Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2001
1 Wòlíì Aísáyà ṣàpèjúwe Jèhófà pé ó jẹ́ Olùkọ́ni Atóbilọ́lá, ẹni tó rọni bíi bàbá pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísá. 30:20, 21) Ṣùgbọ́n báwo la ṣe máa ń gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà ń sọ láti ṣe wá láǹfààní? Jèhófà ń gba ojú ewé Bíbélì bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó sì tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, ó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìpàdé, àpéjọ, àti àpéjọpọ̀ àgbègbè tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè. (Mát. 24:45) A ní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń bá a nìṣó láti máa darí wa ní ọ̀nà tó yẹ kí á máa tọ̀.
2 Lọ́dọọdún, àpéjọpọ̀ àgbègbè máa ń fún wa láǹfààní láti péjọ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kí a sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn ìtọ́ni Jèhófà. Lọ́dún tó kọjá, ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n, ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàasàn-án ó dín mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [576, 874] èèyàn ló wá sí àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” tó ń tuni lára nípa tẹ̀mí. Lọ́dún 2001, a óò ṣe Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” jákèjádò orílẹ̀-èdè yìí, yóò sì jẹ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta. A mọ̀ pé ẹ ń fojú sọ́nà fún ṣíṣètò bí ẹ ṣe máa wà níbẹ̀, nítorí náà, a pèsè àwọn ìtọ́ni tó tẹ̀ lé e yìí láti ràn yín lọ́wọ́.
3 Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Gbígbé: A óò sapá láti pèsè iye fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé tó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé kọ̀ọ̀kan tí a fi sílẹ̀ la kọ ọ̀rọ̀ sí lọ́nà tó yẹ. MÁ ṢE kọ kìkì iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé gbígbé, irú bíi “50 akéde,” sí àlàfo tó yẹ ká kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. Gbogbo ìsọfúnni náà ni kí a kọ nigín-nigín lọ́nà tó ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè ìsọfúnni kíkún ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni tí ń béèrè fún ilé gbígbé jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Kọ orúkọ àwọn ọmọ síbẹ̀ pẹ̀lú. Nígbà kan rí, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà làwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kó ṣòro láti ṣètò ilé gbígbé tí ó tó. Bí ẹ bá nílò àyè sí i ju àlàfo tí a pèsè sórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ lo abala ìwé mìíràn. Bí ẹ bá kọ ju orúkọ ẹnì kan lọ sórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ bí wọ́n ṣe bára tan sí àlàfo ìlà tó wà fún ìyẹn. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́nà pípéye ṣáájú kó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè. Kí akọ̀wé tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ tipẹ́ ṣáájú ìgbà àpéjọpọ̀.
4 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè. Ó kéré tán, ohun méjì la máa ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípa kíkọbi ara sí ìtọ́sọ́nà yìí, àwọn ni:
5 A ń dín ìnáwó àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa kù: Nígbà tí a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society, ó máa ń dín àwọn ará wa ní owó ilé kù. Dípò kí àṣẹ́kù owó wa máa bọ́ sápò àwọn onílé, a lè lò ó lọ́nà tó sàn jù láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àti fún iṣẹ́ wa kárí ayé. Àní bí àwa fúnra wa bá tilẹ̀ lè gba àwọn ilé gbígbé tí wọ́n gbówó lórí pàápàá, ó yẹ ká ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹ̀mí àníyàn fún àwọn ẹlòmíràn yìí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 1 Jòhánù 3:17, ìyẹn sì ni 1 Kọ́ríńtì 10:24 ń sọ.
6 A ń ṣègbọràn sí ìtọ́sọ́nà Society: Kókó yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí àníyàn wa. Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” Bí àwọn arákùnrin wa ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ètò fún àpéjọpọ̀ àgbègbè wa, a fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé a ń tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkún. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kìkì fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta lọ́dọọdún la máa ń béèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀nà dáradára kan lèyí jẹ́ láti ti ìsapá wọn lẹ́yìn. Àní bí ohun tí àwa fúnra wa ń fẹ́ bá tilẹ̀ yàtọ̀, àpẹẹrẹ rere wa, tí àwọn arákùnrin wa àti ayé ń wò, ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìtìlẹ́yìn lárugẹ.—Fílí. 2:1-4.
