“Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run” àti Àwọn Òrìṣà ní Ilẹ̀ Gíríìsì Ha Fohùn Ṣọ̀kan Bí?
NÍ ỌJỌ́ gbígbóná janjan yìí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, oòrùn ń ràn yòò sórí àwọn òkúta tí ń tàn yanranyanran. Ṣùgbọ́n, ooru tí ń mú lọ́nà bíbùáyà náà kò dà bíi pé ó bomi paná ẹ̀mí àti ìpinnu jíjinlẹ̀ ti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn onítara ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì, tí wọ́n ń rìnrìn-àjò ìsìn, tí wọ́n forí lé ṣọ́ọ̀ṣì kékeré tí ó wà lórí òkè.
Ìwọ lè rí obìnrin arúgbó kan tí àárẹ̀ ti mú, tí ó ti rìnrìn-àjò wá láti ìpẹ̀kun kejì orílẹ̀-èdè náà, tí ó ń wọ́ ara rẹ̀ lọ. Gẹ́rẹ́ níwájú, ọkùnrin oníhàáragàgà kan ń mí hẹlẹhẹlẹ bí ó ti ń fi ìháragàgà gbìyànjú láti gba àárín èrò tí ń tira wọn kọjá. Ọmọdébìnrin kan, tí ó dájú pé ó ń jẹ̀rora, tí ìmọ̀lára ìgbékútà sì hàn lójú rẹ̀, ń rákò lórí eékún rẹ̀ tí ń ṣẹ̀jẹ̀. Kí ni góńgó wọn? Láti tètè dókè, kí wọ́n lè gbàdúrà níwájú ère náà, bí ó bá sì ṣeé ṣe, kí ó fọwọ́ kàn án, kí ó sì fẹnu ko ère “ẹni mímọ́” olókìkí náà lẹ́nu.
Àwọn ìran bí irú èyí máa ń wáyé léraléra kárí ayé ní àwọn ibi tí a yà sọ́tọ̀ fún bíbọlá fún “àwọn ẹni mímọ́.” Ó hàn gbangba pé, gbogbo àwọn arìnrìn-àjò ìsìn wọ̀nyí gbà gbọ́ dájú pé, ní ọ̀nà yí, àwọn ń tẹ̀ lé ọ̀nà tí Ọlọ́run ní kí a gbà tọ òun wá, wọ́n sì ń tipa báyìí fi ìfọkànsìn àti ìgbàgbọ́ wọn hàn. Ìwé náà, Our Orthodox Christian Faith, sọ pé: “A ń ṣèrántí [“àwọn ẹni mímọ́”], a sì ń fi ògo àti ọlá fún jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ́ . . . , a sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àdúrà tí wọ́n ń gbà fún wa níwájú Ọlọ́run àti ẹ̀bẹ̀ wọn àti ìrànlọ́wọ́ wọn nínú ọ̀pọ̀ ohun tí a ń ṣe nínú ìgbésí ayé wa. . . . A yíjú sí àwọn Ẹni Mímọ́ oníṣẹ́ àrà . . . fún àìní wa nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara.” Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ ẹgbẹ́ alákòóso ìsìn Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì ti sọ, a gbọ́dọ̀ bá “àwọn ẹni mímọ́” sọ̀rọ̀ bí alárinà láàárín àwa àti Ọlọ́run, a sì gbọ́dọ̀ máa bọlá fún àwọn ohun tí ó jẹ mọ́ “àwọn ẹni mímọ́” àti àwọn ère wọn.
Olórí àníyàn ojúlówó Kristẹni kan yẹ kí ó jẹ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Nítorí ìdí yìí, ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn kókó díẹ̀ yẹ̀ wò nípa ọ̀nà tí a gbà mú àṣà ìsìn bíbọlá fún “àwọn ẹni mímọ́” wọnú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ yẹ kí ó lè jẹ́ ìlàlóye fún ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ láti tọ Ọlọ́run wá lọ́nà tí ó já sí ìtẹ́wọ́gbà fún Un.
