ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 12/15 ojú ìwé 3-4
  • Ìhìn Rere Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Ti Sọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìhìn Rere Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Ti Sọ
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ojú Ìwòye “Àwọn Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀” Nípa Jésù
  • Ó Kọjá Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́
  • Àwọn Ìwé Ìhìn Rere—Ìjiyàn Ṣì Ń Lọ Lọ́wọ́ Lórí Wọn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ẹni Náà Gan-an Tí a Ń Pè Ní Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ṣóòótọ́ Làwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Òtítọ́ Nípa Jésù
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 12/15 ojú ìwé 3-4

Ìhìn Rere Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Ti Sọ

“TA NI àwọn ogunlọ́gọ̀ ń wí pé mo jẹ́?” (Lúùkù 9:18) Jésù béèrè èyí lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rúndún méjì sẹ́yìn. Ìbéèrè yìí fa àríyànjiyàn nígbà náà. Ó dà bí ẹni pé ó ń fa àríyànjiyàn jù bẹ́ẹ̀ lọ nísinsìnyí, ní pàtàkì ní àkókò Kérésìmesì, tí àwọn kan rò pé ó kan Jésù gbọ̀ngbọ̀n. Ọ̀pọ́ gbà pé a rán Jésù láti ọ̀run láti ra aráyé padà. Ìyẹ́n ha jẹ́ èrò rẹ bí?

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan gbé ojú ìwòye mìíràn dìde. Marcus J. Borg, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìsìn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, sọ pé: “Èròǹgbà náà pé Jésù kọ́ni pé òún jẹ́ Ọmọkùnrin Ọlọ́run tí yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ayé kì í ṣe òtítọ́ ọ̀rọ̀ ìtàn.”

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míràn sọ pé Jésù gidi yàtọ̀ sí ẹni tí a kà nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. Àwọn kan gbà gbọ́ pé a kọ gbogbo Ìhìn Rere ní ẹ̀wádún mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn ikú Jésù àti pé nígbà yẹn a ti sọ àsọdùn nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà tẹnu mọ́ ọn pé, kì í ṣe agbára ìrántí àwọn òǹkọ̀wé Ìhìn Rere ni ó ní ìṣòro, bí kò ṣé ìtumọ̀ wọn. Lẹ́yìn ikú Jésù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í ní ojú ìwòye tí ó yàtọ̀ nípa rẹ̀—gẹ́gẹ́ bí Ọmọkùnrin Ọlọ́run, Olùgbàlà, àti Mèsáyà. Àwọn kan fi ìgboyà sọ pé alárìnkiri amòye, olùṣèyípadà ìbáṣepọ̀ ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà kan lásán ni Jésù. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà sọ pé, ìyẹn ni ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ tí kò lábùlà.

Ojú Ìwòye “Àwọn Ọ̀mọ̀wé Akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀” Nípa Jésù

Láti gbèjà ojú ìwòye “àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀” tí wọ́n ní, ó dà bí ẹni pé àwọn olùṣelámèyítọ́ máa ń hára gàgà láti fọwọ́ rọ́ ohunkóhun tí ó bá dà bí àràmàǹdà nípa Jésù tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan sọ pé bíbí tí wúndíá bí Jésù jẹ́ láti fi bàṣírí pé ó jẹ́ ọmọ àlè. Àwọn mìíràn kò tẹ́wọ́ gba àsọtẹ́lẹ̀ Jésù nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ní rírinkinkin pé ṣe ni a fi ìwọ̀nyí há inú àwọn ìwé Ìhìn Rere lẹ́yìn “ìmúṣẹ” wọn. Àwọn kan tilẹ̀ sọ pé ìwòsàn tí Jésù ṣe wulẹ̀ jẹ́ ìfìyíni-léròpadà-ṣèwòsàn—ìrònú nípa ọ̀ràn. Ìwọ́ ha rò pé irú èrò bẹ́ẹ̀ yè kooro tàbí o rò pé ó jẹ́ aláìbọ́gbọ́nmu bí?

Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tilẹ̀ sọ pé ṣe ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù hùmọ̀ àjíǹde láti má baà jẹ́ kí ìgbòkègbodò àjọ wọn dẹnu kọlẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà ṣàlàyé pé, ó ṣe tán, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù kò lè dá ṣe ohunkóhun láìsí i níbẹ̀, nítorí náà wọ́n dọ́gbọ́n fi ìtàn Ọ̀gá wọn há inú àkọsílẹ̀. Ohun tí wọ́n ń sọ ni pé, ìsìn Kristẹni ni a jí dìde, kì í ṣe Kristi. Bí ìyẹ́n bá dà bí ẹni pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn, èrò tí ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Barbara Thiering, gbé kalẹ̀ ńkọ́ pé a kò pa Jésù rárá? Ó gbà gbọ́ pé Jésù yè bọ́ lọ́wọ́ kíkàn tí a kàn án mọ́gi, ó gbéyàwó lẹ́ẹ̀méjì, ó sì bí ọmọ mẹ́ta.

