Énọ́kù—Onígboyà Láìka Gbogbo Àtakò Sí
FÚN ènìyàn rere kan, àkókò tí ó tí ì burú jù lọ ni ó jẹ́. Àìṣèfẹ́ Ọlọ́run gba ilẹ̀ ayé kan. Ipò ìwà rere aráyé lọ sílẹ̀ láìdáwọ́dúró. Ní tòótọ́, a óò sọ láìpẹ́ pé: “Ọlọ́run . . . rí i pé ìwà búburú ènìyàn di púpọ̀ ní ayé, àti pé gbogbo ìrò ọkàn rẹ̀ kìkì ibi ni lójoojúmọ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5.
Énọ́kù, ọkùnrin keje nínú ìlà ìdílé láti ọ̀dọ̀ Ádámù, ní ìgboyà láti dá yàtọ̀. Ó dúró gbọn-in fún òdodo láìka àbájáde rẹ̀ sí. Ìhìn iṣẹ́ Énọ́kù bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run nínú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi fojú sùn ún pé àwọn yóò pa á, Jèhófà nìkan sì ni ó lè ràn án lọ́wọ́.—Júúdà 14, 15.
Énọ́kù àti Àríyànjiyàn Àgbáyé
Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí a tó bí Énọ́kù, a gbé àríyànjiyàn jíjẹ́ ọba aláṣẹ àgbáyé dìde. Ọlọ́run ha ní ẹ̀tọ́ láti ṣàkóso bí? Ní ti gidi, Sátánì Èṣù wí pé bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó jiyàn pé àwọn ẹ̀dá olóye yóò ṣe dáradára jù bí wọn kò bá sí lábẹ́ ìdarí Ọlọ́run. Sátánì gbìyànjú láti fìdí ọ̀rọ̀ rẹ̀ múlẹ̀ ní ìlòdìsí Jèhófà Ọlọ́run nípa fífi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ fa àwọn ẹ̀dá ènìyàn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. A mọ Ádámù, ìyàwó rẹ̀ Éfà, àti ọmọkùnrin wọn àkọ́bí, Kéènì bí ẹni mọ owó pé wọ́n fara mọ́ Sátánì nípa yíyan ìṣàkóso ara ẹni dípò ìṣàkóso Ọlọ́run. Ẹ̀dá ènìyàn méjì àkọ́kọ́ ṣe èyí nípa jíjẹ èso tí Ọlọ́run kà léèwọ̀, Kéènì sì ṣe bẹ́ẹ̀ nípa mímọ̀ọ́mọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ tí ó jẹ́ olódodo, Ébẹ́lì.—Jẹ́nẹ́sísì 3:4-6; 4:8.
Ébẹ́lì fi ìgboyà dúró gbọn-in síhà ọ̀dọ̀ Jèhófà. Níwọ̀n bí ìwà títọ́ Ébẹ́lì ti gbé ìjọsìn mímọ́ gaara lárugẹ, dájúdájú, inú Sátánì dùn láti rí i bí Kéènì ṣe fi ìrunú ṣìkà pa á. Bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà yẹn lọ, Sátánì ti lo “ìbẹ̀rù ikú” gẹ́gẹ́ bí ohun ìjà kan láti kó jìnnìjìnnì báni. Ó ń fẹ́ láti gbin ìbẹ̀rù sínú ọkàn ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìtẹ̀sí láti jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ náà.—Hébérù 2:14, 15; Jòhánù 8:44; Jòhánù Kíní 3:12.
Ní àkókò tí a bí Énọ́kù, ó dà bíi pé èròǹgbà Sátánì pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn kì yóò gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ fẹ́ jóòótọ́. Ébẹ́lì ti kú, a kò sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ rẹ̀. Síbẹ̀, Énọ́kù fi hàn pé òun yàtọ̀. Ó ní ìpìlẹ̀ dídúró gbọn-in fún ìgbàgbọ́, nítorí pé ó mọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ní àmọ̀dunjú.a Ẹ wo bí òun yóò ti ṣìkẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tí ń fi hàn pé Irú-Ọmọ ìlérí kan yóò mú òpin dé bá Sátánì àti ìhùmọ̀ rẹ̀ tó!—Jẹ́nẹ́sísì 3:15.