Bí A Ṣe Mú “Àwọn Ẹni Mímọ́” Wọnú Ìsìn
Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pe gbogbo àwọn Kristẹni ìjímìjí tí a fi ẹ̀jẹ̀ Kristi wẹ̀ mọ́ tónítóní, tí a sì yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní “àwọn ẹni mímọ́.” (Ìṣe 9:32; Kọ́ríńtì Kejì 1:1; 13:13) Tọkùnrin tobìnrin, àwọn olókìkí àti àwọn mẹ̀kúnnù nínú ìjọ, gbogbo wọn ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹni mímọ́,” nígbà tí wọ́n ṣì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. Lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, kí wọ́n tó kú pàápàá ni a ti mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni mímọ́.
Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, nígbà tí ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìdí múlẹ̀, ìtẹ̀sí nígbà náà lọ́hùn-ún jẹ́ láti gbìyànjú mú kí ìsìn Kristẹni fa àwọn ènìyàn mọ́ra, ìsìn kan tí yóò fa àwọn kèfèrí mọ́ra, tí wọn yóò sì lè tẹ́wọ́ gbà láìjanpata. Àwọn kèfèrí wọ̀nyí ń jọ́sìn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọlọ́run, ìsìn tuntun náà sì rinkinkin mọ́ jíjọ́sìn Ọlọ́run kan ṣoṣo. Nítorí náà, ìfohùnṣọ̀kan yóò lè ṣeé ṣe bí a bá mú “àwọn ẹni mímọ́,” tí yóò rọ́pò àwọn ọlọ́run ìgbàanì, àwọn ṣènìyàn-ṣọlọ́run, àti àwọn akọni inú ìtàn àròsọ, wọnú ìsìn. Ní sísọ̀rọ̀ lórí èyí, ìwé náà, Ekklisiastiki Istoria (Ìtàn Ṣọ́ọ̀ṣì), sọ pé: “Fún àwọn tí a sọ di Kristẹni láti inú ìsìn kèfèrí, ó rọrùn fún wọn láti so iṣẹ́ àwọn akọni wọn tí wọ́n ti pa tì pọ̀ mọ́ ti àwọn ajẹ́rìíkú, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọlá fún wọn bí wọ́n ṣe ń bọlá fún àwọn ti àkọ́kọ́. . . . Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, bíbu irú ọlá bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹni mímọ́ wá di ìbọ̀rìṣà paraku.”
Ìwé ìtọ́kasí mìíràn ṣàlàyé bí a ṣe mú “àwọn ẹni mímọ́” wọnú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù: “Nínú bíbọlá fún àwọn ẹni mímọ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì, a rí àmì tí ó ṣe kedere ní ti ipa lílágbára tí ìsìn kèfèrí ní. Àwọn ànímọ́ tí a mọ̀ mọ àwọn ọlọ́run Olympia ṣáájú kí a tó sọ [àwọn ènìyàn] di onísìn Kristẹni ni a ń fún àwọn ẹni mímọ́ nísinsìnyí. . . . Láti ìbẹ̀rẹ̀ ìsìn tuntun náà, ni a ti rí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ tí wọ́n ń fi Wòlíì Èlíjà rọ́pò ọlọ́run oòrùn (Phoebus Apollo), tí wọ́n ń kọ́ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sórí, tàbí sẹ́gbẹ̀ẹ́, òkìtì àlàpà àwọn tẹ́ńpìlì ìgbàanì tàbí ojúbọ ọlọ́run yìí, èyí tí ó pọ̀ jù lọ jẹ́ lórí àwọn òkè kéékèèké àti òkè ńlá, ní ibi gbogbo tí àwọn ará Gíríìsì ìgbàanì ti bọlá fún olùfúnni nímọ̀ọ́lẹ̀ náà, Phoebus Apollo. . . . Wọ́n tilẹ̀ tún so Wúńdíá abo-ọlọ́run ti Athena pọ̀ mọ́ Màríà Wúńdíá alára. Nípa báyìí, abọ̀rìṣà kan tí a yí lọ́kàn pa dà kò nímọ̀lára pé òun ti pàdánù ohunkóhun, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pa ère Athena run.”—Neoteron Enkyklopaidikon Lexikon (Ìwé Atúmọ̀ Èdè Tuntun Tí Ó Jẹ́ Gbédègbẹ́yọ̀), Ìdìpọ̀ Kíní, ojú ìwé 270 àti 271.
