Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1996
1 A gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìmọrírì tí ó ti ọkàn wá láti ẹnu púpọ̀ lára 462,540 ènìyàn tí ó pésẹ̀ síbi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995 ní Nàìjíríà fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń sọ agbára dọ̀tun nípa tẹ̀mí. Ọkàn wa kún fún ayọ̀ ní rírí 7,603 olùyin Jehofa tí wọ́n fi ìyàsímímọ́ wọn hàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Inú wa dùn láti gba ìtẹ̀jáde tuntun méjì náà, Jehovah’s Witnesses and Education àti Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. Níwọ̀n bí a ti gbádùn irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ń runi sókè bẹ́ẹ̀ ní èṣín, tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, ó yẹ kí ó sún wa ní tòótọ́ láti ṣe gbogbo ìsapá láti pésẹ̀ síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a ṣètò fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọrun” ti 1996. Dájúdájú, ó yẹ kí gbogbo wa ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli wa, kí a sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. Àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí yóò já sí orísun ìṣírí àti okun gidi bí a ti ń bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ sin Jehofa tìdùnnútìdùnnú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.
2 Rí i dájú pé o fara balẹ̀ ṣe àwọn ètò dáradára fún àpéjọpọ̀ rẹ ṣáájú àkókò, kí o baà lè wà níbẹ̀ láti gbádùn gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí tí ń gbádùn mọ́ni náà, láti orí orin ìbẹ̀rẹ̀ títí dé àdúrà ìparí. Nítorí iyé owó ọkọ̀ wíwọ̀ tí ń lọ sókè sí i, ìsinsìnyí ni ó yẹ kí o bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó pa mọ́ kí ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ baà lè lọ. Fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àwọn wọnnì tí wọ́n lè nílò ìtìlẹ́yìn, ní pàtàkì àwọn olùfìfẹ́hàn, kún àwọn ìwéwèé rẹ, kí àwọn pẹ̀lú baà lè wà níbẹ̀ fún gbogbo àkókò ìjókòó. Yóò ṣèrànwọ́ gidigidi láti ṣàgbéyẹ̀wò ìsọfúnni inú àkìbọnú yìí pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli èyíkéyìí tí ó bá ń wéwèé láti lọ. (Gal. 6:6, 10) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ohùn orin ní agogo 9:20 òwúrọ̀ ní ọjọ́ Friday tí yóò sì parí ní nǹkan bí agogo 4:30 ìrọ̀lẹ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Saturday yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo 9:00 òwúrọ̀ yóò sì parí pẹ̀lú orin àti àdúrà ní nǹkan bí agogo 4:00 ìrọ̀lẹ́. Àkókò ìjókòó ti ọjọ́ Sunday yóò bẹ̀rẹ̀ ní agogo 9:00 òwúrọ̀, ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà yóò sì parí ní nǹkan bí agogo 3:30 ìrọ̀lẹ́. Ìsọfúnni tí ó tẹ̀ lé e yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìmúrasílẹ̀ tí o bá fẹ́ ṣe.
3 Àwọn Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Gbígbé: Àwa yóò sakun láti pèsè iye àwọn fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé tí ó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé kọ̀ọ̀kan tí a fi sílẹ̀ ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà tí ó yẹ. MÁ ṢE wulẹ̀ kọ iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé gbígbé, irú bí “50 akéde,” sínú àwọn àlàfo tí a ní láti kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. A gbọ́dọ̀ kọ gbogbo ìsọfúnni nigín-nigín kí ó sì ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni náà tí ń béèrè fún ilé gbígbé jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Fi àwọn ọmọ kún àkọsílẹ̀ náà. Ní ìgbà kan, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà ni àwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kí àwọn ìṣètò fún ilé gbígbé ṣòro gan-an. Bí o bá nílò àyè sí i ju èyí tí a pèsè lórí fọ́ọ̀mù náà, lo àfikún abala ìwé. Bí orúkọ tí ó ju ti ẹnì kan lọ bá wà lórí fọ́ọ̀mù náà, jọ̀wọ́ fi ipò ìbátan tí ó wà láàárín àwọn wọnnì tí ń béèrè fún ilé gbígbé hàn ní àlàfo ìlà tí ó bá yẹ. Akọ̀wé ìjọ ní láti rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé náà ni a kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà pípéye ṣáájú kí ó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé àpéjọpọ̀ náà.