Bí ìrètí yìí ti fi ìgbà gbogbo wà níwájú rẹ̀, ìtàn olókìkí nípa ṣíṣìkà tí a ṣìkà pa Ébẹ́lì, èyí tí Èṣù ṣokùnfà rẹ̀ kò kó jìnnìjìnnì bá Énọ́kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń bá a nìṣó láti máa bá Jèhófà rìn, ní lílépa ọ̀nà ìgbésí ayé òdodo jálẹ̀ ìwàláàyè rẹ̀. Énọ́kù ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé, ní yíyẹra fún ẹ̀mí òmìnira rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 5:23, 24.
Síwájú sí i, Énọ́kù fi ìgboyà sọ̀rọ̀, ó sì mú un ṣe kedere pé iṣẹ́ ibi tí Èṣù ń ṣe kì yóò kẹ́sẹ járí. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀, Énọ́kù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ẹni ibi pé: “Wò ó! Jèhófà wá pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ míríádì rẹ̀ mímọ́, láti mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún sí gbogbo ènìyàn, àti láti dá gbogbo àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run lẹ́jọ́ ẹ̀bi nípa gbogbo àwọn ìṣe àìṣèfẹ́ Ọlọ́run wọn èyí tí wọ́n ṣe lọ́nà àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, àti nípa gbogbo àwọn ohun amúnigbọ̀nrìrì tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run ti sọ lòdì sí i.”—Júúdà 14, 15.
Nítorí pípòkìkí tí Énọ́kù fi ìgboyà pòkìkí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, nígbà tí ó ń kọ̀wé sí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù, dárúkọ rẹ̀ mọ́ “àwọ sánmà àwọn ẹlẹ́rìí” ńlá tí wọ́n fi àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ gíga tí ń bẹ lẹ́nu iṣẹ́ lélẹ̀.b (Hébérù 11:5; 12:1) Gẹ́gẹ́ bí ẹni ìgbàgbọ́, Énọ́kù dúró gangan ní ọ̀nà ìwà títọ́ fún ohun tí ó ju 300 ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 5:22) Ẹ wo bí ìṣòtítọ́ Énọ́kù ti ní láti bí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé nínú tó! Àsọtẹ́lẹ̀ mímúná tí Énọ́kù ń sọ mú kí Sátánì kórìíra rẹ̀, ṣùgbọ́n ó mú ààbò Jèhófà wá.
Ọlọ́run Mú Énọ́kù Lọ —Báwo Ni?
Jèhófà kò jẹ́ kí Sátánì tàbí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé pa Énọ́kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, àkọsílẹ̀ onímìísí wí pé: “Ọlọ́run mú un lọ.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:24) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe ọ̀ràn lọ́nà yí pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù nípò pa dà láti má ṣe rí ikú, a kò sì rí i níbi kankan nítorí tí Ọlọ́run ti ṣí i nípò pa dà; nítorí ṣáájú ìṣínípòpadà rẹ̀ ó ní ẹ̀rí náà pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa.”—Hébérù 11:5.
Báwo ni a ṣe “ṣí Énọ́kù nípò pa dà láti má ṣe rí ikú”? Tàbí gẹ́gẹ́ bí a ṣe túmọ̀ rẹ̀ nínú ìtúmọ̀ tí R. A. Knox ṣe, báwo ni a ṣe “mú” Énọ́kù “lọ láìnírìírí ikú”? Ọlọ́run fòpin sí ìwàláàyè Énọ́kù lọ́nà àlàáfíà, ní gbígbà á kúrò lọ́wọ́ ìrora ikú tí àìsàn tàbí tí ìwà ipá láti ọwọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ lè fà. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà ké ìwàláàyè Énọ́kù kúrú ní ẹni ọdún 365—ó jẹ́ ọ̀dọ́ gidigidi ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn alájọgbáyé rẹ̀.