7 Àwọn Tó Níló Àkànṣe Àbójútó: Ìpèsè yìí wà fún kìkì àwọn tó ń fẹ́ ìrànwọ́ àkànṣe látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe àwọn ìwéwèé fún àpéjọpọ̀ àgbègbè wọn, ní pàtàkì ètò ilé gbígbé. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, gẹ́gẹ́ bí ipò olúkúlùkù wọn bá ti rí. Kìkì àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, títí kan àwọn ọmọ wọn tí wọ́n mọ̀wàá hù, tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó, tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sì fọwọ́ sí nìkan ni wọ́n tóótun láti rí ìrànwọ́ gbà lábẹ́ ètò Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó. Àwọn ètò mìíràn láti fi tọ́jú àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó ni kí ìjọ tí wọ́n wà rí sí fúnra wọn dípò títi ojúṣe yìí sí àwọn tí ń ṣètò àpéjọpọ̀ àgbègbè. Àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa ipò ẹni náà lè ṣèrànwọ́ tìfẹ́tìfẹ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde gbé ohun tí àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti bóyá àwọn mìíràn nílò, yẹ̀ wò. Àwọn akéde lè ṣèrànwọ́ nípa mímú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání lọ pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójútó ọ̀ràn wọn láwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Ják. 2:15-17; 1 Jòh. 3:17, 18.
8 Àmọ́ ṣá o, Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò sakun láti pèsè àwọn iyàrá ibùwọ̀ tó bójú mu fáwọn akéde tí wọ́n nílò àkànṣe àbójútó bí àwọn tó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ jíròrò ipò wọn. Kí akọ̀wé bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó iyàrá ibùwọ̀ wọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn lọ́nà tó yẹ, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, lórí èyí tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ÀWỌN TÓ NÍLÒ ÀKÀNṢE ÀBÓJÚTÓ” sí lókè gàdàgbà, ní ojú ìwé àkọ́kọ́. Orúkọ àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó ni kó wà nínú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí o. Ẹni tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ náà ni kó kọ ọ̀rọ̀ sínú rẹ̀. Kí ó dá a padà fún akọ̀wé tí yóò rí sí i pé a kọ ọ̀rọ̀ sínú rẹ̀, pé ó péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú nípa àwọn ipò tó mú ẹni náà tóótun fún irú ìṣètò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢE KÚLẸ̀KÚLẸ̀ ÀLÀYÉ nípa àwọn ipò náà sínú àlàfo tó wà ní òdì kejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí la ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àpéjọpọ̀ àgbègbè náà. Lẹ́yìn náà ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. A óò sọ fún ẹni tó ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ náà ní tààràtà nípa ilé gbígbé náà.
9 Àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó KÒ GBỌ́DỌ̀ lọ béèrè fún iyàrá nígbà tí wọ́n bá dé ọ̀hún, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
10 Ọ̀pọ̀ ti sọ pé àwọn mọrírì ètò tí a máa ń ṣe fún ilé gbígbé nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè. Ṣé ìwọ náà kún fún ìmoore fún ọ̀pọ̀ ètò tí a ń ṣe nítorí rẹ? Inú Society dùn láti máa pèsè àwọn ilé gbígbé tí ń tuni lára, tí kò sì wọ́n nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè, tí ń mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí àpéjọpọ̀ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní.
11 Lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè Mìíràn: A yan ìjọ kọ̀ọ̀kan sí àpéjọpọ̀ àgbègbè tó sún mọ́ ọn jù lọ. Bí a ti gbe é karí iye àwọn akéde tí a yàn sí àpéjọpọ̀ àgbègbè kọ̀ọ̀kan, Society díwọ̀n iye ènìyàn tí yóò wá kí wọ́n lè ṣètò àwọn ìpèsè tó máa tó, bí ìjókòó, ilé gbígbé, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n, bí o bá ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan tó yàtọ̀ sí èyí tí a yàn ọ́ sí, tí o sì ń fẹ́ ilé gbígbé, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. O lè kọ ọ̀rọ̀ sínú rẹ̀, kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i, kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè tí o fẹ́ láti lọ.
12 Èdè Àwọn Adití: A óò ṣètò kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ó tóótun túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ní àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè tó tẹ̀ lé e yìí: Ọ̀tà 2, November 2-4, 2001; North 4, November 16-18, 2001; Ùlì 7, December 7-9, 2001; àti Ùbogò 10, January 11-13, 2002. A fún àwọn adití tó wà ní gbogbo ìjọ ní Nàìjíríà níṣìírí pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé láti lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè wọ̀nyí, ó kéré tán. Kí àwọn alàgbà wádìí dáadáa lọ́wọ́ adití kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìjọ wọn tó bá mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láti rí i dájú pé wọ́n mọ̀ nípa ìṣètò yìí kí wọ́n sì lè mọ̀ bóyá ìrànwọ́ wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè lọ.
13 Àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè wọ̀nyí nìkan ni yóò ní ibi tí a ṣètò lákànṣe fún àwọn adití tí a óò ti fi èdè àwọn adití túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún wọn. A kò ní ṣètò títúmọ̀ lédè àwọn adití ní àpéjọpọ̀ àgbègbè èyíkéyìí mìíràn. Bí adití kan bá bá ẹni tí ń túmọ̀ èdè adití lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè mìíràn, a gbà pé kí olùtumọ̀ túmọ̀ fún adití náà nìkan kí àwọn méjèèjì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, kì í ṣe pé kó máa túmọ̀ níwájú ẹni náà tàbí níwájú àwùjọ kan.
