Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Yóò Ṣe ní Ọdún 2004
1 Kí lo máa ń wọ̀nà fún jù lọ nínú àwọn àpéjọ àgbègbè wa ọdọọdún? Ṣé àwọn àsọyé tí ń gbéni ró àti àwòkẹ́kọ̀ọ́ tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ṣètò ni? (Mát. 24:45-47) Ṣé àwọn ìwé tuntun tó láwọn oúnjẹ tẹ̀mí tó bágbà mu nínú ni? Ṣé àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n ń sọ ìrírí wọn nípa bí Bíbélì ṣe mú kí ìgbésí ayé wọn dára sí i ni? Ṣé ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń tẹ̀ síwájú láwọn ilẹ̀ mìíràn ni? Àbí kẹ̀, ṣé ìfararora pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa lọ́mọdé lágbà ni? Láìsí àní-àní, à ń hára gàgà láti lọ sí àwọn àpéjọ wa nítorí àwọn ìdí wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn ìdí mìíràn!
2 Rí I Pé O Wà Níbẹ̀ Lọ́jọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: Jèhófà tipasẹ̀ Mósè pàṣẹ pé: “Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀ . . . kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.” (Diu. 31:12) Jèhófà ti lo ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye láti pèsè ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan àpéjọ wa. Níwọ̀n bó ti ń kọ́ wa ká bàa lè ‘ṣe ara wa láǹfààní,’ a fẹ́ láti wà níbẹ̀ láti gba gbogbo ìtọ́ni tó máa fún wa. (Aísá. 48:17) Bó bá jẹ́ pé o máa tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀gá rẹ, gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì sọ ohun tó o fẹ́ fún ọ̀gá rẹ, gẹ́gẹ́ bí Nehemáyà ṣe fi ìgboyà sọ ohun tó fẹ́. (Neh. 1:11; 2:4) Bákan náà, á dára kó o tètè jẹ́ káwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé rẹ mọ̀ nípa àwọn ètò tó ò ń ṣe láti lọ sí àpéjọ àgbègbè.
3 Ilé Gbígbé: A ó sapá láti pèsè fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé tó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ìsọfúnni tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé kọ̀ọ̀kan táwọn ará bá fi sílẹ̀. MÁ ṢE kọ kìkì iye akéde tó nílò ilé gbígbé, irú bíi “50 akéde,” sí àlàfo tó yẹ ká kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. Gbogbo ìsọfúnni ni kí a kọ nigín-nigín lọ́nà tó máa ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè ìsọfúnni kíkún nípa ẹni tó ń béèrè fún ilé gbígbé, irú bí orúkọ rẹ̀, ọjọ́ orí rẹ̀, bóyá ọkùnrin ni tàbí obìnrin, àti bóyá aṣáájú ọ̀nà ni tàbí akéde ìjọ. Kọ orúkọ àwọn ọmọ síbẹ̀ pẹ̀lú. Bó o bá nílò àyè sí i ju àlàfo tó wà lórí fọ́ọ̀mù náà, lo abala ìwé mìíràn. Bí orúkọ tó wà lórí fọ́ọ̀mù náà bá ju ẹyọ kan lọ, jọ̀wọ́ kọ bí wọ́n ṣe bára wọn tan sí àlàfo tí a pèsè fún èyí. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́nà pípéye ṣáájú kó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọ àgbègbè. Kí a tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ ṣáájú ìgbà àpéjọ. JỌ̀WỌ́ MÁ ṢE fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Àdírẹ́sì ilẹ̀ àpéjọ tá a yan ìjọ yín sí, èyí tá a fi hàn ní òdìkejì fọ́ọ̀mù náà, ni kí ẹ fi ránṣẹ́ sí.
4 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọ àgbègbè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ń tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí, síbẹ̀ a ṣì ń gbọ́ ìròyìn nípa àwọn kan tí kò fọwọ́ sowọ́ pọ̀. A rọ gbogbo wa láti fi ìfẹ́ hàn sáwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ṣe, kódà bí kì í bá ṣe ilé tí a fẹ́ ni wọ́n fún wa. Jọ̀wọ́, má gbẹ̀yìn Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lọ ṣètò ibi tó o máa dé sí nígbà àpéjọ, àyàfi tó bá jẹ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ kan ló máa gbà ọ́ sílé. Kódà bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀ pàápàá, ó dára láti ṣèwádìí bóyá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ti ṣètò fún ilé náà tẹ́lẹ̀. Bákan náà, jọ̀wọ́ má ṣe gba ẹ̀yìn Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé lọ ṣètò mìíràn nípa sísọ fún àwọn onílé tàbí àwọn tó ń bójú tó hòtẹ́ẹ̀lì pé wàá sanwó tó pọ̀ kó o lè rí ilé tó o fẹ́ gbà. Bá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, a óò dín ìnáwó àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kù, èyí á sì fi hàn pé a wà níṣọ̀kan a sì jẹ́ onígbọràn.—Fílí. 2:1-4; 1 Jòh. 3:17; 1 Kọ́r. 10:24.
