Ìwọ Ha Wà ní Sẹpẹ́ De Ọjọ́ Jèhófà Bí?
“Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yára kánkán.”—SEFANÁYÀ 1:14.
1. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe ṣàpèjúwe ọjọ́ Jèhófà?
“ỌJỌ́ ńlá àti ẹ̀rù” Jèhófà yóò dé sórí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú ti ìsinsìnyí láìpẹ́. Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe ọjọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìjà ogun, òkùnkùn, ìrunú, wàhálà, làásìgbò, ìdáníjì, àti ìsọdahoro. Síbẹ̀, àwọn tí yóò là á já yóò wà, nítorí “ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Olúwa ni a óò gbà là.” (Jóẹ́lì 2:30-32; Ámósì 5:18-20) Bẹ́ẹ̀ ni, ìgbà náà ni Ọlọ́run yóò pa gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ run, tí yóò sì gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là.
2. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ní òye ìjẹ́kánjúkánjú nípa ọjọ́ Jèhófà?
2 Àwọn wòlíì Ọlọ́run so òye ìjẹ́kánjúkánjú pọ̀ mọ́ ọjọ́ Jèhófà. Fún àpẹẹrẹ, Sefanáyà kọ̀wé pé: “Ọjọ́ ńlá Olúwa kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀, ó sì ń yára kánkán.” (Sefanáyà 1:14) Ipò náà túbọ̀ jẹ́ kánjúkánjú lónìí, nítorí pé, Olórí Amúdàájọ́ṣẹ Ọlọ́run, Ọba náà, Jésù Kristi, ti fẹ́ ‘sán idà rẹ̀ mọ́ ìdí rẹ̀ nítorí òtítọ́ àti ìwà tútù àti òdodo.’ (Orin Dáfídì 45:3, 4) Ìwọ ha wà ní sẹpẹ́ fún ọjọ́ yẹn bí?
Ìfojúsọ́nà Wọn Ga
3. Ìfojúsọ́nà wo ni díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ní Tẹsalóníkà ní, ìdí méjì wo sì ni wọ́n fi ṣàṣìṣe?
3 Ọ̀pọ̀ ti ní ìfojúsọ́nà tí kò nímùúṣẹ nípa ọjọ́ Jèhófà. Àwọn Kristẹni ìjímìjí kan ní Tẹsalóníkà wí pé, ‘Ọjọ́ Jèhófà ti dé!’ (Tẹsalóníkà Kejì 2:2) Ṣùgbọ́n, ìdí pàtàkì méjì wà tí kò fi tí ì dé nígbà náà. Ní títọ́ka sí ọ̀kan nínú àwọn ìdí wọ̀nyí, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti wí pé: “Ìgbà yòó wù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn.” (Tẹsalóníkà Kíní 5:1-6) Ní “ìgbà ìkẹyìn” yí, àwa pẹ̀lú ń dúró de ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn. (Dáníẹ́lì 12:4) Àwọn ará Tẹsalóníkà kò tún ní ẹ̀rí kan pé, ọjọ́ ńlá Jèhófà ti dé nígbà yẹn, nítorí Pọ́ọ̀lù sọ fún wọn pé: “Kì yóò dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà kọ́kọ́ dé.” (Tẹsalóníkà Kejì 2:3) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn (ní nǹkan bí ọdún 51 Sànmánì Tiwa), “ìpẹ̀yìndà” kúrò nínú ìsìn Kristẹni tòótọ́ kò tí ì fìdí múlẹ̀ dáradára. Lónìí, a rí i tí ó ti gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ṣùgbọ́n, láìka ìfojúsọ́nà wọn tí kò nímùúṣẹ sí, àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ wọnnì tí wọ́n wà ní Tẹsalóníkà, tí wọ́n ń bá a nìṣó ní fífi òtítọ́ ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run títí dé ojú ikú, rí èrè ti ọ̀run gbà nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Ìṣípayá 2:10) A óò san èrè fún àwa pẹ̀lú, bí a bá dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́, bí a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà.
4. (a) Kí ni a so ọjọ́ Jèhófà pọ̀ mọ́ ní Tẹsalóníkà Kejì 2:1, 2? (b) Ojú ìwòye wo ni àwọn tí a sábà máa ń pè ní Bàbá Ṣọ́ọ̀ṣì ní nípa ìpadàbọ̀ Kristi àti àwọn ọ̀ràn míràn tí ó jẹ mọ́ ọn?
