Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ọdún 2007
1, 2. (a) Báwo ni Mósè ṣe gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì níyànjú pé kí wọ́n jàǹfààní látinú pípéjọpọ̀? (b) Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí?
1 Mósè fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn àtìpó tó wà láàárín wọn ní ìtọ́ni pé kí wọ́n máa pé jọ lọ́dún méje méje kí wọ́n bàa lè ka ìwé Òfin sí wọn létí. Torí kí ni? “Kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.” (Diu. 31:10-12) Jèhófà rí i pé ó pọn dandan láti pe àwọn èèyàn rẹ̀ jọ pọ̀. Láìpẹ́, àwọn èèyàn Jèhófà tún máa pé jọ síbi Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” tí yóò wáyé fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko.
2 Ṣó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra? Ṣé wàá ní láti tọrọ àyè níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́? Ṣó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ́jú owó kó bàa lè ṣeé ṣe fún ìwọ àti ìdílé rẹ̀ láti wà ní àpéjọ náà lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? Ṣé wàá lè ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí wọn kì í ṣe onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé ẹ lọ sí àpéjọ yìí? Ǹjẹ́ o mọ àwọn míì nínú ìjọ tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí àpéjọ yìí? Ṣó o máa lọ sí àpéjọ míì tó yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n yan ìjọ rẹ sí? Ṣé wàá nílò ilé tó o máa dé sí? Àlàyé tó wà nísàlẹ̀ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀.
3. (a) Ọ̀nà wo ni Aísáyà 25:6 gbà ń nímùúṣẹ lónìí? (b) Kí la ti kíyè sí nípa iye àwọn tó máa ń wà ní àpéjọ ní ọjọ́ Friday, kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa sì lè ṣe?
3 Wà Níbẹ̀ ní Gbogbo Ọjọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: Jèhófà máa ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu fáwọn èèyàn rẹ̀. (Aís. 25:6) Lára àwọn oúnjẹ tẹ̀mí náà ni èyí tá a máa ń jẹ láwọn àpéjọ wa ọdọọdún. Àmọ́, a ti wá kíyè sí i pé àwọn tó máa ń wá sí àpéjọ lọ́jọ́ Friday ń kéré gan-an sí iye tó máa ń wá láwọn ọjọ́ yòókù. Rí i pé o wà ní àpéjọ atura tí ètò Jèhófà ti ṣètò sílẹ̀ yìí ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta! Bó o bá máa ní láti gbàyè níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́, fi sínú àdúrà. Kó o sì ‘máyà le’ láti bá ẹni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ sọ̀rọ̀ ní gbàrà tí wọ́n bá ti ṣèfilọ̀ déètì àpéjọ yín. (1 Tẹs. 2:2; Neh. 2:4, 5) Ó sì tún máa dáa kó o ṣàlàyé fẹ́ni tó gbà ẹ́ síṣẹ́ pé apá kan ìjọsìn wa sí Ọlọ́run ni àpéjọ tá à ń ṣe lọ́dọọdún. Bó o bá tètè sọ fún un nígbà tí ọjọ́ àpéjọ náà bá ṣì jìnnà, á jẹ́ kó rọrùn fún un láti ṣètò tó bá yẹ kó lè fún ẹ láyè.
4. Báwo la ṣe lè ran àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn mọ̀lẹ́bí wa tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà?
4 Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Àtàwọn Ìdílé Wọn Lọ́wọ́ Láti Múra Sílẹ̀: Ó máa dáa gan-an tó o bá jẹ́ káwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ̀ lé ẹ lọ sí àpéjọ yìí, káwọn náà tiẹ̀ gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé láàárín “ìjọ ńlá”! (Sm. 22:25) Tètè sọ fún wọn nígbà tọ́jọ́ bá ṣì jìnnà kí wọ́n bàa lè ṣètò tó bá yẹ láti wà níbẹ̀. Jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tó máa ń jẹ́ kó wu ìwọ alára láti máa wà ní àwọn àpéjọ. Kí ara wọn bàa lè wà lọ́nà fún ohun tí wọ́n á máa retí láti rí ní àpéjọ náà, o lè fi àwọn fídíò wa kan tó ṣàfihàn báwọn àpéjọ wa ṣe máa ń rí hàn wọ́n, irú bíi fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní United by Divine Teaching. Bákan náà, jẹ́ káwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ̀ nípa ètò tó ò ń ṣe láti wà ní àpéjọ àgbègbè tọdún yìí. A ò lè sọ, àwọn náà lè fẹ́ ṣètò láti wá wo àwòkẹ́kọ̀ọ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fẹ́ fi ọjọ́ kan, ó kéré tán, wà ní àpéjọ náà.
5, 6. (a) Báwo la ṣe lè jẹ́ ọlọ́làwọ́ gẹ́gẹ́ bí 1 Tímótì 6:18 ṣe sọ? (b) Ètò wo ló wà nílẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọ́n lè nílò ìrànwọ́ ní ti ọ̀ràn ilé gbígbé?
