Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóó Ṣe ní Ọdún 2002
1 “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’” (Sm. 122:1) Bó o ti ń ronú lórí gbólóhùn tí onísáàmù sọ yìí, kíyè sí (1) bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n ké sí i pé kó wá dara pọ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà, (2) àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rere tó ní, táwọn náà nífẹ̀ẹ́ sí ìjọsìn tòótọ́ látọkànwá, àti (3) àwọn ìmúrasílẹ̀ tí wọ́n ti ní láti ṣe láti rí i pé àwọn ké sí àwọn ẹlòmíràn, láti kóra jọ pọ̀, kí wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí ilé Ọlọ́run.
2 Ǹjẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù yìí kò fi bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa hàn nígbà tá a bá gbọ́ pé ètò ti ń lọ lọ́wọ́ fún àpéjọ àgbègbè wa mìíràn? Ńṣe ló máa ń dà bíi pé kí ọjọ́ àpéjọ náà ti dé bá a ti ń rántí àwọn ohun tá a gbádùn nínú àwọn tá a ti ṣe kọjá, tá a sì ń wọ̀nà fún àkànṣe ìkórajọpọ̀ mìíràn pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. A ti ṣètò Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run,” tí yóò gba ọjọ́ mẹ́ta gbáko, jákèjádò Nàìjíríà lọ́dún 2002 àti 2003. Ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká ti bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ láti wà níbẹ̀ ká lè jàǹfààní àsè tẹ̀mí tó ń dúró dè wá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
3 “Olóòótọ́ ìríjú náà, ẹni tí í ṣe olóye,” ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó bá àkókò mu tá a máa gbádùn ní àpéjọ náà sílẹ̀. (Lúùkù 12:42) A ti yan ìjọ kọ̀ọ̀kan sí àpéjọ tí wọ́n máa lọ kí èrò má bàa pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ ní ilẹ̀ àpéjọ kọ̀ọ̀kan. Láfikún sí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò onírúurú ẹ̀ka tó máa wà ní àpéjọ náà kí “ohun gbogbo [lè] ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.” (1 Kọ́r. 14:40) Bí ọ̀pọ̀ nǹkan ti ṣe wà ní sẹpẹ́ báyìí ká bàa lè jàǹfààní kí nǹkan sì rọ̀ wá lọ́rùn, kí làwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè ṣe láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà?
4 Múra sílẹ̀ Nísinsìnyí Láti Wà Níbẹ̀ Lọ́jọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: Ṣé ó máa béèrè pé kó o tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ kó o bàa lè lọ sí àpéjọ tí a yàn ọ́ sí? Jèhófà mọ̀ pé àwọn ọ̀gá kan wà tó “ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn.” (1 Pét. 2:18) Àmọ́ àwọn àpéjọ wa ṣe pàtàkì gan-an ni, a sì fẹ́ ṣe gbogbo ohun tí a bá lè ṣe láti wà níbẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nínú àdúrà nípa ọ̀ràn yìí, ní kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè wà níbẹ̀.—Neh. 2:4.
5 Máa Fi Owó Ti Wà Á Lò fún Àpéjọ Náà Pa Mọ́: Láfikún sí àwọn ètò tó kù, ÌSINSÌNYÍ gan-an ni àkókò láti bẹ̀rẹ̀ sí í fowó pa mọ́ fún lílò ní àpéjọ àgbègbè náà. Ibi táwọn kan ń gbé jìnnà gan-an sí ibi tí àpéjọ náà ti máa wáyé. Bákan náà, onídìílé ńlá làwọn kan. Àwọn ẹni yìí, àti gbogbo wa lápapọ̀, nílò owó tá a máa fi ṣètọrẹ, èyí tá a máa fi wọkọ̀, èyí tá a máa fi ra oúnjẹ nígbà àpéjọ àgbègbè, àti èyí tá a máa fi ṣe àwọn ohun mìíràn tí a kò ronú tẹ́lẹ̀. Ó yẹ káwọn tó ní ìdílé ńlá wéwèé ṣáájú, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú owó tí ó máa tó wọn kó bàa lè ṣeé ṣe fún gbogbo ìdílé wọn láti lọ sí àpéjọ náà. Ohun kan tẹ́ ẹ lè ṣe ni pé kẹ́ ẹ kọ́kọ́ fojú díwọ̀n àròpọ̀ iye owó tẹ́ ẹ máa ná. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìṣirò yìí, á dáa kẹ́ ẹ ro ti pé owó àwọn nǹkan lè lọ sókè mọ́ ọn. Lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ wá pín iye owó náà sí iye oṣù tó wà láàárín ìsinsìnyí àtìgbà tẹ́ ẹ máa ṣe àpéjọ àgbègbè yín. Iye owó yẹn ni kí ẹ máa fi pa mọ́ lóṣooṣù. Ní oṣù kọ̀ọ̀kan, ẹ má gbàgbé láti kọ́kọ́ yọ iye yìí sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí owó àpéjọ àgbègbè. Ẹ lè máa fi sínú àpótí kan tàbí sínú àpòòwé. Síbẹ̀, ẹ tún lè pín owó tẹ́ ẹ̀ ń fi pa mọ́ lóṣooṣù yìí sọ́nà mẹ́rin kẹ́ ẹ sì máa yọ ọ́ sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Kókó tó wà níbẹ̀ ni pé, má ṣe jẹ́ kó dìgbà tó bá ku oṣù kan tàbí oṣù méjì kí àpéjọ náà dé kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í wá owó láti lọ sí ìrìn-àjò ọdọọdún tá a máa ń lọ yìí.—Òwe 21:5.
