ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/8 ojú ìwé 9-10
  • Ìgbàṣọmọ—Ojú Wo Ni Ó Yẹ Kí N Fi Wò Ó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbàṣọmọ—Ojú Wo Ni Ó Yẹ Kí N Fi Wò Ó?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Ó Ṣe Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀ Tó?
  • Ìdí Tí A Fi Ní Láti Ṣọ́ra
  • Dídojú Kọ Òtítọ́
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ìṣòro Jíjẹ́ Ọmọ Àgbàtọ́?
    Jí!—2003
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Ìgbàṣọmọ—Èé Ṣe, Báwo Sì Ni?
    Jí!—1996
  • Ìgbàṣọmọ—Ó Ha Tọ́ Sí Ọ Bí?
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/8 ojú ìwé 9-10

Ìgbàṣọmọ—Ojú Wo Ni Ó Yẹ Kí N Fi Wò Ó?

Ó ṢE kedere pé ìṣòro lè dìde bí àwọn òbí agbaniṣọmọ bá kọra sílẹ̀ tàbí bí ọ̀kan nínú wọ́n bá kú. Àmọ́ ọmọ tí wọ́n gbà ṣọmọ náà, ni ẹ̀dùn ọkàn náà yóò bá jù lọ. Èé ṣe?

Ọ̀pọ̀ nínú wa mọ àwọn òbí tí ó bí wa lọ́mọ. Tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kú nígbà tí a wà ní ọmọdé, à ń rántí wọn, tàbí kí a ní àwọn fọ́tò wọn lọ́wọ́, láti lè jẹ́ kí a máa rántí wọn dáradára sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ọmọ tí a gbé kalẹ̀ fún ìgbàṣọmọ gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí a bí i tán ńkọ́? Ẹgbẹ́ agbàṣọmọ máa ń tọ́jú àwọn àkọsílẹ̀ kíkún nípa ìyá náà, àmọ́ wọn kì í jẹ́ kí ìsọfúnni náà wà lárọ̀ọ́wọ́tó títí tí ọmọ náà yóò fi tójú bọ́. Nínú àwọn ọ̀ràn míràn, ìyá náà máa ń kọ orúkọ tirẹ̀ nìkan sílẹ̀ sínú ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí ọmọ náà tí kò sì ní kọ orúkọ ti baba. Àwọn ọmọ kan jẹ́ àwọn ọmọ tí a gbé sọnù—tí wọ́n sì rí wọn lẹ́yìn tí àwọn òbí tí a kò mọ̀ ti gbé wọn sọnù. Gbogbo àwọn ọmọ tí wọ́n wà nínú ipò yìí kò ní orírun kankan—wọ́n lè nímọ̀lára bí ẹni pé a ti fà wọ́n tu kúrò lára orísun tàbí ìpìlẹ̀ wọn.

Báwo Ni Ó Ṣe Lẹ́sẹ̀ Nílẹ̀ Tó?

Àwọn igí nílò gbòǹgbò tí ó dára kí wọ́n baà lè fẹsẹ̀ múlẹ̀. Èhù tuntun kan tí a lọ́ sára igi tí ó ti gbó kan lè gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, àmọ́ ó tún lè rọ, kí ó má sì mú èso jáde pẹ̀lú. Lọ́nà kan náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí agbaniṣọmọ lè fún un ní gbogbo ìkẹ́ àti ìgẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tí ó ṣeé ṣe, àwọn ọmọ kan kì í bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀dùn ọkàn pé a ti fà wọ́n tu kúrò lára orírun ìpìlẹ̀ wọn.

Gbé ọ̀ràn tí Kate yẹ̀ wò.a Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ará Ìwọ̀ Oòrùn Indies ló bí i, nígbà tí Kate sì wà ní ọmọ ọwọ́, àwọn tọkọtaya aláwọ̀ funfun kan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń ṣìkẹ́ ẹni, gbà á ṣọmọ, àmọ́ kò ṣeé ṣe fún un láti gba kámú pẹ̀lú àyíká tuntun tí ó wà yìí. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún 16, ó fi ilé sílẹ̀, kò sì padà wá mọ́. Ìkorò ọkàn ti di ìkórìíra aláìnírònú nígbà yẹn. Ó máa ń bèèrè pé: “Èé ṣe tí ìyá mi fi gbé mi fún yín?” Ó bani nínú jẹ́ pé ìdílé yìí kò rọ́wọ́ fi jẹ́ iṣu ọ̀ràn náà.

