Ẹnì Kan Wà Tó Bìkítà
ẸGBẸẸGBẸ̀RÚN ènìyàn ló ń fi hàn pé àwọn bìkítà. Àwọn wọ̀nyí kì í ṣe ọ̀dájú, wọn ò lẹ́mìí ìmọtara-ẹni-nìkan, wọn ò sì gbà pé ìṣòro àwọn ẹlòmíràn kò kan àwọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe ni wọ́n ń ṣe—nígbà mìíràn pàápàá wọ́n lè fi ẹ̀mí ara wọn wewu—kí wọ́n baà lè gbọn ìyà nù lára èèyàn. Iṣẹ́ bàǹtà-banta lèyí, iṣẹ́ kan tí àwọn agbára tó ju tiwọn lọ kò jẹ́ kó rọrùn.
Ọkùnrin kan tó ń ṣètò ohun táwọn ènìyàn nílò sọ pé, àwọn nǹkan bí ìwọra, ìwà màgòmágó nínú ìṣèlú, àti àjálù lè dènà àṣeyọrí “ìsapá tí a fi làákàyè tó pé jù lọ gbé kalẹ̀, tí a sì pinnu láti ṣe kí ebi lè kásẹ̀ nílẹ̀.” Mímú kí ebi kásẹ̀ nílẹ̀ jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo péré lára àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ àwọn ènìyàn tó bìkítà. Wọ́n tún ń gbógun ti àwọn ìṣòro bí àìsàn, ipò òṣì, àìsí ìdájọ́ òdodo, àti ìyà ńláǹlà tí ogun ń fà. Ṣùgbọ́n, ṣé wọ́n ń borí?
Ọ̀gá àgbà ọ̀kan lára àjọ tó ń pèsè irú ohun bẹ́ẹ̀ táwọn ènìyàn nílò wí pé, àwọn tí ń ṣe irú “ìsapá tí a fi làákàyè tó pé jù lọ gbé kalẹ̀, tí a sì pinnu láti ṣe” láti lè dín ebi àti ìrora kù dà bí aláàánú ará Samáríà tí Jésù Kristi sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkàwé rẹ̀. (Lúùkù 10:29-37) Ṣùgbọ́n, bí wọ́n ti sapá ọ̀hún tó, iye àwọn tí ìyà ń jẹ ń pọ̀ sí i ni. Nítorí náà, ọ̀gá náà béèrè pé: “Kí ni aláàánú ará Samáríà náà ì bá ṣe ká ní bó ṣe ń gba ọ̀nà yẹn lójoojúmọ́, àní fún ọ̀pọ̀ ọdún, ló ń rí àwọn tí jàǹdùkú ti lù lálùbolẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ lẹ́bàá ọ̀nà bó bá ti ń kọjá lọ?”
Iṣẹ́ náà yóò tètè ‘súni pátápátá,’ yóò sì di àpatì. Lọ́nà tó buyì kúnni, iṣẹ́ yìí kì í sú àwọn tó jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n bìkítà. (Gálátíà 6:9, 10) Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó kọ̀wé sí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Jewish Telegraph, gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn tó jẹ́ pé nígbà ìjọba Nazi ní Jámánì, wọ́n “ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù lọ́wọ́ láti bọ́ nínú ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n ní Auschwitz.” Òǹkọ̀wé náà wí pé: “Nígbà tí kò sí oúnjẹ, wọ́n fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa [ìyẹn àwọn Júù] lára búrẹ́dì tiwọn!” Àwọn Ẹlẹ́rìí ń bá a lọ láti ṣe ìwọ̀n tí wọ́n lè ṣe pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun tí wọ́n ní.
Síbẹ̀, òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò sí iye búrẹ́dì tí èèyàn lè jọ máa pín jẹ tó lè fòpin sí ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn. Kì í ṣe pé a ń sọ èyí láti bẹnu àtẹ́ lu ohun táwọn aláàánú èèyàn ti ṣe o. Ìgbésẹ̀ èyíkéyìí tó bá dín ìyà kú dáa gan-an ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn dín ìyà àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹlẹgbẹ́ wọn kù lọ́nà kan, ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ìjọba Nazi kógbá sílé. Àmọ́, ètò ayé yìí tó ń fa irú ìninilára bẹ́ẹ̀, ṣì wà, àwọn ènìyàn tí kò bìkítà sì ń pọ̀ sí i. Ní tòótọ́, “ìran kan wà tí eyín rẹ̀ jẹ́ idà, tí egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ sì jẹ́ ọ̀bẹ ìpẹran, láti jẹ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tán kúrò lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn òtòṣì kúrò láàárín aráyé.” (Owe 30:14) Bóyá, ìwọ náà ń ṣe kàyéfì nípa ìdí tí ọ̀ràn fi rí báyìí.
Kí Ló Fa Ipò Òṣì àti Ìninilára?