14 Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Tọ́jú Owó fún Àpéjọpọ̀ Náà: Ní àfikún sáwọn ìṣètò yòókù, ÌSINSÌNYÍ ni àkókò láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú owó fún àpéjọpọ̀ àgbègbè. Ibi tí àwọn kan ń gbé jìnnà díẹ̀ sí ibi tí wọn yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè. Bákan náà, àwọn kan ní ìdílé ńlá. Fún irú àwọn ẹni yìí, àti fún gbogbo wa, a nílò owó tí a ó fi ṣètọrẹ, tí a ó fi wọkọ̀, tí a ó fi ra oúnjẹ nígbà àpéjọpọ̀ àgbègbè, àti èyí tí a ó fi ṣe àwọn ohun mìíràn tí a kò ronú tẹ́lẹ̀. Ó yẹ káwọn tí wọ́n ní ìdílé ńlá wéwèé ṣáájú kí wọ́n sì tọ́jú owó tí ó tó kí gbogbo ìdílé lè lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ lè jẹ́ nípa fífojú díwọ̀n àròpọ̀ iye owó tí a nílò. Ó bọ́gbọ́n mu láti ṣírò pé owó nǹkan lè ròkè nígbà tí o bá ń fojú díwọ̀n àròpọ̀ iye tẹ́ẹ máa ná. Fi àròpọ̀ iye oṣù tó wà láàárín ìsinsìnyí àti déètì àpéjọpọ̀ àgbègbè yín pín iye owó tí o fojú díwọ̀n. Iye owó tí o ní láti máa fi pa mọ́ lóṣooṣù nìyẹn. Lóṣooṣù, sọ ọ́ di dandan láti kọ́kọ́ yọ iye owó yìí sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí owó àpéjọpọ̀ àgbègbè. O lè fi èyí pa mọ́ sínú àpótí kékeré kan tàbí sínú àpò ìwé. Síbẹ̀, o tún lè pín iye owó tó yẹ kí o máa fi pa mọ́ lóṣooṣù sí ọ̀nà mẹ́rin kí o sì máa tọ́jú rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o má ṣe dúró dìgbà tí àpéjọpọ̀ àgbègbè bá ku oṣù kan tàbí méjì kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí kówó jọ fún ìrìn àjò ọdọọdún tí a máa ń lọ déédéé yìí.—Òwe 21:5.
15 Ọ̀rọ̀ Ìparí: Bí àkókò ti ń sún mọ́ fún ọ láti lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè yín, gbàdúrà sí Jèhófà pé kí ó jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti lọ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta láìtàsé èyíkéyìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kí o sì jàǹfààní gíga jù lọ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ǹjẹ́ o ti tọrọ àyè kúrò lẹ́nu iṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti àpéjọpọ̀ tí o wéwèé láti lọ? Bí o kò bá tíì tọrọ àyè, ṣe bẹ́ẹ̀ bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó. Wọn kì í sábà fúnni láyè níbi iṣẹ́ bó bá ti pẹ́ jù kí èèyàn tó tọrọ àyè. Ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ti ṣètò Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti ọdún yìí láti pèsè ìtọ́ni tẹ̀mí fún wa àti láti gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Nítorí náà, bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ètò rẹ báyìí láti wà níbẹ̀, ní kíkọbi ara sí ìṣílétí onísáàmù tó sọ pé: “Ẹ fi ìbùkún fún Ọlọ́run nínú àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn”!—Sáàmù 68:26.
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Bí ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣèfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tó tẹ̀ lé e nípa ibi tí Society yàn pé kí ìjọ yín ti ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè àti àwọn ọjọ́ tí ẹ óò ṣe é. Yóò dára kí ẹ fàlà sábẹ́ ìlú tí ìjọ yín yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ àgbègbè àti àwọn ọjọ́ tí ẹ óò ṣe é, kí ẹ sì lẹ apá yẹn nínú àkìbọnú yìí mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ àgbègbè àti àwọn ìfilọ̀ ní àwọn ìpàdé ọjọ́ iwájú. Ó dára kí gbogbo alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i dájú pé wọ́n bójú tó àwọn ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ní kánmọ́kánmọ́, pẹ̀lú ìtara ọkàn, àti lọ́nà tó gbéṣẹ́.]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday
9:20 òwúrọ̀ sí 4:40 ìrọ̀lẹ́
Saturday
9:00 òwúrọ̀ sí 4:20 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:00 òwúrọ̀ sí 3:20 ìrọ̀lẹ́