6 Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Gbígbé: A óò sapá láti pèsè iye fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé tó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ìsọfúnni tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé kọ̀ọ̀kan táwọn ará bá fi sílẹ̀. MÁ ṢE kọ kìkì iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé gbígbé, irú bíi “50 akéde,” sí àlàfo tó yẹ ká kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. Gbogbo ìsọfúnni ni kí a kọ nigín-nigín lọ́nà tó máa ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè ìsọfúnni kíkún ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni tí ń béèrè fún ilé gbígbé jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Kọ orúkọ àwọn ọmọ síbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà kan rí, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà làwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kó ṣòro láti ṣètò ilé gbígbé tí ó tó. Bí ẹ bá nílò àyè sí i ju àlàfo tó wà lórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ lo abala ìwé mìíràn. Bí ẹ bá kọ ju orúkọ ẹnì kan lọ sórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ bí wọ́n ṣe bára tan sí àlàfo tí a pèsè fún ìyẹn. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́nà pípéye ṣáájú kó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọ àgbègbè. Kí akọ̀wé tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ ṣáájú ìgbà àpéjọ. JỌ̀WỌ́ MÁ ṢE fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ránṣẹ́ sí Society. Àdírẹ́sì ilẹ̀ àpéjọ tá a yan ìjọ yín sí, èyí tá a fi hàn ní òdìkejì fọ́ọ̀mù náà ni kí ẹ fi ránṣẹ́ sí.
7 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọ àgbègbè. Ó kéré tán, ohun méjì ni èyí ń mú kó ṣeé ṣe nígbà tá a bá kọbi ara sí ìtọ́sọ́nà yìí, àwọn nìyí:
8 À ń dín ìnáwó àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kù: Nígbà tá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society, ó máa ń dín àwọn ará wa ní owó ilé kù. Dípò kí àṣẹ́kù owó wa máa bọ́ sápò àwọn onílé, a lè lò ó lọ́nà tó sàn jù láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àti fún iṣẹ́ wa kárí ayé. Kódà bí àwa fúnra wa bá tilẹ̀ lágbára àtigba àwọn ilé tó gbówó lórí pàápàá, ńṣe ló yẹ ká gbárùkù ti ìsapá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹ̀mí níní àníyàn fún àwọn ẹlòmíràn yìí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 1 Jòhánù 3:17, kókó yẹn náà sì ni 1 Kọ́ríńtì 10:24 ń sọ.
9 À ń ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Society: Ó yẹ kí kókó yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlànà pàtàkì tó yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà gbogbo. Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” Bí àwọn arákùnrin wa ti ń ṣètò ní ọ̀kan-kò-jọ̀kan fún àpéjọ àgbègbè wa, a fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé à ń tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkún. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kìkì ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta péré láàárín ọdún kan la máa ń béèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀nà dáadáa kan lèyí jẹ́ láti ti ìsapá wọn lẹ́yìn. Àní bí kì í bá tiẹ̀ ṣe ohun tá a fẹ́ ni wọ́n pèsè fún wa, àpẹẹrẹ rere wa, táwọn arákùnrin wa àtàwọn èèyàn ayé ń rí, ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìtìlẹ́yìn lárugẹ.—Fílí. 2:1-4.
10 Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó: Kìkì àwọn tó ń fẹ́ àkànṣe ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ àgbègbè nìkan ni ìṣètò yìí wà fún, pàápàá jù lọ ètò ilé gbígbé. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, ó sinmi lórí bí ipò kálukú wọn bá ṣe rí. Àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó nìkan ni ìṣètò Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó, wà fún, títí kan àwọn ọmọ wọn tó mọ̀wàá hù. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ní láti fọwọ́ sí i kí wọ́n tó lè rí ìrànwọ́ náà gbà. Ìjọ tí àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó ń dara pọ̀ mọ́ ni kó ṣe àwọn ètò mìíràn láti fi bójú tó wọn dípò tí wọ́n á fi ti ojúṣe yìí sí àwọn tí ń ṣètò àpéjọ àgbègbè. Àwọn alàgbà àtàwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa ipò ẹni náà lè fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣèrànwọ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde mọ ohun tí àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera àti bóyá àwọn mìíràn nílò. Àwọn akéde lè ṣèrànwọ́ nípa mímú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójútó ohun tí wọ́n nílò láwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Ják. 2:15-17; 1 Jòh. 3:17, 18.
