Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
“Ilé Ìṣọ́” August 15, 1996, sọ pé: “Nínú apá ìkẹyìn ìpọ́njú ńlá náà, a óò gba ‘ẹran ara’ tí ó ti sá lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà là.” Ìyẹn ha ń dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé lẹ́yìn apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá, ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun yóò wá sí ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
Kókó yẹn kọ́ ni a ń fà yọ.
Ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí nínú Mátíù 24:22 yóò ní ìmúṣẹ pàtàkì ní ọjọ́ iwájú nípa rírí ìgbàlà nígbà apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀, kíkọlu ìsìn. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà sọ pé: “Rántí pé a óò ti gba ‘ẹran ara’ ti àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró àti ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá’ là, nígbà tí Bábílónì Ńlá bá yára kánkán parun pátápátá nínú apá àkọ́kọ́ ìpọ́njú ńlá náà.”
Irú àwọn olùṣòtítọ́ bẹ́ẹ̀ kì yóò sí nínú ewu nígbà tí Jésù àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ọ̀run bá gbégbèésẹ̀ ní apá ìkẹyìn ìpọ́njú náà. Ṣùgbọ́n, àwọn wo ni yóò la apá ìpọ́njú ńlá yẹn kọjá? Ìṣípayá 7:9, 14 fi hàn pé, ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí wọ́n ní ìrètí orí ilẹ̀ ayé yóò là á já. Àwọn Kristẹni tí a fi ẹ̀mí yàn ńkọ́? “Ibeere Lati Ọwọ́ Awọn Onkawe” inú Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1990, jíròrò ìdí tí a kò fi lè sọ ní pàtó gan-an ìgbà tí a óò mú àṣẹ́kù ẹni àmì òróró lọ sí ọ̀run. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ àìpẹ́ yìí (August 15, 1996) kò ṣe pàtó lórí ọ̀ràn náà, ní ṣíṣe àlàyé yìí: “Bákan náà nínú apá ìkẹyìn ìpọ́njú náà, a óò gba ‘ẹran ara’ tí ó ti sá lọ sí ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà là.”
Ní ti bóyá ó lè ṣeé ṣe kí ẹni tuntun èyíkéyìí kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, kí ó sì wá sí ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lẹ́yìn tí ìpọ́njú ńlá bá ti bẹ̀rẹ̀, kíyè sí ọ̀rọ̀ Jésù tí a kọ sílẹ̀ ní Mátíù 24:29-31. Lẹ́yìn tí ìpọ́njú bá ti bẹ̀rẹ̀, àmì Ọmọkùnrin ènìyàn yóò fara hàn. Jésù sọ pé, gbogbo àwọn ẹ̀yà ilẹ̀ ayé yóò lu ara wọn, wọn yóò sì dárò. Kò sọ ohunkóhun nípa àwọn ènìyàn tí ojú wọ́n là sí ohun tí ń ṣẹlẹ̀, tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n mú ìdúró wọn sí ìhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́.
Lọ́nà kan náà, nínú òwe àgùntàn àti ewúrẹ́, Ọmọkùnrin ènìyàn fara hàn, ó sì fi ìdájọ́ ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ lórí ìpìlẹ̀ ohun tí wọ́n ti ṣe tàbí ohun tí wọn kò ṣe nígbà tí ó ti kọjá. Jésù kò sọ ohunkóhun nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n ti fi ìwà bí ewúrẹ́ hàn fún àkókò pípẹ́, tí wọ́n wá yí pa dà lójijì, tí wọ́n sì di àgùntàn. Ó wá láti ṣe ìdájọ́ lórí ìpìlẹ̀ ohun tí àwọn ènìyàn ti fẹ̀rí hàn pé wọ́n jẹ́.—Mátíù 25:31-46.
Ṣùgbọ́n, lẹ́ẹ̀kan sí i, kò sí ìdí láti rin kinkin mọ́ ojú ìwòye ẹni lórí kókó yìí. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá, mọ ohun tí wọ́n ní láti ṣe nísinsìnyí—láti wàásù, kí wọ́n sì sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20; Máàkù 13:10) Nísinsìnyí ni àkókò fún wa láti fi ọ̀rọ̀ ìyànjú náà sọ́kàn pé: “Ní bíbá a ṣiṣẹ́ pa pọ̀, àwa ń pàrọwà fún yín pẹ̀lú láti má ṣe tẹ́wọ́ gba inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí ẹ sì tàsé ète rẹ̀. Nítorí ó wí pé: ‘Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mo gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, àti ní ọjọ́ ìgbàlà mo ràn ọ́ lọ́wọ́.’ Wò ó! Nísinsìnyí ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì. Wò ó! Nísinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—Kọ́ríńtì Kejì 6:1, 2.