Ìwọ́ Ha Ń fara Wé Ọlọ́run Wa Tí Kì í Ṣojúsàájú Bí?
ÀÌṢOJÚSÀÁJÚ—níbo ni a ti lè rí i? Ẹnì kan ń bẹ tí kì í ṣojúsàájú rárá, tí kì í ṣẹ̀tanú, tí kì í ṣègbè, tí ó sì máa ń báni lò lọ́gbọọgba. Òun ni Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá aráyé. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti ẹ̀dá ènìyàn, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, Charles Lamb, fi òótọ́ inú kọ̀wé pé: “Ní ṣókí, ẹlẹ́tanú paraku ni mí—èyí ní àwọn ohun tí mo fẹ́ àti ohun tí n kò fẹ́ nínú.”
Nígbà tí ó bá di ọ̀ràn àìṣojúsàájú, àjọṣepọ̀ ẹ̀dá ènìyàn kù díẹ̀ káà tó. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì ti Ísírẹ́lì sọ pé “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Ìkórìíra ẹ̀yà ìran, ìforígbárí orílẹ̀-èdè kan sí èkejì, àti aáwọ̀ ìdílé ń gbilẹ̀ sí i. Nítorí náà, ó ha bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé, ẹ̀dá ènìyàn fúnra wọn, lè mú àwùjọ tí kì í ṣojúsàájú jáde bí?
A nílò ìsapá àtọkànwá láti darí ìṣarasíhùwà wa, kí a sì mú ẹ̀tanú èyíkéyìí tí ó ti ta gbòǹgbò nínú ọkàn wa kúrò. (Éfésù 4:22-24) Láìmọ̀, a lè tẹ̀ sí níní àwọn ìṣarasíhùwà tí àyíká wa ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ mú jáde àti èyí tí ipò àtilẹ̀wá wa ní ti ìdílé, ẹ̀yà ìran, àti orílẹ̀-èdè pilẹ̀ rẹ̀. Àwọn ìtẹ̀sí wọ̀nyí tí ó dà bí èyí tí kò lè ṣèpalára, sábà máa ń jinlẹ̀ nínú ọkàn-àyà, wọ́n sì máa ń gbé àwọn ìṣarasíhùwà tí ń yọrí sí ṣíṣojúsàájú lárugẹ. Amòfin àti olóòtú tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Scotland, Lord Francis Jeffrey, pàápàá gbà pé: “Kò sí ohun tí ènìyàn kì í tètè fura pé òún ní, bí ẹ̀tanú tí ó ti ta gbongbo nínú ọkàn rẹ̀.”
Lenaa jẹ́ ẹnì kan tí ó gbà pé ó ń béèrè ìsapá àtọkànwá láti lè gbéjà ko ìtẹ̀sí jíjẹ́ olójúsàájú. Láti lè ṣẹ́pá èrò ẹ̀tanú nínú ara ẹni, ó sọ pé, “ó ń béèrè iṣẹ́ takuntakun nítorí pé bí a ṣe tọ́ni dàgbà ń ní agbára ìdarí lílágbára lórí ẹni.” Lena tún sọ pé, a nílò ìránnilétí ìgbà gbogbo.
Àkọsílẹ̀ Àìṣojúsàájú Jèhófà
Jèhófà jẹ́ àpẹẹrẹ pípé ní ti àìṣojúsàájú. Láti àwọn ojú ìwé àkọ́kọ́ Bíbélì, a kà nípa bí ó ṣe fi àìṣojúsàájú rẹ̀ hàn nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn. A lè kọ́ ohun púpọ̀ láti inú àwọn àpẹẹrẹ pípegedé àti ìránnilétí wọ̀nyí.
Jèhófà fi àìṣojúsàájú hàn nínú fífọgbọ́n darí ọ̀ràn kí àpọ́sítélì Pétérù, tí ó jẹ́ Júù, baà lè polongo ìhìn rere náà fún Kọ̀nílíù àti àwọn Kèfèrí mìíràn ní ọdún 36 Sànmánì Tiwa. Ní àkókò yẹn, Pétérù wí pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀ tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.
Nínú gbogbo ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú ìdílé ẹ̀dá ènìyàn, Jèhófà ti fi àìṣojúsàájú rẹ̀ hàn nígbà gbogbo. Kristi Jésù sọ nípa Bàbá rẹ̀ pé: “Òun . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ là sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Ní títúbọ̀ gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú, Pétérù jẹ́rìí sí i pé: “Ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé òun kò ní ìfẹ́ ọkàn pé kí ẹnikẹ́ni parun ṣùgbọ́n ó ní ìfẹ́ ọkàn pé kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—Pétérù Kejì 3:9.