11 Àmọ́ ṣá o, Ẹ̀ka Tí Ǹ Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò sakun láti pèsè àwọn iyàrá tó bójú mu fáwọn akéde tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó bí àwọn tó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ sọ̀rọ̀ nípa ipò wọn. Kí akọ̀wé bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó iyàrá wọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn tí wọ́n ń fẹ́, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, kí ó wá fi lẹ́tà gàdàgbà kọ ọ̀rọ̀ náà, “ÀWỌN TÓ NÍLÒ ÀKÀNṢE ÀBÓJÚTÓ” sí apá òkè ojú ìwé àkọ́kọ́ fọ́ọ̀mù náà. Àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó nìkan ni kó kọ ìsọfúnni sínú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí o. Fúnra ẹni tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ náà ni kó sì kọ ìsọfúnni sínú rẹ̀. Kí ó dá a padà fún akọ̀wé, ẹni tí yóò rí sí i pé a ti kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni sínú rẹ̀, àti pé ìsọfúnni náà péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú nípa àwọn ipò tó mú ẹni náà tóótun fún irú ìṣètò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢE KÚLẸ̀KÚLẸ̀ ÀLÀYÉ nípa àwọn ipò náà sínú àlàfo tó wà ní òdìkejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí la ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àpéjọ àgbègbè náà. Lẹ́yìn èyí ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹ̀ka yìí á wá dá èsì padà fún ẹni tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ náà ní tààràtà nípa ọ̀ràn ilé gbígbé náà.
12 Àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó KÒ GBỌ́DỌ̀ lọ béèrè fún iyàrá nígbà tí wọ́n bá dé ọ̀hún, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
13 Ọ̀pọ̀ ti sọ pé àwọn mọrírì ètò tí a máa ń ṣe fún ilé gbígbé nígbà àpéjọ àgbègbè. Ṣé ìwọ náà kún fún ìmoore fún ọ̀pọ̀ ètò tí à ń ṣe nítorí rẹ? Ó jẹ́ ayọ̀ Society láti máa pèsè àwọn ilé gbígbé tó máa tuni lára, tí kò sì wọ́n nígbà àpéjọ àgbègbè, èyí tó ń mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí àpéjọ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní.
14 Lílọ sí Àpéjọ Mìíràn: Àpéjọ tó sún mọ́ ìjọ kọ̀ọ̀kan jù lọ la yàn wọ́n sí. Iye àwọn akéde tí a yàn sí àpéjọ àgbègbè kọ̀ọ̀kan ni Society fi ń díwọ̀n iye ènìyàn tó máa wá kí wọ́n lè ṣètò àwọn nǹkan bí ìjókòó, ilé gbígbé, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn nǹkan mìíràn, tó máa pọ̀ tó. Ṣùgbọ́n bí o bá nídìí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ kan tó yàtọ̀ sí èyí tí a yàn ọ́ sí, tí o sì ń fẹ́ ilé gbígbé, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. O lè kọ ìsọfúnni sínú rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọ àgbègbè tí o fẹ́ láti lọ.
15 Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Rẹ: Nígbà àpéjọ, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni máa ń ṣèrànwọ́ lóríṣiríṣi ẹ̀ka kí gbogbo nǹkan lè lọ bó ṣe yẹ. Àwọn olùtọ́jú èrò tó máa ń wà ní gbọ̀ngàn àpéjọ àti láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí máa ń pèsè ìtọ́sọ́nà fún wa nípa ọ̀ràn ìjókòó, wọ́n sì máa ń bá wa ṣọ́ àwọn ọkọ̀ wa nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Àǹfààní ló jẹ́ fún Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ìmọ́tótó láti rí sí i pé ìmọ́tótó táwọn èèyàn mọ̀ wá mọ́ kò yingin, wọ́n sì ń jẹ́ kí ibi ìjọsìn wa wà ní mímọ́ ju bó ṣe rí ká tó lò ó lọ. Ǹjẹ́ a lè ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí tàbí àwọn mìíràn tí wọ́n á nílò ìrànlọ́wọ́ wa? Ṣé wàá yọ̀ǹda ara rẹ láti sìn “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ?—Sef. 3:9.