Gbogbo àwọn ìfìtẹnumọ́kéde wọ̀nyí rẹ Jésù sílẹ̀ sí kìkì ipò tí ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ yóò ti tẹ́wọ́ gbà á: gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n kan, púrúǹtù Júù kan, alátùn-únṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà—ní gbígbà á pé ó jẹ́ ohunkóhun àyàfi pé kì í ṣe Ọmọkùnrin Ọlọ́run, ẹni tí ó wá ‘láti fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kan ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’—Mátíù 20:28.

Ó ṣeé ṣe pé ní àkókò yìí nínú ọdún, o ti ka àwọn apá kan nínú Ìhìn Rere, irú bí apá tí ó sọ nípa ìbí Jésù nínú ibùjẹ ẹran. Tàbí o ti lè gbọ́ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ìwọ́ ha tẹ́wọ́ gba àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere náà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó níye lórí, tí ó sì ṣeé gbà gbọ́ bí? Nígbà náà, kíyè sí ipò tí ń múni gbọ̀n rìrì yìí. Nínú ohun tí a pè ní Àpérò Jésù, àwùjọ kan tí ó jẹ́ ti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ti pàdé lẹ́ẹ̀méjì lọ́dún láti ọdún 1985 láti wádìí bí àwọn ọ̀rọ̀ Jésù ṣe jẹ́ òtítọ́ tó. Jésù ha sọ ohun tí Bíbélì sọ pé ó sọ ní ti tòótọ́ bí? Àwọn mẹ́ḿbà àpérò náà dìbò lórí gbólóhùn kọ̀ọ̀kan nípa lílo ìlẹ̀kẹ̀ olóríṣiríṣi àwọ̀. Ìlẹ̀kẹ̀ pupa túmọ̀ sí pé dájúdájú Jésù sọ gbólóhùn náà; ìlẹ̀kẹ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú túmọ̀ sí pé ó ṣeé ṣe kí Jésù sọ ọ́; ìlẹ̀kẹ̀ aláwọ̀ eérú fi hàn pé kò dájú; ìlẹ̀kẹ̀ dúdú sì fi hàn pé irọ́ ni.

Ó lè dà ọ́ láàmú láti gbọ́ pé Àpérò Jésù kéde pé ìpín 82 nínú ọgọ́rùn-ún nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí a sọ pé Jésù sọ, ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé òun kọ́ ni ó sọ ọ́. Ọ̀kan ṣoṣo nínú àyọlò tí a ṣe nínú Ìhìn Rere Máàkù ni a gbà pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. A sọ pé Ìhìn Rere Lúùkù kún fún àhesọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ pé “òtítọ́ tí ó ní nínú kò ṣeé mọ̀.” Gbogbo Ìhìn Rere ti Jòhánù ni ó gba ìlẹ̀kẹ̀ dúdú, tí ó ń fi hàn pé irọ́ ni, àyàfi kìkì ìlà mẹ́ta, ìlẹ̀kẹ̀ aláwọ̀ eérú tí ń fi hàn pé kò dájú ni ìwọ̀nba tí ó ṣẹ́kù sì rí gbà.

Ó Kọjá Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́

Ìwọ́ ha fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà bí? Wọ́n ha ń fún wa ní àwòrán tí ó túbọ̀ péye nípa Jésù ju èyí tí a rí nínú Bíbélì bí? Ìbéèrè wọ̀nyí ju ọ̀ràn tí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ lè jiyàn lé lórí lọ. Ní àkókò yìí nínú ọdún, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, a lè rán ọ létí pé, Ọlọ́run rán Jésù “kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má baà pa run ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Bí Jésù bá jẹ́ amòye alárìnkiri lásán tí a kò lè mọ púpọ̀ nípa rẹ̀, kì yóò sí ìdí fún wa láti “lo ìgbàgbọ́” nínú rẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí àwòrán tí Bíbélì fúnni nípa Jésù bá jẹ́ òtítọ́, ó kan ìgbàlà wa ayérayé. Nítorí náà, a ní láti mọ̀—Bíbélì ha ní òtítọ́ nípa Jésù nínú bí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́