Wọ́n gbé Mervyn sílẹ̀ fún àbójútó ní ẹ̀ka ìjọba kan tí ó wà ní àdúgbò nígbà tí wọ́n bí i, nígbà tí ó sì yá, wọ́n gbé e fún àwọn òbí alágbàtọ́. Nígbà tí ó pé ọmọ oṣù mẹ́sàn-án, wọ́n gbà á ṣọmọ. Ìpìlẹ̀ tí kò ṣe gúnmọ́ tí ó ti ní tẹ́lẹ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú ìkùnsínú gbígbóná janjan tí ó ní nítorí pé ó jẹ́ ẹ̀yà tí ó yàtọ̀, di ìwà tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun tí ń mú ìṣòro púpọ̀ wá fún un, tí ó sì ń mú ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀ wá fún àwọn òbí tí ó gbà á ṣọmọ, àwọn tí wọ́n ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan dáradára fún un. Ìyá rẹ̀ sọ pé: “Bí ẹnì kan bá béèrè ìmọ̀ràn nípa ìgbàṣọmọ lọ́wọ́ mi, ohun tí n óò sọ ni pé, ‘Rò ó re o.’”

Ní òdì kejì, gbé ọ̀ràn ti Robert àti Sylvia yẹ̀ wò. Wọ́n bí ọmọkùnrin kan, wọn kò sì rí ọmọ bí mọ́. Àwọn ènìyàn bèèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti ronú nípa gbígba ọmọ orílẹ̀-èdè míràn ṣọmọ bí?” Kò pẹ́ tí wọ́n fi gba Mak-Chai, ọmọbìnrin olóṣù mẹ́sàn-án kan láti Hong Kong, ṣọmọ. Mak-Chai máa ń sọ pé: “Mo máa ń ṣe kàyéfì ìdí tí wọ́n fi gbé mi sílẹ̀, àbí bóyá mo tilẹ̀ ní ọmọ ìyá lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin. Àmọ́, ó dà bí ẹni pé mo sún mọ́ ìyá àti bàbá tí ó gbà mi ṣọmọ ju bí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ti sún mọ́ àwọn òbí tí ó bí wọn lọ́mọ lọ. Bí mo bá mọ àwọn òbí tí ó bí mi lọ́mọ, ìyẹn kò ní sọ pé kí nǹkan ṣẹ́ pẹ́rẹ́ sí i, yàtọ̀ sí pé bóyá yóò mú kí n túbọ̀ lóye díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ mi sí i.” Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n gbà á ṣọmọ ha lè dámọ̀ràn ìgbàṣọmọ bí? Wọ́n sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé fún àwa, ìrírí àgbàyanu ló jẹ́!”

Ìdí Tí A Fi Ní Láti Ṣọ́ra

Graham àti Ruth gba àwọn ọmọ méjì kan ṣọmọ láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ọmọ ọwọ́, ọkùnrin kan àti obìnrin kan, láti lè jẹ́ kí wọ́n ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ọmọkùnrin kan àti ọmọbìnrin kan tí àwọn fúnra wọ́n bí. Wọ́n tọ́ àwọn ọmọ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin dàgbà gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan tí ó wà pa pọ̀ ní àyíká aláyọ̀. Ruth sọ pé: “Gbogbo àwọn ọmọ wá fi ilé sílẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, wọ́n sì bá tiwọn lọ. À ń kàn sí wọn déédéé, a sì nífẹ̀ẹ́ gbogbo wọn.” Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé àwọn ọmọ méjèèjì tí wọ́n gbà ṣọmọ ló ní ìṣòro lílé kenkà. Èé ṣe?

Graham, tí ó wá rò nísinsìnyí pé àwọn ànímọ́ tí ẹnì kan jogún tún jẹ́ kókó pàtàkì kan, sọ pé: “Dókítà wa sọ fún wa pé àyíká jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì gidigidi fún ọmọdé kan.” Ó fi kún un pé: “Bákan náà, ìlera ìyá náà nígbà tí ó wà nínú oyún ń kọ́? Àwọn òògùn líle, ọtí líle, àti tábà, ni a mọ̀ nísinsìnyí pé ó lè nípa lórí ọmọ tí a kò tí ì bí. Èmi yóò gba àwọn ènìyàn nímọ̀ràn pé kí wọ́n ṣe àyẹ̀wò fínnífínní nípa àwọn òbí méjèèjì, àti nípa àwọn òbí àgbà bí ó bá ṣeé ṣe pàápàá, kí wọ́n tó kọrùn bọ ìgbàṣọmọ.”

Ìyá Peter tún ọkọ fẹ́, ọkọ ìyá Peter sì fìyà jẹ ẹ́ ní ti ara àti ní ti ọpọlọ. Nígbà tí ó pé ọmọ ọdún mẹ́ta, wọ́n gbé e sílẹ̀ fún ètò ìgbàṣọmọ. Peter sọ pé: “Mo kọ àwọn òbí tí ó gbà mi ṣọmọ sílẹ̀ gbàrà tí mo jáde ní ilé ẹjọ́ náà.” Ó fi kún un pé: “Mo ń ba gbogbo ohun tí ọwọ́ mí bá tẹ̀ jẹ́. Nígbà tí mo bá ń sùn lọ́wọ́, mo máa ń lá àwọn àlá bíbani lẹ́rù. Tí mo bá rántí rẹ̀ nísinsìnyí, mo máa ń rí i bí ọkàn mi ti dààmú tó. Lẹ́yìn tí àwọn òbí tí ó gbà mí ṣọmọ tún kọra wọn sílẹ̀, nǹkan burú sí i fún mi—òògùn líle, olè jíjà, ìbaǹkanjẹ́, àìlèkóra-ẹni-níjàánu nínú ohun púpọ̀.