16 Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Tiẹ̀ Ń Kíyè sí Wa? Nígbà àpéjọ àgbègbè kan lọ́dún tó kọjá yìí, ọkùnrin kan tó ti lé ní ogún ọdún sẹ́yìn tó ti jáwọ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ ní òtẹ́ẹ̀lì kan. Ó sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí kan pé òun ti ń ronú báyìí láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì òun padà kóun sì máa lọ sí ìpàdé. Kí ló mú un sọ bẹ́ẹ̀? Ìfẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí fi bá a lò láwọn ọjọ́ tí wọ́n lò ní òtẹ́ẹ̀lì náà ni.
17 Òǹtajà kan ní òtẹ́ẹ̀lì kan sọ nípa àwọn arákùnrin wa pé: “Ẹ̀yin làwọn èèyàn yín ṣì dára jù lọ nínú gbogbo àwọn tó máa ń dé sí òtẹ́ẹ̀lì wa. Wọ́n ní sùúrù gan-an wọ́n sì ṣọmọlúwàbí.” Ẹ ò rí i bí èyí ṣe máa múnú Baba wa ọ̀run dùn gidigidi tó bó ti ń rí wa tá à ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣílétí Jésù pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run”!—Mát. 5:16.
18 Àmọ́ ṣá o, a tún gbọ́ àwọn ìròyìn kan tó ń kọni lóminú láti àwọn àpéjọ kan nípa àwọn ọmọdé àtàwọn àgbàlagbà tí wọ́n ń rìn kiri láìnídìí nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n rí àwọn kan tí wọ́n ń sùn láwọn ilé tí wọ́n dé sí, tí wọ́n kàn wà níbẹ̀ láìsí ìdí gúnmọ́ kan nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Àwọn kan tí wọ́n wá sí àpéjọ jáde lọ mu ẹmu ní àkókò ìsinmi, àmọ́ bí wọ́n ṣe dé nígbà tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ bẹ̀rẹ̀, oorun ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sùn. A tún gbọ́ pé ńṣe làwọn arákùnrin kan àtàwọn arábìnrin kan lọ ń ya fọ́tò lásìkò tí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ń lọ lọ́wọ́. Àwọn òbí tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn jọ ń ya fọ́tò wà lára àwọn wọ̀nyí. Ẹ máà jẹ́ ká di aláìnímọrírì fún àwọn ìpèsè Jèhófà nípa gbígba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ láyè láti tún ṣẹlẹ̀ ní àwọn àpéjọ ọdún yìí o. A rọ gbogbo wa pé ká jọ̀wọ́ lo ìkóra-ẹni-níjàánu. A tún ń rán àwọn òbí létí láti bójú tó àwọn ọmọ wọn dáadáa.—Fílí. 1:9-11; 1 Kọ́r. 10:31; tún fi wé Léfítíkù 10:9.
19 Ẹ jẹ́ kí àwa náà ní irú ẹ̀mí tí Ọba Dáfídì ní, ẹni tó máa ń fi tayọ̀tayọ̀ fojú sọ́nà fún lílọ sí ilé ìjọsìn Jèhófà. Orísun pàtàkì tá a ti ń rí oúnjẹ tẹ̀mí ni àwọn àpéjọ àgbègbè wa jẹ́, wọ́n sì tún ń fún wa ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti ní ìbákẹ́gbẹ́ onífẹ̀ẹ́. Nítorí náà, à ń fi tìtaratìtara rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ètò tó bá yẹ láti pésẹ̀ sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run” ti ọdún yìí!
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Tẹ́ ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìfilọ̀ ibi tí Society yan ìjọ yín sí láti lọ ṣe àpéjọ àgbègbè àti déètì tí yóò jẹ́ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tó máa tẹ̀ lé e. Á dára kẹ́ ẹ fa ìlà sábẹ́ ìlú tí a yan ìjọ yín sí láti lọ ṣe àpéjọ náà àti déètì tí yóò jẹ́, kí ẹ sì lẹ apá yìí nínú àkìbọnú náà mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó àwọn ìsọfúnni àtàwọn ìfilọ̀ tó jẹ mọ́ àpéjọ láwọn ìpàdé tí a óò ṣe lọ́jọ́ iwájú. Kí gbogbo ẹ̀yin alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i pé ẹ fi ìtara bójú tó gbogbo àwọn ìsọfúnni tó bá jẹ mọ́ àpéjọ ní kánmọ́kánmọ́, lọ́nà tó gbéṣẹ́.]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday: 9:20 òwúrọ̀ sí 4:40 ìrọ̀lẹ́
Saturday: 9:00 òwúrọ̀ sí 4:20 ìrọ̀lẹ́
Sunday: 9:00 òwúrọ̀ sí 3:20 ìrọ̀lẹ́