4 Àwọn Àkànṣe Àìní: Ìpèsè yìí wà fún kìkì àwọn akéde àwòfiṣàpẹẹrẹ, títí kan àwọn ọmọ wọn tí wọ́n mọ̀wàáhù, tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ fọwọ́ sí. Ìjọ tí àwọn tí ó ní àkànṣe àìní ti ń lọ sí ìpàdé ni ó yẹ kí ó ṣètò láti bojú tó wọn, dípò gbígbé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe yìí karí àjọ tí ń ṣàbójútó àpéjọpọ̀. Àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa àyíká ipò ẹnì kọ̀ọ̀kan lè fi tìfẹ́tìfẹ́ nawọ́ ìrànlọ́wọ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde gbé àìní àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti bóyá àwọn mìíràn yẹ̀ wò. Àwọn akéde lè nawọ́ ìrànlọ́wọ́ nípa gbígbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójú tó àìní wọn ní àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Jak. 2:15-17; 1 Joh. 3:17, 18.
5 Àmọ́ ṣáá o, Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yóò sakun láti pèsè àwọn yàrá ilé gbígbé tí ó bójú mu fún àwọn akéde tí wọ́n ní àkànṣe àìní bí àwọn tí ó wà nínú ìjọ kò bá lé ṣètìlẹyìn fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè jíròrò ipò wọn pẹ̀lú akọ̀wé ìjọ. Akọ̀wé ní láti bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti rí i bí ó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣètìlẹyìn fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó yàrá ilé gbígbé tiwọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹyìn tí a nílò, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé, lórí èyí tí ó kọ “AKÀNṢE ÀÌNÍ” sí lókè gàdàgbà gàdàgbà. Kìkì àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní ni wọ́n ní láti kọ ọ̀rọ̀ kún inú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí. Ẹni tí ń ṣèbéèrè náà ni kí ó kọ ọ̀rọ̀ kún un. O ní láti dá a padà fún akọ̀wé, tí yóò rí sí i pé a kọ ọ̀rọ̀ kún un, ó péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú àwọn ipò àyíká tí ó mú ẹni náà tóótun fún irú ìgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢÀLÀYÉ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ nípa àwọn ipò àyíká náà sínú àlàfo tí ó wà ní òdì kejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí ni a ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àkókò àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé. Ẹni náà tí ń ṣèbéèrè yìí ni a óò sọ fún ní tààràtà nípa ilé gbígbé náà.
6 Àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní KÒ gbọdọ̀ lọ sí àpéjọpọ̀ kí wọ́n sì béèrè fún yàrá nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, nítorí pé Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
7 Gbígbé Inú Ilé Àdáni: Bí a bá fi ọ́ wọ̀ sínú ilé àdáni arákùnrin kan tàbí ti ará ìta kan, jọ̀wọ́ fi í sọ́kàn pé kò tọ̀nà láti ṣi ẹ̀mí ìgbanilálejò rẹ̀ lò kí o sì retí pé kí ó gbà ọ́ sílé fún ọjọ́ díẹ̀ sí i ṣáájú tàbí lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà. Àwọn ilé gbígbé wọ̀nyí ni a pèsè fún sáà àkókò àpéjọpọ̀ NÌKAN. Àwọn wọnnì tí wọ́n ń gba irú ilé gbígbé bẹ́ẹ̀ ní láti rí i dájú pé àwọn àti àwọn ọmọ wọn hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ní ilé ẹni náà tí ó gbà wọ́n lálejò, kí wọ́n má sì ṣe máa tú ilé kiri tàbí ba àwọn ohun-ìní olùgbanilálejò náà jẹ́ tàbí wọnú àwọn agbègbè àdáni inú ilé náà. Bí onílé bá ní ìṣòro èyíkéyìí lórí ohun tí ó jẹ mọ́ èyí, a ní láti mú un wá sí àfiyèsí alábòójútó ilé gbígbé ní àpéjọpọ̀ ní kíá, òun yóò sì láyọ̀ láti ṣèrànwọ́.
