Fífi Ìwà Rere Jẹ́rìí
1 Nínú àwùjọ òde òní tí ó gbọ̀jẹ̀gẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ̀ ń fi oògùn líle, ìṣekúṣe, ọ̀tẹ̀, àti ìwà ipá ṣe ìgbésí ayé ara wọn báṣubàṣu láìbìkítà. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ìwà àwòfiṣàpẹẹrẹ àwọn ọ̀dọ́ oníwàrere nínú ìjọ Kristẹni ń tuni lára láti kíyè sí, ó sì dájú pé nǹkan ẹwà ni lójú Jèhófà. Ó jẹ́ ẹ̀rí lílágbára tí ó lè fa àwọn ẹlòmíràn wá sínú òtítọ́.—1 Pét. 2:12.
2 Ọ̀pọ̀ ìrírí fi hàn pé ìwà rere àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni tí ní ipa tí ó dára lórí àwọn tí ń kíyè sí wọn. Nígbà tí olùkọ́ kan ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí ó jẹ́ àkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó sọ fún gbogbo kíláàsì náà pé Ọlọ́run ọmọdébìnrin náà, Jèhófà, ni Ọlọ́run tòótọ́. Ó sọ bẹ́ẹ̀ nítorí pé ọmọdébìnrin náà máa ń hùwà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ nígbà gbogbo. Olùkọ́ mìíràn kọ̀wé sí Society, ó sọ pé: “Mo fẹ́ gbóríyìn fún yín nítorí àwọn ọ̀dọ́ rere tí ó wà nínú ẹ̀sìn yín. . . . Àwòfiṣàpẹẹrẹ ni àwọn ọ̀dọ́ yín jẹ́ ní tòótọ́. Wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fún àgbàlagbà, ọmọlúàbí ni wọ́n, wọ́n sì máa ń wọṣọ lọ́nà tí ó bójú mu. Wọ́n mọ Bíbélì gan-an! Ẹ̀sìn gidi nìyẹn!”
3 Olùkọ́ mìíràn ni ìwà rere Ẹlẹ́rìí ọmọ ọdún méje kan tí ó wà ní kíláàsì rẹ̀ wú lórí. Ìwà tútù àti ànímọ́ fífanimọ́ra ọmọdékùnrin yìí, tí ó mú kí ó yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọmọdékùnrin yòókù, fa olùkọ́ náà mọ́ra. Ṣíṣàìkì í fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tí ẹ̀sìn rẹ̀ gbà gbọ́—kì í tijú láti jẹ́ ẹni tí ó yàtọ̀ nítorí ohun tí ó gbà gbọ́, ya olùkọ́ náà lẹ́nu. Ó lè rí i pé a ti dá ẹ̀rí-ọkàn ọmọdékùnrin náà lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣeé ṣe fún un láti “fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́.” (Héb. 5:14) Níkẹyìn, ìyá ọmọdékùnrin yìí bẹ olùkọ́ náà wò, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ó yá, olùkọ́ náà ṣe batisí, ó sì di aṣáájú ọ̀nà déédéé lẹ́yìn náà!
4 Ọ̀dọ́kùnrin kan ni ìwà rere Ẹlẹ́rìí kan tí ó wà ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa lé lórí. Ẹlẹ́rìí náà yàtọ̀ ní tòótọ́—ó ṣọmọlúàbí gan-an, ó ń gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì máa ń wọṣọ lọ́nà tí ó bójú mu nígbà gbogbo; àti pé kì í bá àwọn ọmọdékùnrin dọ́wẹ̀ẹ́kẹ̀ bí ti àwọn ọmọdébìnrin yòókù. Ó rí i pé ọmọdébìnrin yìí ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ọ̀dọ́kùnrin náà béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìsìn rẹ̀, ohun tí ó sì kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kan gidigidi. Ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, láìpẹ́ ó ṣe batisí, ó sì nípìn-ín nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àti nínú iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì níkẹyìn.
5 Bí o bá jẹ́ ọ̀dọ́ Kristẹni kan tí ó fẹ́ jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn lọ́nà tí ó dára, kíyè sí ìwà rẹ ní gbogbo ọ̀nà. Má ṣe jọ̀gọ nù nípa títẹ́wọ́gba ìṣarasíhùwà gbígbọ̀jẹ̀gẹ́, ojú ìwòye, tàbí ọ̀nà ìhùwà ayé. Fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ìwọṣọ, àti ìmúra rẹ, kì í ṣe nígbà tí o bá ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá àti ní àwọn ìpàdé ìjọ nìkan, ṣùgbọ́n nígbà tí o bá wà ní ilé ẹ̀kọ́, àti nígbà tí o bá ń kópa nínú eré ìtura pẹ̀lú. (1 Tím. 4:12) Ojúlówó ìdùnnú yóò jẹ́ tìrẹ nígbà tí ẹnì kan bá fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́ nítorí pé o ‘ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ tàn’ nípa ìwà rere rẹ.—Mát. 5:16.