Ní ọjọ́ Nóà, nígbà tí “ìwà búburú ènìyàn di púpọ̀ ní ayé, àti pé gbogbo ìrò ọkàn rẹ̀ kìkì ibi ni lójoojúmọ́,” Jèhófà pàṣẹ pípa ayé ìran ènìyàn yẹn run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:5-7, 11, 12) Ṣùgbọ́n, lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run àti lọ́nà tí kò pa mọ́ fún àwọn alájọgbáyé rẹ̀, Nóà kan ọkọ̀ áàkì. Bí òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe ń kan ọkọ̀ áàkì náà, Nóà tún jẹ́ “oníwàásù òdodo.” (Pétérù Kejì 2:5) Láìka mímọ èrò ọkàn búburú tí ìran yẹn ní sí, Jèhófà rán ìhìn iṣẹ́ tí ó ṣe kedere sí wọn láìṣojúsàájú. Ó gún èrò inú àti ọkàn-àyà wọn ní kẹ́ṣẹ́ nípa mímú kí Nóà kan ọkọ̀, kí ó sì wàásù. Wọ́n ní gbogbo àǹfààní láti dáhùn padà, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n “kò . . . fiyè sí i títí ìkún omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:39.
Ẹ wo irú àpẹẹrẹ pípegedé tí Jèhófà jẹ́ ní ti àìṣojúsàájú! Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn líle koko wọ̀nyí, ó ń sún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú irú ẹ̀mí àìṣojúsàájú kan náà. Síwájú sí i, wọn kò dẹ́kun pípolongo ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà. Ní gbangba wálíà, wọ́n ń gbé ìhìn iṣẹ́ Jèhófà kalẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gbọ́ ọ, láìṣojúsàájú.—Aísáyà 61:1, 2.
Àwọn ìlérí Jèhófà fún àwọn babańlá, Ábúráhámù, Aísíìkì, àti Jékọ́bù jẹ́ kí ó hàn gbangba pé, òún jẹ́ Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú. Ìlà ìdílé wọn ni Ẹni náà tí a yàn, nípasẹ̀ ẹni tí ‘gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóò ti bù kún ara wọn,’ yóò gbà wá. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; 26:4; 28:14) Kristi Jésù fi hàn pé òun ni Ẹni náà tí a yàn. Nípasẹ̀ ikú Jésù àti àjíǹde rẹ̀, Jèhófà pèsè ọ̀nà ìgbàlà fún gbogbo aráyé onígbọràn. Bẹ́ẹ̀ ni, àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi wà lárọ̀ọ́wọ́tó láìsí ojúsàájú.
Ní ọjọ́ Mósè, ẹ̀mí àìṣojúsàájú tí Jèhófà ní fara rẹ̀ hàn lọ́nà tí ó dùn mọ́ni nínú jù lọ, nínú ọ̀ràn àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì. Àwọn ọmọbìnrin márùn-ún wọ̀nyí dojú kọ ẹtì kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ogún bàbá wọn ní Ilẹ̀ Ìlérí. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ àṣà ní Ísírẹ́lì pé kí a tàtaré ogun ilẹ̀ ẹnì kan sí àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Ṣùgbọ́n, Sélóféhádì kú láìní ọmọkùnrin kankan tí yóò jogún rẹ̀. Nítorí náà, àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì mú ẹ̀bẹ̀ wọn fún ìbálò láìṣojúsàájú wá síwájú Mósè, ní sísọ pé: “Èé ha ṣe tí orúkọ, bàbá wa yóò fi parẹ́ kúrò nínú ìdílé rẹ̀, nítorí tí kò ní ọmọkùnrin? Fún wa ní ilẹ̀ ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.” Jèhófà fetí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ó sì fún Mósè nítọ̀ọ́ni pé: “Bí ọkùnrin kan bá kú, tí kò sì ní ọmọkùnrin, ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ṣe é kí ilẹ̀ ìní rẹ̀ kí ó kọjá sọ́dọ̀ ọmọbìnrin rẹ̀.”—Númérì 27:1-11.
Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àfilélẹ̀ ti àìṣojúsàájú tí èyí jẹ́! Láti rí i dájú pé a kò tàtaré ogún ẹ̀yà náà sí ẹ̀yà míràn nígbà tí àwọn ọmọbìnrin náà bá lọ́kọ, wọ́n gbọ́dọ̀ lọ́kọ kìkì nínú “ìdílé ẹ̀yà bàbá wọn.”—Númérì 36:5-12.
