Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2009 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
1. (a) Àwọn ìbùkún wo la máa rí gbà tá a bá wà ní àpéjọ àgbègbè náà ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta? (b) Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo ló yẹ ká ṣe?
1 Gbogbo wa là ń fojú sọ́nà fún àpéjọ àgbègbè ọdún 2009, níbi tá a ti máa láǹfààní láti pé jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn tá a jọ ń yin Jèhófà, àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mát. 5:3) Pẹ̀lú bí ọjọ́ Jèhófà ti ń yára sún mọ́lé yìí, a rọ gbogbo wa láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, ká bàa lè gbádùn ìfararora pẹ̀lú àwọn ará wa, ká sì tún rí ìṣírí gbà nípa tẹ̀mí, èyí tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀. (Sef. 1:14) Ẹ jẹ́ káwọn olùkọ́ yín àtàwọn tó gbà yín síṣẹ́ mọ̀ pé ohun pàtàkì ni àpéjọ àgbègbè jẹ́ nínú ìjọsìn yín. Ó dájú pé ẹ óò rí ìtìlẹ́yìn Jèhófà tẹ́ ẹ bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀, tẹ́ ẹ sì bẹ̀bẹ̀ fún ìbùkún rẹ̀.—Aísá. 50:10.
2. Bí wọn ò tiẹ̀ yàn wá sí ọ̀kan lára àpéjọ àgbáyé, kí lohun tá à ń retí tó máa mú kí ọ̀pọ̀ àpéjọ àgbègbè dà bí àpéjọ àgbáyé?
2 Àpéjọ Àgbáyé: Níwọ̀n bo ti jẹ́ pé ìwọ̀nba orílẹ̀-èdè àti ìlú la ti máa ṣe àpéjọ àgbáyé, kìkì àwọn tá a bá yàn síbẹ̀ ló gbọ́dọ̀ lọ. Tá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò yìí, ìyẹn kò ní jẹ́ kérò pọ̀ jù níbẹ̀. (1 Kọ́r. 14:40; Héb. 13:17) Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn àpéjọ àgbègbè tá a máa ṣe ló máa dà bí àpéjọ àgbáyé, torí pé àwọn míṣọ́nnárì, àwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì tó ń sìn nílẹ̀ òkèèrè àtàwọn òṣìṣẹ́ káyé máa lọ ṣe àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè wọn.
3. Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sáwọn ará inú ìjọ?
3 Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Lọ: Ǹjẹ́ àwọn kan wà níjọ yín tó nílò ìrànwọ́ láti dé àpéjọ àgbègbè? Àwọn adití lè nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí àpéjọ àgbègbè tá a máa ṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà, ìyẹn Benin City 7, Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà nìkan la máa fi ṣe gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Tó o bá ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti lọ, a jẹ́ pé ńṣe lò ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò pé: “Kí ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.”—Fílí. 2:4.
4, 5. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè míì yàtọ̀ sí èyí tí wọ́n yan ìjọ yín sí?
4 Gbígba Ìsọfúnni: Kí iye àwọn tó ń tẹ ẹ̀ka ọ́fíìsì láago nípa ọjọ́ àpéjọ àgbègbè àti ibi tí wọ́n ti máa ṣe é lè dín kù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ kọ́kọ́ béèrè ohun tẹ́ ẹ bá fẹ́ wádìí lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ yín.
5 Tó o bá fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè tí kì í ṣe èyí tí wọ́n yan ìjọ yín sí, o lè béèrè fún Fọ́ọ̀mù Ilé Gbígbé. Fi fọ́ọ̀mù tó o ti kọ ọ̀rọ̀ kún ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì ibi tí àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ ti máa wáyé, àwọn àdírẹ́sì wọ̀nyẹn wà lẹ́yìn àwọn Fọ́ọ̀mù Ilé Gbígbé ti lọ́ọ́lọ́ọ́. A máa tó fi àwọn ẹ̀dà fọ́ọ̀mù yìí ránṣẹ́ sáwọn akọ̀wé ìjọ.
6. Kí làwọn ohun tó yẹ ní ṣíṣe tí akéde kan tó nílò àkànṣe àbójútó bá béèrè fún ilé gbígbé?
6 Àkànṣe Àbójútó: Bí akéde kan bá ń fẹ́ ilé tó máa dé sí, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ rẹ̀ pinnu bó bá yẹ lẹ́ni tó lè kọ̀rọ̀ sí apá tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, ìyẹn ibi tá a kọ Special Needs sí lórí fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé. Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́ni tó wà nínú fọ́ọ̀mù náà, kí akọ̀wé ìjọ tó fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọ àgbègbè náà.
