Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2008 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
1. (a) Kí nìdí tí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù fi kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lónìí? (Ka Hébérù 10:24, 25.) (b) Àǹfààní wo la máa ní láti fi ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù sílò?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé kí wọ́n máa pé jọ, kí wọ́n sì máa fún ara wọn níṣìírí lẹ́nì kìíní-kejì, “pàápàá jù lọ” bí wọ́n ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé. (Héb. 10:24, 25) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló túbọ̀ ń fi hàn pé “ọjọ́” tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ti dé tán! Torí náà, a máa ń hára gàgà láti pé jọ pẹ̀lú àwọn ará wa, ká lè jọ gba àwọn ìtọ́ni tẹ̀mí tó lè tọ́ wa sọ́nà la àwọn “ọjọ́ ìkẹyìn” tó túbọ̀ ń le koko yìí já. (2 Tím. 3:1) A tún máa nírú àǹfààní yìí nígbà àpéjọ àgbègbè wa ti ọdún yìí tó ń bọ̀ lọ́nà.
2. (a) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká wà ní àpéjọ àgbègbè náà lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? (b) Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí?
2 Wà Níbẹ̀ Lọ́jọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: A rọ̀ ẹ́ pé kó o má pa ọjọ́ kankan jẹ. Bá ò bá “kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀,” a ò ní pàdánù àsè tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì yìí. (Héb. 10:25) Torí náà, tètè bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ báyìí. Á dáa tó o bá tètè sọ fún ọ̀gá rẹ, kó lè ṣàwọn ètò tó máa jẹ́ kó fún ẹ láyè. Bí àpéjọ àgbègbè yín bá máa bọ́ sí ìgbà táwọn ọmọ rẹ ṣì máa wà níléèwé, lọ gbàyè lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ wọn. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé apá tó ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn wa ni àpéjọ àgbègbè jẹ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa bù kún àwọn ìsapá tó o bá ṣe láti fi ire Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́.—Mát. 6:33.
3. Kí la lè ṣe láti fi hàn pé a gba tàwọn ẹlòmíì rò?
3 Ran Àwọn Ẹlòmíì Lọ́wọ́ Láti Wá: Pọ́ọ̀lù tún gba àwọn arákùnrin rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa “gba ti ara [wọn] rò.” (Héb. 10:24) Ṣáwọn kan wà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yín tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè? Ó máa dáa tó o bá lè ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ láti wá sí àpéjọ àgbègbè yìí, bí ò tiẹ̀ ju ọjọ́ kan lọ. Nígbà tó o bá ń sọ fáwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé o máa lọ sí àpéjọ àgbègbè, máa fàsìkò yẹn sọ fún wọn pé káwọn náà wá. Àwọn ìsapá onífẹ̀ẹ́ tó o bá ṣe lè mú àbájáde rere wá.
4. Báwo la ṣe lè gba ìsọfúnni nípa àwọn ọjọ́ tí àpéjọ àgbègbè máa wáyé àti ibi tó ti máa wáyé?
4 Gbígba Ìsọfúnni: Ọdọọdún lọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fi tẹlifóònù pe ẹ̀ka ọ́fíìsì wa láti béèrè ìgbà tí àpéjọ àgbègbè máa wáyé àti ibi tó ti máa wáyé. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé púpọ̀ lára àwọn ará wa tó ti láwọn ìsọfúnni wọ̀nyẹn lọ́wọ́ ló tún ń pè wá. Kẹ́ ẹ tó pe ẹ̀ka ọ́fíìsì, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ kọ́kọ́ wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí lójú ìwé 5 àti 6.
5. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá nílò ìsọfúnni nípa ilé gbígbé ní àpéjọ àgbègbè mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n bá pín ìjọ wa sí?
5 Bó o bá fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè mìíràn yàtọ̀ sí èyí tá a pín ìjọ rẹ sí, tó o sì fẹ́ gba ìsọfúnni lórí ilé gbígbé, o lè kọ̀wé sí ibi tí àpéjọ àgbègbè yẹn ti máa wáyé, àwọn àdírẹ́sì wọ̀nyẹn wà lẹ́yìn àwọn fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé, ìyẹn Room Request Form. A ti fi àwọn ẹ̀dà fọ́ọ̀mù yìí ránṣẹ́ sáwọn akọ̀wé ìjọ. Kó o lè rí èsì gbà, rí i dájú pé o fi àpò ìwé tó ní sítáǹbù ìfìwéránṣẹ́ àti àdírẹ́sì tó o fi ń gbàwé sínú lẹ́tà náà.