Fún àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ipò tí ó wà ní Áténì títí di nǹkan bí òpin ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Tiwa. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùgbé ìlú yẹn ṣì jẹ́ abọ̀rìṣà. Ọ̀kan nínú àwọn ìrúbọ wọn tí ó jẹ́ mímọ́ jù lọ ni àwọn ààtò ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ Eleusinia, ayẹyẹ alápá méjì,a tí a ń ṣe lọ́dọọdún ní February, ní ìlú Eleusis, kìlómítà 23 sí ìlà oòrùn àríwá Átẹ́nì. Láti lè wà níbi àwọn ààtò ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀ wọ̀nyí, àwọn kèfèrí ará Átẹ́nì ní láti gba ojú Ọ̀nà Mímọ́ (Hi·e·raʹ Ho·dosʹ). Nínú ìgbìyànjú láti pèsè ibi ìjọsìn àfidípò, àwọn aṣáájú ìlú fi hàn pé àwọn jẹ́ olóye gidigidi. Ní ojú ọ̀nà kan náà, nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá láti Átẹ́nì, a kọ ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Daphni, láti fa àwọn kèfèrí mọ́ra àti láti dí wọn lọ́wọ́ lílọ sí ibi ààtò ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀. A kọ ṣọ́ọ̀ṣì ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé náà sórí ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì ìgbàanì tí a yà sọ́tọ̀ fún ọlọ́run ilẹ̀ Gíríìsì náà, Daphnaios, tàbí Pythios Apollo.
A tún lè rí ẹ̀rí bí a ṣe mú àwọn ọlọ́run àwọn kèfèrí wọnú àṣà bíbọlá fún “àwọn ẹni mímọ́,” ní erékùṣù Kithira, ní ilẹ̀ Gíríìsì. Ṣọ́ọ̀ṣì kékeré méjì ti Byzantine wà lórí ọ̀kàn nínú àwọn ṣóńṣó òkè erékùṣù náà—a ya ọ̀kan nínú wọn sí mímọ́ fún “Ẹni Mímọ́” George, a sì ya èkejì sí mímọ́ fún Màríà Wúńdíá. Àwọn ìwújáde ṣí i payá pé ibí yìí ni ojúbọ ṣóńṣó òkè Minoa wà, tí o jẹ́ ibi ìjọsìn ní nǹkan bí 3,500 ọdún sẹ́yìn. Ní ọ̀rúndún kẹfà tàbí ìkeje Sànmánì Tiwa, “àwọn Kristẹni” kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wọn fún “Ẹni Mímọ́” George sórí ilẹ̀ náà gan-an tí ojúbọ ṣóńṣó òkè náà wà. Ìgbésẹ̀ yí ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan ní ti gidi; pé ibùdó ìtẹ̀síwájú ti ìsìn Minoa ni ó darí ọ̀nà òkun ti Òkun Aegea. A kọ ṣọ́ọ̀ṣì méjèèjì síbẹ̀ láti rí ojú rere Màríà Wúńdíá àti “Ẹni Mímọ́” George, ọjọ́ kan náà ni a ń ṣayẹyẹ èyí tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn yẹn pẹ̀lú “olùdáàbòbo àwọn ọ̀gákọ̀ òkun,” “Ẹni Mímọ́” Nicholas. Ìwé agbéròyìnjáde kan tí ń ròyìn lórí àwárí yìí wí pé: “Lónìí, àlùfáà [Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìsì] yóò gòkè lọ sí orí òkè ńlá náà, gan-an gẹ́gẹ́ bí àlùfáà Minoa yóò ti ṣe ní àkókò ìgbàanì,” láti lè ṣe ààtò ìsìn!
Ní ṣíṣàkópọ̀ bí ìsìn àwọn kèfèrí ti ilẹ̀ Gíríìsì ti ṣe ní agbára ìdarí lórí ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà tó, olùṣèwàdìí lórí ìtàn kan ṣàlàyé pé: “Ìpìlẹ̀ ìsìn kèfèrí nínú ìsìn Kristẹni sábà máa ń wà láìṣeé yí pa dà nínú ìgbàgbọ́ tí ó lókìkí, tí ń tipa báyìí jẹ́rìí sí bí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti lè wà pẹ́ títí tó.”
