náà láti sọ pé àwọn kò gba ọmọ kan ṣọmọ, tí kò sì ní fi bẹ́ẹ̀ mú kí ọmọ náà ní ẹ̀mí ìjákulẹ̀, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé kò sí ọmọ kankan tí a tì sáàárín.
Ọjọ́ orí tí a fi lélẹ̀ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gba ọmọ ṣọmọ tún wà, bóyá nǹkan bí ọdún 35 tàbí 40 ọdún ní ọjọ́ orí—ṣùgbọ́n èyí sábà máa ń wà fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gba àwọn ọmọ ọwọ́ ṣọmọ, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan tí ó bá jẹ́ àwọn ọmọ tí ó ti dàgbà ni. Àwọn ẹgbẹ́ ìgbàṣọmọ sọ pé ọjọ́ orí tí a fi lélẹ̀ máa ń gba iye ọdún tí ó ṣeé ṣe kí àwọn òbí lọ́la náà lò láyé rò. Bí ó ti wù kí ó rí, wọ́n mọ̀ pé ìrírí ṣíṣeyebíye máa ń bá ọjọ́ orí rìn.
Ní àwọn ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, kìkì àwọn tọkọtaya tí wọ́n ti ṣègbeyàwó nìkan ni ènìyàn lè bá ṣètò ìgbàṣọmọ. Lónìí, ó ṣeé ṣe fún àwọn tí wọn kò tí ì ṣe ìgbéyàwó láti gba àwọn ọmọ kan ṣọmọ. Bákan náà, kò pọn dandan kí a sọ pé a kò ní fún àwọn òbí lọ́la ní ọmọ kìkì nítorí pé wọn kò níṣẹ́ lọ́wọ́ àti nítorí pé wọ́n lábùkù ara. Kókó tí ó wà níbẹ̀ ni pé, Kí ni ohun tí ìṣètò náà lè ṣe fún ọmọ náà?
Àní nígbà tí wọ́n bá ti parí ètò ìgbàṣọmọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pàápàá, wọ́n ṣì lè máa ṣọ́ àwọn òbí náà déédéé láti lè rí i dájú pé nǹkan ń lọ geerege.
Ṣé Ọmọ Ẹ̀yà Míràn Dára?
Ní 30 ọdún sẹ́yìn, ó ṣòro láti gbé àwọn ọmọ aláwọ̀ dúdú kalẹ̀ fún àwọn ìdílé aláwọ̀ dúdú láti gbà ṣọmọ ní ilẹ̀ Britain, nítorí ìdí èyí, ọ̀pọ̀ ni àwọn òbí aláwọ̀ funfun gbà ṣọmọ. Láti ọdún 1989, ó ti di àṣà tí ilẹ̀ Britain tẹ́wọ́ gbà láti máa jẹ́ kí àwọn òbí tí wọ́n gba ọmọ ṣọmọ́ jẹ́ ẹ̀yà ìran kan náà pẹ̀lú rẹ̀. Wọ́n ronú pé lọ́nà yìí, ẹ̀yà àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ọmọ náà yóò lè tètè mọ́ ọn lára. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí ti ṣamọ̀nà sí àwọn ipò onítakora kan.