6. Kí làwọn ohun tá a ní láti fi sọ́kàn nípa fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé?
6 Àwọn Tó Nílò Àkànṣe Àbójútó: Bí akéde kan bá ń fẹ́ ilé tó máa dé sí, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ rẹ̀ pinnu bó bá yẹ lẹ́ni tó lè kọ̀rọ̀ sí apá tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, ìyẹn ibi tá a kọ Special Needs sí lórí fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé. Kí akọ̀wé ìjọ tó fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọ àgbègbè náà, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú fọ́ọ̀mù náà.
7. Báwo la ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ètò tó ti wà nílẹ̀ fún ilé gbígbé? (Wo àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Tó O Máa Dé Sí.”)
7 Ilé Gbígbé: A máa ṣètò fún ilé gbígbé láwọn ibi tí àpéjọ àgbègbè ti máa wáyé kí nǹkan lè rọ̀ yín lọ́rùn. Àwọn ilé tẹ́ ẹ lè dé sí ti wà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan, àwọn ilé náà lè jẹ́ èyí tá a kàn fẹ́ lò fúngbà díẹ̀ tàbí èyí tá a dìídì kọ́ káwọn ará lè máa ríbi dé sí. Jọ̀wọ́ fi sọ́kàn pé ètò Ọlọ́run ò ní lè kọ́lé tó máa gba gbogbo èèyàn tó bá wá sí àpéjọ àgbègbè. Má sì gbàgbé pé kìkì àwọn tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí ló gbọ́dọ̀ sùn sínú ilé tó wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Bó bá jẹ́ pé ibòmíì ni wọ́n ní kó o dé sí, jọ̀wọ́ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, ibi tí wọ́n bá sì fi ẹ́ sí ni kó o sùn. Rántí pé ó ṣeé ṣe kó o nílò owó tó o máa fi wọkọ̀ lọ wọkọ̀ bọ̀ láti ibi àpéjọ náà lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan. Ó sì tún ṣe pàtàkì pé kó o fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Tó bá jẹ́ pé Gbọ̀ngàn Àpéjọ lo dé sí, ó yẹ kó o fowó ṣètìlẹ́yìn fún bíbójú tó ibi tó o dé sí. Torí náà, má gbàgbé láti fi gbogbo èyí sọ́kàn nígbà tó o bá ń tọ́jú owó tó o máa lò ní àpéjọ àgbègbè. (1 Kọ́r. 16:1-4; 2 Kọ́r. 9:7) Kó o tó kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé, ṣàyẹ̀wò àwọn kókó tó wà nínú àpótí náà, “Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Tó O Máa Dé Sí.”
8. (a) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fìyìn fún Jèhófà láwọn ibi tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ àgbègbè wa? (b) Kí làwọn máníjà òtẹ́ẹ̀lì kan ti sọ, nítorí ìwà rere táwọn ará wa hù?