Jésù Kristi sọ nígbà kan pé: “Ẹ ní àwọn òtòṣì pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, nígbàkigbà tí ẹ bá sì fẹ́, ẹ lè ṣe rere fún wọn nígbà gbogbo.” (Máàkù 14:7) Ṣé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé òṣì àti ìninilára kò ní dópin? Gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan, ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé irú ìyà bẹ́ẹ̀ jẹ́ apá kan ìwéwèé Ọlọ́run láti fún àwọn oníyọ̀ọ́nú ní àǹfààní láti fi bí wọ́n ṣe bìkítà tó hàn? Rárá o! Jésù kò gbà bẹ́ẹ̀. Ohun tó wulẹ̀ ń sọ ni pé, níwọ̀n ìgbà tí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí bá ṣì wà, ipò òṣì ò lè tán. Ṣùgbọ́n, Jésù mọ èyí pẹ̀lú pé: Kì í ṣe ète Baba rẹ̀ ọ̀run ní àtètèkọ́ṣe pé kí irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ wà lórí ilẹ̀ ayé.
Nígbà tí Jèhófà Ọlọ́run dá ilẹ̀ ayé, ó fẹ́ kó jẹ́ párádísè ni, kò dá a pé kí ó jẹ́ ilé òṣì, níbi tí kò sí ìdájọ́ òdodo, tí a si ti ń nini lára. Ó fi bó ṣe bìkítà tó nípa ìdílé ènìyàn hàn nípa ṣíṣe àwọn ìpèsè àgbàyanu tí yóò mú kí wọ́n túbọ̀ gbádùn ìgbésí ayé wọn. Họ́wù, gbé orúkọ ọgbà náà gan-an yẹ̀ wò, ọgbà tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, bá ara wọn nínú rẹ̀! A pè é ní Édẹ́nì, tó túmọ̀ sí “Ibi Ìtẹ́lọ́rùn.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9) Ó ré kọjá ti pé Jèhófà pèsè ohun tẹ́nu ń jẹ, tí ó lè gbẹ́mìí èèyàn ró ní àyíká kan tí kò fani mọ́ra, tí ipò nǹkan ti le koko. Nígbà tí Jèhófà parí gbogbo nǹkan tó dá, ó yẹ̀ ẹ́ wò, ó sì kéde pé ó “dára gan-an ni.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.
Bó bá rí bẹ́ẹ̀, èé ṣe tí ipò òṣì, ìninilára, àti àwọn nǹkan mìíràn tí ń fa ìyà fi pọ̀ káàkiri ayé lónìí? Ètò àwọn nǹkan burúkú ti ìsinsìnyí wà nítorí pé àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Èyí ló mú ìbéèrè náà wá pé, ǹjẹ́ ó tọ́ kí Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn ìṣẹ̀dá òun máa ṣègbọràn sí òun? Nítorí náà, Jèhófà ti yọ̀ǹda àkókò pàtó fún àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù láti wà lómìnira. Àmọ́, Ọlọ́run ṣì bìkítà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìdílé ènìyàn. Ó ṣètò láti ṣàtúnṣe gbogbo láburú tí ìṣọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe sí i ti fà. Láìpẹ́ sígbà táa wà yìí, Jèhófà yóò fòpin sí òṣì àti ìninilára—àní, yóò fòpin sí gbogbo ìyà.—Éfésù 1:8-10.
Ìṣòro Tó Kọjá Agbára Ẹ̀dá
Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún láti ìgbà tí a ti dá ènìyàn, ṣe ni aráyé túbọ̀ ń jìnnà sí ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà. (Diutarónómì 32:4, 5) Bí wọ́n ti ń bá a lọ láti pa òfin àti ìlànà Ọlọ́run tì, ènìyàn ti bá ara wọn jà, “ènìyàn [sì] ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Gbogbo ìsapá láti mú àwùjọ tó ń ṣẹ̀tọ́ wá, níbi tí kò ti sí gbogbo ìṣòro tó ń jẹ aráyé níyà lónìí ti já sásán nítorí ìmọtara-ẹni-nìkan àwọn tí wọ́n fẹ́ máa ṣe tinú ara wọn dípò kí wọ́n ṣe ohun tí Ọlọrun ọba aláṣẹ fẹ́.
Ìṣòro mìíràn ṣì wà—èyí tí ọ̀pọ̀ lè sọ pé, ká gbàgbé ẹ̀, ìgbàgbọ́ asán ni. Ẹni tó dáná ọ̀tẹ̀ táwọn èèyàn dì mọ́ Ọlọ́run lọ́jọ́sí ṣì ń sún wọn láti hùwà ibi àti láti jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan. Sátánì Èṣù ni, Jésù Kristi sì pè é ní “olùṣàkóso ayé.” (Jòhánù 12:31; 14:30; 2 Kọ́ríńtì 4:4; 1 Jòhánù 5:19) Nínú ìṣípayá táa fún àpọ́sítélì Jòhánù, a pe Sátánì ni orísun ègbé—ẹni tó wà nídìí ‘ṣíṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé lọ́nà.’—Ìṣípayá 12:9-12.
