Ìyà Pọ̀ Rẹpẹtẹ
“ÈÉ ṢE tí ìyà burúkú tí ń jẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan àti èyí tí ń jẹni lápapọ̀ fi wà . . . ? Ọlọ́run ni ó yẹ kí ó jẹ́ orísun gbogbo ète ìgbésí ayé, síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ni kò nítumọ̀ nínú ayé yìí, ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìyà tí kò nídìí àti ẹ̀ṣẹ̀ tí kò bọ́gbọ́n mu. Ọlọ́run yìí ní tòótọ́ ha jẹ́ irú ẹni tí Nietzsche fẹ̀sùn kàn án pé ó jẹ́ bí: òṣìkà olùṣàkóso, afàwọ̀rajà, ẹlẹ́tàn, aṣekúpani?”—On Being a Christian, láti ọwọ́ Hans Küng.
Ìwọ lè rí i pé ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì náà, Hans Küng, wulẹ̀ ń gbé ìṣòro kan tí ń pin ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́mìí kalẹ̀ ni—èé ṣe tí Ọlọ́run tí ó jẹ́ alágbára gbogbo àti onífẹ̀ẹ́ ṣe fàyè gba ìyà tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ tó bẹ́ẹ̀? Ìwọ kò ha ti gbọ́ tí àwọn ènìyàn béèrè irú ìbéèrè bẹ́ẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní ìyọ́nú yóò kẹ́dùn nítorí ohun tí Küng ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “alagbalúgbú àgbàrá ẹ̀jẹ̀, òógùn àti omijé ìrora, ìbànújẹ́ àti ìfòyà, ìdánìkanwà àti ikú.” Ní tòótọ́, ó dà bí ìyalulẹ̀ omi, ìkún omi ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ àti onílàásìgbò, tí ó ti ṣe ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn báṣabàṣa jálẹ̀ ìtàn.—Jóòbù 14:1.
Ó Kún fún “Làálàá òun Ìbìnújẹ́”
Ronú nípa ìyà tí ogun ń fà, ìrora tí kì í ṣe kìkì àwọn abógunrìn nìkan ni wọ́n nímọ̀lára rẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí wọ́n fi sílẹ̀ sẹ́yìn láti kẹ́dùn, irú bí àwọn òbí àti mọ̀lẹ́bí ọmọ àwọn abógunrìn àti àwọn mìíràn tí a ti hùwà òǹrorò sí pẹ̀lú. Àjọ Alágbèlébùú Pupa sọ láìpẹ́ yìí pé: “Jálẹ̀ ọdún 10 tí ó kọjá, mílíọ̀nù 1.5 ọmọdé ni a pa nínú ìforígbárí olóhun ìjà ogun.” Ní Rwanda ní 1994, àjọ Alágbèélébùú Pupa ròyìn, “ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí a pa pátápátá lọ́nà rírorò.”
Kò yẹ kí a tún gbójú fo ìrora tí àwọn agbéǹkan-gbòdì tí ń bọ́mọdé lò pọ̀ ń fà. Ìyá kan tí ń kẹ́dùn pé ọmọkùnrin òun pa ara rẹ̀ lẹ́yìn tí abánitọ́jú ọmọ kan bá a ṣèṣekúṣe, sọ pé: “Ọkùnrin tí ó bá ọmọkùnrin mi ṣèṣekúṣe . . . pa òun àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọdékùnrin mìíràn run pátápátá, lọ́nà kan tí a gbé gbòdì jù lọ tí a lè finú wòye.” Tún ronú nípa ìrora ìrírí burúkú tí àwọn òjìyà jẹ lọ́wọ́ àwọn òǹrorò apànìyàn tàbí àwọn apànìyàn rẹpẹtẹ, bí irú àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ ní Britain tí wọ́n “jíni gbé, tí wọ́n fipá báni lò pọ̀, tí wọ́n dáni lóró tí wọ́n sì pani fún ọdún 25 láìjìyà rẹ̀”? Jálẹ̀ ìtàn, ó dà bíi pé ohun tí àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti fà fún ẹnì kíní kejì ní ti ìrora àti ìyà kò lópin.—Oníwàásù 4:1-3.
Ní àfikún sí èyí ni ìyà tí àìsàn ti èrò ìmọ̀lára àti àìsàn ti ara ti fà àti ìrora gógó ti ẹ̀dùn ọkàn tí ń fọ́ ìdílé túútúú nígbà tí olólùfẹ́ wọn kan bá kú ní rèwerèwe. Làásìgbò ti àwọn tí ìyàn mú tàbí ti àwọn tí ohun tí a sábà ń pè ní ìjábá ti ìṣẹ̀dá ṣẹlẹ̀ sí tún wà níbẹ̀. Ìwọ̀nba ènìyàn ni yóò jiyàn sí gbólóhùn tí Mósè sọ pé, 70 tàbí 80 ọdún wa kún fún “làálàá òun ìbìnújẹ́.”—Orin Dáfídì 90:10.
Apá Kan Ète Ọlọ́run Ha Ni Bí?
Gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe sọ, ó ha lè jẹ́ pé ìyà tí kò dáwọ́ dúró yìí jẹ́ apá kan ète Ọlọ́run tí ó ṣòro láti lóye? A ha gbọ́dọ̀ jìyà nísinsìnyí láti lè mọrírì ìwàláàyè ‘nínú ayé tuntun tí ń bọ̀’ bí? Gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n èrò orí ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, Teilhard de Chardin, ti gbà gbọ́, òtítọ́ ha ni pé, “ìyà tí ń pani tí ó sì ń múni jẹrà, pọn dandan fún ẹ̀dá, kí ó baà lè wà láàyè, kí ó sì di ẹ̀dá ẹ̀mí”? (The Religion of Teilhard de Chardin; ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá!
Olùṣègbékalẹ̀ kan tí ó jẹ́ agbatẹnirò yóò ha mọ̀ọ́mọ̀ gbé àyíká kan tí ó lè pani run kalẹ̀, kí ó sì wá sọ pé òun jẹ́ oníyọ̀ọ́nú nígbà tí ó bá gba àwọn ènìyàn là kúrò nínú àbájáde rẹ̀ bí? Rárá! Èé ṣe tí Ọlọ́run kan tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ yóò fi ṣe irú ohun bẹ́ẹ̀? Nítorí náà, èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà? Ìyà yóò ha dópin láé bí? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Fọ́tò àjọ WHO láti ọwọ́ P. Almasy