‘Jíjọ́sìn Ohun Tí A Mọ̀’
Jésù wí fún obìnrin ará Samáríà náà pé: “Àwa ń jọ́sìn ohun tí àwa mọ̀. . . . Àwọn olùjọsìn tòótọ́ yóò máa jọ́sìn Bàbá ní ẹ̀mí àti òtítọ́, nítorí pé, ní tòótọ́, irúfẹ́ àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Bàbá ń wá láti máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:22, 23) Ṣàkíyèsí pé jíjọ́sìn ní òtítọ́ pọn dandan! Nítorí náà, kò ṣeé ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí yóò tẹ́wọ́ gbà láìní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ àti ìfẹ́ tí ó jinlẹ̀ fún un. Ìsìn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a gbé karí òtítọ́, kì í ṣe karí àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àti àṣà tí a yá láti inú ìsìn kèfèrí. A mọ̀ bí ìmọ̀lára Jèhófà yóò ṣe rí nígbà tí àwọn ènìyàn bá gbìyànjú láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà òdì. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní ìlú Kọ́ríńtì, ti Gíríìsì ìgbàanì, pé: “Ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì? . . . Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà?” (Kọ́ríńtì Kejì 6:15, 16) Ìgbìyànjú èyíkéyìí láti so tẹ́ńpìlì Ọlọ́run pọ̀ mọ́ àwọn òrìṣà ń kó o nírìíra.
Síwájú sí i, lọ́nà tí ó ṣe kedere gan-an, Ìwé Mímọ́ fagi lé èrò gbígbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́,” kí wọ́n baà lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí alárinà láàárín àwa àti Ọlọ́run. Nínú àdúrà àwòkọ́ṣe rẹ̀, Jésù kọ́ni pé Bàbá nìkan ni kí a darí àdúrà sí, níwọ̀n bí ó ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin gbọ́dọ̀ gbàdúrà ní ọ̀nà yí: ‘Bàbá wa ní àwọn ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọdimímọ́.’” (Mátíù 6:9) Jésù sọ síwájú sí i pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹnì kan tí ó ń wá sọ́dọ̀ Bàbá bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì sọ pé: “Ọlọ́run kan ni ó wà, àti alárinà kan láàárín Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn, ọkùnrin kan, Kristi Jésù.”—Jòhánù 14:6, 14; Tímótì Kíní 2:5.
Bí a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa ní tòótọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí a tọ̀ ọ́ lọ lọ́nà tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ là sílẹ̀. Ní títẹnumọ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tí ó tọ́ láti bá Jèhófà sọ̀rọ̀, Pọ́ọ̀lù tún kọ̀wé pé: “Kristi Jésù ni ẹni náà tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni, jù bẹ́ẹ̀ lọ ẹni náà tí a gbé dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ẹni tí ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa pẹ̀lú.” “Ó lè gba àwọn wọnnì tí wọ́n ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí oun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.”—Róòmù 8:34; Hébérù 7:25.
‘Jíjọ́sìn ní Ẹ̀mí àti ní Òtítọ́’
Ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà kò ní okun tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run láti sún àwọn kèfèrí láti pa ìjọsìn èké wọn tì, kí wọ́n sì tẹ̀ lé àwọn ẹ̀kọ́ tòótọ́ tí Jésù Kristi fi kọ́ni. Ó gba ìgbàgbọ́ àti àṣà àwọn kèfèrí wọlé nínú ìyánhànhàn rẹ̀ fún àwọn tí yóò yí lọ́kàn pa dà, fún agbára, àti fún òkìkí. Nítorí ìdí èyí, kò mú àwọn Kristẹni adúrógbọn-in tí Ọlọ́run àti Kristi tẹ́wọ́ gbà jáde, bí kò ṣe àwọn ayédèrú onígbàgbọ́, “àwọn èpò” tí kò yẹ fún Ìjọba náà.—Mátíù 13:24-30.