4 Bíbélì so “ọjọ́ ńlá Olúwa” pọ̀ mọ́ “wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi.” (Tẹsalóníkà Kejì 2:1, 2) Àwọn tí a sábà máa ń pè ní Bàbá Ṣọ́ọ̀ṣì ní onírúurú èrò nípa ìpadàbọ̀ Kristi, wíwàníhìn-ín rẹ̀, àti Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀. (Ìṣípayá 20:4) Ní ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, Papias ti Hirapólísì fọkàn ṣìkẹ́ ìfojúsọ́nà bí ilẹ̀ ayé yóò ṣe méso jáde lọ́nà yíyanilẹ́nu nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi. Justin Martyr sọ̀rọ̀ léraléra nípa wíwàníhìn-ín Jésù, ó sì retí kí Jerúsálẹ́mù tí a mú pa dà bọ̀ sípò di ibùjókòó Ìjọba Rẹ̀. Irenæus ti Lyons kọ́ni pé, lẹ́yìn tí a bá ti pa Ilẹ̀ Ọba Róòmù run, Jésù yóò fara hàn lọ́nà tí ó ṣeé fojú rí, yóò gbé Sátánì dè, yóò sì ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé.
5. Kí ni àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ nípa “Bíbọ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kejì” ti Kristi àti Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún rẹ̀?
5 Òpìtàn Philip Schaff sọ pé “ìgbàgbọ́ tí ó ta yọ lọ́lá jù lọ” ní sáà tí ó ṣáájú ìdásílẹ̀ Ìgbìmọ̀ Nicaea ní 325 Sànmánì Tiwa ni “ìgbàgbọ́ nínú ìṣàkóso Kristi nínú ògo lórí ilẹ̀ ayé lọ́nà tí ó ṣeé fojú rí, fún ẹgbẹ̀rún ọdún, pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ tí a jí dìde, ṣáájú àjíǹde gbogbogbòò àti ìdájọ́.” Ìwé atúmọ̀ Bíbélì náà, A Dictionary of the Bible, tí James Hastings ṣàyẹ̀wò rẹ̀, sọ pé: “Tertullian, Irenæus, àti Hippolytus ṣì ń wọ̀nà fún ìsúnmọ́lé Bíbọ̀ [Jésù Kristi]; ṣùgbọ́n pẹ̀lú àwọn Bàbá tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ojú ìwòye tí ó pilẹ̀ ní Alẹkisáńdíríà, a wọnú ẹ̀mí ìrònú tuntun kan. . . . Pẹ̀lú kíkọ́ni tí ẹ̀kọ́ Augustine kọ́ni pé ohun kan náà ni Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún àti sáà ìjà àjàkú akátá Ṣọ́ọ̀ṣì jẹ́, a sún Bíbọ̀ Ẹlẹ́ẹ̀kejì náà síwájú di ọjọ́ ọ̀la tí ó jìnnà.”
Ọjọ́ Jèhófà àti Wíwàníhìn-ín Jésù
6. Èé ṣe tí kò fi yẹ kí a parí èrò sí pé ọjọ́ Jèhófà ṣì jìnnà réré?
6 Àṣìlóye ti yọrí sí ìjákulẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe jẹ́ kí a rò pé ọjọ́ Jèhófà ṣì jìnnà réré. Wíwàníhìn-ín Jésù láìṣeé fojú rí, tí Ìwé Mímọ́ so ó pọ̀ mọ́, ti bẹ̀rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti àwọn ìtẹ̀jáde tí ó tan mọ́n ọn tí ó jẹ́ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pèsè ẹ̀rí tí a gbé karí Ìwé Mímọ́ pé, wíwàníhìn-ín Kristi bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1914.a Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, kí ni Jésù sọ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀?
7. (a) Kí ni díẹ̀ nínú àwọn apá àmì wíwàníhìn-ín Jésù àti ti òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan? (b) Báwo ni a ṣe lè gbà wá là?
7 Wíwàníhìn-ín Jésù di kókó ọ̀rọ̀ ìjíròrò kété ṣáájú ikú rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbọ́ ohun tí ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù, àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti Áńdérù béèrè pé: “Nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:1-3; Máàkù 13:3, 4) Ní fífèsì, Jésù sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ogun, ìyàn, ìsẹ̀lẹ̀, àti àwọn apá mìíràn tí “àmì” wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ti ìparí ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ní. Ó tún wí pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a óò gbà là.” (Mátíù 24:13) A óò gbà wá là, bí a bá fi òtítọ́ fara dà á títí dé òpin ìwàláàyè wa ti ìsinsìnyí tàbí ti òpin ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan búburú ti ìsinsìnyí.
