ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 7
  • Ọkùnrin Onígboyà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọkùnrin Onígboyà
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ó Ti Wu Ọlọ́run Dáadáa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Énọ́kù—Onígboyà Láìka Gbogbo Àtakò Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Énọ́kù Bá Ọlọ́run Rìn Nínú Ayé Aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn Lákòókò Hílàhílo Yìí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 7
Énọ́kù

ÌTÀN 7

Ọkùnrin Onígboyà

BÍ ÀWỌN èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i láyé, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló ń ṣe ohun búburú bíi ti Kéènì. Ṣùgbọ́n ti ọkùnrin kan báyìí yàtọ̀. Orúkọ ọkùnrin náà ni Énọ́kù. Ó jẹ́ onígboyà. Gbogbo àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ ló ń hùwà búburú, àmọ́ òun ò ṣíwọ́ sísin Ọlọ́run.

Láyé ìgbà Énọ́kù, ọkùnrin oníwà ipá kan pa ọkùnrin míì

Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn fi ń ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan búburú bẹ́ẹ̀? Ó dára, ṣó o rántí, Ta ló mú kí Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n sì jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ? Áńgẹ́lì búburú kan ni, àbí? Bíbélì pe áńgẹ́lì náà ní Sátánì. Sátánì ń gbìyànjú láti sọ gbogbo èèyàn dẹni búburú.

Ní ọjọ́ kan Jèhófà Ọlọ́run rán Énọ́kù pé kó lọ sọ ohun táwọn èèyàn ò fẹ́ gbọ́ fún wọn. Ohun tí Ọlọ́run ní kó sọ ni pé: ‘Ní ọjọ́ kan, Ọlọ́run yóò pa gbogbo àwọn èèyàn búburú run.’ Ó ṣeé ṣe kí inú ti bí àwọn èèyàn gidigidi nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Bóyá wọ́n tiẹ̀ gbìyànjú láti pa Énọ́kù pàápàá. Nítorí náà, Énọ́kù ní láti nígboyà gan-an kó tó lè sọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fáwọn èèyàn náà.

Àwọn èèyàn búburú ń ṣe ohun búburú nígbà ayé Énọ́kù

Ọlọ́run ò jẹ́ kí Énọ́kù pẹ́ láàárín àwọn èèyàn búburú wọ̀nyẹn. Ìwọ̀nba ọdún díẹ̀ ló lò láyé, èyí sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta, ọgọ́ta ó lé márùn-ún [365] ọdún. Kí nìdí tá a fi sọ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni iye ọdún tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹ̀mí àwọn èèyàn ayé ọjọ́un máa ń gùn ju ti àwa èèyàn òde òní lọ nítorí pé ara wọ́n dá ṣáṣá ju tiwa lọ. Àní, Mètúsélà ọmọ Énọ́kù lo ẹgbẹ̀rún dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] ọdún láyé!

Lẹ́nu kan ṣá, lẹ́yìn tí Énọ́kù kú, ńṣe làwọn èèyàn náà túbọ̀ ń burú sí i. Bíbélì sọ pé ‘gbogbo èrò wọn kìkì ibi ni lójoojúmọ́,’ àti pé ‘ayé kún fún ìjàngbọ̀n.’

Ǹjẹ́ o mọ ọ̀kan nínú àwọn ìdí tí wàhálà fi pọ̀ láyé tó bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà yẹn? Ó jẹ́ nítorí pé Sátánì mọ ọ̀nà tuntun kan tó fi ń mú káwọn èèyàn ṣe ohun búburú.  Ìtàn yìí la ó sọ tẹ̀ lé e.

Jẹ́nẹ́sísì 5:21-24, 27; 6:5; Hébérù 11:5; Júúdà 14, 15.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́