Bó ti wù kí àwọn ènìyàn kan bìkítà nípa àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn tó, wọn kò lè mú Sátánì Èṣù kúrò, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè mú kí ètò tó ń mú kí àwọn tí ìyà ń jẹ máa pọ̀ sí i yí padà láé. Nígbà náà, kí là ń béèrè láti yanjú àwọn ìṣòro aráyé? Ojútùú náà kì í kàn ṣe pé kí ẹnì kan tó bìkítà wà. Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹnì kan wà tó fẹ́ mú Sátánì àti gbogbo ètò aláparútu rẹ̀ kúrò, kí ẹni náà sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.
“Kí Ìfẹ́ Rẹ Ṣẹ . . . Lórí Ilẹ̀ Ayé”
Ọlọ́run ṣèlérí láti pa ètò burúkú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí run. Ó fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì lágbára láti ṣe é. (Sáàmù 147:5, 6; Aísáyà 40:25-31) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Dáníẹ́lì inú Bíbélì, ó sọ pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin”—bẹ́ẹ̀ ni, títí láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìjọba ọ̀run tí yóò wà pẹ́ títí yìí ni Jésù Kristi ní lọ́kàn nígbà tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti bẹ Ọlọ́run nínú àdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.
Jèhófà yóò dáhùn irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó bìkítà gan-an nípa ìdílé ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Sáàmù kejìléláàádọ́rin, Ọlọ́run yóò fún Ọmọ rẹ̀ láṣẹ, ìyẹn Jésù Kristi, láti mú ìtura pípẹ́ títí wá fún àwọn tálákà, àwọn tí a pọ́n lójú, àti àwọn tí a ni lára tí wọ́n kọ́wọ́ ti ìṣàkóso Jésù lẹ́yìn. Nípa báyìí, onísáàmù tí a mí sí náà kọrin pé: “Kí ó [Mèsáyà Ọba tí Ọlọ́run yàn] ṣe ìdájọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn, kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là, kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́. . . . Òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè, ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì, yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.”—Sáàmù 72:4, 12-14.
Nínú ìràn kan tó jẹ́ ti ọjọ́ wa, àpọ́sítélì Jòhánù rí “ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan,” ètò àwọn nǹkan tuntun pátápátá tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀. Ìbùkún ńláǹlà lèyí mà jẹ́ fún aráyé o! Nígbà tí Jòhánù ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí Jèhófà yóò ṣe, ó kọ̀wé pé: “Mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’ Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó wí pé: ‘Kọ̀wé rẹ̀, nítorí pé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’”—Ìṣípayá 21:1-5.
Bẹ́ẹ̀ ni, a lè gbára lé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nítorí wọ́n ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jóòótọ́. Láìpẹ́, Jèhófà yóò mú ipò òṣì, ebi, ìninilára, àìsàn, àti gbogbo ìwà tó jẹ mọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo kúrò. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn yìí ti sábà máa ń fi hàn láti inú Ìwé Mímọ́, ẹ̀rí tó pọ̀ rẹpẹtẹ ń fi hàn pé a ń gbé nísinsìnyí ní àkókò kan tí àwọn ìlérí wọ̀nyí yóò ní ìmúṣẹ. Ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé! (2 Pétérù 3:13) Láìpẹ́, Jèhófà yóò “gbé ikú mì títí láé,” yóò sì “nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.”—Aísáyà 25:8.
Kó tó di pé ìyẹn ṣẹlẹ̀, a lè kún fún ayọ̀ nísinsìnyí pé àwọn kan wà tí wọ́n bìkítà gidigidi fún àwọn èèyàn. Ohun mìíràn tó tún lè mú wa láyọ̀ ni pé Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ bìkítà gidigidi fún ènìyàn. Láìpẹ́, láìjìnnà, yóò mú gbogbo ìninilára àti ìyà kúrò.
O lè gbára lé ìlérí Jèhófà pátápátá. Jóṣúà, ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Láìfi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, ó wí fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run láyé ọjọ́un pé: “Ẹ̀yin sì mọ̀ dáadáa ní gbogbo ọkàn-àyà yín àti ní gbogbo ọkàn yín pé kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” (Jóṣúà 23:14) Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí ṣì wà, má ṣe jẹ́ kí àwọn àdánwò tó bá dé, kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Kó gbogbo àníyàn rẹ̀ lé Jèhófà, nítorí pé, dájúdájú, ó bìkítà.—1 Pétérù 5:7.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ilẹ̀ ayé yóò bọ́ lọ́wọ́ ipò òṣì, ìninilára, àìsàn, àti àìsí ìdájọ́ òdodo