Láìpẹ́ yìí, ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times sọ pé, àwọn òbí aláwọ̀ funfun kan ni a ti “ṣe àtúnpín wọn sí ẹ̀yà ‘adúláwọ̀’” láti baà lè jẹ́ kí wọ́n gba ọmọ aláwọ̀ dúdú ṣọmọ. Kì í ṣe ohun tí ó ṣàjèjì fún àwọn òbí aláwọ̀ funfun láti máa wo ọmọ aláwọ̀ dúdú, èyí tí ó túmọ̀ sí pé wọ́n kàn gbà á wò fún ìgbà díẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá fún wọn ní ẹ̀tọ́ àtigba ọmọ náà ṣọmọ pátápátá, ó máa ń yọrí sí ìbàjẹ́ ọkàn fún ọmọ náà àti àwọn òbí.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tọkọtaya ará Scotland kan tí wọ́n ti gba àwọn ọmọ India méjì kan wò fún ọdún mẹ́fà, dojú kọ ìṣòro kan tí ó sábà máa ń bá gbígba ọmọ tí kì í ṣe ẹ̀yà ìran ẹni ṣọmọ rìn. Ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé, ilé ẹjọ́ náà gbà pé kí àwọn òbí náà gbà wọ́n ṣọmọ tí ó bá ti jẹ́ pé wọn yóò “lo gbogbo ìsapá wọn láti rí i dájú pé àwọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọ náà mọ̀ nípa irú [ẹ̀yà] tí wọ́n jẹ́, tí wọn yóò sì tọ́ wọn dàgbà pẹ̀lú òye ẹ̀yà tí wọ́n ti sẹ̀ àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn.” Nínú ọ̀ràn yìí, àwọn òbí agbàṣọmọ náà ti ń ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ náà ní èdè Punjabi, wọ́n sì máa ń múra fún wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú aṣọ ìbílẹ̀ wọn.
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni yóò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àkíyèsí tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re ilẹ̀ Britain kan sọ, nígbà tí ó sọ pé, ó yẹ kí wọ́n gba àwọn ènìyàn láyè láti máa gba àwọn ọmọ tí kì í ṣe ẹ̀yà ṣọmọ ní fàlàlà. Ó sọ pé: “À ń gbé nínú àwùjọ ènìyàn tí ó jẹ́ ọlọ́pọ̀ ẹ̀yà, ìgbọmọtọ́ àti ìgbàṣọmọ sì gbọdọ̀ fi èyíinì hàn.”
Ṣe Ọmọ Tí Ó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè Dára?
Látàrí ohun tí ìwé agbéròyìnjáde The Independent sọ, gbígba àwọn ọmọ tí ó wá láti orílẹ̀-èdè òkèèrè ṣọmọ ti di ‘òwò tí ń búrẹ́kẹ́.’ Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn fi hàn pé díẹ̀ lára àwọn ìdúnàádúrà yìí kò bófin mu, Ìlà Oòrùn Europe ní ń kó ọmọ lọ sí Britain jù lọ.
Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ti ṣá díẹ̀ lára àwọn ọmọ tí wọ́n bí láti inú ìfipábánilòpọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà ìwólulẹ̀ Yugoslavia tẹ́lẹ̀ tì. Àwọn ènìyàn sọ pé, wọn ì bá ti ṣẹ́ oyún àwọn mìíràn bí kì í bá ṣe pé “afọmọṣọfà” kan dá sí i, tí ó sì ṣèlérí pé òun yóò ṣètò ìgbàṣọmọ bí ìyá náà bá bí ọmọ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé ń dàníyàn nípa àwọn owó tí wọ́n ń san kí ètò ìgbàṣọmọ baà lè ṣeé ṣe.
Ohun tí ó tilẹ̀ tún wá fa ìdàníyàn jù lọ ni ẹ̀sùn ṣíṣe màdàrú ìwé ẹ̀rí, nígbà tí obìnrin bá bímọ, tí àwọn ènìyàn fi ń kan àwọn dókítà. Ìwé agbéròyìnjáde The European ròyìn ẹ̀sùn tí àwọn abiyamọ kan fi sùn ní Ukraine pé wọ́n sọ fún àwọn pé òkú ni àwọ́n bí ọmọ àwọn. Wọ́n tún sọ pé wọ́n ta àwọn ọmọ yìí lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ni. Wọ́n lè sọ fún àwọn abiyamọ mìíràn pé àwọn ọmọ wọn ya dìndìnrìn. Nígbà tí wọ́n bá pin wọ́n lẹ́mìí báyìí, wọ́n tètè máa ń sún àwọn abiyamọ tí ọkàn wọn ti pòkúdu náà láti fọwọ́ síwèé pé kí ẹlòmíràn gba ọmọ àwọn ṣọmọ. Síbẹ̀, ọmọ mìíràn kò ní dé ilé àwọn ọmọ òrukàn tí wọ́n fi wọ́n ṣọwọ́ sí, àmọ́ wọ́n lè ti kó wọn lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè.
Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ń fi ìbínú hàn. Wọ́n ń sọ pé ó yẹ kí àwọn ènìyàn apá Ìwọ̀ Oòrùn ayé ṣe púpọ̀ sí i láti ran àwọn ìdílé tí ó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ́wọ́ láti bojú tó àwọn ọmọ wọn ní àyíká ilẹ̀ wọn, dípò tí wọn yóò fi máa kó wọn lọ sí ilẹ̀ òkèèrè fún ìgbàṣọmọ.
Ìwọ̀ Oòrùn ayé tún gbọ́dọ̀ lóye àṣà ìdílé amẹ́bímúbàátan tí ó ti wà fún ọjọ́ pípẹ́, tí ó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn ènìyàn náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyà kì í jẹ ọmọ kan tí ó bá ń gbé láàárín àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ ẹ̀yà rẹ̀, àní tí àwọn òbí rẹ̀ bá tilẹ̀ ti kú. Yàtọ̀ sí ti àwọn mẹ́ḿbà ìdílé rẹ̀ gangan, irú bí àwọn òbí àgbà, àwọn mẹ́ḿbà ìdílé tí ó jìnnà mìíràn bí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò òbí tí ó jẹ́ obìnrin, àti àwọn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò òbí tí ó jẹ́ ọkùnrin yóò ka ọmọ náà sí tiwọn, wọ́n sì lè ṣi ará ìta kan tí ó bá sọ̀rọ̀ nípa ìgbàṣọmọ lóye, kí wọ́n sì wò ó gẹ́gẹ́ bí ayọjúràn tí a kò tẹ́wọ́ gbà.a
Láti lè ṣètò fún ìgbàṣọmọ kò rọrùn, nígbà tí ènìyàn bá sì tilẹ̀ ti parí ètò rẹ̀ pàápàá, ó nílò iṣẹ́ takuntakun láti lè mú kí ó kẹ́sẹjárí. Gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i, ayọ̀ tí ó pọ̀ tún wà pẹ̀lú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé kínníkínní nípa àṣa fífún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé mìíràn ní àwọn ọmọ, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1988, ojú ìwé 28 sí 30, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọmọ Mi Yóò Ha Wá Mi Kàn Bí?
ÀWỌN òbí mi kọ ara wọn sílẹ̀ nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún 11. Mò ń wá ẹni tí yóò fi ìfẹ́ hàn sí mi ní ojú méjèèjì. Nígbà tí mo wà ní kọ́lẹ́ẹ̀jì, mo kó wọnú ipò ìbátan eléré ìfẹ́ kan; ọ̀nà kan ṣoṣo tí mo fi lè gbà rí ìfẹ́ni nìyẹn. Sí ìyàlẹ́nu mi, nígbà tí ó yá, mo rí i pé mo ti lóyún. Ọ̀rọ̀ ìtìjú pátá gbáà ni. Èmi àti akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi jẹ́ aláìnírìírí pátá gbáà. N kò tí ì lo òògùn, ọtí líle, tàbí tábà rí, ṣùgbọ́n oògùn líle LSD ti ba ti ọ̀rẹ́kùnrin mi jẹ́.
