Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti Ọdún 2006
1. Báwo làwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ ṣe fi ìmọrírì wọn hàn fún ìjọsìn tòótọ́, àǹfààní wo làwa náà ní lónìí tó jọ ìyẹn?
1 Àwọn sárésáré ni Hesekáyà Ọba Júdà ìgbàanì rán láti lọ fún àwọn èèyàn ní lẹ́tà pé kí wọ́n wá síbi àpéjọ ní Jerúsálẹ́mù. (2 Kíró. 30:6, 13) Báwọn èèyàn náà ṣe jẹ́ ìpè Ọba fi hàn pé ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú ìjọsìn tòótọ́. (2 Kíró. 30:10-12) Bákan náà, láwọn oṣù tó ń bọ̀ láìpẹ́, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tòde òní yóò nírú àǹfààní táwọn ará ìgbàanì ní láti fi hàn báwọn náà ṣe mọyì ìkésíni àkànṣe láti pé jọ kí wọ́n sì jọ́sìn Jèhófà. A ti fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí ìjọ yín láti pè yín sí Àpéjọ Àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” Ṣé ẹ máa wá síbẹ̀?
2. Kí la lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí ká bàa lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ látinú àpéjọ náà?
2 Bẹ̀rẹ̀ sí Í Múra Sílẹ̀ Nísinsìnyí: Ká bàa lè jàǹfààní ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tá a ti fìfẹ́ pèsè sílẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, kò yẹ ká pa ọjọ́ kankan jẹ nínú gbogbo ọjọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ó bọ́gbọ́n mu pé kó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe gbogbo ètò tó máa lè jẹ́ kíwọ àti ìdílé rẹ lè pésẹ̀ síbẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. (Òwe 21:5) Àwọn ìṣètò bẹ́ẹ̀ lè kan títọrọ ààyè lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ, bíbá ọkọ tàbí aya rẹ tí kì í ṣe Kristẹni sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ṣíṣètò ibi tó o máa dé sí, gbígba yàrá sí òtẹ́ẹ̀lì àti ríran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Má ṣe dúró dìgbà tọ́jọ́ bá ti sún mọ́ tán. Kàkà bẹ́ẹ̀, fi sínú àdúrà sí Jèhófà pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé ‘òun yóò gbé ìgbésẹ̀.’—Sm. 37:5.
3. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò tó wà nílẹ̀ nípa ilé gbígbé?
3 Ètò Jèhófà ti ṣe gudugudu méje láti rí i pé ilé tó pọ̀ tó wà láti dé sí ní gbogbo ìlú tá a ti máa ṣe àpéjọ. Bá a bá mọrírì ìsapá àwọn akíkanjú arákùnrin tó yọ̀ǹda ara wọn tọkàntọkàn láti ṣètò ilé gbígbé yìí, tá a gba tàwọn ará bíi tiwa tó ń bọ̀ wá sí àpéjọ náà rò, tá a sì bọ̀wọ̀ fún ìṣètò tó bá ìlànà Ọlọ́run mu yìí, ó yẹ ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípa títẹ̀ lé àwọn ìlànà tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.—1 Kọ́r. 13:5; 1 Tẹs. 5:12, 13; Héb. 13:17.
4. Àwọn kókó pàtàkì wo ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń béèrè fún ilé tá a máa dé sí, kí sì nìdí? (Fi àpótí tó wà lójú ìwé 4 kún un.)
