ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/10 ojú ìwé 5-6
  • Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2010 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2010 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2009 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2001
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2008 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọdún 2000
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 4/10 ojú ìwé 5-6

Àpéjọ Àgbègbè Ọdún 2010 ti Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

1. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣètò láti wà ní àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2010 ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta?

1 À ń fojú sọ́nà fún àsè tẹ̀mí tá a máa gbádùn ní àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2010. A rọ gbogbo yín pé kẹ́ ẹ ṣètò láti wà níbẹ̀ ní ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Nígbà àpéjọ náà, a máa fún ara wa ní ìṣírí láti máa rìn nínú ìwà títọ́, bá a ti ń fi Jèhófà ṣe apata wa. (Sm. 26:1, 11; Òwe 2:7) Sọ fún àwọn olùkọ́ àti agbanisíṣẹ́ rẹ ṣáájú àkókò, pé àpéjọ náà jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ. Tó o bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ètò tó yẹ báyìí, tó o sì ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè múra sílẹ̀, ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ.—Sm. 37:5; Òwe 10:22.

2. Ibo la ti lè rí ìsọfúnni nípa àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ àgbègbè àti ìsọfúnni nípa ilé gbígbé?

2 Gbígba Ìsọfúnni: Ẹ máa rí gbogbo ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ lórí ìkànnì wa, ìyẹn www.jw.org. Tó bá pọn dandan fún ọ láti lọ sí àpéjọ míì yàtọ̀ sí èyí tá a yan ìjọ rẹ sí, o lè gba fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé, ìyẹn Room Request Form. Lẹ́yìn tó o bá ti kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù náà, kó o fi ránṣẹ́ sí àdírẹ́sì ibi tí àpéjọ àgbègbè tó o fẹ́ lọ ti máa wáyé, àwọn àdírẹ́sì yìí wà lẹ́yìn àwọn fọ́ọ̀mù tó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́. A máa tó fi àwọn ẹ̀dà fọ́ọ̀mù yìí ránṣẹ́ sí àwọn akọ̀wé ìjọ.

3. Báwo la ṣe lè ran àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó lọ́wọ́?

3 Àkànṣe Àbójútó: Ṣé o mọ ẹnì kan nínú ìjọ rẹ tó ṣeé ṣe kó nílò ìrànlọ́wọ́ láti lọ sí àpéjọ náà? O lè ṣètò láti ràn án lọ́wọ́. (Òwe 19:17) Bí akéde kan bá ń fẹ́ ilé tó máa dé sí, kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ rẹ̀ pinnu bó bá yẹ lẹ́ni tó lè kọ ọ̀rọ̀ sí apá tó wà fún àwọn tó nílò àkànṣe àbójútó, ìyẹn ibi tá a kọ Special Needs sí lórí fọ́ọ̀mù tá a fi ń béèrè fún ilé gbígbé. Kí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́ni tó wà nínú fọ́ọ̀mù náà, kí akọ̀wé ìjọ tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọ àgbègbè náà.

4. (a) Ètò wo la máa ṣe fún ilé gbígbé ní àpéjọ kọ̀ọ̀kan? (b) Àwọn ìránnilétí wo ni kò ní jẹ́ ká ba orúkọ rere tá a ní jẹ́ níbi tá a bá dé sí? (Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Ìtọ́ni Nípa Ilé Gbígbé,” lójú ìwé 6.)

4 Ilé Gbígbé: A máa ṣètò fún ilé gbígbé ní àwọn ibi tá a ti máa ṣe àpéjọ kọ̀ọ̀kan, kí nǹkan bàa lè rọ̀ yín lọ́rùn. Ilé gbígbé máa wà nínú àwọn gbọ̀ngàn àpéjọ kan, ó lè jẹ́ àwọn ilé kẹ́jẹ́bú tá a kọ́ fúngbà díẹ̀ tàbí àwọn ilé gbígbé tá a dìídì kọ́ sí gbọ̀ngàn àpéjọ. Ó ṣeé ṣe ká fi àwọn kan sínú ilé àdáni. A sì máa ṣèrànwọ́ tó bá yẹ fún àwọn tó bá fẹ́ dé sí òtẹ́ẹ̀lì. Ibi yòówù kẹ́ ẹ dé sí, a rọ̀ yín pé kẹ́ ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé.

5. Àwọn ìbùkún wo là ń fojú sọ́nà láti rí gbà ní àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2010?

5 Àpéjọ àgbègbè ti ọdún yìí máa jẹ́ ká ní àǹfààní ńláǹlà, a máa gba ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, a sì tún máa gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ alárinrin pẹ̀lú àwọn ara wa. (Diu. 16:15) Ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún ìsapá wa, bá a ti ń múra sílẹ̀ láti pésẹ̀ sí àpéjọ àgbègbè ti ọdún 2010!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ:

Ọjọ́ Friday àti Saturday

9:20 àárọ̀ sí 4:55 ìrọ̀lẹ́

Ọjọ́ Sunday

9:20 àárọ̀ sí 3:40 ìrọ̀lẹ́

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ìtọ́ni Nípa Ilé Gbígbé:

◼ Jẹ́ kí ilé tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fi ọ́ sí tẹ́ ọ lọ́rùn. Má ṣe dé sínú ilé tó wà nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá ní kó o dé síbẹ̀. Iye ẹ̀yin tẹ́ ẹ máa wà nínú ilé náà ò sì gbọ́dọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé bá fọwọ́ sí lọ.

◼ Má ṣe dé ibi tí onílé kò bá fẹ́ kó o dé. Ibi tí onílé bá sì ti ní kó o dáná ni kó o ti dá a.

◼ Má ṣe torí àtirí ilé gbà, kó o wá lọ fún onílé ní owó tó pọ̀ ju iye tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé san lọ.

◼ Tó o bá fẹ́ ṣètò ilé tó o máa dé sí fúnra rẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ wádìí lọ́dọ̀ Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé, kó má lọ jẹ́ pé ilé tí wọ́n ti gbà nìwọ náà tún fẹ́ gbà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́