5 Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó: Kìkì àwọn tó ń fẹ́ àkànṣe ìrànlọ́wọ́ látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n lè wà ní àpéjọ àgbègbè ni ètò yìí wà fún, pàápàá ọ̀ràn ilé gbígbé. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, ó sinmi lórí ipò kálukú wọn. Àwọn akéde àtàwọn aṣáájú ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó nìkan ni ètò Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó wà fún, ó sì tún kan àwọn ọmọ wọn tó mọ̀wàá hù pẹ̀lú. Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ ní láti fọwọ́ sí i kí wọ́n tó lè rí ìrànwọ́ náà gbà. Ìjọ tí àwọn ẹni wọ̀nyí ń dara pọ̀ mọ́ ni kó ṣe àwọn ètò yòókù láti fi bójú tó wọn dípò tí wọ́n á fi ti ojúṣe yìí sí àwọn tí ń ṣètò àpéjọ àgbègbè. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rán àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà létí pé kí wọ́n “máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá [wọn] tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gál. 6:10) Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n lọ́jọ́ lórí, àwọn aláìlera, àwọn òbí anìkàntọ́mọ tàbí àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lè má sọ fún ọ pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní àwọn ìṣòro kan tí wọ́n ní láti borí kí wọ́n lè lọ sí àpéjọ. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ọ láti “ṣe ohun rere” sí wọn nípa ṣíṣèrànwọ́ fún wọn? Ní pàtàkì, ó yẹ kí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tí wọ́n jẹ́ Kristẹni àtàwọn alàgbà mọ̀ nípa ipò tí àwọn ẹni wọ̀nyí wà.
6 Bí akéde kan bá fi fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé fún Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó sílẹ̀, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ yóò tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyí nígbà tí wọ́n bá ń yẹ fọ́ọ̀mù náà wò. Kí wọ́n wò ó bóyá ó ṣeé ṣe fún àwọn ará nínú ìjọ láti pèsè ohun tí ẹni náà nílò. Bí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fẹ́ béèrè ìbéèrè èyíkéyìí nípa àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, wọn yóò kàn sí akọ̀wé ìjọ.
7 Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò sapá láti pèsè àwọn yàrá tó bójú mu fún àwọn akéde tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó bí àwọn tó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ sọ̀rọ̀ nípa ipò wọn. Kí akọ̀wé bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bá wọn wá ilé. Bí ìjọ kò bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn, akọ̀wé lè fún wọn ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, kí ó sì kọ ọ̀rọ̀ náà, “ÀWỌN TÓ NÍLÒ ÀKÀNṢE ÀBÓJÚTÓ” ní lẹ́tà gàdàgbà sí apá òkè ojú ìwé àkọ́kọ́ fọ́ọ̀mù náà. Àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó nìkan ni kó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tí a kọ nǹkan sókè rẹ̀ yìí. Fúnra ẹni tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ náà ni kó kọ ìsọfúnni sínú rẹ̀. Kí ó dá a padà fún akọ̀wé, ẹni tí yóò rí sí i pé a ti kọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìsọfúnni sínú rẹ̀ àti pé ìsọfúnni náà péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú nípa àwọn ipò tó mú ẹni náà tóótun fún ètò yìí. Akọ̀wé ní láti ṢE KÚLẸ̀KÚLẸ̀ ÀLÀYÉ nípa àwọn ipò ẹni náà sínú àlàfo tó wà ní òdìkejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí la ní láti tètè ṣe ṣáájú igba àpéjọ àgbègbè. Lẹ́yìn èyí ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹni tó nílò àkànṣe àbójútó náà ni Ẹ̀ka yìí yóò fi ìsọfúnni nípa ilé gbígbé náà ránṣẹ́ sí ní tààràtà.
8 Àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó KÒ GBỌ́DỌ̀ lọ béèrè fún yàrá nígbà tí wọ́n bá dé àpéjọ àgbègbè, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
9 Lílọ sí Àpéjọ Mìíràn: Nítorí ipò rẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpéjọ mìíràn lo máa lọ yàtọ̀ sí èyí tá a yan ìjọ yín sí. Bó o bá nílò ibi tí wàá dé sí, jọ̀wọ́ sọ fún akọ̀wé ìjọ, yóò sì fún ọ ní fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. Fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ. Bó bá jẹ́ pé àpéjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n fẹ́ ṣe ní ìlú náà, rí i dájú pé déètì àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ hàn ketekete nínú fọ́ọ̀mù tó o fi ránṣẹ́.
10 Níbi àpéjọ kan tí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn, Ẹ́sírà àtàwọn ọmọ Léfì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sétí àwọn tó pé jọ, wọ́n sì ṣàlàyé rẹ̀. Kí ni èyí yọrí sí? Ìwé Nehemáyà 8:12 jẹ́ ká mọ̀ pé “gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ . . . wọ́n sì ń bá a lọ nínú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà, nítorí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.” Ǹjẹ́ a ò dúpẹ́ pé gẹ́gẹ́ bíi ti Ẹ́sírà àtàwọn ọmọ Léfì, ẹgbẹ́ ẹrú tí a fi àmì òróró yàn ń lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n ń ṣàlàyé rẹ̀, wọ́n sì ń jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè fi sílò nínú ìgbésí ayé wa? Bí ẹrú náà ṣe ń ṣe èyí fi ojúlówó ìfẹ́ àti àníyàn Jèhófà fún gbogbo àwọn èèyàn Rẹ̀ hàn. Pinnu pé wàá wà ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Bá Ọlọ́run Rìn” ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday
9:20 òwúrọ̀ sí 4:50 ìrọ̀lẹ́
Saturday
9:00 òwúrọ̀ sí 4:30 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:00 òwúrọ̀ sí 3:20 ìrọ̀lẹ́