8. Ṣáájú òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù, kí ni a gbọ́dọ̀ ṣàṣeparí nígbà náà lọ́hùn-ún, kí sì ni a ti ṣe nípa èyí lónìí?
8 Kí òpin náà tó dé, apá kan tí ó ṣe pàtàkì gidigidi nínú wíwàníhìn-ín Jésù yóò nímùúṣẹ. Nípa rẹ̀, ó wí pé: “A óò sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Kí àwọn ará Róòmù tó pa Jerúsálẹ́mù àti ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù tí ó parí ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa run, Pọ́ọ̀lù lè sọ pé, ‘a ti wàásù ìhìn rere náà nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’ (Kólósè 1:23) Ṣùgbọ́n, lónìí, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù tí ó túbọ̀ gbòòrò sí i “ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” Ní àwọn ọdún díẹ̀ tí ó ti kọjá, Ọlọ́run ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún jíjẹ́rìí ńláǹlà ní Ìlà Oòrùn Europe. Pẹ̀lú ilé ìtẹ̀wé àti àwọn ilé lílò míràn tí ó wà kárí ayé, ètò àjọ Jèhófà ti gbára dì fún ìgbòkègbodò púpọ̀ sí i, àní ní “ìpínlẹ̀ tí a kò tí ì fọwọ́ kàn.” (Róòmù 15:22, 23) Ọkàn àyà rẹ ha sún ọ láti ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti jẹ́rìí fúnni ṣáájú kí òpin tó dé bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run lè fún ọ lókun láti nípìn-ín títẹ́nilọ́rùn nínú iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú.—Fílípì 4:13; Tímótì Kejì 4:17.
9. Àlàyé wo ni Jésù ṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Mátíù 24:36?
9 Iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba àti àwọn apá mìíràn nínú àmì wíwàníhìn-ín Jésù tí a sọ tẹ́lẹ̀ ti ń nímùúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Nítorí náà, òpin kù sí dẹ̀dẹ̀ fún ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí. Lóòótọ́, Jésù wí pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn kò sí ẹnì kan tí ó mọ̀, kì í ṣe àwọn áńgẹ́lì àwọn ọ̀run tàbí Ọmọkùnrin, bí kò ṣe Bàbá nìkan.” (Mátíù 24:4-14, 36) Ṣùgbọ́n, àsọtẹ́lẹ̀ Jésù lè ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní sẹpẹ́ fún “ọjọ́ àti wákàtí yẹn.”
Wọ́n Wà Ní Sẹpẹ́
10. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti wà lójúfò nípa tẹ̀mí?
10 Láti la ọjọ́ ńlá Jèhófà já, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí a sì dúró gbọn-in fún ìjọsìn tòótọ́. (Kọ́ríńtì Kíní 16:13) A mọ̀ pé irú ìfaradà bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe, nítorí ìdílé kan tí ó jẹ́ oníwà-bí-Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì la Ìkún Omi tí ó pa àwọn ẹ̀dá ènìyàn búburú run ní ọdún 2370 ṣááju Sànmánì Tiwa já. Ní fífi sànmánì yẹn wé wíwàníhìn-ín rẹ̀, Jésù wí pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọjọ́ Nóà ti rí, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí. Nítorí bí wọ́n ti wà ní àwọn ọjọ́ wọnnì ṣáájú ìkún omi, wọ́n ń jẹ wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ náà tí Nóà wọ inú ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni wíwàníhìn-ín Ọmọkùnrin ènìyàn yóò rí.”—Mátíù 24:37-39.
11. Ipa ọ̀nà wo ni Nóà tẹ̀ lé láìka ìwà ipá tí ó wà ní ọjọ́ rẹ̀ sí?
11 Gẹ́gẹ́ bíi tiwa, Nóà àti ìdílé rẹ̀ gbé nínú ayé oníwà ipá. Àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn tí wọ́n jẹ́ “ọmọ Ọlọ́run” ti para dà, wọ́n sì ti fẹ́ àwọn aya tí wọ́n tipasẹ̀ wọn di bàbá àwọn Néfílímù olókìkí—àwọn abúmọ́ni tí kò sí àníàní pé, wọ́n túbọ̀ mú kí ìwà ipá gbilẹ̀ sí i. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2, 4; Pétérù Kíní 3:19, 20) Ṣùgbọ́n, “Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn” nínú ìgbàgbọ́. Ó “fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí aláìlárìíwísí láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀”—ìran búburú ti ọjọ́ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:9-11, NW) Pẹ̀lú fífi àdúrà gbára lé Ọlọ́run, a lè ṣe ohun kan náà nínú ayé búburú àti oníwà ipá yìí, bí a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà.