“Nígbà tí mo di ọmọ ọdún 27, mo rí i pe kò sí ìdí tí ó fi yẹ kí n máa gbé ayé lọ, mo sì ń ronú láti ṣe ikú pa ara mi. Àmọ́ ní ọjọ́ kan, àjèjì kan fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan tí a gbé karí Bibeli, tí ó sọ pé láìpẹ́ ayé yìí yóò di Paradise, lé mi lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ náà fà mí lọ́kàn mọ́ra. Ó dún bí ẹni pé òtítọ́ ni. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bibeli, mò ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé àti ìhùwà mi, ṣùgbọ́n léraléra ni mo ń padà sínú àwọn ìwà mi àtijọ́. Lẹ́yìn ìṣírí púpọ̀ àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristian tí ń ranni lọ́wọ́, mo láyọ̀ sí i nísinsìnyí, mo sì láàbò sí i nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọrun ju bí mo ti lérò lọ ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn. Ó tún ti ṣeé ṣe fún mi láti mú àjọṣepọ̀ onífẹ̀ẹ́ dàgbà pẹ̀lú ìyá mi, èyí sì ń mú ìdùnnú wá.”

Dídojú Kọ Òtítọ́

Nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn ìgbàṣọmọ, ìmọ̀lára máa ń gbóná janjan. A máa ń rí ìfẹ́ àti ìmọrírì gígọntiọ pa pọ̀ pẹ̀lú ìkorò ọkàn àti àìnímọrírì. Fún àpẹẹrẹ, Edgar Wallace kò dárí ji ìyá rẹ̀ fún jíjá tí ó já a jù sílẹ̀, ohun tí ó ka ìwà ìyá rẹ̀ sí nìyẹn. Ìyá náà lọ wò ó nígbà tí ó kù gẹ̀rẹ̀ kí ìyá náà kú, ó fi ìtìjú wá ìrànwọ́ owó lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, àmọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Edgar lówó rẹpẹtẹ nígbà yẹn, ó fi pẹ̀lú ìgbékútà kọ̀ jálẹ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, nígbà tí ó gbọ́ pé wọn ì bá ti sin ìyá òun sí sàárè àwọn àrè, bí kì í bá ṣe ti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ṣàánú láti san owó fún ìsìnkú rẹ̀, ó kábàámọ̀ gidigidi nípa ìwà ọ̀dájú tí ó hù.

Àwọn ènìyàn tí ń ronú ìgbàṣọmọ gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ láti dojú kọ àwọn ìṣòro àti ìpèníjà tí ó lè dìde ní ti tòótọ́. Àwọn ọmọ kì í fi ìgbà gbogbo fi ìmọrírì hàn fún ohun tí àwọn òbí wọn—ì báà jẹ́ èyí tí ó gbà wọ́n ṣọmọ tàbí èyí tí ó bí wọn lọ́mọ—bá ṣe fún wọn, bí ó ti wù kí ó dára tó. Bibeli gan-an tilẹ̀ sọ pé àwọn ènìyàn ìgbà tiwa yóò jẹ́ “aláìní ìfẹ́ni àdánidá” àti pé wọn yóò jẹ́ “aláìlọ́pẹ́” àti “aláìdúróṣinṣin.”—2 Timoteu 3:1-5.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ṣíṣí ilé rẹ—àti ọkàn rẹ—sílẹ̀ fún ọmọ kan tí ó nílò òbí lè jẹ́ ìrírí tí ó dára, tí ó sì ń mú èrè wá. Fún àpẹẹrẹ, Cathy ṣọpẹ́ fún àwọn òbí tí ó gbà á ṣọmọ lọ́pọ̀lọpọ̀ fún pípèsè ilé Kristian fún un àti fún bíbójú tó àwọn àìní rẹ̀ nípa ti ara àti ti ẹ̀mí.—Wo àpótí “Kò Bu Wá Lọ́wọ́,” ní ojú ewé 8.

Nígbà tí àwọn òbí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ bá ń ṣàpèjúwe ìmọ̀lára wọn nípa àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n gbà ṣọmọ, wọ́n lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ olórin náà pé: “Àwọn ọmọ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Oluwa; ìbùkún gidi ni wọ́n jẹ́.”—Orin Dafidi 127:3, Today’s English Version.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà kí a lè fi bò wọ́n láṣìírí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́