Ìgbàṣọmọ—Ó Ha Tọ́ Sí Ọ Bí?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN
ÒṢÌṢẸ́ afẹ́nifẹ́re ará Britain kan sọ pé: “Ìgbàṣọmọ jẹ́ ètò kan tí à ń ṣe fún ire àwọn ọmọ, kì í ṣe ètò tí à ń ṣe láti wá ọmọ fún àwọn tọkọtaya tí kò rọ́mọ bí.” Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀tọ́ wo ni ọmọ kan sábà máa ń ní nínú gbígbà tí a gbà á ṣọmọ?
Ìwọ́ ha ń ronú nípa gbígba ọmọ kan ṣọmọ bí? Nígbà náà, kì í ṣe kìkì ìpinnu tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn nìkan ni o dojú kọ, àmọ́ èyí tí kò tún ṣeé yí padà. Báwo ni ara ọmọ náà yóò ti mọlé tó nínú ìdílé rẹ?
Bí ìwọ́ bá jẹ́ ọmọ kan tí a gbà ṣọmọ, o ha mọ àwọn tí ó jẹ́ òbí tí ó bí ọ gangan bí? Bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, báwo ni o ṣe rò pé yóò rí lára rẹ bí o bá mọ̀ wọ́n?
Ìwọ́ ha jẹ́ ìyá kan tí ń ronú bóyá kí o gbé ọmọ rẹ sílẹ̀ fún àwọn tí yóò gbà á ṣọmọ bí? Ìgbàṣọmọ ha ni kìkì ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà, ó ha sì dára fún ire ọmọ rẹ bí?
Ní ọdún 1995, ó lé ní 50,000 ọmọ tí wọ́n gbà ṣọmọ ní United States, nǹkan bí 8,000 lára wọn ló sì jẹ́ àwọn tí a bí ní ilẹ̀ òkèèrè. Àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i ló ń gba àwọn ọmọ tí a bí ní orílẹ̀-èdè òkèèrè ṣọmọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Time ti sọ, ní ọdún 25 tí ó kọjá, àwọn ìdílé tí ó wà ní United States ti gba àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ òkèèrè tí iye wọ́n lé ní 140,000 ṣọmọ. Iye tí ó ṣeé fi wéra pẹ̀lú ti ilẹ̀ Europe ni 32,000 ní Sweden, 18,000 ní Holland, 15,000 ní Germany, àti 11,000 ní Denmark.
Ọ̀ràn yìí ha kàn ọ́ lọ́nàkọnà bí? Kíkọrùn bọ ọ̀ràn ìgbàṣọmọ túmọ̀ sí pé, ìgbésí ayé rẹ—kì í ṣe ìgbésí ayé ọmọ náà nìkan—kò tún ní rí bí ó ti rí tẹ́lẹ̀ mọ́. Àwọn òbí tí wọ́n gbọmọ ṣọmọ́ ní ìdí pàtàkì láti máa fojú sọ́nà fún ọ̀pọ̀ ìgbádùn, àmọ́ wọ́n tún gbọ́dọ̀ máa múra sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ìṣòro àti ìjákulẹ̀. Bákan náà, ẹ̀dùn ọkàn tí ìyá kan máa ń ní nígbà tí ó bá gbé ọmọ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìgbàṣọmọ lè má lọ tán láéláé.
Ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan gbé ìpèníjà dìde ní ti gbígbé ìgbésí ayé ọmọdé kan ró tàbí ṣíṣàtúnkọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò fi díẹ̀ lára àwọn ayọ̀—àti ìpèníjà—tí ń wá láti inú ìgbàṣọmọ hàn.