Ṣùgbọ́n, ní àkókò òpin yìí, lábẹ́ ìdarí Jèhófà, àwọn ìgbòkègbodò mánigbàgbé kan ń lọ lọ́wọ́ nínú mímú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò. Àwọn ènìyàn Jèhófà kárí ayé, láìka ipò àtilẹ̀wá wọn ní ti àṣà ìbílẹ̀, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, tàbí ìsìn sí, ń gbìyànjú láti mú ìgbésí ayé wọn àti ìgbàgbọ́ wọn bá ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì mu. Bí o bá fẹ́ láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa bí a ṣe lè jọ́sìn Ọlọ́run “ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́,” jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi tí o ń gbé. Inú wọn yóò dùn jọjọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, lórí ìpìlẹ̀ agbára ìmọnúúrò rẹ àti ìmọ̀ pípéye nípa Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo pàrọwà fún yín nípasẹ̀ ìyọ́nú Ọlọ́run, ẹ̀yin ará, láti fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín. Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ̀yin lè fún ara yín ní ẹ̀rí ìdánilójú ìfẹ́ inú Ọlọ́run tí ó dára tí ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà tí ó sì pé.” Ó sì kọ̀wé sí àwọn ará Kólósè pé: “Láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa rẹ̀, àwa kò ṣíwọ́ gbígbàdúrà fún yín àti bíbéèrè pé kí ẹ lè kún fún ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ inú rẹ̀ nínú ọgbọ́n gbogbo àti ìfinúmòye ti ẹ̀mí, kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú iṣẹ́ rere gbogbo tí ẹ sì ń pọ̀ sí i nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run.”—Róòmù 12:1, 2; Kólósè 1:9, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọdọọdún ni a ń ṣe ayẹyẹ Eleusinia Títóbi Jù ní September, ní Átẹ́nì àti Eleusis.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Lílo Parthenon Lọ́nà Tí A Kò Retí
Olú Ọba Theodosius Kejì, tí ó jẹ́ “Kristẹni,” ní lílo àwọn òfin tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìlú Átẹ́nì (438 Sànmánì Tiwa), fi òpin sí àwọn ààtò kèfèrí àti ààtò ẹgbẹ́ ìmùlẹ̀, ó sì ti àwọn tẹ́ńpìlì kèfèrí pa. Lẹ́yìn náà, a lè sọ wọ́n di ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni. Ohun àbéèrèfún kan ṣoṣo fún kíkẹ́sẹjárí nínú sísọ tẹ́ńpìlì kan di ṣọ́ọ̀ṣì ni láti sọ ọ́ di mímọ́ nípa ríri àgbélébùú kan mọ́lẹ̀ sínú rẹ̀!
Parthenon jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tẹ́ńpìlì tí a kọ́kọ́ sọ di ṣọ́ọ̀ṣì. Àtúnṣe ńlá lára ilé náà wáyé láti baà lè mú kí Parthenon ṣe é lò gẹ́gẹ́ bíi tẹ́ńpìlì “Kristẹni.” Láti 869 Sànmánì Tiwa, a lò ó gẹ́gẹ́ bíi kàtídírà ti Átẹ́nì. Lákọ̀ọ́kọ́, a bọlá fún un gẹ́gẹ́ bíi ṣọ́ọ̀ṣì “Ọgbọ́n Mímọ́.” Èyí ì bá ti jẹ́ ìránnilétí lílágbára ní ti òtítọ́ náà pé “ẹni tí ó ni” tẹ́ńpìlì náà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, Athena, jẹ́ abo-ọlọ́run ọgbọ́n. Lẹ́yìn náà, a yà á sí mímọ́ fún “Màríà Wúńdíá ti Átẹ́nì.” Lẹ́yìn ọ̀rúndún mẹ́jọ tí àwọn onísìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ń lò ó, a sọ tẹ́ńpìlì náà di ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ti Màríà Mímọ́ ti Átẹ́nì. Irú “àlòtúnlò” Parthenon bẹ́ẹ̀ ní ti ìsìn ń bá a nìṣó nígbà tí àwọn ará Turkey sọ ọ́ di mọ́ṣáláṣí ní ọ̀rúndún kẹẹ̀dógún.
Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ń ṣèbẹ̀wò sí Parthenon, tẹ́ńpìlì Doric ìgbàanì ti Athena Parthenos (“Wúńdíá”), abo-ọlọ́run ọgbọ́n ti àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì, kìkì nítorí tí o jẹ́ àgbà iṣẹ́ ìkọ́lé ti àwọn ará ilẹ̀ Gíríìsì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Daphni—ibi ìjọsìn àfidípò kan fún àwọn kèfèrí ní Átẹ́nì ìgbàanì