ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 11/1 ojú ìwé 3-6
  • Ìtùnú Fún Àwọn Tí A Ń ni Lára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtùnú Fún Àwọn Tí A Ń ni Lára
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Olùkíyèsí Ìnilára Ní Ìgbà Àtijọ́
  • Ìnilára Yóò Dópin Láìpẹ́
  • Ẹnì Kan Wà Tó Bìkítà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Tu Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ibo La Ti Lè Rí Ojúlówó Ìtùnú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ta Ló Lè Dá Àwọn Tó Ń kígbe Fún Ìrànlọ́wọ́ Nídè?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 11/1 ojú ìwé 3-6

Ìtùnú Fún Àwọn Tí A Ń ni Lára

OHA ti kíyè sí i pé jálẹ̀ àkókò ìwàláàyè rẹ, àwọn ọ̀rọ̀ kan wà tí a ti tẹ̀ jáde léraléra nínú àwọn àkọlé ìròyìn? Ó ha ti sú ọ láti máa ka àwọn ọ̀rọ̀ bí ogun, ìwà ọ̀daràn, jàm̀bá, ebi, àti ìjìyà? Àmọ̀ ṣáá o, ọ̀rọ̀ kán ti sọnù nínú ìròyìn lọ́nà tí ó fara hàn gbangba. Síbẹ̀, ó jẹ́ ọ̀rọ̀ kan tí ó dúró fún ohun kan tí aráyé nílò gidigidi. Ọ̀rọ̀ náà ni “ìtùnú.”

“Láti tù nínú” túmọ̀ sí “láti fi okun àti ìrètí fúnni” àti “láti pẹ̀tù sí ẹ̀dùn ọkàn tàbí ìṣòro tí” ẹnì kán ní. Pẹ̀lú gbogbo rúkèrúdò tí ayé ti là kọjá ní ọ̀rúndún ogún, a nílò ìrètí àti pípẹ̀tù sí ẹ̀dùn ọkàn gidigidi. Lóòótọ́, díẹ̀ nínú wa lónìí ń gbádùn àwọn ohun amáyédẹrùn ju bí àwọn babańlá wa ìgbàanì ti lè ronú wòye pé yóò ṣeé ṣe tó. Ọpẹ́lọpẹ́ ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni ó mú kí èyí ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kò tí ì tù wá nínú ní èrò ìtumọ̀ mímú gbogbo okùnfà ìjìyà kúrò fún aráyé. Kí ni àwọn okùnfà wọ̀nyí?

Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà, Sólómọ́nì, sọ̀rọ̀ nípa okùnfà kan pàtàkì tí ń fa ìjìyà nígbà tí ó sọ pé: “Ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kò tí ì lè yí ìtẹ̀sí tí ènìyàn ní láti fẹ́ ṣe olórí ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ padà. Ní ọ̀rúndún ogún, èyí ti yọrí sí ìṣàkóso bóo fẹ́ bóo kọ̀ tí ń nini lára láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ó sì ti yọrí sí ogun tí ń bani lẹ́rù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.

Láti 1914 wá, a ti pa èyí tí ó ju ọgọ́rùn-ún mílíọ̀nù ènìyàn lọ nítorí ogun. Ronú nípa làásìgbò tí iye yìí ti mú bá ẹ̀dá ènìyàn—ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ìdílé tí ń ṣọ̀fọ̀, tí wọ́n nílò ìtùnú. Ogun sì tún ń yọrí sí irú àwọn ìjìyà míràn yàtọ̀ sí ikú oró. Ní òpin Ogun Àgbáyé Kejì, ó ju mílíọ̀nù 12 olùwá-ibi-ìsádi tí ó wà ní Europe. Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí gan-an, èyí tí ó ju mílíọ̀nù kan ààbọ̀ sá kúrò ní agbègbè tí ogun tí ń jà ní Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà. Ogun jíjà ní àwọn orílẹ̀-èdè Balkan tí fipá mú kí èyí tí ó ju mílíọ̀nù méjì lọ sá fi ilé wọn sílẹ̀—ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, láti sálà kúrò lọ́wọ́ “pípa ẹ̀yà lápatán.”