12. (a) Yàtọ̀ sí kíkan áàkì, iṣẹ́ wo ni Nóà ṣe? (b) Báwo ni àwọn ènìyàn ṣe hùwà pa dà sí ìwàásù Nóà, kí sì ni ó yọrí sí fún wọn?
12 A mọ Nóà bí ẹni mowó gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó kan ọkọ̀ áàkì kan fún pípa ìwàláàyè mọ́ jálẹ̀ Àkúnya náà. Ó tún jẹ́ “oníwàásù òdodo,” ṣùgbọ́n àwọn alájọgbáyé rẹ̀ ‘kò fiyè sí’ ìhìn iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi fún un. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n ń bímọ, wọ́n sì ń bá àlámọ̀rí ìgbésí ayé lọ títí tí Ìkún Omi fi gbá gbogbo wọn lọ. (Pétérù Kejì 2:5; Jẹ́nẹ́sísì 6:14) Wọn kò fẹ́ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ àti ìwà tí ó tọ́, àní bí ìran búburú ti òde òní ṣe di etí rẹ̀ sí ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ nípa “ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run,” ìgbàgbọ́ nínú Kristi, òdodo, àti “ìdájọ́ tí ń bọ̀.” (Ìṣe 20:20, 21; 24:24, 25) Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nípa iye ènìyàn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Nóà polongo ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ohun kan dájú, iye olùgbé ayé dín kù jọjọ ní ọdún 2370 ṣááju Sànmánì Tiwa! Àkúnya náà gbá àwọn ẹni búburú kúrò, ní dídá kìkì àwọn tí wọ́n wà ní sẹpẹ́ fún ìgbésẹ̀ Ọlọ́run yẹn sí—Nóà àti àwọn méje mìíràn nínú ìdílé rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 7:19-23; Pétérù Kejì 3:5, 6.
13. Àṣẹ ìdájọ́ wo ni Nóà fi ìgbọ́kànlé pátápátá sínú rẹ̀, báwo sì ni ó ṣe hùwà ní ìbámu pẹ̀lú èyí?
13 Ọlọ́run kò sọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an tí Ìkún Omi náà yóò ṣẹlẹ̀ fún Nóà ṣáájú. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Nóà jẹ́ ẹni 480 ọdún, Jèhófà pàṣẹ pé: “Ẹ̀mí mi kì yóò fi ìgbà gbogbo bá ènìyàn jà, ẹran ara sáà ni òun pẹ̀lú: ọjọ́ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọgọ́fà ọdún.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:3) Nóà fi ìgbọ́kànlé pátápátá sínú àṣẹ ìdájọ́ àtọ̀runwá yìí. Lẹ́yìn tí ó di ẹni 500 ọdún, ó “bí Ṣémù, Hámù àti Jáfétì,” àṣà ayé ìgbàanì sì ni pé, àwọn ọmọkùnrin yóò ti lé ní 50 sí 60 ọdún kí wọ́n tó lè gbéyàwó. Nígbà tí a sọ fún Nóà láti kan áàkì fún ìpàwàláàyè-mọ́ jálẹ̀ Ìkún Omi, ó hàn gbangba pé, àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyẹn àti àwọn aya wọn ràn án lọ́wọ́ nínú akitiyan yẹn. Kíkan áàkì náà bọ́ sí àkókò kan náà pẹ̀lú iṣẹ́ ìsìn Nóà gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo,” ní mímú kí ọwọ́ rẹ̀ dí fún 40 sí 50 ọdún tí ó kẹ́yìn ṣáájú Ìkún Omi náà. (Jẹ́nẹ́sísì 5:32; 6:13-22) Fún gbogbo ọdún wọ̀nyẹn, òun àti ìdílé rẹ̀ fi ìgbàgbọ́ gbégbèésẹ̀. Ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú fi ìgbàgbọ́ hàn bí a ṣe ń wàásù ìhìn rere, tí a sì ń dúró de ọjọ́ Jèhófà.—Hébérù 11:7.