8 Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà: Ṣíṣègbọràn sófin Jèhófà pé ká máa pé jọ fún ìjọsìn ń jẹ́ ká lè máa ‘ṣe ara wa láǹfààní.’ Pàtàkì jù lọ ni pé, ó ń jẹ́ ká lè máa gbé orúkọ Jèhófà ga. (Aísá. 48:17) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń rí “àwọn iṣẹ́ àtàtà” wa láwọn àpéjọ àgbègbè, àwọn kan sì ti sọ bí ohun tí wọ́n rí ṣe wú wọn lórí tó. (1 Tím. 5:25) Nílùú kan tá a ti sábà máa ń ṣe àpéjọ àgbègbè wa lọ́dọọdún, máníjà òtẹ́ẹ̀lì kan níbẹ̀ sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ làwọn èèyàn ń sọ nílùú yìí nípa ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn àǹfààní tá a máa ń rí nígbà àwọn àpéjọ àgbègbè yín. A mọ báwọn èèyàn yín ṣe tún gbọ̀ngàn ìlú ṣe, a sì tún rí bí ẹ̀yin náà ṣe tún àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí ṣe. Inú wa dùn láti gbà yín tọwọ́ tẹsẹ̀ lákòókò yìí. A óò tún máa retí yín nígbà míì.” Lẹ́yìn tí máníjà òtẹ́ẹ̀lì kan sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n máa ń ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tó máa ń wá lo òtẹ́ẹ̀lì wọn, ó sọ̀rọ̀ nípa báwọn ará wa ṣe máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ tí wọ́n bá dé sí òtẹ́ẹ̀lì náà. Ó sọ pé, “Ì bá wù wá kí gbogbo àwọn oníbàárà wa dà bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Ó dájú pé ìwà táwọn ará wa hù tó mú kí wọ́n máa sọ irú àwọn ọ̀rọ̀ rere bí èyí ti ní láti múnú Jèhófà, Ọlọ́run wa dùn gan-an ni! Ibi yòówù kó o dé sí, yálà òtẹ́ẹ̀lì, ilé àdáni tàbí Gbọ̀ngàn Àpéjọ, rí i dájú pé o hùwà ọmọlúwàbí, kó o sì jẹ́ kí ibẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní.
9. Báwo ni Mátíù 4:4 ṣe jẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà?
9 Jésù sọ pé wíwà tá a wà láàyè sinmi lórí fífetí sí “gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Láwọn àpéjọ àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, Jèhófà máa ń lo “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti fún wa ní “oúnjẹ [tẹ̀mí] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Iṣẹ́ kékeré kọ́ ló wà nídìí pípèsè àsè tẹ̀mí yìí. Ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé a wà níbẹ̀, ká sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, ká lè fi hàn pé a mọrírì bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa.
[Àpótí tó wà lójú ewé 3]
Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ:
Friday àti Saturday
9:20 àárọ̀ sí 4:55 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:20 àárọ̀ sí 4:00 ìrọ̀lẹ́
[Àpótí tó wà lójú ewé 4]
Bó O Ṣe Lè Béèrè fún Ilé Tó O Máa Dé Sí:
1. Gba fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ rẹ.
2. Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lásìkò. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o kọ ìsọfúnni náà lọ́nà tó kún rẹ́rẹ́, ìyẹn ìsọfúnni bí orúkọ, ọjọ́ orí rẹ, bóyá o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin àti bóyá o jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Kó o sì rí i pé o kọ àwọn ìsọfúnni náà lọ́nà tó gún régé tó sì ṣe é kà.
3. Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé wọ́n kọ àwọn ìsọfúnni tó bá wà nínú fọ́ọ̀mù náà lọ́nà tó yẹ, kó buwọ́ lù ú, kó sì fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní ìlú tí àpéjọ àgbègbè bá ti máa wáyé, kó MÁ ṢE FI RÁNṢẸ́ SÍ Ẹ̀KA Ọ́FÍÌSÌ O. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kí fọ́ọ̀mù náà pẹ́ kó tó dọ́wọ́ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé tó bá jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí.
4. Rí i dájú pé o tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Èyí ló máa jẹ́ kí wọ́n lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti wá ilé tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn.
5. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé á jẹ́ kó o mọ ohun tó bá yẹ kó o mọ̀ nípa ilé náà kó tó di ọjọ́ àpéjọ, wọ́n sì lè ní kó o san owó tí wọ́n á fi bá ẹ gbà á sílẹ̀.
Jọ̀wọ́
◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ẹ́ sí tẹ́ ẹ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tó wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá ní kó o dé síbẹ̀. Iye ẹ̀yin tẹ́ ẹ máa wà nínú ilé náà ò gbọ́dọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí lọ.
◼ Má ṣe débi tí onílé ò bá fẹ́ kó o dé. Ibi tí onílé bá sì ti ní kó o dáná ni kó o ti dá a.
◼ Má ṣe torí àtirí ilé gbà, kó o wá lọ fún onílé ní owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ.
◼ Tó o bá fẹ́ ṣètò ilé tó o máa dé sí fúnra rẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà nìwọ náà tún fẹ́ gbà.