ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 3/1 ojú ìwé 8
  • “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn Níwájú Àwọn Ènìyàn”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn Níwájú Àwọn Ènìyàn”
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Pé Jọpọ̀ “Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà Tí Ń Yin Jehofa Lógo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Iwa Ti O Ṣe Iṣẹ-ojiṣẹ Kristian Wa Lọ́ṣọ̀ọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 3/1 ojú ìwé 8

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

“Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn Níwájú Àwọn Ènìyàn”

NÍNÚ Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” Ó ń bá a lọ láti rọ̀ wọ́n pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín kí wọ́n sì lè fi ògo fún Bàbá yín tí ń bẹ ní àwọn ọ̀run.”—Mátíù 5:14-16.

Ní Ítálì, iṣẹ́ àtàtà Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lọ láìgbàfiyèsí. Fún àpẹẹrẹ, ìwà dáradára wọn nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí àwọn àpéjọpọ̀ wọn ọdọọdún máa ń mú ìyìn wá fún Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó tẹ̀ lé e yìí ti fi hàn:

▪ Fún ọ̀pọ̀ ọdún, obìnrin kan ní Terni, Ítálì, ran ọmọbìnrin rẹ̀ lọ́wọ́ láti bójú tó ilé àrójẹ rẹ̀ tí ó wà nítòsí pápá ìṣeré ní ìlú náà. Ó ròyìn pé: “Mo kíyè sí ìyàtọ̀ ńlá láàárín àwọn tí ó wá wòran bọ́ọ̀lù àti àwọn àyànṣaṣojú ní àpéjọpọ̀ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbẹ̀. Ìmúra Àwọn Ẹlẹ́rìí wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wọ́n sì jẹ́ aláìlábòsí àti ẹni tí ń bọ̀wọ̀ fúnni. Mo sábà máa ń bi ara mi, bí ó ṣe ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti inú onírúurú ẹ̀yà ìran láti wà nírẹ̀ẹ́pọ̀ dáradára bẹ́ẹ̀.

“Ní ọjọ́ kan, Ẹlẹ́rìí kan dá mi dúró ní òpópónà, ó sì béèrè bóyá mo mọ orúkọ Ọlọ́run. N kò mọ̀ ọ́n, níwọ̀n bí mo sì ti mọ̀ pé ènìyàn àtàtà ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo gbà pé kí ó ṣèbẹ̀wò sí ilé mi. Mo béèrè ìbéèrè nípa ipò àwọn òkú, èyí tí ó dáhùn láti inú Bíbélì. Kíákíá, mo tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí i lọ sí àwọn ìpàdé ní ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà.

“Lákọ̀ọ́kọ́, ọmọbìnrin mi ṣàtakò sí mi, ṣùgbọ́n ìwà àti ìpinnu mi yí ìṣarasíhùwà rẹ̀ pa dà. Mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ní oṣù mẹ́sàn-án sẹ́yìn. Lónìí, ọmọbìnrin mi àti ọkọ rẹ̀ máa ń sọ ọ̀rọ̀ onímọrírì sí Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ń wá sí ilé àrójẹ wọn. Ní ti èmi, mo ṣèrìbọmi ní àpéjọpọ̀ kan ní pápá ìṣeré yìí.”

▪ Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ kan ní Roseto degli Abruzzi, alábòójútó ọgbà ìpàgọ́ kan, sọ pé: “Mo ti kíyè sí i pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ aláìlábòsí nínú gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe. Ní ọ̀sẹ̀ tí ó kọjá, 40 lára wọn wá sí ọgbà ìpàgọ́ mi, wọn kò sì fún mi ní ìṣòro kankan rárá. Ní òdì kejì, àwọn nìkan ni yóò wá sọ fún ọ bí ẹnì kan bá kún wọn nínú ọkọ̀ onílé àgbérìn tàbí àgọ́ wọn. Ní ti èmi, àwọn ni oníbàárà tí ó dára jù lọ tí o lè ní.”

▪ Lẹ́yìn àpéjọpọ̀ kan náà, alábòójútó hòtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé: “Ènìyàn àlàáfíà ni gbogbo Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọn kì í ṣe aláriwo, wọ́n sì tètè máa ń lọ sùn. Onínúure, aláìlábòsí, àti ọmọlúwàbí ènìyàn ni wọ́n ní tòótọ́. Nǹkan ì bá dára ká ní gbogbo ènìyàn dà bíi wọn. Àwọn ènìyàn yòó kù máa ń jí ohun gbogbo—àwo òdòdó, àwo eérú sìgá, àní bébà àfinùdí àti ṣúgà pàápàá! A ò tí ì nírìírí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú yín rí. Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá mú ice cream láti inú fìríìjì, ní ìrọ̀lẹ́, èmi kì í wulẹ̀ lọ wo ohun tí wọ́n mú. Wọ́n máa ń ṣí iye owó tí wọ́n jẹ mí, wọ́n a sì wá san án fún mi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn gidigidi. Ẹ wo bí nǹkan ì bá ti dára tó ká ní àwọn yòó kù rí báyẹn! Mo dàníyàn pé kí gbogbo àwọn àlejò mi jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

A mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáradára ní Ítálì, gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wọ́n ní ọ̀pọ̀ ibòmíràn nínú ayé. Wọ́n ‘ń tọ́jú ìwà wọn kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,’ wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú ìyìn wá fún Ọlọ́run tòótọ́ náà, tí wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́.—Pétérù Kíní 2:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́