ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/01 ojú ìwé 4
  • A Pé Jọpọ̀ “Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Pé Jọpọ̀ “Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1996
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1997
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2006
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2008 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 9/01 ojú ìwé 4

A Pé Jọpọ̀ “Lọ́nà Tí Ó Bójú Mu àti Nípa Ìṣètò”

1 Kí àpéjọpọ̀ àgbègbè kan tó lè kẹ́sẹ járí, ọ̀pọ̀ ìsapá ni a ní láti pawọ́ pọ̀ ṣe. Ẹ̀ka tó ń bójú tó àpéjọpọ̀ máa ń ṣètò ibi yíyẹ fún ìpàdé àti ilé gbígbé. Ẹnì kọ̀ọ̀kan àti àwọn ìdílé yóò wéwèé ìrìn àjò wọn. Ìjọ yóò sì ṣe kòkáárí àwọn tí yóò yọ̀ǹda ara wọn látinú ìjọ láti ṣiṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ẹ̀ka tí yóò wà ní àpéjọpọ̀. Ohun tí a ń lépa ni pé kí “ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.

2 Bí o ti ń jẹ́ kí ìsapá rẹ bá ti ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó àpéjọpọ̀ mu, fi sọ́kàn pé ìmúrasílẹ̀ tí a ń fẹ́ yìí máa ń gba ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọ̀pọ̀ ọdún nígbà mìíràn. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn arákùnrin máa ń lo àkókò wọn láti ṣètò àwọn nǹkan. Lára nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe ni, kíkó àwọn ohun èèlò jọ àti wíwá àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni. Ìmúrasílẹ̀ ṣáájú yìí máa ń mú ìbùkún tẹ̀mí bá gbogbo èèyàn. Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́?

3 Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Ìṣètò Ilé Gbígbé: Ó ṣe kókó pé kí gbogbo wa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tí a ṣe fún àpéjọpọ̀. Èyí túbọ̀ pọndandan bó bá lọ jẹ́ pé àwa fúnra wa ló ṣètò ibi táa máa dé sí. Ní ti gidi, ọgọ́rọ̀ọ̀rún iyàrá la nílò fún àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará wa ni kò fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ilé olówó pọ́ọ́kú ni wọ́n sì ń wá. A ti sapá gidigidi láti wá àwọn iyàrá olówó pọ́ọ́kú táa lè rí. A gbọ́dọ̀ fìfẹ́ gba àìní àwọn ẹlòmíràn rò kí a sì ‘má ṣe máa mójú tó ire ara wa nìkan, ṣùgbọ́n kí á máa mójú tó ire àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’—Fílí. 2:4.

4 Títẹ̀ lé àwọn ìlànà àpéjọpọ̀ fún gbígba iyàrá máa ń ṣàǹfààní fún gbogbo àwọn tọ́ràn kàn. Ṣíṣàìnáání àwọn ìlànà yìí máa ń fa ìṣòro tí kì bá tí ṣẹlẹ̀. Lọ́nà wo? Nígbà tí a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn àbá wọ̀nyí, àwọn onílé yóò ti mọ iye ilé tí a ti gbà sílẹ̀. Èyí máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwéwèé wọn, ó sì lè mú kí owó ilé túbọ̀ dín kù lọ́jọ́ iwájú. Bí ọ̀pọ̀ lára wa bá fagi lé orúkọ táa ti fi sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ fún ilé gbígbé tàbí bí a bá lọ ṣe ètò mìíràn, èyí máa ń fa ìnira fún àwọn onílé àti àwọn ará wa tó jẹ́ pé àwọn náà ti lè fẹ́ dé sí ilé náà tẹ́lẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí irú àwọn onílé bẹ́ẹ̀ má yọ̀ǹda iyàrá púpọ̀ fún wa mọ́ ní àwọn àpéjọpọ̀ tí ń bọ̀, wọ́n lè máa ronú pé a ò ní pa àdéhùn wa mọ́. Ó mà dára o bí a kì í bá yẹ àdéhùn tí a ti ṣe, kí á jẹ́ kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni wa túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni’!—Mát. 5:37.

5 Ṣàyẹ̀wò Àwọn Àbájáde Rere Yìí: Lẹ́yìn tí àpéjọpọ̀ kan parí, olùdarí ibì kan táwọn àlejò máa ń dé sí sọ pé: “Mo ti kíyè sí i pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe. Lọ́sẹ̀ tó kọjá, ogójì wọn ló dé sí ọ̀dọ̀ mi, wọn kò sì fa wàhálà kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn nìkan ló máa ń wá sọ bó bá jẹ́ pé ẹlòmíràn tún wá dara pọ̀ mọ́ wọn nínú [ibi tí wọ́n dé sí]. Lójú tèmi o, àwọn ni oníbàárà tó dára jù lọ.” Ohun àgbàyanu ni yóò mà jẹ́ o bó bá jẹ́ pé báyìí lọ̀rọ̀ á ṣe rí lára gbogbo àwọn tí ń fi ilé wọn háyà fún wa! Ẹ̀rí ńláǹlà mà nìyẹn yóò jẹ́ o!

6 Olùdarí ẹlẹ́kùnjẹkùn fún òtẹ́ẹ̀lì kan sọ pé: “Mi ò lè rántí pé mo tíì rí irú àwùjọ ńlá bẹ́ẹ̀ rí bíi ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọ́n fi ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ṣèwà hù. A retí pé ẹ óò tún padà wá.” Gbólóhùn yìí fi hàn pé kì í ṣe àwa nìkan ni ìwà rere máa ń fà mọ́ra, ṣùgbọ́n ó tún ń fa ọ̀pọ̀ tó ń wò wá nínú ayé mọ́ra.

7 Àwọn Ọ̀nà Pàtàkì Tí A Lè Gbà Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀: Àwọn ohun kéékèèké wà táa lè ṣe láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tí a ṣe fún àpéjọpọ̀ nípa ilé gbígbé. (1) Má ṣe wá ilé mìíràn bí o bá ti fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé sílẹ̀. (2) Kí àwọn òbí bójú tó àwọn ọmọ wọn kí wọ́n má bàa hùwà ewèlè. (3) Bí onílé kò bá fàyè gba síse oúnjẹ nínú iyàrá, a kò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. (4) Rántí pé àwọn onílé àti àwọn tó ní òtẹ́ẹ̀lì retí pé ká pa òfin àwọn mọ́, ẹ̀tọ́ wọn sì nìyẹn.

8 Bí a ti jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, a láǹfààní láti máa gbé ànímọ́ rẹ̀ yọ nínú gbogbo ohun tí a bá ṣe. Èyí kan ṣíṣètò fún àpéjọpọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run àti lílọ síbẹ̀. Rántí pé, òun “kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.” (1 Kọ́r. 14:33) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a óò jẹ́ kí àwọn tó ń wò wá fòye mọ àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní yìí látinú ohun tí wọ́n bá rí lára wa, ìyẹn ìwà wa àti ìṣesí wa bí a ti ń wéwèé fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” àti nígbà tí a bá lọ. Ǹjẹ́ kí àwọn olóòótọ́ ọkàn tó ń wò wá rí i pé àpéjọpọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́ èyí tí a ṣe “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—Sm. 68:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́