Dájúdájú, àwọn olùwá-ibi-ìsádi nílò ìtùnú, ní pàtàkì, àwọn tí wọ́n lọ kúrò ní ilé wọn láìmú ohunkóhun lọ́wọ́ ju ohun ìní tí wọ́n lè gbé dání, láìmọ ibi tí wọn yóò forí lé tàbí ohun tí ọjọ́ ọ̀la ní fún àwọn àti ìdílé wọn. Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ wà lára àwọn tí a ń ni lára lọ́nà tí ó ṣeni láàánú jù lọ; wọ́n nílò ìtùnú.

Ní àwọn ibi tí ó túbọ̀ ní àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ń sìnrú fún ètò ìgbékalẹ̀ ọrọ̀ ajé àgbáyé. Lóòótọ́, àwọn kan ní àwọn ohun ti ara lọ́pọ̀ yanturu. Ṣùgbọ́n, àwọn tí ó pọ̀ jù lọ ń dojú kọ ìjàkadì ojoojúmọ́ láti gbọ́ bùkátà. Ọ̀pọ̀ ń wá ibùgbé tí ó bójú mu kiri. Iye tí ó ń pọ̀ sí i kò rí iṣẹ́ ṣe. Ìwé agbéròyìnjáde kan ti Áfíríkà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ayé ń forí lé yánpọnyánrin tí a kò tí ì rí irú rẹ̀ rí ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, àfikún bílíọ̀nù 1.3 sí i ni yóò máa wá iṣẹ́ kiri nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2020.” Dájúdájú, àwọn tí a ń ni lára ní ti ọrọ̀ ajé nílò “okun àti ìrètí”—ìtùnú.

Ní ìhùwàpadà sí àwọn àyíká ipò àìnírètí, àwọn kan ti di ọ̀daràn. Àmọ̀ ṣáá o, èyí wulẹ̀ ń fìyà jẹ àwọn tí wọ́n bá kọlù ni, iye ìwà ọ̀daràn tí ó sì ń ga sókè ń fi kún ìnilára tí a ń nírìírí rẹ̀. Àkọlé ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, The Star, ti Johannesburg, Gúúsù Áfíríkà, kà pé: “Ọjọ́ kan nínú ìgbòkègbodò ‘orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ apànìyàn jù lọ lágbàáyé.’” Àpilẹ̀kọ náà ṣàpèjúwe ọjọ́ alápẹẹrẹ kan nínú àti yíká Johannesburg. Ní ọjọ́ kan ṣoṣo yẹn, àwọn ènìyàn mẹ́rin ni a pa, a sì fipá gba ọkọ̀ àwọn mẹ́jọ. A ròyìn ọ̀ràn ilé fífọ́ 17 ní àdúgbò kan tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀. Ní àfikún sí i, iye àwọn ìdigunjalè mélòó kan ṣẹlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ṣe sọ, àwọn ọlọ́pàá ṣàpèjúwe èyí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ kan “tí ó pa rọ́rọ́ ní ìfiwéra.” Ó lè yéni pé, àwọn ìbátan àwọn tí a pa àti àwọn tí a fọ́ ilé wọn, àti àwọn tí a gba ọkọ̀ wọn nímọ̀lára ìnilára gidigidi. Wọ́n nílò ìfọkànbalẹ̀ àti ìrètí—ìtùnú.

Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn òbí kan wà tí wọ́n ń fi àwọn ọmọ wọn ṣòwò iṣẹ́ aṣẹ́wó. Ìròyìn fi tó wa létí pé, orílẹ̀-èdè Éṣíà kan tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ máa ń wọ́ lọ fún “ìrìn àjò nítorí ìbálòpọ̀” ní mílíọ̀nù méjì aṣẹ́wó, tí púpọ̀ nínú wọn jẹ́ àwọn ọmọdé tí a rà tàbí tí a jí gbé. Àwọn kan ha ń bẹ tí a ni lára ju àwọn òjìyà tí àánú wọn ń ṣeni wọ̀nyí bí? Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí òwò tí ó burú bàlùmọ̀ yìí, ìwé ìròyìn Time, ròyìn nípa ìpàdé àpérò kan, ti ọdún 1991, tí àwọn àjọ àwọn obìnrin Gúúsù Ìlà Oòrùn Éṣíà ṣe. Níbẹ̀, a fojú díwọ̀n rẹ̀ pé “30 mílíọ̀nù obìnrin ni a ti tà jákèjádò ayé láti àárín àwọn ọdún 1970 wá.”