Àwọn ènìyàn gbà mí nímọ̀ràn pé kí n ṣẹ́yún náà, àmọ́ bàbá mi sọ pé kí n má ṣe bẹ́ẹ̀. N kò fẹ́ lóyún, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì fẹ́ gba ẹ̀mí bákan náà. Nígbà tí mo bí ọmọ mi ní ọdún 1978, mo pinnu láti má ṣe fi orúkọ bàbá rẹ̀ sórí ìwé ìbí rẹ̀ láti má baà jẹ́ kí bàbá rẹ̀ wá ọmọ mi rí. Ní ti gidi, mo gbà láti jẹ́ kí ẹlòmíràn gba ọmọ náà ṣọmọ láti ìgbà tí mo ti bí i; nítorí náà, lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n ti gbé e kúrò lọ́dọ̀ mi, tí wọ́n sì gbè e lọ sí ilé ìtọ́jú onígbà díẹ̀ kan. N kò tilẹ̀ rí i. Àmọ́ nígbà tí ó yá, mo yí ọkàn mi padà. Mo gbé ọmọ mi kúrò ní ilé ìtọ́jú onígbà díẹ̀, mo sì gbìyànjú taratara láti tọ́ ọ dàgbà fúnra mi. Ṣùgbọ́n n kò lè ṣe é, ìdààmú ọkàn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa mí.
Nǹkan bí ọmọ oṣù mẹ́fà ni ọmọ mi jẹ́ nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí ìwé ètò ìgbàṣọmọ náà, tí ó sì di pé kí n gbé e sílẹ̀. Mó rántí pé ń ṣe ló dà bí ẹni pé ẹnì kan ṣẹ̀ṣẹ̀ gún mi lọ́bẹ. Mo ti kú sára. Kìkì ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtọ́jú àwọn amọṣẹ́dunjú ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn ni mo tó lè máa gbé ìbáṣepọ̀ tí ó nítumọ̀ ró. N kò lè banú jẹ́—ọmọ mi kò kú. Ṣùgbọ́n bákan náà ni n kò lè ronú nípa rẹ̀—n kò gba ara mi láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó burú jáì.
Ohun tí ó máa ń dùn mí jù ni ní ìgbà tí àwọn ènìyàn bá ń sọ pé: “Bí o bá gbé ọmọ rẹ sílẹ̀ kí ẹlòmíràn gbà á ṣọmọ, o kò nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ ni.” Àmọ́ ìyẹn kì í ṣe òtítọ́ nínú ọ̀ràn tèmi! Nítorí pé mo nífẹ̀ẹ́ ọmọ mi ni mo ṣe gbé e sílẹ̀! Títí tí ó fi di ìṣẹ́jú tí ó kẹ́yìn ni mò ń bi ara mi pé: ‘Kí ló tún kù tí n óò ṣe báyìí o? Kí ni mo lè ṣe?’ Kò sí síṣe, kò sí àìṣe. Ohun tí mo mọ̀ ni pé agbára mi kò ká a, àti pé ìyà yóò jẹ ọmọ mi bí mo bá gbìyànjú láti máa dá tọ́jú rẹ̀.
Ní England, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́ gba àwọn ìdílé olóbìí kan nísinsìnyí—àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bí ọmọ mi. Ó dà bí ẹni pé kí n ti lè bojú tó ọmọ mi dáradára. Mo lérò pé ìmọ̀ràn tí mo rí gbà lẹ́nu àìpẹ́ yìí ì bá ti ṣèrànlọ́wọ́, àmọ́ ẹ̀pa kò bóró mọ́ nísinsìnyí. Ǹjẹ́ ọmọ mi ṣì wà láàyè? Irú ọmọ wo ló yà? Tí àwọn ọmọ tí ènìyàn gbà ṣọmọ bá ti pé ọdún 18, lábẹ́ òfin, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti wá àwọn òbí wọn kàn. Mo máa ń ṣe kàyéfì bóyá ọmọ mi yóò wá mi kàn.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Kò Bu Wá Lọ́wọ́
PẸ̀LÚ àwọn ọmọkùnrin ọ̀dọ́langba méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ wa, a jẹ́ ìdílé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan tí ó ní ìtẹ́lọ́rùn, tí ó sì wà ní ìṣọ̀kan. Èrò níní ọmọbìnrin—tí ó jẹ́ ẹ̀yà míràn—kò tilẹ̀ tí ì wá sí wa lọ́kàn rí. Àfi ìgbà tí Cathy wọnú ìgbésí ayé wa. Wọ́n bí Cathy ní London, England. Wọ́n sì tọ́ ọ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Roman Kátólíìkì, ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ní ọmọdé, ó máa ń bá ìyá rẹ̀ lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 10, wọ́n mú un lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan le fún un ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lọ́hùn-ún, ó ṣì ń tiraka láti máa dá lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, níbẹ ni a sì ti pàdé rẹ̀. Cathy jẹ́ ọmọbìnrin kan tí ó máa ń ronú jinlẹ̀. Nígbà tí èmi àti ìyàwó mi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ilé ìtọ́jú àwọn ọmọdé, a ṣàkíyèsí pé àwọn àwòrán ẹranko àti àwòrán ìran àrọ́ko ni ó lẹ̀ mọ́ ògiri tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀, kò ṣe bíi ti àwọn ọmọbìnrin yòókù tí wọ́n fi àwòrán àwọn olórin aláriwo tí ó gbayì kọ́ sára ògiri.