5 Bó O Ṣe Lè Ran Àwọn Ará Lọ́wọ́: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tí wọ́n rí já jẹ níyànjú “láti máa ṣe rere, láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, láti jẹ́ aláìṣahun, kí wọ́n múra tán láti ṣe àjọpín.” (1 Tím. 6:17, 18) A lè jẹ́ ọlọ́làwọ́ gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ bá a bá ń gba tàwọn àgbàlagbà tó wà láàárín wa rò, tá ò sì gbàgbé àwọn aláìlera, àwọn tó wà nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún, àwọn òbí tó ń dá tọ́mọ àtàwọn míì nínú ìjọ tí wọ́n lè nílò ìrànwọ́ kí wọ́n bàa lè wà ní àpéjọ yẹn. Òótọ́ ni pé ojúṣe àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó wà nínú òtítọ́ ni, síbẹ̀ báwọn alàgbà àtàwọn míì bá kíyè sí irú àwọn ará tó nílò ìrànwọ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́.—Gál. 6:10; 1 Tím. 5:4.
6 Bá a bá rí ẹni tó nílò ìrànwọ́ lórí ọ̀ràn ilé gbígbé, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ pinnu bóyá irú akéde bẹ́ẹ̀ yẹ lẹ́ni tí wọ́n lè fún ní fọ́ọ̀mù Ilé Gbígbé fún Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó.
7. Ìtọ́ni wo ni ètò Jèhófà fún wa bó bá pọn dandan láti lọ sí àpéjọ mìíràn tó yàtọ̀ sí èyí tó jẹ́ ti ìjọ wa?
7 Bó O Bá Fẹ́ Lọ sí Àpéjọ Mìíràn: O lè ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti lọ sí àpéjọ kan tó yàtọ̀ sí èyí tá a yan ìjọ rẹ sí. Bó o bá máa nílò ilé tó o máa dé sí, jọ̀wọ́ rí akọ̀wé ìjọ kó bàa lè fún ẹ ní fọ́ọ̀mù Ilé Gbígbé. Àdírẹ́sì ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ tó o fẹ́ lọ ni kó o fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí. Bó bá jẹ́ pé àpéjọ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n máa ṣe nílùú tó o ti fẹ́ lọ ṣe àpéjọ, rí i pé o kọ déètì tí wọ́n máa ṣe àpéjọ tó o máa lọ sínú fọ́ọ̀mù náà.
8. Ìtọ́ni pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn nígbà tá a bá fẹ́ béèrè ilé gbígbé, kí sì nìdí? (Fi àlàyé tó wà nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 4 kún un.)
8 Ètò Ilé Gbígbé: Kó bàa lè rọrùn fún ẹ, a ó ṣètò ibi tó o lè dé sí láwọn ìlú tí àpéjọ á ti wáyé. Láwọn ibì kan lára ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ yìí, a ó ṣètò ilé gbígbé sínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ, àwọn ilé náà lè jẹ́ ilé tá a kàn fẹ́ lò fún ìgbà díẹ̀ tàbí èyí tá a dìídì kọ́ káwọn ará lè máa ríbi dé sí. Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé ètò Ọlọ́run ò ní lè kọ́lé tó máa gba gbogbo èèyàn tó bá wá sí àpéjọ kan. Kìkì àwọn tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ló máa lè sùn sínú ilé tá a kọ́ sínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Bó bá jẹ́ pé ibòmíì ni wọ́n fi ẹ́ wọ̀ sí, jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó o sì wà níbi tí wọ́n bá fi ẹ́ wọ̀ sí. Bó bá jẹ́ pé ṣe lo fẹ́ máa wọkọ̀ lọ wọkọ̀ bọ̀ sí ibi àpéjọ náà lójoojúmọ́, rántí pé ìnáwó kan nìyẹn náà. Ó sì tún ṣe pàtàkì pé kó o fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń tọ́jú owó tó o máa lò ní àpéjọ, ó ṣe pàtàkì kó o fìyẹn náà kún un. (1 Kọ́r. 16:1-4; 2 Kọ́r. 9:7) Kó o tó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, gbé àwọn kókó tó wà nínú àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Gbígbé” yẹ̀ wò.
9, 10. (a) Àwọn nǹkan wo ló ti máa ń wà ní sẹpẹ́ ká tó dé ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ? (b) Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì akitiyan táwọn ará wa ń ṣe nítorí tiwa, báwo la sì ṣe lè dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn? (Ka Hébérù 13:17.)