Àmọ́ ṣáá o, kò dìgbà tí a bá fi àwọn ọmọdé ṣòwò iṣẹ́ aṣẹ́wó, kí ó tó di pé a fìtínà wọn. Iye tí ń pọ̀ sí i ni àwọn òbí àti àwọn ìbátan ń fìyà jẹ tàbí tí wọ́n ń fipá bá lò pọ̀ pàápàá, nínú ilé wọn. Irú àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀ lè ní ọgbẹ́ ní ti èrò ìmọ̀lára fún àkókò gígùn kan. Dájúdájú, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a ń ni lára lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́, wọ́n nílò ìtùnú.

Olùkíyèsí Ìnilára Ní Ìgbà Àtijọ́

Ẹnu ya Ọba Sólómọ́nì láti rí bí ìnilára ẹ̀dá ènìyàn ti tó. Ó kọ̀wé pé: “Bẹ́ẹ̀ ni mo padà, mo sì ro ìnilára gbogbo tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn; mo sì wo omijé àwọn tí a ń ni lára, wọn kò sì ní olùtùnú; àti lọ́wọ́ aninilára wọn ni ipá wà; ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú.”—Oníwàásù 4:1.

Bí ọlọ́gbọ́n ọba náà bá mọ̀ ní 3,000 ọdún sẹ́yìn pé àwọn tí a ni lára nílò olùtùnú gidigidi, kí ni òun yóò sọ lónìí? Bí ó ti wù kí ó rí, Sólómọ́nì mọ̀ pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé kankan, títí kan òun alára, tí ó lè pèsè ìtùnú tí aráyé nílò. A nílò ẹnì kan tí ó tóbi ju ẹ̀dá ènìyàn lọ láti fòpin sí agbára àwọn aninilára. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ha wà bí?

Nínú Bíbélì, Orin Dáfídì 72 sọ̀rọ̀ nípa atóbilọ́lá olùtùnú kan fún gbogbo ènìyàn. Ọba Dáfídì, bàbá Sólómọ́nì, ni ó kọ sáàmù náà. Àkọlé rẹ̀ sọ pé: “Nípa Sólómọ́nì.” Ó hàn gbangba pé, Ọba Dáfídì arúgbó ni ó kọ ọ́ nípa Ẹnì kan tí yóò jogún ìtẹ́ rẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú sáàmù náà, Ẹni yìí yóò mú ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìnilára wá, èyí tí yóò wà pẹ́ títí. “Ní ọjọ́ rẹ̀ ni àwọn olódodo yóò gbilẹ̀: àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà níwọ̀n bí òṣùpá yóò ti pẹ́ tó. Òun óò sì jọba láti òkun dé òkun, àti . . . dé òpin ayé.”—Orin Dáfídì 72:7, 8.

Ó ṣeé ṣe pé, nígbà tí Dáfídì fi kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, òun ń ronú nípa ọmọkùnrin rẹ̀ Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n Sólómọ́nì rí i pé ó kọjá agbára òun láti ṣiṣẹ́ sin aráyé lọ́nà tí a ṣàpèjúwe nínú sáàmù náà. Ó lè mú àwọn ọ̀rọ̀ sáàmù náà ṣẹ kìkì lọ́nà kíkéré jọjọ, tí yóò sì jẹ́ fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kì í ṣe fún àǹfààní gbogbo ilẹ̀ ayé. Ní kedere, sáàmù alásọtẹ́lẹ̀ tí a mísí yìí tọ́ka sí ẹnì kan tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀ ju Sólómọ́nì lọ. Ta ni ẹni yẹn? Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ni ó lè jẹ́.