14. Kí ni Jèhófà sọ fún Nóà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, èé sì ti ṣe?
14 Bí áàkì náà ti ń parí lọ, Nóà ti lè máa ronú pé Ìkún Omi náà ti sún mọ́lé, bí òun kò tilẹ̀ mọ ọjọ́ náà pàtó tí yóò ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jèhófà sọ fún un pé: “Ní ọjọ́ méje sí i, èmi óò mú òjò rọ̀ sí ilẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ní ogójì òru.” (Jẹ́nẹ́sísì 7:4) Ìyẹn fún Nóà àti ìdílé rẹ̀ ní àkókò tí ó tó láti mú gbogbo onírúurú ẹranko wá sínú áàkì náà, kí àwọn pẹ̀lú sì wọ inú rẹ̀ kí Ìkún Omi tó bẹ̀rẹ̀. Kò pọn dandan fún wa láti mọ ọjọ́ àti wákàtí náà fún ìbẹ̀rẹ̀ ìparun ètò ìgbékalẹ̀ yí; a kò fi lílà á já àwọn ẹranko lé wa lọ́wọ́, àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí yóò sì ṣeé ṣe fún láti là á já ti ń wọnú áàkì ìṣàpẹẹrẹ náà nísinsìnyí, párádísè tẹ̀mí ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run.
“Ẹ Máa Bá A Nìṣó Ní Ṣíṣọ́nà”
15. (a) Ní ọ̀rọ̀ tìrẹ, báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Jésù tí a rí ní Mátíù 24:40-44? (b) Ipa wo ni ṣíṣàìmọ àkókò náà gan-an tí Jésù yóò wá láti mú ẹ̀san Ọlọ́run ṣẹ ní?
15 Nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀, Jésù ṣàlàyé pé: “Nígbà náà àwọn ọkùnrin méjì yóò wà [lẹ́nu iṣẹ́] nínú pápá: a óò mú ọ̀kan lọ a óò sì pa èkejì tì; awọn obìnrin méjì yóò máa lọ [ọkà di ìyẹ̀fun] lórí ọlọ ọlọ́wọ́: a óò mú ọ̀kan lọ a óò sì pa èkejì tì. Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ mọ ohun kan, pé ká ní baálé ilé mọ ìṣọ́ tí olè ń bọ̀ ni, òun ì bá wà lójúfò kì bá sì tí yọ̀ǹda kí a fọ́ ilé rẹ̀. Ní tìtorí èyí ẹ̀yin pẹ̀lú ẹ wà ní ìmúratán, nítorí pé ní wákàtí tí ẹ̀yin kò ronú pé yóò jẹ́, ni Ọmọkùnrin ènìyàn ń bọ̀.” (Mátíù 24:40-44; Lúùkù 17:34, 35) Ṣíṣàìmọ àkókò náà gan-an tí Jésù yóò wá láti mú ẹ̀san Ọlọ́run ṣẹ ń mú kí a wà lójúfò, ó sì ń fún wa ní àǹfààní ojoojúmọ́ láti fi hàn pé a ń fi ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.
16. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ‘tí a pa tì’ àti àwọn ‘tí a mú lọ’?
16 Olúkúlùkù ‘tí a pa tì’ fún ìparun pẹ̀lú àwọn ẹni búburú yóò ní àwọn tí a ti là lóye nígbà kan rí nínú, ṣùgbọ́n tí wọ́n ri ara wọn bọnú ọ̀nà ìgbésí ayé onímọtara-ẹni-nìkan. Ǹjẹ́ kí a lè wà lára àwọn tí ‘a mú lọ,’ àwọn tí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ pátápátá fún Jèhófà, tí wọ́n sì fi ìmoore tòótọ́ hàn fún àwọn ìpèsè tẹ̀mí rẹ̀ nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú.” (Mátíù 24:45-47) Títí dé òpin, ẹ jẹ́ kí a fi “ìfẹ́ láti inú ọkàn àyà tí ó mọ́ tónítóní àti láti inú ẹ̀rí ọkàn rere àti láti inú ìgbàgbọ́ láìsí àgàbàgebè,” ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run.—Tímótì Kíní 1:5.
Ìṣe Mímọ́ Ṣe Pàtàkì
17. (a) Kí ni a sọ tẹ́lẹ̀ ní Pétérù Kejì 3:10? (b) Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ìṣe tí Pétérù Kejì 3:11 fún níṣìírí?