A túbọ̀ rí òye inú síwájú sí i nípa ẹ̀mí àìṣojúsàájú tí Jèhófà ní, ní ọjọ́ àwọn onídàájọ́ àti wòlíì Sámúẹ́lì. Jèhófà pàṣẹ pé kí ó yan ọba tuntun kan ti ẹ̀yà Júdà nínú ìdílé Jésè ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin mẹ́jọ ni Jésè ní. Ta ni a óò wá yàn gẹ́gẹ́ bí ọba? Ìdúró Élíábù fa Sámúẹ́lì mọ́ra. Ṣùgbọ́n, ìrísí òde kì í ní agbára lórí Jèhófà. Ó sọ fún Sámúẹ́lì pé: “Má ṣe wo ojú rẹ̀, tàbí gíga rẹ̀; . . . nítorí tí Olúwa kì í wò bí ènìyàn ti í wò, ènìyàn a máa wo ojú, Olúwa a máa wo ọkàn.” Dáfídì, ọmọkùnrin tí o kéré jù lọ nínú àwọn ọmọkùnrin Jésè, ni a yàn.—Sámúẹ́lì Kìíní 16:1, 6-13.
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Láti Inú Ẹ̀mí Àìṣojúsàájú Tí Jèhófà Ní
Yóò dára kí àwọn Kristẹni alàgbà fara wé Jèhófà nípa wíwo àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni kan ní. Ó rọrùn láti ṣèdájọ́ ẹnì kan nípa ọ̀pá ìdiwọ̀n tiwa, ní yíyọ̀ọ̀da fún ìmọ̀lára ara ẹni tí àwa fúnra wa láti yí ìdájọ́ wa po. Alàgbà kan sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà tí yóò mú inú Jèhófà dùn, kì í ṣe lórí èrò tí mo ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀.” Ẹ wo bí yóò ti ṣàǹfààní tó fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà láti lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá ìdiwọ̀n wọn!
Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì tí a ti mẹ́nu kàn wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti bá ìmọ̀lára ẹ̀yà tèmi lọ̀gá tàbí ẹ̀tanú orílẹ̀-èdè tí ó wà lọ́kàn wa jìjàkadì. Nípa fífara wé ẹ̀mí àìṣojúsàájú Jèhófà, a ń dáàbò bo ìjọ Kristẹni kúrò lọ́wọ́ ẹ̀tanú, àìbánilò lọ́gbọọgba, àti ṣíṣègbè.
Àpọ́sítélì Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ pé “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:34) Ọ̀tá ni ṣíṣègbè jẹ́ fún ẹ̀mí àìṣojúsàájú, ó sì ń tẹ ìlànà ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan lójú. Jésù rọ àwọn òtòṣì, àwọn aláìlera, àti àwọn ẹni rírẹlẹ̀, ó sì mú ẹrù wọn fúyẹ́. (Mátíù 11:28-30) Ó yàtọ̀ gédégédé sí àwọn aṣáájú ìsìn Júù, tí wọ́n jẹ gàba lé àwọn ènìyàn lórí, ní dídi ẹrù ìlànà wíwúwo lé wọn lórí. (Lúùkù 11:45, 46) Dájúdájú, ṣíṣe èyí àti gbígbè sẹ́yìn àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn gbajúmọ̀ kò bá àwọn ẹ̀kọ́ Kristi mu.—Jákọ́bù 2:1-4, 9.
Lónìí, àwọn Kristẹni alàgbà ń tẹrí ba fún ipò orí Kristi, wọ́n sì ń fi ẹ̀mí àìṣojúsàájú hàn sí gbogbo àwọn ènìyàn Jèhófà tí wọ́n ti ṣe ìyàsímímọ́. Bí wọ́n ‘ti ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn,’ wọ́n yàgò fún ṣíṣègbè nítorí ipò ẹni ní ti ọrọ̀ ajé, ìyàtọ̀ ní ti àkópọ̀ ìwà, tàbí ìdè ìdílé. (Pétérù Kìíní 5:2) Nípa fífara wé Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú àti kíkọbi ara sí ìkìlọ̀ rẹ̀ sí àwọn ìṣe tí ó lè fi ẹ̀mí ìṣègbè hàn, àwọn Kristẹni alàgbà ń gbé ẹ̀mí àìṣojúsàájú lárugẹ nínú ìjọ.
Ìjọ Kristẹni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Ó jẹ́ ẹ̀rí tí ó ṣeé fojú rí pé, lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, àwùjọ tí ó bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀tanú, tí kì í sì í ṣojúsàájú lè wà. Àwọn Ẹlẹ́rìí ti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúró ṣinṣin.” (Éfésù 4:24) Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àpẹẹrẹ pípé ti Ọlọ́run tí kì í ṣojúsàájú, Jèhófà, wọ́n sì ní ìfojúsọ́nà fún ìyè ayérayé nínú ayé tuntun tí ó bọ́ lọ́wọ́ gbogbo ojúsàájú.—Pétérù Kejì 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ àfidípò.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àpọ́sítélì Pétérù kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run kì í ṣojúsàájú