ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 1/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbàṣọmọ—Ó Ha Tọ́ Sí Ọ Bí?
    Jí!—1996
  • Ìgbàṣọmọ—Ojú Wo Ni Ó Yẹ Kí N Fi Wò Ó?
    Jí!—1996
  • Ìgbàṣọmọ—Èé Ṣe, Báwo Sì Ni?
    Jí!—1996
  • Kí Ni Dídi Àtúnbí Máa Jẹ́ Kó Ṣeé Ṣe?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 1/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ìgbàṣọmọ Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ìgbàṣọmọ—Ayọ̀ àti Ìpèníjà Rẹ̀.” (May 8, 1996) Ńṣe ni wọ́n gbà mí ṣọmọ, n kò sì mọ̀ tẹ́lẹ̀ bí mo ṣe lè jíròrò ọ̀rọ̀ yí pẹ̀lú àwọn òbí tí wọ́n gbà mí ṣọmọ. Nítorí náà, ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti rí ìtẹ̀jáde Jí! yìí gbà. Kò sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tí ì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an tó bí ìwọ̀nyí ti ṣe rí.

F. R. M., Brazil

Ńṣe ni wọ́n gbà mí ṣọmọ, mo sì pinnu lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa ohun tí mo lè ṣe nípa àwọn òbí tí wọ́n bí mi lọ́mọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo rí àwọn ìsọfúnni tí ó gbéṣẹ́ nípa àwọn òbí mi gbà, mo tún mọ̀ pé ìyá mi tọ́jú mi fún oṣù mẹ́ta kí ó tóó gbé mi lọ fún ìgbàṣọmọ. Ìyẹn dùn mí gan-an! Mo bi ara mi léèrè pé, ‘Báwo ló ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?’ Ní gidi, àpótí náà, “Ọmọ Mi Yóò Ha Wá Mi Kàn Bí?” jẹ́ kí n ní ojú ìwòye tí ìyá kan ní. Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kékeré yẹn ṣe ṣàǹfààní fún mi láti kojú ipò náà tó!

C. S., United States

Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà korò bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì gbádùn mọ́ mi. Mo gbé ọmọkùnrin mi lọ fún ìgbàṣọmọ ní ọdún 23 sẹ́yìn. Ohun tó jẹ́ kí n ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé mo mọ̀ pé n kò lè tọ́jú rẹ̀. Mo máa ń ṣe kàyéfì lójoojúmọ́ pé, ‘Báwo ló ṣe wà? Kí ló ti ń ṣẹlẹ̀ sí ìgbésí ayé rẹ̀? N óò ha rí i mọ́ láé bí?’ Ìmọ̀lára ẹ̀bi náà máa ń pò mí rúurùu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà fún ìfẹ́ àti àánú rẹ̀.

S. F., United States

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa fúnra wa bí ọmọkùnrin kan, èmi àti ọkọ mi ti ń ronú nípa gbígba ọmọdébìnrin kékeré kan ṣọmọ. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí ire àti ibi tí ó wà níbẹ̀, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu wa.

J. G., United States

Èrò tí ó wá sí mi lọ́kàn ni pé ẹ ń kìlọ̀ nípa gbígba àwọn oníyọnu ọmọ ṣọmọ. Àmọ́ kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ bí a bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀? Lónìí, a ní àwọn ìṣòro kan pẹ̀lú ọmọkùnrin wa tí a gbà ṣọmọ. Àmọ́ irú àwọn ìṣòro wo ni irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ yóò mú bá àwùjọ bí wọn kò bá rí ìfẹ́ àti ààbò lọ́dọ̀ ìdílé kan?

D. M., Germany

Àánú àwọn ọmọ tí a ti fi àbójútó àwọn òbí onífẹ̀ẹ́ dù ṣe wá. A kò kọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà láti máà fún gbígba àwọn “oníyọnu” ọmọ ṣọmọ níṣìírí, ṣùgbọ́n láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tọkọtaya láti “ṣírò iye tí yóò ná wọn” láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí ó gbàrònú gidi. (Fi wé Lúùkù 14:28.) Ó yẹ kí àwọn òbí tí wọ́n fẹ́ gba ọmọ ọlọ́mọ ṣọmọ ronú bí wọ́n bá ní àwọn ohun pípọndandan tí yóò gbà ní ti èrò ìmọ̀lára, nípa tẹ̀mí, tàbí ti ìnáwó láti kájú àwọn àìní irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ ní gidi. Ó tún yẹ kí wọ́n gbé àwọn ipa tí ìgbàṣọmọ náà lè ní lórí àwọn ọmọ tí wọ́n ti ní nílé tẹ́lẹ̀ yẹ̀ wò.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.

A ní àwọn ọmọ márùn-ún tí a gbà ṣọmọ, ní àfikún sí àwọn ọmọ mẹ́ta tí a bí fúnra wa. A ti nírìírí ìdùnnú lílégbákan tí ẹ kọ nípa rẹ̀ àti àròdùn ọkàn. Gbogbo àwọn ọmọ wa ni wọ́n jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà yàtọ̀ sí ọmọkùnrin wa nìkan. Lẹ́yìn tí a gbà á ṣọmọ nígbà tí ó wà ní ọmọ ọdún 16, ó fìbálòpọ̀ fìtínà mẹ́ta lára àwọn ọmọbìnrin wa. Ẹ̀ka ìgbàṣọmọ kò sọ fún wa nípa ìgbésí ayé àtilẹ̀wá rẹ̀. Nítorí náà, ó yẹ kí ènìyàn gba ìsọfúnni bí ó bá ṣe lè pọ̀ tó nípa ìgbésí ayé àtilẹ̀wá nígbà tí ó bá ń ronú nípa ìgbàṣọmọ—pàápàá jù lọ bí ènìyàn bá ń ronú nípa gbígba ọmọ tí ó ti dàgbà díẹ̀. Ẹ máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín dáradára, ẹ sì máa ń gbé ìhà méjèèjì tí ọ̀ràn ní kalẹ̀ ní kedere.

P. B., United States

Ó bà mí nínú jẹ́ gan-an láti mọ̀ pé àwọn òbí kan tí wọ́n gbọmọ ṣọmọ ti ní irú àwọn ìrírí búburú bẹ́ẹ̀. Èmi àti ọkọ mi gba àwọn arẹwà ọmọ méjì ṣọmọ, wọ́n sì ti mú ìdùnnú wá sínú ìgbésí ayé wa. A kì í fi ohunkóhun pamọ́ fún wọn nípa ìgbàṣọmọ wọn. A ran ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìyá tó bí wọn lọ́mọ kò ‘tà wọ́n’ àmọ́ wọ́n ṣètò fún àbójútó wọn nítorí pé wọn kò lè bójú tó ọmọ lákòókò yẹn nínú ìgbésí ayé wọn. Àwọn ènìyàn sábà máa ń wí fún wa nípa bí àwọn ọmọ wa ṣe rìnnà kore tó pé a gbà wọ́n ṣọmọ. Síbẹ̀síbẹ̀, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé àwa la rìnnà kore.

B. M., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́