Báwo ní a ṣe fún Énọ́kù ní “ẹ̀rí . . . pé ó ti wu Ọlọ́run dáadáa”? Ẹ̀rí wo ni ó ní? Ó ṣeé ṣe pé, Ọlọ́run mú kí Énọ́kù bọ́ sí ojúran, àní bí a ṣe “gba” àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù “lọ,” tàbí tí a ṣí i nípò pa dà, tí ó hàn gbangba pé ó ń rí ìran nípa párádísè tẹ̀mí ọjọ́ ọ̀la ti ìjọ Kristẹni. (Kọ́ríńtì Kejì 12:3, 4) Ìjẹ́rìí, tàbí ẹ̀rí pé Énọ́kù wu Ọlọ́run ti ní láti kan rírí ìran fìrí nípa Párádísè ilẹ̀ ayé ti ọjọ́ ọ̀la níbi tí gbogbo àwọn tí ń gbé ibẹ̀ yóò ti ti ipò ọba aláṣẹ Ọlọ́run lẹ́yìn. Bóyá nígbà tí Énọ́kù ń nírìírí ìran arùmọ̀lára-sókè kan ni Ọlọ́run mú un lọ nínú ikú aláìnírora láti sùn títí di ọjọ́ àjíǹde rẹ̀. Ó dà bíi pé, bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Mósè, Jèhófà palẹ̀ òkú Énọ́kù mọ́, nítorí “a kò . . . rí i níbi kankan.”—Hébérù 11:5; Diutarónómì 34:5, 6; Júúdà 9.
A Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ
Lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń polongo ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ Énọ́kù. Láti inú Ìwé Mímọ́, wọ́n ń fi hàn bí a óò ti mú un ṣẹ nígbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn aláìṣèfẹ́ rẹ̀ run ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́. (Tẹsalóníkà Kejì 1:6-10) Ìhìn iṣẹ́ tí wọ́n ń jẹ́ kò jẹ́ kí wọ́n gbajúmọ̀, nítorí pé ó yàtọ̀ pátápátá sí ojú ìwòye ayé yìí àti àwọn góńgó rẹ̀. Àtakò tí wọ́n ń bá pàdé kò yà wọ́n lẹ́nu nítorí Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin yóò . . . jẹ́ ohun ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.”—Mátíù 10:22; Jòhánù 17:14.
Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí Énọ́kù, àwọn Kristẹni lónìí ní ìdánilójú pé a óò dá wọn nídè nígbẹ̀yìngbẹ́yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Jèhófà mọ bí a ti í dá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfọkànsin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ dè ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” (Pétérù Kejì 2:9) Ọlọ́run lè rí i pé ó tọ́ láti mú ìṣòro kan tàbí ipò kan tí ń dẹni wò kúrò. Inúnibíni lè wá sí òpin. Ṣùgbọ́n, bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, òun mọ bí yóò ṣe “ṣe ọ̀nà àbájáde” kí àwọn ènìyàn rẹ̀ baà lè fi àṣeyọrí fara da ìdánwò wọn. Àní Jèhófà máa ń pèsè “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” nígbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀.—Kọ́ríńtì Kíní 10:13; Kọ́ríńtì Kejì 4:7.
Gẹ́gẹ́ bí “olùsẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a,” Jèhófà yóò tún fi ìyè àìnípẹ̀kun bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin. (Hébérù 11:6) Fún èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára wọn, èyí yóò jẹ́ ìyè ayérayé nínú párádísè ilẹ̀ ayé. Gẹ́gẹ́ bí Énọ́kù, ǹjẹ́ kí àwa nígbà náà fi àìṣojo pòkìkí ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run. Nínú ìgbàgbọ́, ẹ jẹ́ kí a ṣe èyí láìka gbogbo àtakò sí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹni ọdún 622 ni Ádámù nígbà tí a bí Énọ́kù. Énọ́kù wà láàyè fún nǹkan bí ọdún 57 lẹ́yìn tí Ádámù kú. Nítorí náà, wọ́n jọ wà láàyè fún sáà díẹ̀.
b Ìtúmọ̀ náà, “àwọn ẹlẹ́rìí” ní Hébérù 12:1 wá láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, marʹtys. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà, Wuest’s Word Studies From the Greek New Testament ti sọ, ọ̀rọ̀ yí túmọ̀ sí “ẹni tí ó ń jẹ́rìí sí, tàbí tí ó lè jẹ́rìí sí ohun tí ó rí tàbí tí ó gbọ́ tàbí tí ó mọ̀ nípasẹ̀ ọ̀nà èyíkéyìí mìíràn.” Ìwé náà, Christian Words, láti ọwọ́ Nigel Turner sọ pé, ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ “láti inú ìrírí ara ẹni . . . , àti láti inú ìdánilójú nípa òtítọ́ àti ojú ìwòye.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]
A Sọ Orúkọ Ọlọ́run Di Aláìmọ́
Ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́rin ṣáájú Énọ́kù, a bí Énọ́ṣì, ọmọ-ọmọ Ádámù. Jẹ́nẹ́sísì 4:26 wí pé: “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe orúkọ OLÚWA.” Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nípa èdè Hébérù gbà gbọ́ pé ó yẹ kí ẹsẹ yìí kà pé, “bẹ̀rẹ̀ sí í” pe orúkọ Ọlọ́run “lọ́nà àìmọ́” tàbí, “nígbà náà ni ìsọdàìmọ́ bẹ̀rẹ̀.” Nípa sáà yẹn nínú ìtàn, Targum ti Jerúsálẹ́mù wí pé: “Ìyẹn ni ìran náà tí ó jẹ́ pé ní ìgbà tirẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́ṣẹ̀, tí wọ́n sì ṣe òrìṣà fún ara wọn, tí wọ́n sì fi orúkọ Ọ̀rọ̀ Olúwa sọ àwọn òrìṣà wọn.”