4 Ilé Gbígbé: Kó bàa lè rọrùn fún ọ, a ó ṣètò ibi tó o máa wọ̀ sí ní ìlú tá a ó ti ṣe àpéjọ náà. Lọ́pọ̀ àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí, a ó ṣètò ilé gbígbé sínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Èyí lè jẹ́ ilé tá a kàn fẹ́ lò fún ìgbà díẹ̀ tàbí èyí tá a dìídì kọ́ káwọn ará lè máa ríbi dé sí. Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé ètò Ọlọ́run ò ní lè kọ́lé tó máa gba gbogbo èèyàn tó bá wá sí àpéjọ kan. Kìkì àwọn tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ló máa lè sùn sínú ilé tá a kọ́ sínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Síbẹ̀, látàrí bí àbójútó àwọn ilé náà ṣe ń náni lówó gegere, à ń rọ àwọn tó bá wọ̀ sínú àwọn ilé náà láti fi owó ṣètìlẹ́yìn látọkànwá fún àǹfààní tí wọ́n ní láti sùn nínú ọgbà náà. Bó bá jẹ́ pé ibòmíì ni wọ́n fi ọ́ wọ̀ sí, jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó o sì wà níbi tí wọ́n fi ọ́ wọ̀ sí. Tó bá jẹ́ pé ṣe lo fẹ́ máa wọkọ̀ lọ wọkọ̀ bọ̀ sí ibi àpéjọ náà lójoojúmọ́, rántí pé ìnáwó kan nìyẹn náà. Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń tọ́jú owó tó o máa lò ní àpéjọ, ó ṣe pàtàkì kó o fìyẹn náà kún un. (1 Kọ́r. 16:1-4; 2 Kọ́r. 9:7) Kó o tó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, gbé àwọn kókó tó wà nínú àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Gbígbé,” yẹ̀ wò.
5, 6. Báwo la ṣe lè bójú tó àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó?
5 Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó: Òwe 3:27 sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” Báwo lo ṣe lè máa ṣe ohun rere fáwọn ẹlòmíràn lásìkò àpéjọ? Àwọn akéde tó ti dàgbà, àwọn aláìlera, àwọn tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àtàwọn mìíràn lè nílò ìrànlọ́wọ́ nípa bí wọ́n ṣe máa wọkọ̀ lọ síbẹ̀ tàbí nípa ibi tí wọ́n máa dé sí. Ojúṣe mọ̀lẹ́bí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni láti bójú tó wọn. (1 Tím. 5:4) Àmọ́, bí wọn ò bá wá lè ṣe é, ó ṣeé ṣe káwọn ará ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gál. 6:10) Kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wo àwọn tó wà nínú àwùjọ rẹ̀ láti lè mọ àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, kó sì rí i pé ìṣètò ti wà ní sẹpẹ́ fún wọn ṣáájú àkókò àpéjọ àgbègbè náà.
6 Kìkì àwọn akéde tó nílò àbójútó nítorí pé ó máa ń ṣòro fún wọn láti ríbi dé sí, tí ìdílé wọn tàbí ìjọ ò sì lágbára láti ṣèrànwọ́ nìkan ni kó kọ ọ̀rọ̀ sínú apá tó wà fún àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, ìyẹn “Special Needs,” nínú fọ́ọ̀mù Room Request Form. Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ yẹ àwọn akéde tí wọ́n bá máa fún ní fọ́ọ̀mù náà wò kí wọ́n rí i pé wọ́n kúnjú òṣùwọ̀n níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó wà nínú fọ́ọ̀mù náà. Àwọn akéde tó ní orúkọ rere nínú ìjọ àtàwọn ọmọ wọn tó mọ̀wàá hù nìkan ni ìṣètò yìí wà fún.
7. (a) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé àpéjọ tí wọ́n yan ìjọ wa sí la gbọ́dọ̀ lọ? (b) Àwọn ìgbésẹ̀ wo la gbọ́dọ̀ gbé bó bá pọn dandan pé a máa lọ sí àpéjọ tó yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n yan ìjọ wa sí?
7 Lílọ sí Àpéjọ Mìíràn: Kí ìṣètò tá a ṣe nípa ìjókòó, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ibùgbé, àtàwọn nǹkan míì lè gún régé, à ń rọ̀ ọ́ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a yan ìjọ rẹ sí. Ṣùgbọ́n bí o bá ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ kan tó yàtọ̀ sí èyí tá a yan ìjọ rẹ sí, jọ̀wọ́ rí akọ̀wé ìjọ rẹ kó lè fún ọ ní àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ tó o fẹ́ lọ náà, èyí tá a tẹ̀ sẹ́yìn fọ́ọ̀mù àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, ìyẹn Room Request Form. Tó bá jẹ́ pé àpéjọ tí wọ́n á ṣe níbẹ̀ ju ẹyọ kan lọ, rí i pé o kọ déètì àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ sínú fọ́ọ̀mù náà.
8. Ọ̀nà wo la lè gbà fi kún ayọ̀ àpéjọ tó ń bọ̀ yìí?