Nígbà kan lẹ́yìn ìyẹn, ó di pé kí Cathy fara hàn níwájú ìgbìmọ̀ ayẹniwò kan, tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bí yóò bá fẹ́ láti fi ilé ìtọ́jú náà sílẹ̀, kí ó sì máa gbé pẹ̀lú ìdílé kan dípò rẹ̀. Ó dáhùn pé: “Àyàfi tí ó bá jẹ́ ìdílé àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa!” Nígbà tí Cathy sọ fún wa nípa èyí àti ohun tí ó sọ, ó mú kí a máa ronú nípa nǹkan kan. A ní yàrá kan tí ó ṣófo. A ha lè gbé bùkátà irú èyí bí? A sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, a sì gbàdúrà nípa rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ni a wá mọ̀ pé ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe é yìí—bíbèèrè èrò ọmọ kan lọ́wọ́ rẹ̀—jẹ́ ọ̀nà ìgbàdánǹkanwò tuntun tí ẹ̀ka afẹ́nifẹ́re náà ṣe, ìdánǹkanwò tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀.
Ẹ̀ka afẹ́nifẹ́re náà wádìí wa wò fínnífínní lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá àti dókítà wa, wọ́n sì gba orúkọ àwọn ènìyàn tí àwọn lè bèèrè ọ̀rọ̀ nípa wa lọ́wọ́ wọn. Kò pẹ́ tí gbogbo rẹ̀ fi lójú. Wọ́n sọ fún wa pé a lè máa mú Cathy lọ fún àkókò dán-an-wò ráńpẹ́, àti pé a lè dá a padà bí a kò bá fẹ́ràn rẹ̀! Èyí kó ìpayà bá wa, a sì fi ìdánilójú sọ pé a kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Ọmọ ọdún 13 ni Cathy nígbà tí wọ́n fọwọ́ sí i pé kí a mú un sọ́dọ̀ láti gbà á ṣọmọ.
Ìdè ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ tí ó wà láàárín gbogbo wa ń lágbára sí i. Cathy ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà (oníwàásù alákòókò kíkún) ní ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ń sọ èdè Faransé ní àríwá London. Ní ọdún tí ó fi ilé sílẹ̀ láti lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ó kọ ìwé tí ń wọni lọ́kàn kan sí wa pé: “Àwọn ènìyàn máa ń sọ pé ‘a kì í yan ìdílé tí ènìyàn yóò bọ́ sí.’ Bí ó ti wù kí ó rí, n óò fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yin tọkàntọkàn fún yíyàn mí.”
A dúpẹ́ pé Cathy wá sínú ìdílé wa! Sísọ ọ́ di apá kan ìdílé wa ti bù kún ìgbésí ayé wa. Kò bu wa lọ́wọ́!—A kọ ọ́ ránṣẹ́.
[Àwòrán]
Cathy àti àwọn òbí tí ó gbà á ṣọmọ àti àwọn arákùnrin rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ọ̀pọ̀ ọmọ ló ń sunkún ìfẹ́ni àti ààbò òbí