8 Yíyan Àpéjọpọ̀ Rẹ: A to ìlú àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan àti àwọn àyíká (tàbí apákan lára wọn) tí a yàn láti lọ sí àpéjọpọ̀ náà lẹ́sẹẹsẹ sísàlẹ̀, bí déètì wọn ti tẹ̀ léra. Àyàfi bí àwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ bá wà, àpéjọpọ̀ tí a pín àyíká tàbí ìjọ rẹ sí ni ó yẹ kí o lọ. Níbi tí a bá ti ń ṣe àpéjọpọ̀ méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ibì kan náà, o ní láti lọ ní déètì tí a fi hàn fún àyíká rẹ tàbí apá kan lára rẹ̀. Bí o ti ń ṣe àwọn ìwéwèé rẹ láti wà níbẹ̀, fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ kún un, pàápàá jù lọ àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun, kí àwọn pẹ̀lú baà lè wà níbẹ̀ fún gbogbo àkókò ìjókòó.—Gal. 6:10.
9 Èdè Àwọn Adití: Ní àpéjọpọ̀ ỌTA 7, tí a óò ṣe ní December 13 sí 15, 1996, àti ní àpéjọpọ̀ ULI 7, tí a óò ṣe ní January 10 sí 12, 1997, a óò ṣe ìpèsè fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí wọ́n tóótun láti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití. A fún gbogbo àwọn adití ní gbogbo ìjọ tí ó wà ní Nàìjíríà ní ìṣírí láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò láti lọ sí ọ̀kan lára àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, ó kéré tán. Àwọn alàgbà ní láti wádìí dáradára lọ́wọ́ adití kọ̀ọ̀kan tí ó bá wà nínú ìjọ wọn, tí ó lóye Èdè Àwọn Adití, láti rí i dájú pé àwọn wọ̀nyí mọ̀ nípa ìṣètò yìí kí wọ́n sì pinnu bóyá wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí kí wọ́n baà lè lọ.
10 Àwọn Àyànṣaṣojú Tí Ń Lọ sí Àgbègbè Tí Kì í Ṣe Tiwọn: Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ọ̀ràn, ibi tí a yàn fún ọ láti lọ ni èyí tí ó sún mọ́ ìjọ rẹ jù lọ. Níní àyè ìjókòó, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, oúnjẹ, yàrá ilé gbígbé, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó pọ̀ tó, ni a gbé karí èrò náà pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn akéde yóò lọ sí àpéjọpọ̀ tí a pín ìjọ wọn sí. Bí ó ti wù kí ó rí, fún ìdí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ kan, bí ìwọ yóò bá lọ sí àpéjọpọ̀ kan tí ó yàtọ̀ sí tìrẹ, tí o sì nílò ilé gbígbé, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Gbígbé. Ìwọ lè kọ ọ̀rọ̀ kún un kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i ṣáájú kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọpọ̀ tí o fẹ́ láti lọ.