Nígbà tí áńgẹ́lì kan kéde ìbí Jésù, ó sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò . . . fi ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀ fún un.” (Lúùkù 1:32) Ní àfikún sí i, Jésù tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ.” (Lúùkù 11:31) Láti ìgbà tí a ti jí Jésù dìde sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó ti wà ní ọ̀run, ní ibi tí ó ti lè mú àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dáfídì 72 ṣẹ. Síwájú sí i, ó ti gba agbára àti ọlá àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run láti fọ́ àjàgà àwọn ẹ̀dá ènìyàn aninilára . (Orin Dáfídì 2:7-9; Dáníẹ́lì 2:44) Nítorí náà, Jésù ni ẹni náà tí yóò mú àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dáfídì 72 ṣẹ.

Ìnilára Yóò Dópin Láìpẹ́

Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí pé òmìnira kúrò lọ́wọ́ gbogbo onírúurú ìnilára ẹ̀dá ènìyàn yóò ṣeé ṣe láìpẹ́. Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìjìyà àti ìnilára tí kò sí irú rẹ̀ rí, tí a ti fojú rí ní ọ̀rúndún ogún yìí pé yóò jẹ́ apá kan àmì tí yóò sàmì sí “ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.” (Mátíù 24:3) Ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè yóò dìde sí orílẹ̀-èdè àti ìjọba sí ìjọba.” (Mátíù 24:7) Apá àsọtẹ́lẹ̀ yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ rẹ̀ ní àkókò tí Ogun Àgbáyé Kìíní bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún 1914. Jésù fi kún un pé: “Nítorí pípọ̀ sí i ìwà àìlófin ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) Ìwà àìlófin àti àìnífẹ̀ẹ́ ti mú ìran kan tí ó jẹ́ oníwà búburú àti aninilára jáde. Nítorí náà, ó ní láti jẹ́ pé àkókò náà ti sún mọ́ fún Jésù Kristi láti dá sí ọ̀ràn yìí gẹ́gẹ́ bí Ọba tuntun fún ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:32-34) Kí ni ìyẹn yóò túmọ̀ sí fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí a ń ni lára, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, tí wọ́n sì ń wò ó gẹ́gẹ́ bí Olùtùnú aráyé tí a yàn látọ̀runwá?

Láti dáhùn ìbéèrè yẹn, jẹ́ kí a ka àfikún àwọn ọ̀rọ̀ Orin Dáfídì 72 díẹ̀ sí i, tí ó ní ìmúṣẹ nínú Kristi Jésù pé: “Yóò gba aláìní nígbà tí ó bá ń ké: tálákà pẹ̀lú, àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun óò dá tálákà àti aláìní sí, yóò sì gba ọkàn àwọn aláìní là. Òun óò ra ọkàn wọn padà lọ́wọ́ ẹ̀tàn àti ìwà agbára: iyebíye sì ni ẹ̀jẹ̀ wọn ní ojú rẹ̀.” (Orin Dáfídì 72:12-14) Nípa báyìí, Ọba tí Ọlọ́run yàn, Jésù Kristi, yóò rí i dájú pé kì yóò sí ẹni tí yóò jìyà nítorí ìnilára. Ó ní agbára láti fòpin sí gbogbo onírúurú àìṣèdájọ́ òdodo.

Ẹnì kan lè sọ pé, ‘Ìyẹn dún bí ohun ìyanu, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ńkọ́? Ìtùnú wo ni ó wà fún àwọn tí ń jìyà nísinsìnyí?’ Ní tòótọ́, ìtùnú wà fún àwọn tí a ń ni lára. Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjì tí ó tẹ̀ lé e nínú ìwé ìròyìn yìí, yóò fi hàn bí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ṣe ń rí ìtùnú gbà nísinsìnyí nípa mímú ipò ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà pẹ̀lú Ọlọ́run tòótọ́ náà, Jèhófà, àti pẹ̀lú Ọmọkùnrin àyànfẹ́ rẹ̀, Jésù Kristi. Irú ipò ìbátan bẹ́ẹ̀ lè tù wá nínú ní àwọn àkókò tí ń nini lára wọ̀nyí, ó sì lè ṣamọ̀nà ẹnì kan sí ìyè àìnípẹ̀kun, tí ó bọ́ kúrò lọ́wọ́ ìnilára. Jésù sọ nínú àdúrà sí Ọlọ́run pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Kì yóò sí ẹ̀dá ènìyàn kankan tí yóò ni ẹlòmíràn lára nínú ayé tuntun Ọlọ́run

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́