8 A Nílò Àwọn Tó Lè Fínnúfíndọ̀ Yọ̀ǹda Ara Wọn: Kò sí tàbí-ṣùgbọ́n pé gbogbo àwọn tó bá wà ní àpéjọ ọdún yìí ni inú wọ́n á dùn tí wọ́n á sì jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó dà bí oúnjẹ tẹ̀mí náà àti pé wọ́n á gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ tí ń gbéni ró. Inú wa á túbọ̀ dùn bá a bá yọ̀ǹda ara wa láti ṣèrànwọ́ láti ṣe àwọn iṣẹ́ tó bá yẹ ní ṣíṣe, kí àpéjọ náà bàa lè máa lọ bó ṣe yẹ kó lọ. (Ìṣe 20:35) Ìgbìmọ̀ Àpéjọ ti ọ̀dọ̀ yín máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í pè yín láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà. Ṣé o lè yọ̀ǹda ara rẹ?—Sm. 110:3.
9. Kí ló wù ẹ́ nínú àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, kí sì ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpinnu rẹ?
9 Nígbà tí ọmọdékùnrin ọlọ́dún márùn-ún kan wà ní àpéjọ àgbègbè, ó sọ pé: “Àpéjọ àgbègbè ni ohun tó wù mí jù nínú ìjọsìn Jèhófà.” Ọ̀rọ̀ tó tọkàn wá tí ọmọdékùnrin yẹn sọ jẹ́ ká rí bá a ṣe máa ń gbádùn wíwà ní àpéjọ àgbègbè wa tó lọ́dọọdún. Bí onísáàmù ṣe sọ ọ́ gan-an ló rí pé: “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn.” (Sm. 84:10) Dáfídì sọ èrò rẹ̀ jáde pé ṣe lòun fẹ́ ‘máa gbé inú ilé Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé òun kí òun bàa lè máa fi ìmọrírì hàn fún tẹ́ńpìlì Jèhófà.’ (Sm. 27:4) Ó dùn mọ́ Dáfídì gidigidi pé òun wà lára àwọn olùjọsìn Jèhófà. Ǹjẹ́ káwa náà fara wé ọ̀nà tó gbà mọrírì ìjọsìn tòótọ́ nípa wíwà ní àpéjọ àgbègbè “Ìdáǹdè Kù sí Dẹ̀dẹ̀!” lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday 9:20 àárọ̀ sí 4:55 ìrọ̀lẹ́
Saturday 9:00 àárọ̀ sí 4:05 ìrọ̀lẹ́
Sunday 9:00 àárọ̀ sí 3:40 ìrọ̀lẹ́
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Gbígbé
1. Gba fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ rẹ.
2. Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lásìkò. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o kọ ìsọfúnni náà lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, ìyẹn ìsọfúnni bí orúkọ, ọjọ́ orí rẹ, bóyá o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin àti bóyá aṣáájú-ọ̀nà ni ọ́ tàbí akéde ìjọ.
3. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé ìsọfúnni inú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé péye kó sì fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní ìlú tí àpéjọ náà yóò ti wáyé. MÁ ṢE FI RÁNṢẸ́ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó pẹ́ kó tó dọ́wọ́ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé tó bá jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí.
4. Má ṣe sọ fún onílé pé wàá san owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ nítorí kó o lè rí ilé gbà.
5. Nígbà tó o bá ń ṣètò ilé tó o má wọ̀ sí fúnra rẹ, dákun kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà ni ìwọ náà tún fẹ́ gbà.
Jọ̀wọ́
◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ọ́ sí tẹ́ ọ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tó wà nínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá fi ọ́ síbẹ̀. Iye ẹ̀yin tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ni kẹ́ ẹ jọ wà nínú ilé náà.
◼ Má ṣe débi tí ẹni tó ni ilé tí wọ́n bá fi ẹ́ wọ̀ sí ò bá fẹ́ kó o dé. Bí onílé bá gbà pé o lè dáná ni kó o tó dáná, kó sì jẹ́ níbi tó bá ti ní kó o dáná.
◼ Rí i pé o tètè fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ìyẹn ló máa jẹ́ kí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lè ní àsìkò tó pọ̀ tó láti wá ilé tó bójú mu fún ọ.
◼ Jẹ́ kí ìsọfúnni tó o máa kọ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé gún régé, kó sì ṣeé kà.