7. (a) Báwo la ṣe lè béèrè fún ilé tá a máa dé sí? (b) Àwọn ìránnilétí wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní ba orúkọ rere tá a ní jẹ́ níbi tá a bá dé sí? (Wo àpótí náà “Ìtọ́ni Nípa Ilé Gbígbé.”)
7 Bíbéèrè fún Ilé Gbígbé: Tó o bá máa nílò Ilé Gbígbé ní ìlú tó o ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè, tó o sì máa nílò ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, àwọn ohun tó wà nísàlẹ̀ yìí ni kó o ṣe:
◼ Gba Fọ́ọ̀mù Ilé Gbígbé lọ́wọ́ akọ̀wé ìjọ rẹ.
◼ Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà lásìkò. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o kọ ìsọfúnni pípéye, nípa orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá o jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin àti bóyá o jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Kó o sì rí i pé o kọ àwọn ìsọfúnni náà lọ́nà tó ṣeé kà.
◼ Kí akọ̀wé ìjọ rí i pé àwọn tó nílò ilé gbígbé kọ ìsọfúnni tó wà nínú fọ́ọ̀mù náà lọ́nà tó yẹ, kó buwọ́ lù ú, kó sì fi ránṣẹ́ sí ibi tí àpéjọ àgbègbè ti máa wáyé, kó MÁ ṢE fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì o. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kí fọ́ọ̀mù náà pẹ́ kó tó dé ibi tí àpéjọ náà ti máa wáyé tó bá jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì lẹ kọ́kọ́ fi ránṣẹ́ sí.
◼ Rí i dájú pé o tètè fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ní àkókò tó pọ̀ tó láti wá ilé tó máa tẹ́ ẹ lọ́rùn.
8. Tá a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, báwo nìyẹn á ṣe jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí ilé tówó ẹ̀ ò ní pọ̀ jù?
8 A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè ló máa fẹ́ dé sí ilé tá a kọ́ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Àwọn kan máa fẹ́ dé sí hòtẹ́ẹ̀lì. Tó bá jẹ́ pé hòtẹ́ẹ̀lì la fẹ́ dé sí, a gbọ́dọ̀ béèrè bóyá Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ti ṣètò ibẹ̀ fún àwọn míì. Tírú ìṣètò bẹ́ẹ̀ bá ti wà nílẹ̀, a dáa ká fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀. Tá a ba fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò yìí, a ó lè jẹ́ kí gbogbo èèyàn rí ilé tówó ẹ̀ ò ní pọ̀ jù.—1 Kọ́r. 10:24.
9. Kí ló yẹ kó máa jẹ wá lọ́kàn bá a ti ń múra sílẹ̀ fún àpéjọ àgbègbè ọdún 2009?
9 Àwọn Iṣẹ́ Tó Ń Fògo fún Ọlọ́run: Tá a bá ń fi èso tẹ̀mí ṣèwà hù nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe, ní pàtàkì jù lọ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, nígbà tá a bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ hòtẹ́ẹ̀lì sọ̀rọ̀ níbi tá a ti lọ ṣe àpéjọ, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí orúkọ rere táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní túbọ̀ dára sí i, a sì tún ń tipa bẹ́ẹ̀ yàgò fún mímú àwọn ẹlòmíì kọsẹ̀. (1 Kọ́r. 10:31; 2 Kọ́r. 6:3, 4) Ǹjẹ́ kí wíwà tó o bá wà ní àpéjọ náà àti ìṣesí rẹ fi ògo fun Ọlọ́run ní àpéjọ àgbègbè ọdún 2009!—1 Pét. 2:12.
[Àpótí tó wà lójú ewé 4]
Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ:
Thursday (Àpéjọ Àgbáyé Nìkan)
1:20 ọ̀sán sí 4:55 ìrọ̀lẹ́
Friday àti Saturday
9:20 àárọ̀ sí 4:55 ìrọ̀lẹ́
Sunday
9:20 àárọ̀ sí 4:00 ìrọ̀lẹ́
[Àpótí tó wà lójú ewé 5]
Ìtọ́ni Nípa Ilé Gbígbé:
◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ẹ́ sí tẹ́ ẹ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tó wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá ní kó o dé síbẹ̀. Iye ẹ̀yin tẹ́ ẹ máa wà nínú ilé náà ò sì gbọ́dọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí lọ.
◼ Má ṣe débi tí onílé ò bá fẹ́ kó o dé. Ibi tí onílé bá sì ti ní kó o dáná ni kó o ti dá a.
◼ Má ṣe torí àtirí ilé gbà, kó o wá lọ fún onílé ní owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ.
◼ Tó o bá fẹ́ ṣètò ilé tó o máa dé sí fúnra ẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà nìwọ náà tún fẹ́ gbà.