9 Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Pẹ̀lú Ìṣètò Tó Wà Nílẹ̀: Nígbà tá a bá dé sí ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ, a máa ń rí i pé àwọn ará ti ṣiṣẹ́ gan-an ká bàa lè ríbi dé sí. Àwọn arákùnrin onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí olùtọ́jú èrò máa ń kí wa káàbọ̀, wọ́n á fún wa ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà, wọ́n á sì fi ibi tá a lè jókòó sí hàn wá. Àwọn ará kan á ti mú kí gbogbo àyíká wà ní mímọ́ tónítóní, wọ́n á sì ti rí i pé orí pèpéle rí nigín nigín. Bákan náà, iṣẹ́ ribiribi làwọn ará máa ń gbé ṣe kó tó dìgbà àpéjọ kí wọ́n lè múra iṣẹ́ wọn sílẹ̀, kí wọ́n dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn onílé, kí wọ́n sì tún bójú tó ọ̀pọ̀ iṣẹ́ mìíràn.
10 Kí àpéjọ kan tó lè wáyé, ọ̀pọ̀ oṣù làwọn ará fi máa ń ṣiṣẹ́ àṣelàágùn láti ṣe àwọn ètò tó bá yẹ, ìdílé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn yìí sì máa ń ṣe bẹbẹ nípa mímú kó ṣeé ṣe fún wọn láti bójú tó àwọn ìṣètò pàtàkì bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ ká fi ìmọrírì hàn fún báwọn ará wọ̀nyí ṣe ń fi àwọn nǹkan kan du ara wọn nítorí tiwa? A lè fi hàn pé a moore bá a bá tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn ìtọ́ni míì tó ṣeé ṣe ká fi ránṣẹ́ lẹ́yìn èyí. (Héb. 13:17) Bí gbogbo wa bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tinútinú, ó dájú pé ohun gbogbo á “ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.
11. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwa èèyàn Jèhófà máa pé jọ lákòókò wa yìí? (b) Kí wá lẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe báyìí?
11 Bá a ṣe ń “rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé,” ó túbọ̀ ń ṣe pàtàkì pé káwọn èèyàn Ọlọ́run máa pé jọ. (Héb. 10:25) Láwọn àpéjọ wa, ẹrú olóòótọ́ àti olóye máa ń fún wa ní ìsọfúnni tó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa “kíyè sára láti mú gbogbo ọ̀rọ̀” Jèhófà tó fẹ́ ká máa tẹ̀ lé ṣẹ. (Diu. 31:12) Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò ní báyìí kó o lè wà ní Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Máa Tọ Kristi Lẹ́yìn!” ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, kó o bàa lè jàǹfààní látinú àwọn ìtọ́ni Ọlọ́run àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday 9:00 àárọ̀ sí 4:35 ìrọ̀lẹ́
Saturday 9:00 àárọ̀ sí 4:35 ìrọ̀lẹ́
Sunday 9:00 àárọ̀ sí 3:40 ìrọ̀lẹ́
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]
Bó O Ṣe Lè Béèrè Ilé Tó O Máa Dé Sí
1. Gba fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ rẹ.
2. Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lásìkò. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o kọ ìsọfúnni náà lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, ìyẹn ìsọfúnni bí orúkọ, ọjọ́ orí rẹ, bóyá o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin àti bóyá o jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Kó o sì rí i pé o kọ àwọn ìsọfúnni náà lọ́nà tó gún régé tó sì ṣe é kà.
3. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé ìsọfúnni inú fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé péye, kó sì fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní ìlú tí àpéjọ náà yóò ti wáyé, kó MÁ ṢE FI RÁNṢẸ́ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó pẹ́ kó tó dọ́wọ́ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé tó bá jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí.
4. Rí i pé o tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé nígbà tí ọjọ́ àpéjọ náà bá ṣì jìnnà dáadáa. Èyí ló máa jẹ́ kí wọ́n lè ní àkókò tó tó láti wá ilé tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.
5. Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé á jẹ́ kó o mọ ohun tó bá yẹ ní mímọ̀ nípa ilé náà kó tó di ọjọ́ àpéjọ, wọ́n sì lè ní kó o san owó tí wọ́n á fi bá ẹ gbà á sílẹ̀.
Jọ̀wọ́
◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ẹ́ sí tẹ́ ẹ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tó wà nínú ọgbà Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá fi ẹ́ síbẹ̀. Iye ẹ̀yin tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ni kẹ́ ẹ jọ wà nínú ilé náà.
◼ Má ṣe débi tí ẹni tó ni ilé tí wọ́n bá fi ẹ́ wọ̀ sí ò bá fẹ́ kó o dé. Bí onílé bá gbà pé o lè dáná ni kó o tó dáná, kó sì jẹ́ níbi tó bá ti ní kó o dáná.
◼ Má ṣe tìtorí àtilè rí ilé gbà kó o wá sọ fún onílé pé wàá san owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ.
◼ Nígbà tó o bá ń ṣètò ilé tó o máa wọ̀ sí fúnra rẹ̀, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà ni ìwọ náà tún fẹ́ gbà.