17 Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a óò sì wá rí.” (Pétérù Kejì 3:10) Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ kò ní la ìgbóná janjan ìbínú Ọlọ́run tí ń jó fòfò já. Nítorí náà, Pétérù fi kún un pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run!” (Pétérù Kejì 3:11) Pípésẹ̀ déédéé sí àwọn ìpàdé Kristẹni, ṣíṣe ohun rere fún àwọn ẹlòmíràn, àti nínípìn-ín ti ó ṣe gúnmọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere wà lára àwọn ìṣe wọ̀nyí.—Mátíù 24:14; Hébérù 10:24, 25; 13:16.
18. Bí a bá ń mú ìsopọ̀ kan dàgbà pẹ̀lú ayé, kí ni ó yẹ kí a ṣe?
18 “Àwọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run” béèrè pé kí a ‘pa ara wa mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé.’ (Jákọ́bù 1:27) Ṣùgbọ́n bí a bá ń mú ìsopọ̀ pẹ̀lú ayé yìí dàgbà ńkọ́? Bóyá ti a ré wa lọ sínú ipò kan tí ó léwu lójú Ọlọ́run, nípa wíwá eré ìnàjú ẹlẹ́gbin tàbí nípa títẹ́tísí orin tí ń gbé ẹ̀mí àìṣèfẹ́ Ọlọ́run, tí ó jẹ́ ti ayé yìí lárugẹ. (Kọ́ríńtì Kejì 6:14-18) Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a wá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà, kí a má baà bá ayé lọ, ṣùgbọ́n kí a lè dúró bí ẹni ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn. (Lúùkù 21:34-36; Jòhánù Kíní 2:15-17) Bí a bá ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, dájúdájú, a óò fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti gbé ipò ìbátan wa pẹ̀lú rẹ̀ ró, kí a sì máa bá ipò ìbátan ọlọ́yàyà nìṣó pẹ̀lú rẹ̀, kí a lè tipa báyìí wà ní sẹpẹ́ fún ọjọ́ ńlá àti ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ti Jèhófà.
19. Èé ṣe tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùpòkìkí Ìjọba ṣe lè retí láti la òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ìsinsìnyí já?
19 Nóà oníwà-bí-Ọlọ́run àti ìdílé rẹ̀ la Ìkún Omi náà tí ó pa ayé ìgbàanì run já. Àwọn oníwà títọ́ la òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ti àwọn Júù já ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa. Fún àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Jòhánù ṣì ń bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní nǹkan bí ọdún 96 sí 98 Sànmánì Tiwa, nígbà tí ó kọ ìwé Ìṣípayá, àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀, àti lẹ́tà mẹ́ta mìíràn tí a mí sí. Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ tòótọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ la òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn Júù já. (Ìṣe 1:15; 2:41, 47; 4:4) Lónìí, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùpòkìkí Ìjọba ń retí láti wà láàyè la òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan burúkú yìí já.
20. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a jẹ́ “oníwàásù òdodo” tí ó jẹ́ onítara?
20 Pẹ̀lú ìpàwàláàyè-mọ́ wọnú ayé tuntun tí ó wà níwájú wa, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ onítara “oníwàásù òdodo.” Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti ṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí! Ẹ sì wo irú ìdùnnú tí ó jẹ́ láti darí àwọn ènìyàn sínú “áàkì” òde òní, párádísè tẹ̀mí tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń gbádùn! Ǹjẹ́ kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí wọ́n wà nínú rẹ̀ nísinsìnyí dúró bí olùṣòtítọ́, kí wọ́n wà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì wà ní sẹpẹ́ de ọjọ́ Jèhófà. Ṣùgbọ́n, kí ni yóò ran gbogbo wa lọ́wọ́ láti wà lójúfò?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí 10 àti 11 ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí a tẹ̀ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Àwọn ìfojúsọ́nà wo ni àwọn kan ti ní nípa ọjọ́ Jèhófà àti wíwàníhìn-ín Kristi?
◻ Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Nóà àti ìdílé rẹ̀ wà ní sẹpẹ́ fún Ìkún Omi náà?
◻ Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí “ń bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà” àti àwọn tí kò ṣe bẹ́ẹ̀?
◻ Èé ṣe tí àwọn ìṣe mímọ́ fi ṣe pàtàkì, ní pàtàkì, bí a ṣe ń sún mọ́ ọjọ́ ńlá Jèhófà?