11 A Nílò Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Rẹ: Ìkẹ́sẹjárí ìṣètò ilé gbígbé yìí sinmi lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo àwọn wọnnì tí ọ̀ràn kan. (Heb. 13:17) Nípa báyìí, a ń béèrè lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìṣètò ilé gbígbé tí Society ṣe. Jọ̀wọ́ fi tayọ̀tayọ̀ tẹ́wọ́ gba ilé gbígbé tí a bá yàn fún ọ tàbí fún àwùjọ tàbí fún ìjọ rẹ. Bí ìwọ bá ní láti ṣètò àdáṣe tìrẹ, bóyá nítorí pé ìwọ kò fẹ́ ilé gbígbé tí a yàn fún ọ, o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n má ṣe gbìyànjú láti gba ilé gbígbé kan tí Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà ti gbà tẹ́lẹ̀ nípa gbígbà láti san iye owó tí ó pọ̀ ju èyí tí a ti fohùn ṣọ̀kan lé lórí ṣáájú. Èyí kì yóò fi inú rere àti ìfẹ́ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ, ó sì jẹ́ ìwà àìṣòótọ́ sí ètò àjọ Jehofa. A mọ̀ pé gbogbo àwọn ará ló ń fẹ́ láti rí ilé gbígbé sí ìtòsí ilẹ̀ àpéjọpọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni a lè rí ilé gbígbé fún lọ́nà yìí. Àwọn díẹ̀ ní láti wà ní ibì kan tí ó jìn díẹ̀ sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó yí kàn ọ́ láti wà ní ilé gbígbé kan tí ó jìn sí ilẹ̀ àpéjọpọ̀, ka èyí sí ìrúbọ tí o ní láti ṣe kí o sì fi ìmọrírì hàn fun iṣẹ́ àṣekára tí Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà ti ṣe ní ṣíṣètò ilé gbígbé kan fún ọ. Fún kìkì ọjọ́ díẹ̀ ni, ìwọ yóò sì padà sí ìjọ àdúgbò rẹ lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n bí o bá fẹ́ láti ṣe àwọn ètò tìrẹ, jọ̀wọ́ kọ́kọ́ ṣèwádìí lọ́wọ́ Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé yálà wọ́n ti gba ilé náà tí ìwọ ń ṣètò láti gbà tàbí wọn kò tí ì ṣe bẹ́ẹ̀. Yóò jẹ́ ìfojúsùn Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ní àpéjọpọ̀ náà láti rí sí i pé àwọn ará wa àti àwọn àyànṣaṣojú mìíràn ni a rí ilé gbígbé tí ó tura tí kò sì gbówó lórí fún, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àyíká ipò wọn, kí ara baà lè tù wọ́n kí ó sì lè ṣeé ṣe fún wọn láti gbádùn àwọn àǹfààní rere tẹ̀mí ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní kíkún.
12 Ìrélànàkọjá èyíkéyìí nínú gbogbo àwọn agbègbè tí a mẹ́nu kàn lókè yìí máa ń mú kí ó ṣòro láti ṣe ìdúnàádúrà fún àwọn ilé gbígbé, wọ́n sì ń mú ẹ̀gàn wá sórí orúkọ Jehofa àti ètò àjọ rẹ̀. (Orin Da. 119:168) Nítorí náà, Society yóò sọ fún Ẹ̀ka tí Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé láti wádìí lọ́dọ̀ àwọn onílé láti mọ̀ bí èyíkéyìí nínú wọn bá ń ní àwọn ìṣòro àti ẹni tí ń fa ìṣòro náà. Àwọn olùṣàbójútó àpéjọpọ̀ ń ṣiṣẹ́ kára láti gba àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ ìnáwó púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Nítorí náà, ó jẹ́ fún ire gbogbo wa jù lọ láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú ìṣètò Society fún ilé gbígbé kí ìpèsè yìí baà lè máa bá a lọ. A mọrírì ìtìlẹyìn onídùúróṣinṣin rẹ fún ìpèsè tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Jehofa nípasẹ̀ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú náà yìí lọ́pọ̀lọpọ̀.
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Bí ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe ìfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tí ó tẹ̀ lé e nípa ibi àpéjọpọ̀ àti déètì tí Society yàn fún ìjọ yín. Yóò dára láti fàlà sábẹ́ ìlú àpéjọpọ̀ àti déètì tí a yàn fún ìjọ yín, kí ẹ sì lẹ apá kan àkìbọnú yẹn mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kí ó bójú tó àwọn àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá tan mọ́ àpéjọpọ̀ àti àwọn ìfilọ̀ ní àwọn ìpàdé ọjọ́ iwájú. Ó yẹ kí gbogbo alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i dájú pé àwọn ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ náà ni a bójú tó ní kánmọ́kánmọ́, pẹ̀lú ìtara ọkàn, àti lọ́nà tí ó gbéṣẹ́.]