Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Iwa Ti O Ṣe Iṣẹ-ojiṣẹ Kristian Wa Lọ́ṣọ̀ọ́
APỌSTELI Peteru ṣí awọn Kristian leti pe: “Ki iwa yin laaarin awọn Keferi ki o dara.” (1 Peteru 2:12) Apọsteli Pọọlu fihan pe nipa iwa rere wa, awa “nṣe ẹkọ Ọlọrun Olugbala wa ni ọsọ ninu ohun gbogbo.” (Titu 2:10) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yika gbogbo aye ni orukọ rere fun hihuwa daradara. Ṣakiyesi awọn apẹẹrẹ diẹ.
Èró Atẹ̀mọ́nilọ́kaǹ Ti Olukọ Nipa Iwa Rere
◻ Ọ́fíìsì ẹka Watch Tower Society ni Costa Rica rohin pe iye awọn ọdọ pupọ rẹpẹtẹ ni orilẹ-ede yẹn nfi apẹẹrẹ rere lelẹ. Arakunrin kan sọ ohun ti o fa oun sinu otitọ. O rohin pe: “Ohun ti o fà mi mọra julọ ni iwa rere awọn ewe ati awọn agbalagba ṣugbọn ni pataki julọ awọn ọdọ. Nigba ti mo nṣiṣẹ gẹgẹ bi olukọ, mo ni anfaani lati fiṣọra ṣakiyesi awọn Ẹlẹrii ni ile-ẹkọ mi. Niwọn bi mo si ti ngbe papọ pẹlu idile awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, mo ṣakiyesi iwa awọn ọmọ wọn pẹlu.
“Emi ko lè ṣalai ṣakiyesi iyatọ naa ti o wà laaarin awọn akẹkọọ ti wọn jẹ Ẹlẹrii ati awọn ọmọ ile-ẹkọ miiran ni ile-ẹkọ mi. Awọn Ẹlẹrii maa nde lakooko nigba gbogbo ti wọn si maa nhuwa daradara, wọn kii purọ, wọn a maa ṣe iṣẹ aṣetilewa wọn nigba gbogbo. Mo ṣakiyesi pẹlu pe wọn jẹ alailabosi nigba ti wọn ba nṣe idanwo, bi o ti lẹ jẹ pe awọn ọmọ ile-ẹkọ yooku nigbogbogboo maa nṣe ìrẹ́jẹ. Siwaju sii, wọn jẹ ọmọluwabi gan-an ti wọn si nbọwọ fun mi gẹgẹ bi olukọ wọn. Bi a ti wú mi lori nipasẹ awọn ọdọ Ẹlẹrii ni ile-ekọ ati ni ile nibi ti mo ngbe, mo bẹrẹ si ṣayẹwo isin yii ti mo si tẹwọ gba otitọ nígbẹ̀hìn gbẹ́hín.”
Iwa Kristian ni Apejọpọ kan Yọrisi Rere
◻ Ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ijọ kan ti o wa ni apa iwọ oorun El Salvador fẹ lati ṣalabaapin ihinrere Ijọba naa pẹlu awọn arakunrin rẹ nipa ti ara meji. Ọkan fetisilẹ o si bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Arakunrin keji jẹ ara Ṣọọṣi Ajinhinrere ti a npe ni Ọmọ Alade Alaafia, ti o si sọ fun arakunrin rẹ pe: “Maṣe sọrọ si mi; iwọ nṣiṣẹ fun ifẹ ọkan Eṣu.”
Nigba ti akoko naa tó fun apejọpọ agbegbe, eyi ti o ti nkẹkọọ ké si arakunrin rẹ pe ki o ba oun lọ si apejọpọ naa. Arakunrin naa sọ pe: “O dara, emi yoo ba ọ lọ; emi wulẹ nlọ lati le ri ibi ti mo ti le gbá awọn Ẹlẹrii mú.” Awọn arakunrin mejeeji lọ si apejọpọ naa papọ. Iye awọn eniyan pupọ jaburata ti wọn wa ati iṣeto rere ni apejọpọ naa wu ọmọ ijọ Ajihinrere naa lori, ẹni ti o wi pe oun ko tii ri ohun kan ti o dabi rẹ ri. Nigba ti o pada de ile, o sọ fun arakunrin rẹ pe: “Fun mi ni ọwọ rẹ.” Arakunrin rẹ beere pe, “Ki ni gbogbo eyi tumọ si?” “Ṣáà fun mi ni ọwọ rẹ,” ni ifesi pada naa. Wọn bọ ara wọn lọwọ, arakunrin naa ti o ti jẹ ara Ṣọọṣi Ajihinrere sọ pe: “Lati isinsinyi lọ emi yoo kẹkọọ pẹlu awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Niti tootọ, emi ko mọ ohun ti emi npadanu.” Bayii oun pẹlu jẹ oluṣedeede ati onitara olupolongo ihinrere Ijọba Ọlọrun.