Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Ń Tàn bí Ìmọ́lẹ̀
1. Báwo ni Bíbélì ṣe sọ pé àwọn Kristẹni máa rí, báwo lèyí sì ṣe kan àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ lónìí?
1 Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Mát. 5:14, 16) Bí ìlú tó wà lórí òkè téńté ṣe máa ń tàn yòò nínú oòrùn làwọn náà ṣe dá yàtọ̀. Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ni wọ́n “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé” nípa ìwà ìdúróṣinṣin tí wọ́n ń hù àti bí wọ́n ṣe ń fi ìtara wàásù.—Flp. 2:15; Mál. 3:18.
2. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà jẹ́rìí fáwọn olùkọ́ àtàwọn tẹ́ ẹ jọ wà ní kíláàsì?
2 Nílé Ẹ̀kọ́: Báwo lo ṣe lè wàásù nílé ẹ̀kọ́? Àwọn ọ̀dọ́ kan ti lo àǹfààní ìjíròrò tí wọ́n máa ń ṣe ní kíláàsì, èyí tó máa ń dá lórí onírúurú kókó ọ̀rọ̀, bí oògùn olóró, ẹfolúṣọ̀n, ìpakúpa àtàwọn kókó míì, láti wàásù. Arábìnrin kan tí wọ́n ní kó kọ àròkọ lórí ìpániláyà lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí pé Ìjọba Ọlọ́run ni ìrètí kan ṣoṣo tí ẹ̀dá ní. Inú olùkọ́ rẹ̀ dùn gan-an sí àròkọ tó fọgbọ́n yọ yẹn èyí sì mú kó láǹfààní láti jẹ́rìí síwájú sí i.
3. Báwo lo ṣe lè máa tipasẹ̀ ìwà rẹ tàn bí ìmọ́lẹ̀ nílé ẹ̀kọ́?
3 O tún lè tàn bí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìwà tó ò ń hù, aṣọ tó bojú mu tó ò ń wọ̀ àti ọ̀nà tó o gbà ń múra. (1 Kọ́r. 4:9; 1 Tím. 2:9) Báwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù àtàwọn olùkọ́ bá rí i pé ìwà rere tó ò ń hù yàtọ̀ sí tàwọn, ó lè sún àwọn kan lára wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí ìyẹn sì fún ọ láǹfààní láti gbin òtítọ́ Bíbélì sí wọn lọ́kàn. (1 Pét. 2:12; 3:1, 2) Ó lè má rọrùn láti máa fi ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ ṣèwà hù ṣùgbọ́n Jèhófà á fi ìbùkún sí i fún ọ. (1 Pét. 3:16, 17; 4:14) Bó o bá fẹ́ kí ọkàn àwọn tó wà nítòsí rẹ fà sí ìhìn rere, o lè máa ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lákòókò ìsinmi ọ̀sán tàbí kó o fi síbi tẹ́ni tó ń kọjá ti lè rí i.
4. Kí làwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa wàásù nílé ẹ̀kọ́?
4 Bó o bá ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nílé ẹ̀kọ́, á fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun á sì jẹ́ kó o mọ̀ pé kò sí ohun iyì tó tó kéèyàn máa sin Jèhófà. (Jer. 9:24) Bákan náà ló tún jẹ́ ààbò fún ọ. Arábìnrin kan sọ pé: “Àǹfààní kan tí mo rí nínú sísọ ohun tí mo gbà gbọ́ ni pé kì í jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù máa fi ohun tí kò bá Bíbélì mu lọ̀ mí.”
5. (a) Báwo làwọn ọ̀dọ́ kan ṣe mú iṣẹ́ ìsìn wọn gbòòrò sí i? (b) Kí làwọn ohun tẹ̀mí tó o fi ṣe àfojúsùn rẹ?
5 Ṣíṣe Púpọ̀ Sí I Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Ọ̀nà mìíràn táwọn ọ̀dọ́ tún máa ń gbà tàn bí ìmọ́lẹ̀ ni nípa ṣíṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn tí arákùnrin kan jáde nílé ẹ̀kọ́ girama, ó lọ síbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù tó pọ̀ sí i. Ìjọ tó ní alàgbà kan ṣoṣo ló ti lọ sìn. Lẹ́tà tó kọ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan kà pé: “Mò ń gbádùn ara mi níbi tí mo wà yìí o. Bíi ká má padà sílé mọ́ ni tá a bá lọ sóde ẹ̀rí! A máa ń lò tó ogún ìṣẹ́jú nílé tá a bá ti wàásù nítorí pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ gbọ́ gbogbo ohun tá a bá ní í sọ.” Ó wá fi kún un pé: “Ì bá wù mí ká ní gbogbo ọ̀dọ́ ló lè lọ síbi tí wọ́n ti ń fẹ́ oníwàásù púpọ̀ sí i, káwọn náà sì rí bí iṣẹ́ náà ṣe lárinrin tó. Kò sí ohun tó dà bíi kéèyàn sin Jehófà tọkàntara.”
6. Kí ló ń mú orí rẹ wú lára àwọn ọ̀dọ́ ìjọ yín?
6 Ẹ̀yin ọ̀dọ́ tẹ́ ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ nínú ayé yìí mà ṣeé mú yangàn o! (1 Tẹs. 2:20) Bẹ́ ẹ ṣe ń bá a lọ láti máa sin Jèhófà pẹ̀lú gbogbo ọkàn, gbogbo èrò inú àti gbogbo okùn yín, ẹ ó “gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí . . . àti nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀, ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30; 12:30.