Ní àkókò Énọ́ṣì, ṣíṣi orúkọ Jèhófà lò bú rẹ́kẹ. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn ènìyàn lo orúkọ àtọ̀runwá náà fún ara wọn tàbí fún àwọn ènìyàn kan nípasẹ̀ àwọn ẹni tí wọ́n díbọ́n pé àwọn gbà ń tọ Jèhófà Ọlọ́run lọ nínú ìjọsìn. Tàbí ó lè jẹ́ pé wọ́n sọ àwọn òrìṣà ní orúkọ àtọ̀runwá náà. Bí ó ti wù kí ọ̀ràn náà jẹ́, Sátánì Èṣù mú kí ìran ènìyàn kó sínú ìdẹkùn ìbọ̀rìṣà. Nígbà tí a óò fi bí Énọ́kù, ìjọsìn tòótọ́ ṣọ̀wọ́n. Ẹnikẹ́ni bí Énọ́kù, tí ń fi òtítọ́ ṣèwàhù, tí ó sì ń wàásù rẹ̀ kò gbajúmọ̀, nítorí náà a ṣe inúnibíni sí i.—Fi wé Mátíù 5:11, 12.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 31]
Énọ́kù Ha Lọ sí Ọ̀run Bí?
“Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Énọ́kù nípò pa dà láti má ṣe rí ikú.” Nígbà tí wọ́n ń túmọ̀ apá ibí yìí nínú Hébérù 11:5, àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan fi hàn pé Énọ́kù kò kú ní ti gidi. Fún àpẹẹrẹ, A New Translation of the Bible, láti ọwọ́ James Moffatt, wí pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni a fi mú Énọ́kù lọ sí ọ̀run tí kò fi kú rárá.”
Ṣùgbọ́n, ní nǹkan bí 3,000 ọdún lẹ́yìn ọjọ́ Énọ́kù, Jésù Kristi wí pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti gòkè re ọ̀run bí kò ṣe ẹni tí ó sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, Ọmọkùnrin ènìyàn.” (Jòhánù 3:13) Ìtúmọ̀ The New English Bible kà pé: “Kò sí ẹni tí ó lọ sí òkè ọ̀run rí àyàfi ẹni tí ó ti ọ̀run sọ kalẹ̀ wá, Ọmọkùnrin Ènìyàn.” Nígbà tí Jésù fi sọ gbólóhùn yẹn, kò tilẹ̀ tí ì gòkè re ọ̀run.—Fi wé Lúùkù 7:28.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Énọ́kù àti àwọn mìíràn tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ àwọ sánmà ńlá ti àwọn ẹlẹ́rìí ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni lápapọ̀ “kú” wọn “kò rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.” (Hébérù 11:13, 39) Èé ṣe? Nítorí pé gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, títí kan Énọ́kù, ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù. (Orin Dáfídì 51:5; Róòmù 5:12) Ọ̀nà kan ṣoṣo sí ìgbàlà jẹ́ nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù. (Ìṣe 4:12; Jòhánù Kíní 2:1, 2) Ní ọjọ́ Énọ́kù, a kò tí ì san ìràpadà yẹn. Nítorí náà, Énọ́kù kò lọ sí ọ̀run, ṣùgbọ́n ó ń sùn nínú ikú ní dídúró de àjíǹde lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 5:28, 29.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]
A tún un tẹ̀ jáde láti inú Illustrirte Pracht - Bibel/Heilige Schrift des Alten und Neuen Testaments, nach der deutschen Uebersetzung D. Martin Luther’s